July 4-10
2 SÁMÚẸ́LÌ 18-19
- Orin 138 àti Àdúrà 
- Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.) 
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
- “Mọ̀wọ̀n Ara Ẹ Bíi Ti Básíláì”: (10 min.) 
- Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì: (10 min.) - 2Sa 19:24-30—Kí la rí kọ́ lára Méfíbóṣétì tó lè fún ìgbàgbọ́ wa lókun? (w20.04 30 ¶19) 
- Àwọn ìṣúra wo lo tún rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí nípa Jèhófà, iṣẹ́ ìwàásù tàbí àwọn nǹkan míì? 
 
- Bíbélì Kíkà: (4 min.) 2Sa 19:31-43 (th ẹ̀kọ́ 2) 
TẸRA MỌ́ IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
- Fídíò Nígbà Àkọ́kọ́: (5 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò Ohun Tí Ọlọ́run Fẹ́ fún Wa—Jẹ 1:28. Ẹ dá fídíò náà dúró láwọn ibi tẹ́ ẹ bá ti rí ìbéèrè, kẹ́ ẹ sì dáhùn ìbéèrè náà kẹ́ ẹ tó máa wò ó lọ. 
- Nígbà Àkọ́kọ́: (3 min.) Àkòrí ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ ni kó o fi bẹ̀rẹ̀.a Ẹni náà sọ ohun táwọn èèyàn sábà máa ń sọ ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín tí wọn kò bá fẹ́ gbọ́ ìwàásù. Fèsì ní ṣókí, kó o sì máa bá ọ̀rọ̀ rẹ lọ. (th ẹ̀kọ́ 1) 
- Àsọyé: (5 min.) w21.08 23-25 ¶15-19—Àkòrí: Àwọn Nǹkan Wo Lo Lè Fi Ṣe Àfojúsùn Tí Ipò Rẹ Ò Bá Jẹ́ Kó O Lè Ṣe Tó Bó O Ṣe Fẹ́? (th ẹ̀kọ́ 20) 
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
- “Ohun Tó O Lè Fi Ṣe Àfojúsùn ní Ọdún Iṣẹ́ Ìsìn Tó Ń Bọ̀—Iṣẹ́ Aṣáájú-Ọ̀nà”: (15 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò Ẹ Jẹ́ Onígboyà . . . Ẹ̀yin Aṣáájú-Ọ̀nà. 
- Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) lff ẹ̀kọ́ 11 
- Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min.) 
- Orin 97 àti Àdúrà 
a Wo àpilẹ̀kọ tó wà ní ojú ìwé 16.