ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ijwwd àpilẹ̀kọ 34
  • Bí Ẹja Grunion Ṣe Ń Yé Ẹyin

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bí Ẹja Grunion Ṣe Ń Yé Ẹyin
  • Ta Ló Ṣiṣẹ́ Àrà Yìí?
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
  • “Ọ̀pọ̀ Jaburata Ọlà Àwọn Òkun”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
Ta Ló Ṣiṣẹ́ Àrà Yìí?
ijwwd àpilẹ̀kọ 34
Ẹja California grunion mẹ́ta ń yé ẹyin létíkun.

Blue Planet Archive/Mark Conlin

TA LÓ ṢIṢẸ́ ÀRÀ YÌÍ?

Bí Ẹja Grunion Ṣe Ń Yé Ẹyin

Ẹja kékeré kan wà tí wọ́n ń pè ní California grunion, ẹja yìí máa ń yé ẹyin sí àwọn etíkun tó wà ní California lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà àti Baja California lórílẹ̀-èdè Mẹ́síkò. Àwọn ẹja yìí máa ń mọ ọjọ́ àti ìgbà tó yẹ kí wọ́n yé ẹyin kí àwọn ọmọ náà má bàa kú.

Rò ó wò ná: Lásìkò tí òṣùpá tuntun bá ṣẹ̀ṣẹ̀ yọ tàbí tó yọ roboto tán, òkun máa ń ru gan-an. Alẹ́ ọjọ́ kẹta sí kẹrin làwọn ẹja yìí máa ń yé ẹyin wọn sí etíkun. Tí wọ́n bá yé ẹyin wọn ṣáájú àkókò yẹn, ríru òkun náà máa gbá ẹyin wọn pọ̀ mọ́ iyẹ̀pẹ̀ pa dà sínú òkun. Torí pé lẹ́yìn àsìkò tí òkun ń ru gan-an ni wọ́n yé ẹyin wọn, wọ́n máa ń rí iyẹ̀pẹ̀ tó pọ̀ tó láti dáàbò bo ẹyin náà.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ akọ àti abo ẹja grunion wà létíkun lálẹ́.

Wally Skalij/Los Angeles Times via Getty Images

Yàtọ̀ síyẹn, lásìkò tí wọ́n máa ń yé ẹyin wọn ní oṣù March sí October, òkun máa ń ru gan-an lálẹ́ ju bó ṣe máa ń ru lọ́sàn-án. Ìyẹn máa ń jẹ́ káwọn ẹja yìí lè wẹ̀ dé ibi tó jìnnà dáadáa ní etíkun, kí wọ́n lè yé ẹyin síbi tí omi tó ń ru náà ò ti ní ṣan ẹyin wọn pa dà sínú òkun.

Táwọn ẹja grunion bá fẹ́ lọ yé ẹyin, wọ́n máa dúró de ìrugùdù tó lágbára tó lè gbé wọn lọ síbi tó jìnnà dáadáa ní etíkun níbi tí iyẹ̀pẹ̀ pọ̀ sí. Tí omi náà bá ti pa dà, abo ẹja náà máa gbẹ́ ihò tí ò jìn ju ìka kan lọ, á wá ki ìrù ẹ̀ bọ inú ihò náà kó lè yé ẹyin sí i. Lẹ́yìn náà, akọ kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ máa wá da àtọ̀ sórí ẹyin náà. Àwọn ẹja náà á wá dúró dìgbà tí omi á tún ru wá, kó lè gbé wọn pa dà sínú òkun.

Báwọn ẹyin náà ṣe ń dàgbà nínú yẹ̀pẹ̀, wọ́n nílò ìrugùdù òkun kí wọ́n tó lè di ẹja. Lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ méjì, òkun náà máa bẹ̀rẹ̀ sí í ru gan-an, ẹyin náà á sì di ẹja. Àmọ́ nígbà míì, ó lè tó ọ̀sẹ̀ mẹ́rin kí àwọn ẹyin náà tó di ẹja.

Kí lèrò rẹ: Ṣé ẹja grunion kàn ṣàdédé mọ ìgbà àti ibi tó yẹ kó yé ẹyin sí ni, àbí ẹnì kan ló ṣiṣẹ́ àrà yìí?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́