ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 5/22 ojú ìwé 17-21
  • Lahar—Àtubọ̀tán Òkè Ńlá Pinatubo

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Lahar—Àtubọ̀tán Òkè Ńlá Pinatubo
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àtubọ̀tán Onígbà Pípẹ́
  • Ìjábá Lẹ́ẹ̀kan Sí I
  • Ìfẹ́ Sún Àwọn Mìíràn Láti Ṣèrànwọ́
  • A Dá Wa Nídè Kúrò Nínú Lahar!
    Jí!—1996
  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
    Jí!—1997
  • Ǹjẹ́ O Lóye Ìgbà Tí A Wà Yìí?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Kíkọbiara Sí Ìkìlọ̀ Gba Ẹ̀mí Wọn Là
    Ẹ Máa Ṣọ́nà!
Àwọn Míì
Jí!—1996
g96 5/22 ojú ìwé 17-21

Lahar—Àtubọ̀tán Òkè Ńlá Pinatubo

LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYIN JÍ! NÍ PHILIPPINES

OMÍ yalé. Òwò dojú dé. Omí gbá àwọn ọkọ̀ lọ. Omí bo ilé mọ́lẹ̀. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún ènìyàn sá lọ tipátipá. Ó ká àwọn kan mọ́, wọn kò lè sá lọ. Kí ló fà á? Ìsẹ̀lẹ̀? Ìrọ́gììrì yìnyín? Rárá. Ìran àpéwò tí ń bá a lọ tí lahar (läʹhär) ń dá sílẹ̀ nìyí. Kí ní ń jẹ́ bẹ́ẹ̀? Àwọn ìṣàn omi àti ìgẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ òkè ayọnáyèéfín, tí ó ní erùpẹ̀ kíkúnná, èérún àpáta tí ń dán yanranyanran, àti pàǹtírí tí ń wá láti inú ìbúgbàù lọ́ọ́lọ́ọ́ àti àwọn ti ìṣáájú, nínú ní ń jẹ́ lahar.

Ó ṣeé ṣe kí o máà tí ì gbọ́ nípa Òkè Ńlá Pinatubo, ní Philippines, ní ẹ̀wádún kan sẹ́yìn. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìbúgbàù kíkàmàmà ní June 15, 1991, “Pinatubo” di orúkọ tí a mọ̀ dunjú ní apá ibi púpọ̀ lágbàáyé. Òkè Ńlá Pinatubo tí kò bú gbàù fún nǹkan bí 500 ọdún tú àwọn ohun ayọnáyèéfín rẹ̀ jáde nínú ọ̀kan lára àwọn eruku onírìísí olú kíkàmàmà jù lọ nínú ọ̀rúndún yìí. Erùpẹ̀, iyanrìn, àti àwọn àpáta ń ta jáde láti inú òkè ayọnáyèéfín náà, wọ́n sì ń rọ̀ bí òjò sórí ilẹ̀ lọ́nà tí ẹ̀dá ènìyàn fẹ́rẹ̀ẹ́ máà rí rí.a

Òkè ayọnáyèéfín náà tú ìwọ̀n nǹkan rẹpẹtẹ, tí ó ga ju 20 kìlómítà lọ, sínú afẹ́fẹ́ àyíká ayé. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, àwọn kan lára wọ́n padà sílẹ̀, ògìdìgbó eruku wà ní ojú òfuurufú síbẹ̀—kì í sì í ṣe eruku lásán, bí kò ṣe ọ̀pọ̀ yanturu afẹ́fẹ́ sulfur dioxide, tí ó wọn nǹkan bí 20 mílíọ̀nù tọ́ọ̀nù!

Ó ṣeé ṣe kí o rántí díẹ̀ lára ipa tí ó ní lórí àgbáyé: wíwọ̀ oòrùn tí ó rẹwà ta yọ fún sáà díẹ̀; ìmúṣókùnkùn oòrùn pátápátá tí ó mọ́lẹ̀ lọ́nà àràmàǹdà ní Mexico àti agbègbè ìtòsí rẹ̀ ní 1991; ìyípadà nínú ìrísí ojú ọjọ́, títí kan ipa ìmútutù ojú ọjọ́ ní àwọn apá ibì kan ní ìhà Àríwá Ìlàjì Ayé; àfikún ìparun ìpele ozone orí ilẹ̀ ayé. O sì ti lè gbọ́ nípa ìbísí nínú ebi àti àrùn tí ó kan àwọn ènìyàn tí ìbúgbàù náà ṣí nípò.

