Ojú Ìwòye Bíbélì
Àwọn UFO Ońṣẹ́ Láti Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Ni Wọ́n Bí?
BÍ Ọ̀RÚNDÚN ogún ti ń lọ sópin ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, tí ipò nǹkan sì ń bàjẹ́ sí i lórí ilẹ̀ ayé láìdábọ̀, ìgbàgbọ́ nínú àwọn ohun àìmọ̀ tí ń fò (àwọn UFO) àti àwọn èrò inú wọn, àwọn olùgbé òde ayé, ń tàn kálẹ̀ sí i. Àròsọ lásán, màkàrúrù, ẹ̀tàn tí àwọn ènìyàn tí wọ́n fẹ́ láti fi ìwà òmùgọ̀ àwọn aráàlù ṣe yẹ̀yẹ́ ṣe ha ni àwọn UFO bí?
Àwọn tí wọ́n sọ pé àwọ́n ti rí àwọn UFO tàbí àwọn olùgbé òde ayé tí wọ́n jẹ́ èrò inú wọn rí ní àwọn aṣeégbíyèlé, tí ó jọ pé orí wọ́n pé nínú; ní ti gidi, àwọn tí wọ́n gbà gbọ́ nínú àwọn àlejò yìí láti pílánẹ́ẹ̀tì míràn ní àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n àti onímọ̀ ìjìnlẹ̀ tí wọ́n kàwé dáadáa nínú. Wọ́n gbà gbọ́ pé àwọn olùgbé òde ayé ń ṣàkíyèsí àwọn ènìyàn, wọ́n sì ń bá wọn sọ̀rọ̀ pọ̀ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Àwọn tí a pè ní àwùjọ àwọn alátìlẹ́yìn àwọn olùgbé òde ayé wà lárọ̀ọ́wọ́tó láti ṣèrànwọ́ fún àwọn ènìyàn tí wọ́n wí pé àwọ́n ti bá àwọn àlejò láti gbalasa òfuurufú sọ̀rọ̀ rí.a
Ìwéwèé Lílàájá Bí Àjèjì
Nínú ìwé Aliens Among Us, Ruth Montgomery fọ̀rọ̀ wá díẹ̀ lára àwọn ènìyàn tí ń pọ̀ sí i, tí wọ́n gbà gbọ́ pé àwọ́n jẹ́ olùgbé òde ayé tí ó jẹ́ àjèjì, tí ń gbé nínú ara ènìyàn. Àwọn díẹ̀ lára àwọn wọ̀nyí tí wọ́n sọ pé àwọ́n jẹ́ ẹ̀dá olùgbé òde ayé nínú ara ènìyàn sàsọtẹ́lẹ̀ pé ní ọdún 2000, “ìṣẹ̀lẹ̀ ńlá kan tí àwùjọ àwọn áńgẹ́lì jàǹkànjàǹkàn àti àwọn ọ̀gá ti ń múra sílẹ̀ fún yóò ṣẹlẹ̀.” Àwọn ènìyàn kán gbà gbọ́ pé àwọn ẹ̀dá olùgbé òde ayé kan ń lo àwọn UFO láti ṣàkójọ, kí wọ́n sì pa àwọn àpẹẹrẹ ẹ̀yà irúgbìn àti ẹranko mọ́ tàbí pé a óò lo UFO bí ìhùmọ̀ agbéniresánmà tí ń yọni nínú ewu láti gbé àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn lọ kúrò nítorí ìsọdahoro tí ń bọ̀ sórí ilẹ̀ ayé. Lẹ́yìn ìparun ńlá náà, a óò dá àwọn ènìyàn padà láti bẹ̀rẹ̀ “Sànmánì Tuntun àti Ètò Tuntun” ti ìwàlójúfò tẹ̀mí. Ọ̀dọ́kùnrin kan láti Colorado, U.S.A., tí ó jẹ́ mẹ́ḿbà àwùjọ kan tí wọ́n pe ara wọn ní “Àjèjì Èwe,” fi taratara wí fún Jí! pé: “Èmi àti àwọn ọ̀rẹ́ mi ń dúró de àwọn baba ńlá wa tí wọ́n jẹ́ àjèjì láti gbà wá lọ.”
