ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 1/8 ojú ìwé 16-20
  • Ilé Ìgbọ́únjẹ Lè Gbádùn Mọ́ni

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ilé Ìgbọ́únjẹ Lè Gbádùn Mọ́ni
  • Jí!—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kíkẹ́kọ̀ọ́ Nínú “Iyàrá Ìkẹ́kọ̀ọ́” Ilé Ìgbọ́únjẹ
  • Gbígbọ́únjẹ Ń Gbádùn Mọ́ni!
  • Ìṣọ̀kan Ìdílé
  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
    Jí!—1997
  • 2. Jẹ́ Onímọ̀ọ́tótó
    Jí!—2012
  • Kọ́ Ọmọ Rẹ Láti Ìgbà Ọmọdé Jòjòló
    Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé
  • Bẹ́ Ẹ Ṣe Lè Dáàbò Bo Àwọn Ọmọ Yín
    Jí!—2007
Àwọn Míì
Jí!—1997
g97 1/8 ojú ìwé 16-20

Ilé Ìgbọ́únjẹ Lè Gbádùn Mọ́ni

“MÁ ṢE wọ ilé ìgbọ́únjẹ!” Ọ̀pọ̀ ọmọdé tí ebi ń pa ti gba ìkìlọ̀ yẹn nígbà tí wọ́n bá ń gbìyànjú láti lọ jẹ oúnjẹ kí a tó bù ú fún wọn. Bí ó ti wù kí ó rí, dípò ṣíṣàìjẹ́ kí wọ́n máa wọ ilé ìgbọ́únjẹ, ìdí rere wà fún àwọn òbí láti ké sí àwọn ọmọ wọn wá síbẹ̀. Èé ṣe tó fi jẹ́ bẹ́ẹ̀? Nítorí pé, ó ṣe kedere pé ilé ìgbọ́únjẹ jẹ́ iyàrá ìkẹ́kọ̀ọ́ tí ó gbádùn mọ́ni.

Ilé ìgbọ́únjẹ jẹ́ ibi tí àwọn ọmọ ti lè mú òye ìdánúṣe àti ti yíyanjú ìṣòro dàgbà, ibi tí wọ́n ti lè kọ́ bí a ṣe ń ṣiṣẹ́ sin àwọn ẹlòmíràn, kí a sì ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí apá kan agbo òṣìṣẹ́, ibi tí ìjíròrò tí ó mọ́yán lórí, tí ń wọni lọ́kàn ti lè jáde látọkànwá, ibi tí a ti lè gbin àwọn ìlànà tí a fọwọ́ ìjẹ́pàtàkì mú síni lọ́kàn láìsí ariwo. Bẹ́ẹ̀ ni, nígbà tí a bá wà nínú ilé ìgbọ́únjẹ, ọ̀pọ̀ ohun tí ó mọ́yán lórí ni a lè kọ́ kí a sì fi sílò nígbà tí a bá ń gbọ́ oúnjẹ tí ó kàn.

Ní sànmánì onímọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ àti ìgbésọfúnni-kiri yìí, èé ṣe tí a fi ń lo ilé ìgbọ́únjẹ láti dá àwọn ọmọ lẹ́kọ̀ọ́? Ìdáhùn náà ni àkókò. Ọ̀pọ̀ òbí mọ̀ pé kò wulẹ̀ sí àfidípò lílo àkókò—tí ó pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ!a Ìṣòro náà ni ibi tí a ti lè rí i. Àwọn ògbógi kan rọ àwọn òbí láti yẹ iṣẹ́ àṣetúnṣe tí wọ́n ń ṣe ní ilé wò gẹ́gẹ́ bí àǹfààní láti ṣe nǹkan pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn, kí wọ́n sì kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́. Èyí wà ní ìbámu pẹ̀lú òfin kan tí Ọlọ́run fún àwọn òbí ní orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ìgbàanì pé: “Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, tí mo pa láṣẹ fún ọ ní òní, kí ó máa wà ní àyà rẹ: Kí ìwọ kí ó sì máa fi wọ́n kọ́ àwọn ọmọ rẹ gidigidi, kí ìwọ kí ó sì máa fi wọ́n ṣe ọ̀rọ̀ í sọ nígbà tí ìwọ bá jókòó nínú ilé rẹ, àti nígbà tí ìwọ bá ń rìn ní ọ̀nà, àti nígbà tí ìwọ bá dùbúlẹ̀, àti nígbà tí ìwọ bá dìde.”—Diutarónómì 6:6, 7.