Àtubọ̀tán Onígbà Pípẹ́

Ọ̀kan lára àwọn àtubọ̀tán líle koko ìbúgbàù Pinatubo, bóyá, tí ayé kò sì fiyè sí tó bẹ́ẹ̀ ni ohun tí a wá mọ̀ sí lahar. Bí a ti mẹ́nu bà á ní ìpínrọ̀ àkọ́kọ́ àpilẹ̀kọ yìí, lahar ti fa ìjìyà tí kò ṣeé fẹnu sọ fún ẹgbẹẹgbàárùn-ún ènìyàn. Nítorí lahar náà, àbájáde ìbúgbàù Òkè Ńlá Pinatubo kò tán nílẹ̀. A ń mọ̀ wọ́n lára di báyìí. Ó lè ṣàìkàn ọ́ ní tààrà, ṣùgbọ́n ní agbègbè Òkè Ńlá Pinatubo, àwọn okòwò, iṣẹ́, ilé, ẹ̀mí, àní odindi ìlú pàápàá ń parun nìṣó. Lahar Pinatubo ló fà á.

Bí púpọ̀ wọn tilẹ̀ jọ àwọn odò ẹlẹ́rẹ̀ tí ó ní ìgẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ tí kò wọ́pọ̀ nínú, nígbà tí lahar bá ní ìgẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ tí ó jẹ́ ìpín 60 nínú ọgọ́rùn-ún nínú, yóò bẹ̀rẹ̀ sí í jọ kọnkéré ṣíṣàn. Èyí ń sọ nǹkan dahoro lọ́nà bíbùáyà. Ìwé pẹlẹbẹ A Technical Primer on Pinatubo Lahars sọ pé: “Ẹrẹ̀ yìí wúwo (ju ìlọ́po méjì ìwúwo omi lọ) tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi máa ń gbé àwọn àfọ́kù àpáta ńláńlá, apẹ̀rẹ̀ olókùúta ńláńlá, ọkọ̀, ilé oníkọnkéré, àti afárá pàápàá, lọ.”

Báwo ni lahar ṣe ń bẹ̀rẹ̀? O lè rántí pé ọ̀pọ̀ nǹkan ni Òkè Ńlá Pinatubo tú jáde nígbà tí ó bú gbàù. Àwọn kan lára wọ́n tú ká sínú afẹ́fẹ́ àyíká, ṣùgbọ́n púpọ̀ wọ́n wà lórí òkè ńlá náà àti nítòsí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àkójọpọ̀ ìṣàn àbájáde ìbúgbàù (tí òkè ayọnáyèéfín fà). Báwo ni wọ́n ṣe tó? Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn kan láti Ilé Ẹ̀kọ́ Ìmọ̀ Òkè Ayọnáyèéfín àti Ìmìtìtì Ilẹ̀ ti Philippines ṣe sọ, ó jẹ́ 6.65 bílíọ̀nù mítà ní ìwọ̀n gígùn, òró àti ìbú. Onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa òkè ayọnáyèéfín, C. G. Newhall, ọmọ ilẹ̀ United States, sọ pé pàǹtírí tí ó tú jáde tó láti fi “tẹ́ títì aláwẹ́ mẹ́rin ní àlọ àti àbọ̀ la ilẹ̀ United States já ní ìgbà 10, ó kéré tán.” Nínú èyí, 3.45 bílíọ̀nù mítà ní ìwọ̀n gígùn, òró àti ìbú ṣeé wọ́ lọ—tí ó wulẹ̀ wà níbẹ̀ de òjò láti ṣàn án lọ sí àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀, tí ń di lahar. Ní Philippines, àwọn ìjì àti àjà lè di àfikún wàhálà. Àrágbáyamúyamù òjó lè rọ̀ ní ìwọ̀n àkókò díẹ̀, kí ó sì di lahar rẹpẹtẹ.

