ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb25 March ojú ìwé 14-15
  • April 28–May 4

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • April 28–May 4
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2025
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2025
mwb25 March ojú ìwé 14-15

APRIL 28–MAY 4

ÒWE 11

Orin 90 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

1. Má Ṣe Sọ Ọ̀rọ̀ Tí Kò Yẹ!

(10 min.)

Má ṣe sọ ọ̀rọ̀ tó máa ba “ọmọnìkejì” rẹ lórúkọ jẹ́ (Owe 11:9; w02 5/15 26 ¶4)

Má ṣe sọ ọ̀rọ̀ tó máa da àárín àwọn èèyàn rú (Owe 11:11; w02 5/15 27 ¶2-3)

Má ṣe sọ ọ̀rọ̀ àṣírí síta (Owe 11:12, 13; w02 5/15 27 ¶5)

Nínú Ilé Ìpàdé, àwọn arákùnrin méjì ń bá ara wọn sọ̀rọ̀. Ọ̀kan nínú wọn ń sọ ohun tí kò dáa nípa arákùnrin tó ń bọ̀ lọ́dọ̀ wọn.

RONÚ LÓRÍ ÌBÉÈRÈ YÌÍ: Báwo ni ohun tí Jésù sọ ní Lúùkù 6:45 ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ ká má bàa sọ ohun tí kò dáa nípa àwọn ẹlòmíì?

2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì

(10 min.)

  • Owe 11:17—Àǹfààní wo la máa rí tá a bá jẹ́ onínúure? (g20.1 11, àpótí)

  • Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?

3. Bíbélì Kíkà

(4 min.) Owe 11:1-20 (th ẹ̀kọ́ 5)

TẸRA MỌ́ IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa

(4 min.) ÌWÀÁSÙ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ. Lo àǹfààní tó yọ láti sọ ohun tó o kọ́ nípàdé lẹ́nu àìpẹ́ yìí fún ẹnì kan. (lmd ẹ̀kọ́ 2 kókó 4)

5. Pa Dà Lọ

(4 min.) ÌWÀÁSÙ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ. Fi ọ̀kan lára àwọn fídíò tó wà nínú Àpótí Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ han ẹni náà. (lmd ẹ̀kọ́ 8 kókó 3)

6. Sọ Àwọn Èèyàn Di Ọmọ Ẹ̀yìn

(4 min.) ÌWÀÁSÙ NÍBI TÍ ÈRÒ PỌ̀ SÍ. Bi ẹni náà bóyá ó máa fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kó o sì fi bá a ṣe ń ṣe é hàn án. (lmd ẹ̀kọ́ 10 kókó 3)

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Orin 157

7. Má Ṣe Fi Ọ̀rọ̀ Ẹnu Rẹ Dá Wàhálà Sílẹ̀

(15 min.) ìjíròrò.

A máa ń ṣi ọ̀rọ̀ sọ nígbà míì torí pé aláìpé ni wá. (Jem 3:8) Àmọ́, tá a bá fi sọ́kàn pé ọ̀rọ̀ ẹnu wa lè dá wàhálà sílẹ̀, á jẹ́ ká máa ṣọ́ ohun tá à ń sọ ká má bàa sọ ohun tá a máa kábàámọ̀. Díẹ̀ rèé lára àwọn ọ̀rọ̀ tó lè dá wàhálà sílẹ̀ nínú ìjọ:

  • Kéèyàn máa fọ́nnu. Ẹni tó bá ń fọ́nnu lè mú káwọn míì máa jowú tàbí kí wọ́n máa bá ara wọn díje.—Owe 27:2

  • Ọ̀rọ̀ tí kì í ṣe òótọ́. Èyí kọjá kéèyàn kàn máa parọ́, ó tún kan kéèyàn mọ̀ọ́mọ̀ sọ ohun tó máa ṣi àwọn míì lọ́nà. Kódà kó jẹ́ ìwà àìṣòótọ́ tó dà bíi pé kò tó nǹkan la hù, ó lè bà wá lórúkọ jẹ́ káwọn èèyàn má sì fọkàn tán wa mọ́.—Onw 10:1

  • Òfófó. Ẹni tó bá ń ṣòfófó máa ń tojú bọ ọ̀rọ̀ tí kò kàn án nípa ìgbésí ayé àwọn ẹlòmíì. Ohun tó máa ń sọ nípa àwọn èèyàn lè má jẹ́ òótọ́ délẹ̀délẹ̀ tàbí kó máa sọ ọ̀rọ̀ àṣírí wọn. (1Ti 5:13) Irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lè dìjà kó sì da àárín àwọn èèyàn rú

  • Ọ̀rọ̀ téèyàn fìbínú sọ. Èyí ni ọ̀rọ̀ tí kò dáa téèyàn sọ láìronú sẹ́ni tó múnú bí i. (Ef 4:26) Irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ máa ń dunni.—Owe 29:22

Apá kan nínú fídíò “Ẹ Yẹra fún Ohun Tó Lè Ba Àlàáfíà Jẹ́—Àyọlò.” 1. Emily àti Celia jókòó síbi tí wọ́n ti ń mu kọfí. Celia ń wo ohun tí Haley gbé sórí ìkànnì àjọlò rẹ̀. 2. Haley fìbínú sọ̀rọ̀ sí Celia níbi ìgbọ́kọ̀sí ní Ilé Ìpàdé.

Jẹ́ káwọn ará wo FÍDÍÒ Ẹ Yẹra fún Ohun Tó Lè Ba Àlàáfíà Jẹ́—Àyọlò. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:

  • Kí lo rí kọ́ nípa ìdí tó fi yẹ ká kíyè sí ohun tá à ń sọ?

Tó o bá fẹ́ mọ ohun tí wọ́n ṣe tí àlàáfíà fi pa dà wà láàárín wọn, wo fídíò ‘Máa Wá Àlàáfíà, Kó O sì Máa Lépa Rẹ̀.’

8. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ

(30 min.) bt orí 25 ¶14-21

Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min.) | Orin Tuntun ti Àpéjọ Agbègbè 2025 àti Àdúrà

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́