Díẹ̀ lára àwọn tí wọ́n tẹnu mọ́ ọn pé àwọ́n jẹ́ olùgbé òde ayé sọ pé Ọlọ́run ní ń ṣamọ̀nà àwọn, àwọn mìíràn sì sọ pé àwọ́n ń bá a sọ̀rọ̀ fàlàlà fún àmọ̀ràn ní ṣíṣèrànwọ́ fún aráyé. Ọlọ́run ha ń lo àwọn àlejò láti pílánẹ́ẹ̀tì míràn láti gba aráyé là nínú àjálù tí ń bọ̀ sórí ayé bí?
Bí Ọlọ́run Ṣe Ń Bá Aráyé Sọ̀rọ̀
Ní kùtùkùtù ìtàn aráyé, Ọlọ́run bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀. Àkọsílẹ̀ Bíbélì ṣàpèjúwe ìjíròrò àtọ̀runwá pẹ̀lú Ádámù àti Éfà, Nóà, Ábúráhámù, àti àwọn mìíràn.b (Jẹ́nẹ́sísì 3:8-10; 6:13; 15:1) Àlá, ohùn, àti ìran ni a lò láti sọ ìfẹ́ Ọlọ́run àti láti ṣèmújáde Bíbélì. Bí ó ti wù kí ó rí, lẹ́yìn tí a ti parí kíkọ Bíbélì, àìní kan ha wà fún bíbá aráyé sọ̀rọ̀ ní tààràtà láti ọ̀run bí? Bẹ́ẹ̀ kọ́, níwọ̀n bí Bíbélì ti sọ pé Ìwé Mímọ́ mú kí “ènìyàn Ọlọrun . . . pegedé ní kíkún, tí a mú gbaradì pátápátá fún iṣẹ́ rere gbogbo.” (Tímótì Kejì 3:17) Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ti sọ, ìtọ́sọ́nà nípa àwọn àkókò tí ó kún fún wàhálà wọ̀nyí yóò wá láti inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí a kọ sílẹ̀. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ìdí èyíkéyìí ha wà láti gbà gbọ́ pé a óò máa gba ìsọfúnni tàbí àkànṣe ìtọ́ni ní tààràtà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run nípasẹ̀ agbọ̀rọ̀sọ kan tí ó jẹ́ olùgbé òde ayé bí? Bẹ́ẹ̀ kọ́, nítorí pé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Àní bí àwa tàbí áńgẹ́lì kan láti ọ̀run bá polongo fún yín gẹ́gẹ́ bí ìhìn rere ohun kan tí ó ré kọjá nǹkan tí a ti polongo fún yín gẹ́gẹ́ bí ìhìn rere, kí ó di ẹni ègún.”—Gálátíà 1:8.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ohun tí àwọn tí a sọ pé wọ́n jẹ́ olùgbé òde ayé ń tẹnu mọ́ jọ pé ó bára mu pẹ̀lú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì pé ilẹ̀ ayé yóò nírìírí àwọn ìyípadà oníjàábá líle koko láìpẹ́, wọ́n pèsè ọ̀nà àtilàájá tí ń fọkàn tẹ ohun tí a ṣẹ̀dá. Bíbélì kò rọ àwọn ènìyàn láti sá àsálà lọ sínú ìhùmọ̀ agbéniresánmà ti àjèjì tí a rò pé kò léwu tàbí lọ sí ibi èyíkéyìí mìíràn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó wí fún wa láti wá ààbò nínú ipò ìbátan tí a yà sí mímọ́ sí Ọlọ́run, ìyàsímímọ́ tí a fi àmì ìṣàpẹẹrẹ rẹ̀ hàn nípasẹ̀ ìbatisí nínú omi. (Pétérù Kìíní 3:21; fi wé Sáàmù 91:7; Mátíù 28:19, 20; Jòhánù 17:3.) Jésù sì sọ pé “ẹni tí ó bá fara dà á dé òpin ni ẹni tí a óò gbà là.”—Mátíù 24:13.