Èyí gẹ́lẹ́ ni ohun tí ó ti ń ṣẹlẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún. Léraléra, ìjì ti fi omi tí ń wọ́ àwọn pàǹtírí òkè ayọnáyèéfín rẹ wọ́n. Lahar ti sọ àwọn ilẹ̀ oko ọlọ́ràá dí aṣálẹ̀, ó sì ti sọ àwọn ìlú di ibi tí a ti ń rí òrùlé nìkan lórí ilẹ̀. Nínú àwọn ọ̀ràn kan, ó ti ṣẹlẹ̀ lóru. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún ilé ti ṣègbé, a sì ti ṣí àwọn ènìyàn nídìí kúrò ní ilẹ̀ ìbí wọn, a fipá mú wọn láti tún bẹ̀rẹ̀ ìgbé ayé lọ́tun níbòmíràn. Títí di ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1995, lahar ti kó ìpín 63 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn pàǹtírí tí ìbúgbàù fà lọ sí àwọn ilẹ̀ títẹ́jú, ṣùgbọ́n síbẹ̀, ìyẹ́n ṣì fi ìpín 37 nínú ọgọ́rùn-ún sílẹ̀ lórí òkè ńlá náà, tí ó wà níbẹ̀ láti ṣe ìjàm̀bá lọ́jọ́ iwájú. Ọ̀pọ̀ jù lọ lára ìpín 63 nínú ọgọ́rùn-ún tí ó sì ti wálẹ̀ ṣì jẹ́ ewu síbẹ̀. Omi tí ń wá láti inú òjò ńláńlá tún ń gbẹ́ ọ̀nà ọ̀gbàrá nínú àwọn pàǹtírí tí ó ti kóra jọ sí òkè odò tẹ́lẹ̀. Èyí sì tún ń fa kí lahar gbéra lẹ́ẹ̀kan sí i, tí ń fewu wu ìwàláàyè àti ohun ìní tí ó bá wà níbi tí ó ń ṣàn lọ. Ní July 1995, ìwé agbéròyìnjáde Manila Bulletin ròyìn pé: “Àwọn barangay (abúlé) 91 . . . ti pa rẹ́ lórí àwòrán ilẹ̀ Àárín Gbùngbùn Luzon, pàǹtírí òkè ayọnáyèéfín ti bò wọ́n mọ́lẹ̀.”

Ìjábá Lẹ́ẹ̀kan Sí I

Ní ìrọ̀lẹ́ Saturday, September 30, 1995, ìjì líle Mameng (tí a mọ̀ kárí ayé sí Sybil) kọ lu Luzon. Àrágbáyamúyamù òjó rọ̀ ní agbègbè Òkè Ńlá Pinatubo. Èyí já sí ìjábá. Lahar tún ti gbéra sọ lẹ́ẹ̀kan sí i. Gbogbo ohun tí ń bẹ lọ́nà ní ń gbá lọ. Ní àdúgbò kan, ògiri ìdènà wó lulẹ̀, ó sì fàyè gba lahar tí ó jìn tó mítà mẹ́fà láti dé ibi tí kò dé rí. Omí ya gbogbo ilé tí kò tó alájà mẹ́ta. Àwọn ènìyán sáré gun òrùlé láti dáàbò bo ẹ̀mí wọn. Níbi tí lahar náà ti nípọn gan-an, ó gbé àfọ́kù àpáta, ọkọ̀, àti ilé pàápàá lọ.

Ipa mìíràn tí lahar tún ń ní ni àkúnya omi, nítorí wọ́n máa ń yí ipa ọ̀nà àwọn odò àti ojú àgbàrá padà. Omí bo ẹgbẹẹgbẹ̀rún ilé, títí kan àwọn kan tí wọ́n jẹ́ ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, àti àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba mélòó kan.

