Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
Mo Ń Kà Á Láti Páálí Dé Páálí Mo máa ń fẹ́ràn Jí!, ṣùgbọ́n mo máa ń ka àwọn àpilẹ̀kọ tí ó gbà mí láfiyèsí nìkan. Nísinsìnyí, mo ń kà á láti páálí dé páálí, mo sì wá ń fẹ́ràn àwọn kókó tí ǹ bá fò tẹ́lẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, mo ṣẹ̀ṣẹ̀ parí kíka “Àṣà Ìṣẹ̀dálẹ̀ Àwọn Amerind Ìgbàanì Kan” (March 8, 1996), mo sì gbádùn rẹ̀ ní tòótọ́!
E. A. S., Brazil
Ṣíṣẹ Ẹlòmíràn Àpilẹ̀kọ náà, “Ojú Ìwòye Bíbélì: Ohun Tí Ó Yẹ Kí O Ṣe Bí O Bá Ṣẹ Ẹlòmíràn” (February 8, 1996), bọ́ sákòókò yíyẹ gẹ́lẹ́. Kristẹni arábìnrin kan ṣàdéédéé bẹ̀rẹ̀ sí í yàn mí lódì. Mo bi í bóyá mo ṣẹ̀ ẹ́ ni, mo sì tọrọ àforíjì. Ṣùgbọ́n èyí kò yí ìṣarasíhùwà rẹ̀ pa dà. Èyí ká mi lára gan-an, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé Jèhófà kò tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ ìsìn mi sí i. Ẹ wo bí ó ṣe tù mí nínú tó nígbà tí mo ka ìpínrọ̀ tí ó kẹ́yìn nínú àpilẹ̀kọ náà! Ó sọ pé “níwọ̀n bí o ti ṣe gbogbo ohun tí o lè ṣe láti wá àlàáfíà, inú Jèhófà yóò dùn láti tẹ́wọ́ gba ìjọsìn rẹ.”
M. R., Ajẹntínà
Ṣèbé Àpilẹ̀kọ náà, “Ìwọ Yóò Ha Fẹ́ Láti Wo Ṣèbé?” (March 22, 1996), wọni lọ́kàn gan-an. Ṣùgbọ́n àlàyé àwòrán kan ní ojú ìwé 16 kà pé: “Ṣèbé dúdú kan fẹ abẹ̀bẹ̀ orí rẹ̀ níbi tí ó ti ń yáàrùn lórí àpáta lílọ́wọ́ọ́wọ́ọ́.” Gbogbo ohun tí mo mọ̀ ni pé, ṣèbé máa ń fẹ abẹ̀bẹ̀ orí rẹ̀ nígbà tí ó bá nímọ̀lára ewu tàbí tí a bá mú ṣèbé náà bínú.
R. F., Germany
A ṣàlàyé èyí nínú àpilẹ̀kọ náà, ní ojú ìwé 18, ìpínrọ̀ 1, àti ní ojú ìwé 20, ìpínrọ̀ 2. Aṣojúkọ̀ròyìn wa ní Íńdíà sọ pé, nínú fọ́tò náà, ṣèbé náà ń hùwà pa dà sí ìmúnibínú láti ọ̀dọ̀ olùrànlọ́wọ́ ayafọ́tò náà ni.—Olùyẹ̀wòṣàtúnṣe.
Awakọ̀ Tí Ó Jẹ́ Aláàbọ̀ Ara Àpilẹ̀kọ náà, “Aláàbọ̀ Ara—Tí Ó Sì Tún Lè Wakọ̀” (May 8, 1996), bọ́ sákòókò yíyẹ. Gẹ́gẹ́ bí aláàbọ̀ ara kan, mo rí i pé iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni mi mọ níwọ̀n. Ọpẹ́ ni fún Jèhófà pé, mo ní ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ kan tí ó bá ipò mi mu nísinsìnyí, àpilẹ̀kọ yìí sì ti ta mí jí láti mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ mi gbòòrò sí i.
A. A. V., Brazil
Ijó Jíjó Mo máa ń gbádùn jíjó sí àwọn orin abágbàmu, orin Látìn, àti orin lílókìkí tí ń dún jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìgbòkègbodò àkókò ọwọ́dilẹ̀. Ní tòótọ́, mo mọrírì àpilẹ̀kọ náà, “Ojú Ìwòye Bíbélì: Ijó Jíjó Ha Yẹ fún Àwọn Kristian Bí?” (May 8, 1996) Ó ràn mí lọ́wọ́ láti túbọ̀ ṣàyẹ̀wò irú eré ìtura yìí dáradára sí i. Àwọn ìbéèrè tí ń yẹnú ọkàn wò tí ẹ béèrè yóò ràn mí lọ́wọ́ láti wà láìlábàwọ́n àti “láìní èérí kúrò nínú ayé.”—Jákọ́bù 1:27.
D. D. G., Trinidad
Ọmọ ọdún 15 ni mí, ó sì ṣòro fún mi láti pinnu ohun tí ó tọ́ tàbí ohun tí kò tọ́, bí ó bá di ọ̀ràn ijó jíjó. Nípa lílo ìtọ́sọ́nà tí àpilẹ̀kọ náà pèsè—pa pọ̀ mọ́ àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ti ẹ yọ lò láti inú Bíbélì—mo lè pinnu ohun tí ó tọ́ nísinsìnyí.
M. R., United States
Ìpèsè fún Àwọn Adití Mo dití, mo sì fọ́jú, mo sì fẹ́ẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ yín fún àpilẹ̀kọ náà, “Bíbá Àwọn Ènìyàn Sọ̀rọ̀ Pẹ̀lú Ọwọ́ Tí Ń Ṣàpèjúwe.” (April 8, 1996) Ó sọ nípa àwọn Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Àwọn Onídùnnú-Ayọ̀ Olùyìn” ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, níbi tí wọ́n ti lo èdè àwọn adití. Ó fún mi níṣìírí pé ọ̀pọ̀ àwọn afọ́jú, tí wọ́n tún yadi, ló wà níbẹ̀. Mo dúpẹ́ púpọ̀ lọ́wọ́ àwọn tí wọ́n ṣògbufọ̀ ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọpọ̀ náà fún mi nígbà tí a ṣe àpéjọpọ̀ wa níhìn-ín ní December 1995. N kò kẹ́kọ̀ọ́ bí a ṣe ń ka ìwé àwọn afọ́jú rí, nítorí náà, mo ti kọ́ ẹsẹ Bíbélì 121 sórí, kí n lè máa wàásù fún àwọn ẹlòmíràn. Ó jẹ́ ìfẹ́ ọkàn mi láti rí ìmúṣẹ ìlérí Ọlọ́run nínú Aísáyà 35:5, 6, tí ó sọ nípa adití tí ń gbọ́ràn àti odi tí ń sọ̀rọ̀. Mo fẹ́ kí n lè kọrin ìyìn sí Jèhófà nínú Párádísè tí ń bọ̀!
A. F. A., Ajẹntínà