SIERRA LEONE ÀTI GUINEA
Ọmọdé Sójà Pa Dà Di Aṣáájú-Ọ̀nà Déédéé
ỌMỌ ọdún mẹ́rìndínlógún [16] ni mí nígbà táwọn ọmọ ogun ọlọ̀tẹ̀ fipá sọ mí di ara wọn. Wọ́n máa ń fún mi lóògùn olóró àti ọtí, oògùn yẹn ló sì sábà máa ń gùn mí nígbà tí mo bá ń jagun. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ni mo bá wọn lọ sójú ogun, mo sì hùwà ìkà tó burú jáì. Mo kábàámọ̀ gbogbo rẹ̀ gan-an ni.
Lọ́jọ́ kan, bàbá àgbàlagbà kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá wàásù ní àgọ́ àwa ológun. Èyí tó pọ̀ jù lára àwọn aráàlú ló bẹ̀rù àwa sójà ọlọ̀tẹ̀, wọ́n sì kórìíra wa, síbẹ̀ bàbá yìí máa ń wá kọ́ wa ní ẹ̀kọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Nígbà tó ní kí n wá sí ìpàdé, mo lọ. Mi ò tiẹ̀ rántí ohun tí wọ́n sọ nínú ìpàdé náà, àmọ́ mo rántí bí wọ́n ṣe fi ọ̀yàyà kí mi.
Nígbà tí ogun wá gbóná gan-an, mi ò rí àwọn Ẹlẹ́rìí mọ́. Mo ṣèṣe gan-an lójú ogun, wọ́n wá gbé mi lọ sí àgbègbè tó wà lábẹ́ àwọn ọmọ ogun ọlọ̀tẹ̀ títí ara mi fi yá. Àmọ́ kí ogun tó parí mo sá lọ sí àgbègbè tó wà lábẹ́ ìjọba, wọ́n sì gbà mí sínú ètò tí ìjọba ṣe láti fi mú kí ẹni tó bá ń jagun kó ohun ìjà rẹ̀ sílẹ̀, kó fi iṣẹ́ àti ìwà ológun sílẹ̀, kó sì dẹni tó tún ń gbé ìgbé ayé bí aráàlú yòókù.
Mo fẹ́ sún mọ́ Ọlọ́run lójú méjèèjì. Mo wá bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì àwọn Gba-Jésù. Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ìjọ ibẹ̀ sọ pé èmi ni Sátánì tó wà láàárín àwọn. Ni mo bá bẹ̀rẹ̀ sí í wá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Bí mo ṣe rí wọn, mo bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ́ọ̀ Bíbélì mo sì ń lọ sípàdé. Nígbà tí mo jẹ́wọ́ àwọn nǹkan burúkú tí mo ti ṣe, àwọn ará ka ọ̀rọ̀ ìtùnú tí Jésù sọ sí mi létí. Ó ní: “Àwọn ẹni tí ó ní ìlera kò nílò oníṣègùn, ṣùgbọ́n àwọn tí ń ṣòjòjò nílò rẹ̀. . . . Èmi kò wá láti pe àwọn olódodo, bí kò ṣe àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.”—Mát. 9:12, 13.
Ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ yẹn mà wọ̀ mí lọ́kàn o! Mo fún arákùnrin tó ń kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní ọ̀bẹ aṣóró mi, mo ní: “Ṣe ni mo tọ́jú ohun ìjà yìí láti fi gbèjà ara mi tí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ gbẹ̀san lára mi. Àmọ́ ní báyìí tí mo ti wá mọ̀ pé Jèhófà àti Jésù nífẹ̀ẹ́ mi, mi ò fẹ́ mọ́.”
Àwọn ará kọ́ mi láti mọ̀ọ́kọ mọ̀ọ́kà. Nígbà tó yá mo ṣèrìbọmi, mo sì di aṣáájú-ọ̀nà déédéé. Ní báyìí, tí mo bá wàásù fún àwọn tá a jọ jẹ́ ọmọ ogun ọlọ̀tẹ̀ tẹ́lẹ̀, wọ́n máa ń sọ fún mi pé àwọn yìn mí gan-an bí mo ṣe yí pa dà di èèyàn Ọlọ́run. Kódà mo kọ́ ọ̀kan lára àwọn ọ̀gá ẹgbẹ́ ọmọ ogun tí mo wà tẹ́lẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
Mo bí ọmọkùnrin mẹ́ta nígbà tí mo ṣì jẹ́ sójà. Lẹ́yìn tí mo kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, mo fẹ́ ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè sún mọ́ Ọlọ́run. Inú mi sì dùn gan-an pé méjì lára wọn kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́! Ọ̀kan nínú wọn ti di akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi, èyí tó dàgbà jù nínú wọn sì ń ṣe olùrànlọ́wọ́ aṣáájú-ọ̀nà báyìí.