Àwọn mìíràn tilẹ̀ ní ìrírí tí ó túbọ̀ bani nínú jẹ́. Àwọn kan yóò rì sínú lahar tí ń ṣàn lọ tàbí sínú ẹrẹ̀ tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ gbá jọ, tí ó ń mú kí ó ṣòro láti sá là. Kìkì lẹ́yìn ọ̀pọ̀ wákàtí tàbí ọjọ́ ni yóò ṣẹ̀ṣẹ̀ le tó láti rìn lórí rẹ̀. Báwo ni àwọn ènìyàn ṣe sá là? Àwọn kan gbé orí òrùlé tàbí igi tí ó ga ju lahar náà lọ títí tí wọ́n fi lè rìn lórí rẹ̀. Níwọ̀n bí lahar náà ti ga tó okùn tẹlifóònù tí a ta sókè, okùn yìí ni àwọn kán rọ̀ mọ́ tàbí tí wọ́n ń rìn lórí rẹ̀. Àwọn kan ń rákòrò lórí ẹrẹ̀ tí kò ì le tán tí lahar náà fi sílẹ̀. Àwọn kan ò rù ú là. Ìjọbá fi hẹlikọ́pítà ránṣẹ́ sí àwọn ibi tí ó nira jù láti kó àwọn ènìyàn láti orí òrùlé.—Wo àpilẹ̀kọ tí a fi kún èyí: “A Dá Wa Nídè Kúrò Nínú Lahar!” fún ẹ̀kún rẹ́rẹ́ àlàyé síwájú sí i.

Ìfẹ́ Sún Àwọn Mìíràn Láti Ṣèrànwọ́

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa láyọ̀ láti mọ̀ pé, bí ọ̀pọ̀ ibùgbé àti Gbọ̀ngàn Ìjọba tilẹ̀ wó tàbí bà jẹ́ gidigidi, kò sí èyíkéyìí lára àwọn Kristian arákùnrin tàbí arábìnrin wọn tí ó pàdánù ẹ̀mí rẹ̀. Síbẹ̀, ó ṣe kedere pé àìní ńláǹlà wà láàárín àwọn tí lahar tàbí àkúnya bá kọ lù. Àwọn Ẹlẹ́rìí kan sá là pẹ̀lú kìkì aṣọ ọrùn wọn tí ẹrẹ̀ lahar rin gbìndìngbìndìn. Báwo ni àwọn Kristian ẹlẹgbẹ́ wọ́n ṣe dáhùn padà sí àìní náà?

Àwọn alàgbà láti inú àwọn ìjọ àdúgbò náà sapá láti mọ̀ bóyá àwọn Kristian arákùnrin wọ́n wà láìléwu tàbí wọ́n nílò ìrànlọ́wọ́ láti ṣípò padà. Èyí kò rọrùn rárá nítorí àwọn pàǹtírí lahar náà ṣì rọ̀ ní ọ̀pọ̀ agbègbè. Guillermo Tungol, alàgbà kan ní Ìjọ Bacolor, sọ pé: “A lọ láti ṣèrànwọ́. A rìn lórí okùn tẹlifóònù láti dé ọ̀dọ̀ àwọn ará náà.” Wilson Uy, òjíṣẹ́ alákòókò kíkún kan nínú ìjọ kan náà, fi kún un pé: “A fẹ́rẹ̀ẹ́ má lè débẹ̀, nítorí a ní láti wọ́ omi tó muni dé àyà, tó sì ń yára ṣàn gan-an.” Ṣùgbọ́n, pẹ̀lú ìṣọ́ra, wọ́n débẹ̀, wọ́n sì lè mọ ipò àwọn ará nínú ìjọ náà, wọ́n sì ṣèrànwọ́ níbi tó yẹ.

Nígbà tí ó fi di òwúrọ̀ Monday, October 2, ẹ̀ka ilé iṣẹ́ Watch Tower Society ti mọ̀ nípa àìní náà dáradára. Àwọn 345 òṣìṣẹ́ olùyọ̀ǹda ara ẹni ní ẹ̀ka náà yóò lè ṣèrànwọ́ bí? Bẹ́ẹ̀ ni! Ìdáhùnpadà ojú ẹsẹ̀ ni. Nígbà tí yóò fi di agogo mẹ́wàá òwúrọ̀, àwọn òṣìṣẹ́ wọ̀nyí nìkan ti dá aṣọ tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó tọ́ọ̀nù kan jọ fún àwọn Kristian arákùnrin wọn tí ó ṣaláìní. A fi ọkọ̀ kó èyí, pa pọ̀ pẹ̀lú oúnjẹ àti owó díẹ̀ ránṣẹ́, ó sì dé ọ̀hún lọ́jọ́ kan náà.

