Orílẹ̀-Èdè Dominican
LỌ́DÚN 1492, ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Christopher Columbus wakọ̀ lọ sí àwọn ilẹ̀ kan tó pè ní Ayé Tuntun. Àwọn ilẹ̀ tuntun náà fani mọ́ra, ó lè rí tajé ṣe níbẹ̀, ó sì lè ṣàwárí àwọn nǹkan tuntun. Orúkọ tó fún ọ̀kan lára àwọn erékùṣù tó gúnlẹ̀ sí ni La Isla Española tàbí Hispaniola. Ìdá méjì nínú mẹ́ta erékùṣù náà jẹ́ ti Orílẹ̀-èdè Dominican báyìí. Ní báyìí, ọ̀pọ̀ àwọn tó ń gbé lórílẹ̀-èdè yẹn ti wá ṣàwárí ohun tó yàtọ̀ pátápátá sí ti Columbus, ìyẹn ni ayé tuntun níbi tí òdodo yóò ti gbilẹ̀ títí láé lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run. (2 Pét. 3:13) Ìtàn alárinrin tá a fẹ́ sọ yìí dá lórí àwọn èèyàn tó lọ́kàn rere tí wọ́n ṣe àwárí tó pabanbarì náà.