May 22-28
2 KÍRÓNÍKÀ 25-27
- Orin 80 àti Àdúrà 
- Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.) 
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
- “Jèhófà Mọ Bó Ṣe Máa Fi Èyí Tó Pọ̀ Ju Bẹ́ẹ̀ San Án Fún Ọ”: (10 min.) 
- Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì: (10 min.) - 2Kr 26:4, 5—Kí la lè rí kọ́ lára Ùsáyà tó bá di pé ká ní ọ̀rẹ́ tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀? (w07 12/15 10 ¶1-2) 
- Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo tún rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí nípa Jèhófà, iṣẹ́ ìwàásù tàbí àwọn nǹkan míì? 
 
- Bíbélì Kíkà: (4 min.) 2Kr 25:1-13 (th ẹ̀kọ́ 12) 
TẸRA MỌ́ IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
- Nígbà Àkọ́kọ́: (3 min.) Àkòrí ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ ni kó o fi bẹ̀rẹ̀. Ṣàlàyé bá a ṣe máa ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kó o sì fún un ní káàdì ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. (th ẹ̀kọ́ 2) 
- Ìpadàbẹ̀wò: (4 min.) Àkòrí ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ ni kó o fi bẹ̀rẹ̀. Sọ fún ẹni náà nípa ìkànnì wa, kó o sì fún un ní káàdì ìkànnì jw.org. (th ẹ̀kọ́ 15) 
- Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì: (5 min.) lff ẹ̀kọ́ 10 ọ̀rọ̀ ìbẹ̀rẹ̀ àti kókó 1-3 (th ẹ̀kọ́ 3) 
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
- Ohun Tá A Bá Yááfì Nítorí Ìyè Àìnípẹ̀kun Tó Bẹ́ẹ̀, Ó Jù Bẹ́ẹ̀ Lọ (Mk 10:29, 30): (15 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò náà. Lẹ́yìn náà, bi wọ́n pé: Tá a bá fi ohun tí Jésù sọ nínú Máàkù 10:29, 30 sọ́kàn, kí nìyẹn máa mú ká ṣe? Kí ni Jésù ṣe nígbà táwọn àbúrò ẹ̀ ò kọ́kọ́ nígbàgbọ́ nínú ẹ̀? Irú ojú wo ló yẹ ká fi máa wo àwọn mọ̀lẹ́bí wa tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà? 
- Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) lff ẹ̀kọ́ 46 
- Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min.) 
- Orin 51 àti Àdúrà