Benjamin Boothroyd—Ọ̀mọ̀wé Tó Ṣàyẹ̀wò Bíbélì Fúnra Ẹ̀
Ọkùnrin kan wà tí kò kàwé táwọn òbí ẹ̀ ò sì lówó lọ́wọ́, àmọ́ ó kọ́ bó ṣe lè ka èdè Hébérù fúnra ẹ̀, ó ṣàyẹ̀wò Bíbélì látòkè délẹ̀, èyí jẹ́ kó lè tú Bíbélì lédè Hébérù sí èdè Gẹ̀ẹ́sì, ó sì fi orúkọ Ọlọ́run sáwọn ibi tó yẹ kó wà.