Níwọ̀n ọjọ́ díẹ̀, a fi tó àwọn ìjọ ìgboro ìlú Manila létí. A fi àfikún aṣọ tí ó ju tọ́ọ̀nù márùn-ún lọ, pẹ̀lú àwọn ìpèsè míràn tí a nílò ránṣẹ́. Ẹlẹ́rìí kan láti Japan ń ṣèbẹ̀wò sí Philippines nígbà ìjábá náà. Ó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé láti Hong Kong, níbi tí ó ti ra àwọn aṣọ kan fún ìlò ara rẹ. Nígbà tí ó gbọ́ nípa àìní àwọn Kristian ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ nítòsí Òkè Ńlá Pinatubo, ó fún wọn ní gbogbo aṣọ tí ó rà náà, ó sì padà sí Japan. Ẹ wo bí ó ti tuni lára tó láti rí bí àwọn Kristian tòótọ́ ṣe ń fi ìfẹ́ hàn sí àwọn tí ó ṣaláìní—kì í wulẹ̀ ṣe nípa wíwúre fún wọn, ṣùgbọ́n nípa ‘fífún wọn ní awọn ohun kòṣeémánìí fún ara wọn.’—Jakọbu 2:16.

Òtítọ́ náà pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa kò jẹ́ kí irú ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ sọ ìtara wọn fún àwọn ohun tẹ̀mí di akùrẹtẹ̀ yẹ fún oríyìn. Àwọn ìpàdé Kristian ń bá a nìṣó—àní nínú ọ̀ràn kan, níbi tí omi náà ti muni dé orúnkún nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba pàápàá. Ní mímọ ìjẹ́pàtàkì mímú ìhìn iṣẹ́ Bibeli tọ àwọn mìíràn lọ, àwọn Kristian wọ̀nyí ń bá wíwàásù láti ilé dé ilé lọ. Àwọn kan ní láti wọ́ omi lọ sí agbègbè tí wọ́n ti máa wàásù—níbi tí àkúnya náà kò ti pọ̀ tó bẹ́ẹ̀. Wọ́n kó aṣọ dání, wọ́n sì ń pààrọ̀ aṣọ níbi tí ilẹ̀ bá túbọ̀ gbẹ díẹ̀. Nítorí náà, bí àwọn Kristian wọ̀nyí tilẹ̀ ń jìyà fúnra wọn, wọn kò jẹ́ kí èyí ṣí wọn lọ́wọ́ dídàníyàn nípa àwọn ẹlòmíràn.

Bẹ́ẹ̀ ni, àtubọ̀tán Pinatubo ju ohun tí ọ̀pọ̀ ènìyán mọ̀ pé yóò jẹ́ lọ. Ìtàn tí yóò sì máa bá a lọ fún ọ̀pọ̀ ọdún sí i ni. A ti ṣe ọ̀pọ̀ ìsapá láti kápá lahar, ṣùgbọ́n ó máa ń kọjá agbára ẹ̀dá ènìyàn lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Ẹ wo bí ó ti ń dùn mọ́ni tó pé, nígbà tí irú ipò bẹ́ẹ̀ bá wà, àwọn Kristian tòótọ́ ń lò wọ́n bí àǹfààní láti ṣàfihàn ìfẹ́ wọn fún Ọlọrun àti aládùúgbò wọn!

