ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • yb15 ojú ìwé 24-ojú ìwé 27 ìpínrọ̀ 1
  • Ikorajo Awa Elerii Jehofa Ti Ero Po sí Ju Lo

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ikorajo Awa Elerii Jehofa Ti Ero Po sí Ju Lo
  • Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2015
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa Eto-ajọ ti Ó Wà Lẹhin Orukọ Naa
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Fídíò Tuntun Tí A Ó Máa Fi Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2014
  • Àwọn Èrọ Tó Ń Gbé Ohùn àti Fídíò Jáde Ń Mú Ká Túbọ̀ Gbádùn Àwọn Àpéjọ Wa
    Bá A Ṣe Ń Ná Owó Tẹ́ Ẹ Fi Ń Ṣètọrẹ
  • A Bù Kún Ìdánúṣe Tó Lò
    Jí!—2002
Àwọn Míì
Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2015
yb15 ojú ìwé 24-ojú ìwé 27 ìpínrọ̀ 1
Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24

ÀWỌN OHUN PÀTÀKÌ TÓ ṢẸLẸ̀ LỌ́DÚN TÓ KỌJÁ

Ìkórajọ Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Tí Èrò Pọ̀ sí Jù Lọ

NÍ ỌJỌ́ Sátidé, October 5, ọdún 2013, ọ̀kẹ́ méjìlá ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbàásàn-án, igba àti mẹ́rìnléláàádọ́rùn-ún [257,294] èèyàn láti ilẹ̀ mọ́kànlélógún [21] ló pésẹ̀ síbi ìpàdé ọdọọdún, ìkọkàndínláàádóje [129] irú rẹ̀, ti àjọ Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania. Àwọn kan wà níbẹ̀, àwọn míì sì wò ó bó ṣe ń lọ lọ́wọ́ nípasẹ̀ ẹ̀rọ alátagbà. Ní òpin ọ̀sẹ̀ yẹn kan náà, àwọn míì tún wò ó nígbà tí a tún gbé e sáfẹ́fẹ́. Àròpọ̀ iye àwọn tó pésẹ̀ jẹ́ mílíọ̀nù kan, ẹgbẹ̀rún lọ́nà ìrínwó àti mẹ́tàlá, ẹgbẹ̀ta àti mẹ́rìndínlọ́gọ́rin [1,413,676] láti ilẹ̀ mọ́kànlélọ́gbọ̀n [31]. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ò tíì pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ rí níbi ìkórajọ wa!

Láti ọdún 1922 làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń lo tẹlifóònù àti rédíò láti ṣe àtagbà àwọn àpéjọ wa láti orílẹ̀-èdè kan sí òmíràn. Ní báyìí, Íńtánẹ́ẹ̀tì ti mú kó ṣeé ṣe fún àwọn tó wà níbi tó jìnnà láti gbọ́ ohun tó ń lọ, kí wọ́n sì máa wò ó lójú ẹsẹ̀ tàbí kété lẹ́yìn tó wáyé.

Ó lé ní ọdún kan tí àwọn ará láti onírúurú ẹ̀ka ọ́fíìsì fi ṣiṣẹ́ lórí bí wọ́n á ṣe fi Íńtánẹ́ẹ̀tì ṣe àtagbà ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà. Lópin ọ̀sẹ̀ tí wọ́n ṣe àtagbà náà, ìlú Brooklyn, ìpínlẹ̀ New York, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ni àwọn amojú ẹ̀rọ wa ti bójú tó ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà. Tọ̀sán tòru ni wọ́n fi ń gbaṣẹ́ lọ́wọ́ ara wọn bí wọ́n ṣe ń gbé ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà sáfẹ́fẹ́ ní ibi mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí àkókò wọn yàtọ̀ síra.

Ìsọfúnni Ṣókí​—Nípa Àwọn Ibi Tí A Ta Á Látagbà Sí

  • Ibi tó bọ́ sí tòsí jù: Gbọ̀ngàn Àpéjọ Jersey City, nílẹ̀ Amẹ́ríkà Iye àwọn tó pésẹ̀: 4,732

  • Ibi tí èrò pọ̀ sí jù: Ìlú Perth, ní Ọsirélíà Iye àwọn tó pésẹ̀: 7,186

  • Ibi tó jìnnà jù ní àríwá: Ìlú Fairbanks, ìpínlẹ̀ Alaska, ní Amẹ́ríkà Iye àwọn tó pésẹ̀: 255

  • Ibi tó jìnnà jù ní gúúsù: Ìlú Invercargill, ní New Zealand Iye àwọn tó pésẹ̀: 190

  • Ibi tó jìnnà jù lọ: Ìlú Perth, ní Ọsirélíà, ó tó nǹkan bí 18,700 kìlómítà sí ìlú Jersey City

Bí A Ṣe Ṣe Àtagbà Fídíò Náà

  1. A fi onírúurú kámẹ́rà fídíò gba ohun tó ń lọ nípàdé náà sílẹ̀.

  2. A fi fídíò náà ránṣẹ́ sórí ẹ̀rọ tó máa mú èyí tó dára jù lára rẹ̀.

  3. Ẹ̀rọ yìí wá fi fídíò náà ránṣẹ́ sórí kọ̀ǹpútà tó wà níbi tá a fi ṣe ojúkò àtagbà náà.

  4. Látibẹ̀ la ti sọ fídíò náà di oríṣi mẹ́ta tí àwòrán rẹ̀ tóbi jura lọ bí ìpàdé náà ṣe ń lọ lọ́wọ́.

  5. A wá gé e sí kéékèèké tí ọ̀kọ̀ọ̀kan rẹ̀ kò gùn ju ìṣẹ́jú àáyá mẹ́wàá-mẹ́wàá lọ.

  6. A gbé àwọn fídíò kéékèèké yìí sórí àwọn ẹ̀rọ alátagbà tó ń lo Íńtánẹ́ẹ̀tì.

  7. Ẹ̀rọ kan láwọn ibi tí wọ́n ti fẹ́ wo fídíò náà wa àwọn fídíò kéékèèké yìí jáde látorí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Ó kó wọn jọ síbì kan, ó sì tò wọ́n pọ̀ di odindi fídíò tó máa ṣeé wò láìkọsẹ̀.

  8. Àwọn ará wo ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà, wọ́n sì gbọ́ ọ ketekete.

Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26, 27
    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́