ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ijwwd àpilẹ̀kọ 12
  • Bí Ẹyẹ Gannet Ṣe Máa Ń Bẹ́ Ludò

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bí Ẹyẹ Gannet Ṣe Máa Ń Bẹ́ Ludò
  • Ta Ló Ṣiṣẹ́ Àrà Yìí?
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun Alààyè Ń Mú Ìmọ́lẹ̀ Jáde
    Ta Ló Ṣiṣẹ́ Àrà Yìí?
  • Èèpo Ọsàn Pomelo Tó Rára Gba Nǹkan Sí
    Ta Ló Ṣiṣẹ́ Àrà Yìí?
  • Bí Eṣinṣin Ìgbẹ́ Ṣe Máa Ń Dábírà Tó Bá Ń Fò
    Ta Ló Ṣiṣẹ́ Àrà Yìí?
Ta Ló Ṣiṣẹ́ Àrà Yìí?
ijwwd àpilẹ̀kọ 12
Ẹyẹ gannet kan tó ń já wọnú omi.

TA LÓ ṢIṢẸ́ ÀRÀ YÌÍ?

Bí Ẹyẹ Gannet Ṣe Máa Ń Bẹ́ Ludò

Ẹyẹ òkun tó tóbi làwọn ẹyẹ Gannet. Tí wọ́n bá fẹ́ bẹ́ sínú òkun, wọ́n máa sá eré tó tó igba ó dín mẹ́wàá (190) kìlómítà láàárín wákàtí kan. Tí ẹyẹ gannet bá bẹ́ ludò, ìró rẹ̀ máa ń lágbára nígbà ogún (20) ju agbára òòfà lọ. Báwo làwọn ẹyẹ náà ṣe ń rù ú là tí wọ́n á sì tún pa dà já wọnú omi láìsí ewu kankan fún wọn?

Rò ó wò ná: Kí ẹyẹ gannet tó já wọnú omi, ó máa ń pa ìyẹ́ apá rẹ̀ méjèèjì pọ̀ sọ́wọ́ ẹ̀yìn, èyí á wá mú kó rí ṣóńṣó bí ẹnu ọfà. Yàtọ̀ síyẹn, ó tún máa ń pa awọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tó wà lójú rẹ̀ dé, á wá mú kí ẹran tó wà ní ọrùn àti àyà rẹ̀ túbọ̀ tóbi. Ohun tó ń ṣe yìí máa jẹ́ kí ara ẹ̀ dà bíi tìmùtìmù tí ò ní jẹ́ kó mọ̀ ọ́n lára nígbà tó bá já ṣòòròṣò wọnú omi.

Bí ẹyẹ gannet bá ṣe ń já ṣòòròṣò wọnú omi, ìkó ẹnu rẹ̀, orí rẹ̀ àti ọrùn rẹ̀ lápapọ̀ á wá rí bí igi gbọọrọ tó lẹ́nu ṣóńṣó. Ohun tó ń ṣe yìí máa jẹ́ kí gbogbo iṣan ọrùn ẹ̀ gba omi náà sára, kò ní jẹ́ pé iṣan kan péré ló máa mọ̀ ọ́n lára tó bá já wọnú omi. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ tó bá sì ti wọnú omi ló máa la ojú ẹ̀ pa dà kó lè rí ìsàlẹ̀ omi náà kedere.

Ibo ni ẹyẹ gannet máa ń dé dúró tó bá bẹ́ ludò? Bí ẹyẹ náà ṣe ń yára fò lè mú kó rìn jìnnà dé nǹkan bí ẹsẹ̀ bàtà mẹ́rìndínlógójì (36) tàbí mítà mọ́kànlá, ṣùgbọ́n tó bá tún fẹ́ lọ jìnnà si í, ṣe ló máa ń fi ìyẹ́ rẹ̀ àti ẹsẹ̀ ẹ̀ lúwẹ̀ẹ́. Kódà, a ti rí àwọn ẹyẹ gannet tó já ṣòòròṣò wọnú omi dé ìwọ̀n ẹsẹ̀ bàtà méjìlélọ́gọ́rin (82) tàbí mítà mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25) nísàlẹ̀ omi òkun. Lẹ́yìn tí ẹyẹ gannet bá ti já wọnú omi tán, ìrọ̀rùn ló máa fi léfòó pa dà wá sókè, táá sì tún máa fò lọ.

Ẹyẹ gannet rèé tó ń já wọnú omi

Àwọn tó ń ṣèwádìí ti fi ẹ̀rọ ṣe ohun tó dà bí ẹyẹ gannet kó lè ràn wọ́n lọ́wọ́ tí wọ́n bá ń ṣèwádìí tí wọ́n sì ń dóòlà ẹ̀mí. Wọ́n ṣe àwọn róbọ́ọ̀tì yìí kí wọ́n lè máa fò, kí wọ́n máa já ṣòòròṣò wọnú omi, kí wọ́n sì tún máa fò lẹ́yìn tí wọ́n bá jáde nínú omi. Ṣùgbọ́n nígbà kan tí wọ́n dán ọ̀kan lára àwọn róbọ́ọ̀tì tí wọ́n ṣe wò, ọ̀pọ̀ ìgbà ló fọ́ torí agbára tó fi balẹ̀ sínú omi. Èyí mú kí àwọn olùṣèwádìí náà gbà pé bí ẹyẹ táwọn fi ẹ̀rọ ṣe náà “ṣe ń já wọnú omi kò lágbára tó ti ẹyẹ gannet.”

Kí lèrò rẹ? Ṣé bí ẹyẹ gannet ṣe lè já wọnú omi láì ní àfiwé kàn ṣàdédé wà ni? Àbí ẹnì kan ló ṣiṣẹ́ àrà yìí?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́