Nítorí pé a ní láti máa lo àkókò déédéé nínú ilé ìgbọ́únjẹ lọ́nàkọnà, yóò dà bí ibi tí a ti lè ṣàjọpín ìgbòkègbodò ìdílé. Láìdàbí àwọn àkànṣe ìjádelọ, tí ó sábà ní láti gbélẹ̀ títí a óò fi ní àkókò, agbára, tàbí owó láti ṣètò fún un, ìyánnú fún oúnjẹ lọ́nà títọ́ kò jẹ́ gbà kí a gbé òun sílẹ̀ dìgbà míràn. Yàtọ̀ sí ìyẹn, ilé ìgbọ́únjẹ máa ń fa àwọn ọmọdé mọ́ra lọ́nà àdánidá. Ó ṣe tán, ibo ni a ti tún ń kọ́ wọn bí a ṣe ń lo ọ̀bẹ tìṣọ́ratìṣọ́ra àti bí a ṣe ń lo àwọn ohun èèlò ìgbọ́únjẹ mìíràn? Àwọn ọmọdé tí wọ́n ń ṣeré lè dá ìṣòro sílẹ̀ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan! Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, àwọn ẹ̀kọ́ wo ni a lè rí kọ́ ní ilé ìgbọ́únjẹ?

Kíkẹ́kọ̀ọ́ Nínú “Iyàrá Ìkẹ́kọ̀ọ́” Ilé Ìgbọ́únjẹ

Louise Smith—tí àwọn ọmọ ọlọ́dún mẹ́rin tí ó ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ mọ́ sì Olùṣekéèkì Atalẹ̀ Tó Ládùn—sọ ọ̀rọ̀ tí a gbé karí ìrírí tí ó ti ní fún ọdún 17 tí ó ti ń kọ́ àwọn ọmọdé ní bí a ṣe ń gbọ́únjẹ pé: “Oúnjẹ jẹ́ ohun ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ tí ó dára jù lọ nítorí pé ohun tí gbogbo ọmọdé lóye ni. Agbára ìgbóòórùn, ìtọ́wò, àti ìfọwọ́kàn wọ́n máa ń hára gàgà gan-an nígbà ọmọdé débi pé wọ́n máa ń fara fún un pátápátá. O sì lè kọ́ wọn ní ìró èdè, ìṣirò, àti awọn òye iṣẹ́ atánṣòro nípaṣẹ̀ oúnjẹ.” Dída nǹkan, gígún nǹkan, bíbẹ nǹkan, jíjọ nǹkan, ríro nǹkan, àti lílọ nǹkan ń ran àwọn ọmọdé lọ́wọ́ láti mú òye ìfọwọ́ṣiṣẹ́ àti ìṣiṣẹ́pọ̀ ojú òun ọwọ́ dàgbà. Ṣíṣa nǹkan (yíyọ àwọn èso oníwóóníṣu sọ́tọ̀ kúrò lára hóró) àti títo nǹkan ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ (kíki àwọn ife ìwọnǹkan bọnú ara wọn létòlétò) ń kọ́ni ní èròǹgbà tí ń ṣiṣẹ́ bí ìpìlẹ̀ fún kíkẹ́kọ̀ọ́ ìṣirò. Títẹ̀lé ìtọ́ni inú ìlànà ìgbọ́únjẹ kan jẹ́ ìdánrawò nínú ìlò nọ́ńbà, ìwọ̀n, wíwo àkókò, ríronú lọ́nà ṣíṣe sàn-án, àti èdè. Ẹnì kan kò sì lè dáwọ́ lé ọ̀ràn nípa ilé ìgbọ́únjẹ tí ó díjú, tí ó sì kún fún ewu, láìkọ́ ohun kan nípa ààbò, ẹrù iṣẹ́, ìwàlétòlétò, àti ìjùmọ̀ṣiṣẹ́.

