ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb24 January ojú ìwé 11
  • February 12-18

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • February 12-18
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2024
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2024
mwb24 January ojú ìwé 11

FEBRUARY 12-18

SÁÀMÙ 5-7

Orin 118 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

1. Jẹ́ Olóòótọ́ Láìka Ohun Táwọn Míì Bá Ṣe Sí

(10 min.)

Àwọn ìgbà kan wà tí Dáfídì jẹ́ kí ohun táwọn míì ṣe kó ẹ̀dùn ọkàn bá a (Sm 6:6, 7)

Ó bẹ Jèhófà pé kó ran òun lọ́wọ́ (Sm 6:2, 9; w21.03 15 ¶7-8)

Dáfídì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pátápátá, ìyẹn sì mú kó jẹ́ olóòótọ́ (Sm 6:10)

Nínú àwòrán tó wà nínú, arábìnrin kan pariwo mọ́ arábìnrin mí ì níwájú Ilé Ìpàdé. Nígbà tó yá, arábìnrin tí wọ́n pariwo mọ́ náà gbàdúrà nígbà tó délé.

BI ARA RẸ PÉ, ‘Ǹjẹ́ mò ń sapá kí ìgbàgbọ́ mi lè lágbára débi tí màá fi jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà láìka ohun táwọn míì bá ṣe sí?’—w20.07 8-9 ¶3-4.

2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì

(10 min.)

  • Sm 5:9—Báwo ni ọ̀fun àwọn ẹni burúkú ṣe dà bíi sàréè tó ṣí sílẹ̀? (it-1 995)

  • Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?

3. Bíbélì Kíkà

(4 min.) Sm 7:1-11 (th ẹ̀kọ́ 10)

TẸRA MỌ́ IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa

(3 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. (lmd ẹ̀kọ́ 1 kókó 3)

5. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa

(2 min.) ÌWÀÁSÙ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ. Wá ọ̀nà tó o lè gbà jẹ́ kẹ́ni náà mọ̀ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ẹ́ láìjẹ́ pé o mẹ́nu ba ọ̀rọ̀ Bíbélì. (lmd ẹ̀kọ́ 2 kókó 4)

6. Pa Dà Lọ

(2 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Ẹni náà fẹ́ máa bá ẹ jiyàn. (lmd ẹ̀kọ́ 4 kókó 5)

7. Ṣàlàyé Ohun Tó O Gbà Gbọ́

(4 min.) Àṣefihàn. ijwfq 64—Àkòrí: Kí Nìdí Táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Fi Máa Ń Fi Tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ Kọ̀ Láti Ka Ẹ̀jẹ́ Tàbí Kọ Orin Orílẹ̀-Èdè? (lmd ẹ̀kọ́ 3 kókó 4)

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Orin 99

8. Ìròyìn Iṣẹ́ Ìsìn Ọdọọdún

(15 min.) Ìjíròrò. Kọ́kọ́ ka lẹ́tà látọ̀dọ̀ ẹ̀ka ọ́fíìsì nípa ìròyìn iṣẹ́ ìsìn ọdọọdún, jẹ́ kí àwọn ará sọ àwọn ohun tó wú wọn lórí nínú Ìròyìn Iṣẹ́ Ìsìn Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Kárí Ayé ti Ọdún 2023. Lẹ́yìn náà, fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu àwọn akéde kan tó o ti yàn, kí wọ́n sọ àwọn ìrírí tó ń gbéni ró tí wọ́n ní lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ní ọdún iṣẹ́ ìsìn tó kọjá.

9. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ

(30 min.) bt orí 5 ¶16-22, àpótí ojú ìwé 42

Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min.) | Orin 83 àti Àdúrà

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́