July 17-23
Ẹ́SÍRÀ 9-10
- Orin 89 àti Àdúrà 
- Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.) 
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
- “Téèyàn Bá Ṣàìgbọràn, Ó Máa Jìyà Ẹ̀”: (10 min.) 
- Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì: (10 min.) - Ẹsr 10:44—Kí nìdí tí wọ́n fi lé àwọn ìyàwó tó jẹ́ àjèjì náà lọ tọmọtọmọ? (w06 1/15 20 ¶2) 
- Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo tún rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí nípa Jèhófà, iṣẹ́ ìwàásù tàbí àwọn nǹkan míì? 
 
- Bíbélì Kíkà: (4 min.) Ẹsr 9:1-9 (th ẹ̀kọ́ 2) 
TẸRA MỌ́ IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
- Nígbà Àkọ́kọ́: (3 min.) Fi ìwé àṣàrò kúkúrú náà Ǹjẹ́ Ìyà Lè Dópin? nasẹ̀ àkòrí ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ. (th ẹ̀kọ́ 13) 
- Ìpadàbẹ̀wò: (4 min.) Àkòrí ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ ni kó o fi bẹ̀rẹ̀. Pe ẹni náà wá sípàdé, kó o sì ṣe bíi pé ẹ wo fídíò Kí Ló Máa Ń Ṣẹlẹ̀ Nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba? (àmọ́ ẹ má ṣe wò ó) (th ẹ̀kọ́ 6) 
- Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì: (5 min.) lff ẹ̀kọ́ 11 ọ̀rọ̀ ìbẹ̀rẹ̀ àti kókó 1-3 (th ẹ̀kọ́ 14) 
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
- Ìgbọràn Máa Ń Dáàbò Bò Wá (2Tẹ 1:8): (15 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò náà. Lẹ́yìn náà, béèrè àwọn ìbéèrè yìí: Kí ló máa ṣẹlẹ̀ kí Amágẹ́dọ́nì tó bẹ̀rẹ̀? - Àǹfààní wo la máa rí tá a bá jẹ́ onígbọràn báyìí? - Báwo ni Amágẹ́dọ́nì àti ìgbọràn ṣe so kọ́ra? 
- Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) lff ẹ̀kọ́ 50 kókó 6-7 àti kókó pàtàkì, kí lo rí kọ́? àti ohun tó yẹ kó o ṣe 
- Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min.) 
- Orin 133 àti Àdúrà