A kò tún ní gbójú fo ìjẹ́pàtàkì kíkọ́ bí a ṣe ń gbọ́únjẹ dá. Kò ṣàìwọ́pọ̀ pé kí àwọn ọmọ tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ nípa ṣíṣèrànwọ́ ní ilé ìgbọ́únjẹ lè se gbogbo oúnjẹ nígbà tí wọ́n bá máa fi dàgbà di àwọn ọdún ìbàlágà wọn. Òbí tí ọwọ́ rẹ̀ dí wo ni kò ní fẹ́ ìyẹn lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan? Síwájú sí i, gbígbọ́únjẹ ń ran àwọn èwe lọ́wọ́ láti mú ìgbọ́kànlé àti ẹ̀mí ohun-moní-tó-mi dàgbà—tí ó jẹ́ àwọn ànímọ́ tí ó lè ṣàǹfààní fún wọn nígbà tí wọ́n bá tẹ́rí gba àwọn ẹrù iṣẹ́ àgbàlagbà, yálà wọ́n ṣègbéyàwó tàbí wọ́n ń bá a lọ ní ipò àpọ́n.—Fi wé Tímótì Kíní 6:6.

Lee, tí ó ń bá a lọ ní ipò àpọ́n títí ó fi lé díẹ̀ ní ẹni 30 ọdún, rántí pé: “Ìyá mi ti bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ mi ní àwọn iṣẹ́ oúnjẹ gbígbọ́ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ láti ìgbà tí mo ti wà ní nǹkan bí ọmọ ọdún mẹ́fà. Lákọ̀ọ́kọ́, mo nífẹ̀ẹ́ sí ṣíṣe bisikíìtì, kéèkì, àti àwọn ohun dídùn míràn. Ṣùgbọ́n ní ìgbà tí mo pé ọmọ ọdún mẹ́sàn-án, mo ti lè wéwèé, kí n sì gbọ́ oúnjẹ gbogbo ìdílé wa, mo sì máa ń ṣe é déédéé. Nígbà tó yá, gẹ́gẹ́ bí àpọ́n, mo wá mọ̀ pé mímọ bí a ṣe ń ṣe onírúurú iṣẹ́ ilé, títí kan oúnjẹ gbígbọ́, mú kí ìgbésí ayé túbọ̀ rọrùn. N óò sì sọ ní pàtó pé èyí tí fi kún gbígbádùn tí mo ń gbádùn ìgbéyàwó tí ó kẹ́sẹ járí.”

Gbígbọ́únjẹ Ń Gbádùn Mọ́ni!

Báwo ni òbí kan ṣe lè wá àkókò láti dá àwọn ọmọ lẹ́kọ̀ọ́ ní ilé ìgbọ́únjẹ? Ìyá kan dámọ̀ràn ṣíṣètò àkókò sí ìgbà tí ìpínyà ọkàn bá mọ níwọ̀n. Bí o bá ní ọmọ púpọ̀, o lè fẹ́ láti ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú ọmọ kan lákòókò tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ nípa ilé ìgbọ́únjẹ. Láti ṣe èyí, yan àkókò tí àwọn ọmọ yòó kù ń rẹjú tàbí nígbà tí wọ́n bá wà nílé ẹ̀kọ́. Wéwèé láti lo àkókò púpọ̀ ju ìgbà tí o bá ń dá gbọ́únjẹ. Sì múra láti jẹ́ kí ilé ìgbọ́únjẹ gbádùn mọ́ni!