Àwọn ẹsẹ ìwé mímọ́ wọ̀nyí kò ha tẹnu mọ́ ipò ìbátan tẹ̀mí pẹ̀lú Ọlọ́run fún lílàájá dípò ibi ìsádi kan tí ó ṣeé fojú rí bí? Nítorí náà, dípò kí àwọn ìtàn nípa ‘àwọn ẹ̀dá aláìjénìyàn’ ṣèrànwọ́ fún aráyé láti làájá, wọ́n ń yí àfiyèsí àwọn ènìyàn padà kúrò nínú ohun tí Ọlọ́run béèrè fún ní ti gidi fún ire ayérayé wọn ni.
Ta ló lè máa gbìyànjú láti darí aráyé kúrò lójú ọ̀nà ìpèsè fún lílàájá tí Ọlọ́run ṣe, kí ó sì máa sọ pé òún ń ṣojú fún Ọlọ́run? Ed Conroy sọ nínú ìwé rẹ̀, Report on Communion, pé “àwọn akíkanjú onímọ̀ UFO tí wọ́n gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ nínú ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ ìfìṣemọ̀rònú àti àjọṣe ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà” fi àwọn ìwádìí àfiwéra nípa “‘àwọn àlejò inú iyàrá,’ àwọn àǹjànnú, àwọn àǹjànnú aláriwo, àwọn ìran abàmì, àwọn ìran onísìn, àti àwọn tí a kà sí ẹ̀mí èṣù” kún ìwádìí wọn. Ọ̀pọ̀ àwọn onímọ̀ UFO àti àwọn tí wọ́n sọ pé àwọ́n jẹ́ olùgbé òde ayé ní ìrísí ènìyán sọ pé, fún apá púpọ̀ jù lọ, lílo àwọn ìhùmọ̀ agbéniresánmà láti rìnrìn àjò kò pọn dandan. Wọ́n sọ pé àwọn ẹ̀dá wọ̀nyí lè rìnrìn àjò láìjẹ́ pé a rí wọn, wọ́n sì lè fara hàn níbikíbi lórí ilẹ̀ ayé láìbá ìhùmọ̀ agbéniresánmà wá.
Bíbélì kìlọ̀ pé ète Sátánì àti àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ jẹ́ láti ṣi aráyé lọ́nà. Wọ́n ń fi ìbọ́hùn àti ipò àìnírètí aráyé ṣèfà jẹ láti fi àwọn ojútùú fífani mọ́ra ṣùgbọ́n tí ó jẹ́ èké lọni. (Kọ́ríńtì Kejì 11:14) Nítorí èyí, Bíbélì kìlọ̀ pé: “Ní ìkẹyìn àwọn sáà àkókò, àwọn kan yóò yẹsẹ̀ kúrò ninu ìgbàgbọ́, ní fífi àfiyèsí sí àwọn gbólóhùn àsọjáde onímìísí tí ń ṣini lọ́nà àti àwọn ẹ̀kọ́ ẹ̀mí èṣù.”—Tímótì Kìíní 4:1.
Bákan náà, lónìí, irú ìbẹ̀wò èyíkéyìí bẹ́ẹ̀ àti ìtọ́sọ́nà tí a lè rò pé ó ṣàǹfààní láti ọ̀dọ̀ irú àwọn ẹ̀dá bẹ́ẹ̀ ni a gbọ́dọ̀ kọ̀, láìka irú èyí tí ó lè jẹ́ sí. Ó dájú pé a óò ṣi àwọn tí wọn fẹ́ láti tẹ̀ lé àmọ̀ràn àwọn “olùgbé òde ayé” dípò Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lọ́nà—àṣìṣe ńláǹlà ni ó jẹ́ lákòókò líle koko yìí.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fún ìjíròrò nípa UFO àti ìwàláàyè àwọn olùgbé òde ayé, wo ìtẹ̀jáde Jí!, October 8, 1990, àti July 8, 1991.
b Òǹkọ̀wé Bíbélì náà, Ìsíkẹ́ẹ̀lì, rí ohun tí àwọn kan túmọ̀ sí UFO. (Ìsíkẹ́ẹ̀lì, orí 1) Bí ó ti wù kí ó rí, èyí jẹ́ ọ̀kan lára ọ̀pọ̀ àwọn ìran ìṣàpẹẹrẹ tí Ìsíkẹ́ẹ̀lì àti àwọn wòlíì míràn ṣàpèjúwe, kì í ṣe fífi ojúyòójú rí i ní ti gidi bí àwọn kan ṣe sọ ní òde òní.