ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • yb16 ojú ìwé 100
  • Ẹgbẹ́ Bibelkring

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹgbẹ́ Bibelkring
  • Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2016
Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2016
yb16 ojú ìwé 100

INDONÉṢÍÀ

Ẹgbẹ́ Bibelkring

OHUN kan ṣẹlẹ̀ láàárín ọdún 1936 sí 1939. Àwọn tíṣà mélòó kan kó ara wọn jọ ní àgbègbè Adágún Toba tó wà ní North Sumatra, wọ́n sì dá ẹ̀sìn tuntun kan sílẹ̀ tí wọ́n pè ní Bibelkring tó túmọ̀ sí “àwùjọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì” lédè Dutch. Ó jọ pé aṣáájú-ọ̀nà kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Eric Ewins tó wá wàásù ní àgbègbè yẹn lọ́dún 1936 ló bá àwọn tíṣà yìí pàdé tó sì fún wọn láwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ohun táwọn tíṣà yìí kà nínú ìwé tí wọ́n gbà mú kí wọ́n fi ṣọ́ọ̀ṣì tí wọ́n ń lọ tẹ́lẹ̀ sílẹ̀, wọ́n sì dá ẹgbẹ́ àwọn tó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nínú ilé sílẹ̀. Ẹgbẹ́ tí wọ́n dá sílẹ̀ náà bẹ̀rẹ̀ sí í pọ̀ sí i títí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ náà fi di ọgọ́rọ̀ọ̀rún.a

Limeria Nadap-Dap tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Bibelkring tẹ́lẹ̀

Dame Simbolon ọmọ ẹgbẹ́ Bibelkring tẹ́lẹ̀ tó wá di arábìnrin

Àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n gbà lọ́wọ́ aṣáájú-ọ̀nà yẹn làwọn èèyàn náà kà tí wọ́n fi lóye àwọn òtítọ́ Bíbélì kan. Obìnrin kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Dame Simbolon tí òun náà wà nínú ẹgbẹ́ yẹn kó tó di Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́dún 1972 sọ pé: “Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Bibelkring kì í kí àsíá orílẹ́-èdè, wọn kì í ṣayẹyẹ Kérésì, wọn kì í sì ṣe ọjọ́ ìbí. Kódà, àwọn kan máa ń wàásù láti ilé dé ilé.” Àmọ́, nítorí ètò Ọlọ́run kọ́ ló ń darí ẹgbẹ́ yìí, àwọn ọmọ ẹgbẹ́ kan bẹ̀rẹ̀ sí í fi èrò ara wọn darí ẹgbẹ́ náà dípò èrò Ọlọ́run. Arábìnrin Limeria Nadapdap tóun náà jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ yìí tẹ́lẹ̀ sọ pé: “Àwọn òfin máṣu-mátọ̀ ni wọ́n gbé kalẹ̀. Wọn ò gbà káwọn obìnrin ṣe ara lóge, wọ ohun ọ̀ṣọ́ tàbí wọ aṣọ ìgbàlódé. Àní wọn ò tiẹ̀ gbọ́dọ̀ wọ bàtà pàápàá. Wọ́n tún ní àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ò gbọ́dọ̀ gba káàdì ìdánimọ̀ orílẹ̀-èdè wọn, ńṣe lèyí sì kóyà jẹ wọ́n lọ́dọ̀ ìjọba.”

Kò pẹ́ kò jìnnà, àwọn ọmọ ẹgbẹ́ kò gbọ́ra wọn yé mọ́, ni olúkálukú bá lọ dá ẹgbẹ́ tirẹ̀ sílẹ̀. Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ẹgbẹ́ Bibelkring pòórá pátápátá. Ìgbà táwọn aṣáájú-ọ̀nà fi máa pa dà dé sí Adágún Toba, ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Bibelkring tẹ́lẹ̀ ló di Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

a Àwọn kan tiẹ̀ fojú bù ú pé àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Bibelkring tó ẹgbẹẹgbẹ̀rún nígbà yẹn.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́