Fún àkókò tí ẹ óò kọ́kọ́ lò, o lè jẹ́ kí ọmọ rẹ yan ohun tí ó fẹ́ràn láti máa jẹ. Wá ìlànà ìgbọ́únjẹ tí ó rọrùn, tí ó sì tètè ń mú àwọn àbájáde wá. Rí i dájú pé ó ní àwọn iṣẹ́ òpò tí ọmọ náà lè ṣe yanjú nínú. Láti jẹ́ kí ara ọmọ rẹ balẹ̀, kí ó má sì sú u, jẹ́ kí ó ti wá àwọn èròjà àti ohun èlò ìgbọ́únjẹ tí ẹ nílò ṣáájú àkókò. O tilẹ̀ lè ṣètò díẹ̀ lára àwọn èròjà náà ṣáájú àkókò kí ẹ má baà pẹ́ jù, kí ó má sì sú u.

Ka ìlànà ìgbọ́únjẹ náà pẹ̀lú ọmọ rẹ, kí o sì fi bí yóò ṣe ṣe òpò kọ̀ọ̀kan hàn án. Fún ọmọ rẹ ní àyè tirẹ̀ nínú ilé ìgbọ́únjẹ—bóyá ibi ìkóǹkansí kan tí ó ní àwọn àwo kòtò àti ohun èèlò ìgbọ́únjẹ bíi mélòó kan nínú—kí o sì fún un ní aṣọ ìgbọ́únjẹ kan. Dípò jíjẹ́ kí ọmọdékùnrin wọ aṣọ ìgbọ́únjẹ ti obìnrin, o lè wá èyí tí wọ́n rán fún ọkùnrin fún un. Láti ìbẹ̀rẹ̀, tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì ààbò, sì gbé àwọn òfin tí ó bọ́gbọ́n mu kalẹ̀ fún ilé ìgbọ́únjẹ.—Wo àpótí tí a fún ní àkọlé “Ẹ̀kọ́ Àkọ́kọ́—Ààbò,” ojú ìwé 18.

Lékè gbogbo rẹ̀, gbìyànjú láti jẹ́ kí ó gbádùn mọ́ni. Má ṣe jẹ́ kí ọmọ rẹ wulẹ̀ máa wò ọ́; jẹ́ kí o fọ ọwọ́ rẹ̀, kí wọ́n má dilẹ̀ nínú gbígbọ́ oúnjẹ náà gan-an. Fún un láǹfààní láti ṣàwárí, kí ó ṣàyẹ̀wò, kí ó sì béèrè àwọn ìbéèrè. Bí kò bá sì gbọ́únjẹ kan dáradára tó, má ṣe dààmú. Bí ọmọ rẹ bá gbọ́únjẹ náà fúnra rẹ̀, ó ṣeé ṣe kí ó jẹ ẹ́ lọ́nàkọnà!