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Fún ìsọfúnni síwájú sí i, wo àkọ́kọ́ ìròyìn Jí! lórí ìbúgbàù náà, “Ọjọ́ Tí Iyanrìn Ń Rọ̀ Bí Òjò,” nínú ìtẹ̀jáde February 8, 1992 (Gẹ̀ẹ́sì), ojú ìwé 15 sí 17.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Bí Òkè Ńlá Pinatubo Ṣe Nípa Lórí Ayé

GBÀRÀ tí ìbúgbàù òkè ayọnáyèéfín irú ti Òkè Ńlá Pinatubo bá ti rọlẹ̀ tàbí kásẹ̀ nílẹ̀, ipa rẹ̀ náà ti dópin nìyẹn. Ṣé bẹ́ẹ̀ ni? Rárá o! Fiyè sí díẹ̀ lára àwọn ipa tí ń bá a nìṣó lórí ayé.

◼ O lè ti kíyè sí wíwọ̀ oòrùn tí ó rẹwà ta yọ fún sáà díẹ̀ lẹ́yìn ìbúgbàù náà.

◼ Ìmúṣókùnkùn oòrùn pátápátá tí ó mọ́lẹ̀ lọ́nà àràmàǹdà ní July 11, 1991, ya àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ní Mexico lẹ́nu. Kí ní fà á? Ìbúgbàù Òkè Ńlá Pinatubo. Àwọn egunrín erukuru rẹ̀ fọ́n ìmọ́lẹ̀ àyíká oòrùn ká ju bí ó ti sábà máa ń rí lọ.

◼ Ó tún nípa lórí ojú ọjọ́. Ní nǹkan bí oṣù mẹ́ta lẹ́yìn ìbúgbàù náà, ìròyìn sọ pé ìtànṣán oòrùn ní tààrà ní Tokyo, Japan, fi bí ìpín 10 nínú ọgọ́rùn-ún dín sí bí ó ti máa ń rí. Eruku ìbúgbàù dí apá kan oòrùn lójú. Ìwé ìròyìn Science News tọ́ka sí ìlọsílẹ̀ nǹkan bí ìwọ̀n 1 lórí òṣùwọ̀n Celsius nínú ìpíndọ́gba ìwọ̀n ìgbóná òun ìtutù ní àwọn apá ibì kan ní ìhà Àríwá Ìlàjì Ayé.

◼ Ipa mìíràn tí ó ní ni àfikún ìparun ìpele ozone orí ilẹ̀ ayé. Omiró imí ọjọ́ tí ìbúgbàù náà tú dà sáfẹ́fẹ́ para pọ̀ mọ́ àtọwọ́dá èròjà chlorine tí àwọn ènìyán ṣe, tí ó yọrí sí ìdínkù ozone. Ìpele ozone ni ó yẹ kí ó pèse ìji afẹ́fẹ́ àyíká tí ń dáàbò bo àwọn ènìyàn lọ́wọ́ àrùn jẹjẹrẹ. Kò pẹ́ lẹ́yìn ìbúgbàù náà tí ìpele ozone ní agbègbè Antarctica fi lọ sílẹ̀, tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ dé orí òfo; ó lọ sílẹ̀ ní ìpín 20 nínú ọgọ́rùn-ún ní agbègbè ìlà agbedeméjì òbìrí ayé.

◼ Ebi àti àrùn tún jẹ́ àbájáde búburú síwájú sí i. A fipá mú àwọn ènìyàn tí wọ́n ṣípò padà nítorí òkè ayọnáyèéfín náà láti gbé àwọn ibùdó ìṣíkúrò, níbi tí àìsàn ti yára tàn kálẹ̀. Àwọn tí ó kàn jù ni àwọn Aeta, ẹ̀yà ènìyàn kan tí ìbúgbàù náà fipá lé kúrò lórí ilẹ̀ wọn sí inú àyíká kan tí kò mọ́ wọn lára.

[Àwòrán]

Àwọn tí ń ṣípò padà láti ibi àkúnya tàbí ibi tí “lahar” ti ṣọṣẹ́

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Ilé tí “lahar” gbé lọ

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Ó bo àwọn ilé alájà méjì dé ọ̀gangan òrùlé

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

“Lahar” sọ ọ̀pọ̀ ilẹ̀ oko rírẹwà di aṣálẹ̀

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]

Lókè: Ilé báńkì tí “lahar” mù dé ìdajì ní Bacolor, Pampanga, March 1995

Nísàlẹ̀: Báńkì kan náà tí “lahar” bò bámúbámú lẹ́yìn náà, September 1995

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́