SIERRA LEONE ÀTI GUINEA
Àwọn Ẹgbẹ́ Awo
ẸGBẸ́ awo pọ̀ káàkiri Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà, oríṣiríṣi èèyàn tí ẹ̀yà, àṣà ìbílẹ̀ àti èdè wọn yàtọ̀ síra ló sì máa ń wà nínú àwọn ẹgbẹ́ náà. Àwọn ẹgbẹ́ yìí máa ń ní àwọn òfin tó kan àjọṣe, ìmọ̀ àti ìgbòkègbodò òṣèlú àwọn ọmọ ẹgbẹ́ wọn. Àmọ́ ẹ̀sìn ni olórí ohun tí wọ́n máa ń ṣe. Méjì lára àwọn ẹgbẹ́ yìí tí àwọn èèyàn ń ṣe jù ni ẹgbẹ́ Poro (tó wà fún àwọn ọkùnrin) àti ẹgbẹ́ Sande (tó wà fún àwọn obìnrin).a Bí àpẹẹrẹ, ẹgbẹ́ Poro máa ń gbìyànjú “láti darí àwọn ẹ̀mí, kí wọ́n lè rí i dájú pé wọn ń ṣe aráyé lóore.”—Ìwé Initiation, 1986.
Wọ́n máa ń kọ́ àwọn tó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ wọ ẹgbẹ́ Poro ní àṣírí àwọn ẹ̀mí òkùnkùn àti agbára àwọn àjẹ́, wọ́n sì máa ń ṣe ètùtù tí wọ́n fi ń sàmì ẹgbẹ́ sí wọn lára. Wọ́n máa ń kọ́ àwọn obìnrin tó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ wọ ẹgbẹ́ Sande ní iṣẹ́ awo, wọ́n sì máa ń dá abẹ́ fún wọn, àmọ́ wọ́n ti jáwọ́ nínú àṣà yìí láwọn ibì kan.
Àwọn míì lára àwọn ẹgbẹ́ yìí máa ń ṣe òfin tó dá lórí ìbálòpọ̀, wọ́n sì máa ń fi ẹ̀mí òkùnkùn wo ẹni tó bá ní àrùn ọpọlọ tàbí àwọn àrùn míì. Nígbà ogun abẹ́lé tó wáyé nílẹ̀ Sierra Leone, ẹgbẹ́ awo kan sọ pé àwọn ní ayẹta. Àmọ́, irọ́ ni wọ́n pa.
Ara èèwọ̀ àwọn ẹgbẹ́ yìí ni pé wọn kò gbọ́dọ̀ tú àṣírí ẹgbẹ́ àtàwọn ètùtù wọn fún àwọn tí kì í ṣe ara wọn. Wọ́n gbà pé ẹni tó bá tàpá sí òfin àtàwọn ìlànà ẹ̀gbẹ́ ń fi ikú ṣeré nìyẹn.
a Láwọn ibòmíì, Bondo ni wọ́n ń pe ẹgbẹ́ Sande.