Ìṣọ̀kan Ìdílé

Láìsí àníàní, àwọn àǹfààní gíga jù lọ tí yóò wá láti ilé ìgbọ́únjẹ kan ìṣọ̀kan àti ìjẹ́pàtàkì ìdílé. O lè ti ṣàkíyèsí pé ní àwọn agbo ilé kan lónìí, àwọn mẹ́ńbà ìdílé máa ń gbájú mọ́ ìgbòkègbodò wọn lọ́tọ̀ọ̀tọ̀ láìsí àjọṣe gidi kan pẹ̀lú ẹnì kíní kejì wọn. Lábẹ́ irú ipò bẹ́ẹ̀, ilé lè wá di ibi ìsinmi ráńpẹ́, tí a ti ń yára jẹun, tí a óò sì kúrò níbẹ̀. Ní ìyàtọ̀ sí èyí, ó ṣeé ṣe gan-an kí ìdílé tí ń gbọ́únjẹ pọ̀ máa jẹun pọ̀, kí wọ́n sì jùmọ̀ fọ àwọn abọ́. Àwọn ìgbòkègbodò yí ń fún wọn ní àǹfààní déédéé láti jùmọ̀ sọ̀rọ̀ pọ̀, láti jùmọ̀ ṣe pọ̀, kí wọ́n sì máa kàn sí ara wọn. Ìyá kan rántí pé: “Ibi ìfọbọ́ ní ilé ìgbọ́únjẹ ni mo ti máa ń bá àwọn ọmọkùnrin mi sọ ọ̀rọ̀ tí ó mọ́yán lórí jù.” Hermann, bàbá kan tí ó jẹ́ Kristẹni, sì fi kún un pé: “A mọ̀ọ́mọ̀ wà láìní ẹ̀rọ ìfọbọ́ fún ọ̀pọ̀ ọdún, kí a baà lè máa fi ọwọ́ fọbọ́, kí á sì máa nù wọ́n. A máa ń yanṣẹ́ fún àwọn ọmọkùnrin wa láti máa nù wọ́n, lẹ́nì kan tẹ̀ lé òmíràn. Kò sí àkókò tí ó sàn ju ìyẹn lọ fún ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ tí a kò wéwèé ṣáájú.”

Bẹ́ẹ̀ ni, àkókò tí o ń lò ní ilé ìgbọ́únjẹ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ—látọ̀sẹ̀dọ́sẹ̀, látọdúndọ́dún—ń pèsè ìpìlẹ̀ tí a ti lè mú ìjẹ́pàtàkì tẹ̀mí àti àwọn ànímọ́ oníwà-bí-Ọlọ́run dàgbà. Ní irú àwọn àkókò ìṣọ̀kan ìdílé tí ara silẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni ìjíròrò àtọkànwá láàárín òbí àti ọmọ lè wáyé wẹ́rẹ́ àti pé ipá ìdarí àpẹẹrẹ òbí lè ní ipa lórí ọkàn àyà ọmọ. Irú ìdánilẹ́kọ̀ọ́ bẹ́ẹ̀ lè ṣe ọmọ kan láǹfààní títí gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀, nítorí pé Òwe 22:6 sọ pé: “Tọ́ ọmọdé ní ọ̀nà tí yóò tọ̀: nígbà tí ó sì dàgbà tán, kì yóò kúrò nínú rẹ̀.”

Nítorí náà, bí ìwọ gẹ́gẹ́ bí òbí bá ń wá ọ̀nà láti lo àkókò púpọ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ, èé ṣe tí o kò ké sí wọn láti wá ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣe kéèkì tàbí odindi oúnjẹ? O lè rí i pé ṣíṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú wọn nínú ilé ìgbọ́únjẹ jẹ́ ọ̀nà láti bọ́ ìdílé rẹ, kí o sì fún wọn ní àbójútó.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Fún ìjíròrò lórí kókó yìí, wo ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà, “‘Ojulowo Akoko’ Ti A Funni Ní Ìwọ̀n Líláàlà,” nínú Jí!, ìtẹ̀jáde May 22, 1993, ojú ewé 16 sí 17.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 18]

Ẹ̀kọ́ Àkọ́kọ́—Ààbò

Wà Lójúfò Nípa Ààbò

• Ní ọ̀nà tí ó gba èrò ṣùgbọ́n tí kò páni láyà, ṣàlàyé àwọn ewu tí ó wà nínú ṣíṣiṣẹ́ ní ilé ìgbọ́únjẹ, lọ́nà kan náà tí ìwọ yóò gbà ṣàlàyé àwọn ewu ètò ìrìnnà ọkọ̀ lójú òpópó tí ọkọ̀ kún fọ́fọ́. Ìwọ pẹ̀lú ní láti fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀.

