MAY 5-11
ÒWE 12
Orin 101 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
1. Tó O Bá Ṣiṣẹ́ Kára, Wàá Jèrè
(10 min.)
Má ṣe fàkókò ẹ ṣòfò lórí àwọn nǹkan tí kò ní láárí (Owe 12:11)
Máa ṣiṣẹ́ kára, kó o sì ṣe é tọkàntọkàn (Owe 12:24; w16.06 30 ¶7)
Wàá jèrè iṣẹ́ àṣekára rẹ (Owe 12:14)
ÌMỌ̀RÀN: A máa gbádùn iṣẹ́ àṣekára wa tá a bá ń ronú nípa àǹfààní tó ń ṣe àwọn míì.—Iṣe 20:35; w15 2/1 5 ¶4-6.
2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
(10 min.)
Owe 12:16—Báwo ni ìlànà tó wà nínú ẹsẹ yìí ṣe lè jẹ́ ká túbọ̀ máa forí ti àwọn ìṣòro wa? (ijwyp àpilẹ̀kọ 95 ¶10-11)
Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?
3. Bíbélì Kíkà
(4 min.) Owe 12:1-20 (th ẹ̀kọ́ 5)
4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa
(2 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. (lmd ẹ̀kọ́ 1 kókó 4)
5. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa
(3 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ ẹni náà. (lmd ẹ̀kọ́ 5 kókó 4)
6. Pa Dà Lọ
(3 min.) ÌWÀÁSÙ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ. Fi ìkànnì wa han ẹnì kan tó láwọn ọmọ. (lmd ẹ̀kọ́ 9 kókó 3)
7. Ṣàlàyé Ohun Tó O Gbà Gbọ́
(3 min.) Àṣefihàn. ijwfq àpilẹ̀kọ 3—Àkòrí: Ṣé Ẹ Gbà Pé Ẹ̀sìn Yín Nìkan Lẹ̀sìn Tòótọ́? (lmd ẹ̀kọ́ 4 kókó 3)
Orin 21
8. Gbára Lé Jèhófà Tí Àtijẹ-Àtimu Bá Ṣòro
(15 min.) Ìjíròrò.
Ṣé ò ń ṣàníyàn nípa bó o ṣe máa ríṣẹ́ tàbí bí èyí tó ò ń ṣe báyìí ò ṣe ní bọ́ mọ́ ẹ lọ́wọ́, àbí bó o ṣe máa rówó gbọ́ bùkátà ara ẹ báyìí tàbí nígbà tó o bá darúgbó ló ń jẹ ọ́ lọ́kàn? Ká sòótọ́, ọrọ̀ ajé ò láyọ̀lé. Àmọ́, Jèhófà jẹ́ kó dá wa lójú pé tá a bá fi ìjọsìn ẹ̀ sákọ̀ọ́kọ́, òun máa bójú tó wa, tí nǹkan bá tiẹ̀ yí pa dà láìròtẹ́lẹ̀.—Sm 46:1-3; 127:2; Mt 6:31-33.
Wo FÍDÍÒ Jèhófà Ò Fi Wá Sílẹ̀ Rárá. Lẹ́yìn náà béèrè pé:
Kí lo kọ́ nínú ìrírí Arákùnrin Alvarado?
Ka 1 Tímótì 5:8. Lẹ́yìn náà béèrè pé:
Báwo ni ẹsẹ yìí ṣe jẹ́ kó dá wa lójú pé gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa pèsè ohun táwa ìránṣẹ́ rẹ̀ nílò?
Àwọn ìlànà Bíbélì yìí máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè fara dà á tí àtijẹ-àtimu bá ṣòro:
Jẹ́ kí ohun ìní díẹ̀ tẹ́ ẹ lọ́rùn. Ohun tó o nílò ni kó o rà, má sì tọrùn bọ gbèsè.—Mt 6:22
Tó o bá fẹ́ pinnu iṣẹ́ tí wàá ṣe àti bó o ṣe máa kàwé tó, rí i dájú pé o ṣèpinnu táá jẹ́ kó o lè fi ìjọsìn Jèhófà sípò àkọ́kọ́.—Flp 1:9-11
Jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, má sì fojú kéré iṣẹ́ èyíkéyìí. Tí iṣẹ́ bá bọ́ lọ́wọ́ ẹ, ṣe tán láti ṣe àwọn iṣẹ́ míì títí kan iṣẹ́ táwọn èèyàn ò kà sí, kó o lè gbọ́ bùkátà ìdílé ẹ.—Owe 14:23
Máa fún àwọn èèyàn ní nǹkan, tó ò bá tiẹ̀ fi bẹ́ẹ̀ ní lọ́wọ́.—Heb 13:16
9. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ
(30 min.) bt orí 26 ¶1-8, àwọn àpótí ojú ìwé 204, 208