• Gẹ́gẹ́ bí àgbàlagbà, máa ṣe àbójútó nígbàkigbà tí àwọn ọmọ bá ń ṣiṣẹ́ ní ilé ìgbọ́únjẹ. Má ṣe gbà kí ọmọ kan lo ohun èlò ìgbọ́únjẹ tàbí ohun èlò èyíkéyìí, ní pàtàkì ohun abánáṣiṣẹ́, títí di ìgbà tí yóò lè lò ó láìséwu.

• Jẹ́ kí ilé ìgbọ́únjẹ rẹ wà létòlétò. Nu àwọn ohun tí ó bá ta sílẹ̀, kí o sì kó àwọn ẹrù wúruwùru kúrò ní kánmọ́. Àwọn ohun ọ̀sìn ilé àti àwọn ohun tí ó lè pín ọkàn níyà míràn ni ẹ gbọ́dọ̀ kó kúrò ní ilé ìgbọ́únjẹ nígbà tí ẹ bá ń gbọ́únjẹ lọ́wọ́.

Dáàbò Bo Ìka

• Àwọn ẹ̀rọ ìpoǹkanpọ̀ oníná, ẹ̀rọ ìlọǹkan, àti ẹ̀rọ ìgbọ́únjẹ ni a gbọ́dọ̀ lò kìkì nígbà tí àgbàlagbà kan bá ń bójú tó wọn. Rí i dájú pé ẹ paná ohun èlò náà, ẹ sì yọ ọ́ nínú iná, kí ọmọ rẹ tóó ki ṣíbí bọ inú àwo kòtò ohun èlò náà.

• Pọ́n àwọn ọ̀bẹ, níwọ̀n bí ọ̀bẹ tí ó ku ti nílò agbára, èyí sì lè mú kí ó yọ̀.

• Nígbà tí ọmọ rẹ bá ń kọ́ bí a ṣe ń lo ọ̀bẹ jẹun, jẹ́ kí ó tẹ̀ lé ìgbésẹ̀ yí: (1) mú èèkù ọ̀bẹ náà dání, (2) gbé ọ̀bẹ lé oúnjẹ náà, (3) gbé ọwọ́ kejì lé ẹ̀yìn ọ̀bẹ náà, àti (4) lo agbára láti gé oúnjẹ náà.

• Lo pátákó ìgéǹkan. Láti má ṣe jẹ́ kí ewébẹ̀ máa dà nù sílẹ̀ nígbà tí ọmọ rẹ bá ń gbìyànjú láti gé wọn, kọ́kọ́ gé wọn sí ààbọ̀, kí o sì tò wọ́n sórí pátákó ìgéǹkan.

Ṣọ́ra fún Ìfọwọ́jóná

• Máa yí iná sítóòfù àti ibi ìyan-ǹkan pa tí ẹ kò bá lò wọ́n. Kó àwọn tówẹ̀ẹ̀lì, ìwé ìlànà ìgbọ́únjẹ, àti iga ìgbékaná kúrò lórí ibi tí iná ti ń jó.

• Yí ọwọ́ àwọn páànù sí ìhà àárín sítóòfù, níbi tí a kò ti ní lè tètè ta lù wọ́n, kí nǹkan sì ta dà nù.

• Bí o bá jẹ́ kí ọmọ rẹ ṣiṣẹ́ lórí sítóòfù, rí i dájú pé ibi tí ó dúró sí le, ó sì fìdí múlẹ̀.

• Má ṣe gbé nǹkan gbígbóná, àyàfi bí ó bá ti mọ ibi tí o fẹ́ láti gbé e sí. Rí i dájú pé àwọn mìíràn tí wọ́n wà nínú ilé ìgbọ́únjẹ mọ ìgbà tí o bá gbé nǹkan gbígbóná, ní pàtàkì bí o bá fẹ́ẹ́ gba ẹ̀yìn wọn.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́