ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 2/22 ojú ìwé 28-29
  • Wíwo Ayé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wíwo Ayé
  • Jí!—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Ríran Àwọn Adití Lọ́wọ́ ní Áfíríkà
  • Fọ Ọwọ́ Rẹ!
  • Rẹ́rìn-ín, Kí Ẹ̀mí Rẹ Sì Gùn Kẹ̀?
  • Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì Nínú “Àkókò Ewu” Kan
  • Ìtẹ̀síwájú Nípa Bíbojúwẹ̀yìn
  • Ẹja Dolphin Ń Dáàbò Bo Ìwàláàyè
  • Ara Olúwa “Nínú Ike”
  • Àwọn Ẹyẹlé Tí Ń Wọkọ̀
  • Ìpínlẹ̀ Australia Fòfin Gbe Fífikú Bàṣírí Olókùnrùn Lẹ́yìn
  • Wọ́n Yí Ṣọ́ọ̀ṣì Pa Dà
Jí!—1997
g97 2/22 ojú ìwé 28-29

Wíwo Ayé

Ríran Àwọn Adití Lọ́wọ́ ní Áfíríkà

Ìwé ìròyìn Ẹgbẹ́ Àwọn Adití Orílẹ̀-Èdè Uganda (UNAD) sọ pé: “Ìwé ìròyìn UNAD NEWS gbóríyìn fún ọkàn ìfẹ́ àìmọtara-ẹni àti ìsapá Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti kọ́ èdè àwọn adití.” Ìwé ìròyìn náà sọ pé àwùjọ Àwọn Ẹlẹ́rìí tí kò dití ní Kampala, Uganda, ti ń kọ́ èdè àwọn adití kí wọ́n lè pèsè àbójútó tẹ̀mí fún àwọn ènìyàn tí wọ́n ní ìṣòro etí ní orílẹ̀-èdè náà. Ìròyìn náà fi kún un pé, àwọn ògbufọ̀ tí ó ṣeé gbára lé méjì “jẹ́ aṣáájú ọ̀nà déédéé tàbí [àwọn òjíṣẹ́] alákòókò kíkún nínú ọ̀kan lára àwọn ìsìn tí ń yára gbèrú, tí a sì bọ̀wọ̀ fún jù lọ lágbàáyé, tí a mọ̀ kárí ayé nítorí ìrọ̀tímọ́tímọ́ rẹ̀ mọ́ àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì.”

Fọ Ọwọ́ Rẹ!

Ìwé agbéròyìnjáde The New York Times ròyìn pé, Ẹgbẹ́ Àwọn Ẹlẹ́kọ̀ọ́ Ohun Alààyè Tí Kò Ṣeé Fojú Lásán Rí ní America ṣonígbọ̀wọ́ ìwádìí kan láìpẹ́ yìí láti fi mọ iye ènìyàn tí ń fọ ọwọ́ wọn lẹ́yìn tí wọ́n bá lo ilé ìtura ará ìlú. Ó ṣe kedere pé, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo wọn ló mọ̀ pé ó yẹ kí wọ́n fọ ọwọ́ wọn. Nínú ìwádìí orí tẹlifóònù kan láàárín 1,004 àgbàlagbà, ìpín 94 nínú ọgọ́rùn-ún sọ pé àwọn máa ń fọ ọwọ́ àwọn ní gbogbo ìgbà tí àwọn bá lo ilé ìtura ará ìlú. Ṣùgbọ́n, ǹjẹ́ wọn ń ṣe bẹ́ẹ̀? Àwọn olùwádìí tí ń ṣàkíyèsí ohun tí ń lọ ní àwọn ilé ìtura ní ìlú ńlá márùn-ún nílẹ̀ America rí i pé, láàárín 6,333 ènìyàn, ìpín 61 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọkùnrin àti ìpín 74 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn obìnrin péré ní ń fọ ọwọ́ wọn lẹ́yìn tí wọ́n bá lo ilé ìtura náà. Àwọn ọwọ́ dídọ̀tí ń yára tan àrùn kálẹ̀, òṣìṣẹ́ ilé àrójẹ kan ṣoṣo péré tí kò fọ ọwọ́ rẹ̀ sì lè sọ ọ̀pọ̀ ènìyàn di olókùnrùn. Apá kan ìṣòro náà lè jẹ́ àìsí ìdarí àwọn òbí. Dókítà Gail Cassell sọ pé: “Àwọn mọ́mì òde òní kì í sábà sọ fún àwọn ọmọ wọn pé kí wọ́n fọ ọwọ́ wọn. A kì í sọ fún àwọn ọmọ nípa rẹ̀ nílé ẹ̀kọ́. Ó yẹ kí a rán ara wa létí pé èyí ṣe pàtàkì.”

Rẹ́rìn-ín, Kí Ẹ̀mí Rẹ Sì Gùn Kẹ̀?

Ó pẹ́ tí a ti gbà gbọ́ pé ẹ̀rín rírín jẹ́ egbòogi dáradára kan. Lọ́dún mẹ́wàá sẹ́yìn, àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ní Yunifásítì Ìpínlẹ̀ ní New York pinnu láti mọ ìdí tí ó fi rí bẹ́ẹ̀. Láìpẹ́ yìí, wọ́n ṣí àwárí wọn payá pé ẹ̀rín máa ń mú kí àwọn omi ìsúnniṣe lílágbára tí ń fún agbára ìgbóguntàrùn ènìyàn kan lágbára tú jáde. A ti rí i pé ìsọ̀wọ́ àwọn omi ìsúnniṣe kan tí ń jẹ́ cytokine máa ń ṣagbátẹrù akitiyan àwọn sẹ́ẹ̀lì ẹ̀jẹ̀ funfun tí a nílò láti darí àwọn àrùn tí fáírọ́ọ̀sì òun bakitéríà ń fà kúrò lára, tí ó sì tún ń pa àwọn sẹ́ẹ̀lì tí ó ṣeé ṣe kí wọ́n di alárùn jẹjẹrẹ. Ìwé agbéròyìnjáde The Sunday Times ti London sọ pé, ìwọ̀nyí wulẹ̀ jẹ́ “ọ̀kan lára àwọn èròjà tí ẹ̀rín ń sọ di púpọ̀ nínú ẹ̀jẹ̀.” Ìsopọ̀ tí ń bẹ láàárín ẹ̀rín àti omi ìsúnniṣe cytokine ti mú kí àwọn olùwádìí kan máa pè é ní omi ìsúnniṣe aláyọ̀. Nípa bẹ́ẹ̀, ìwé agbéròyìnjáde náà pe ẹ̀rín ní “ìgbésẹ̀ ẹ̀mí gígùn.”

Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì Nínú “Àkókò Ewu” Kan

Ìwé agbéròyìnjáde Star-Telegram ti Arlington, Texas, sọ pé, ìwé kan tí àwùjọ àwọn ènìyàn kan tí ó ní bíṣọ́ọ̀bù méje nínú kọ jáde ṣàpèjúwe Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó wà nínú “àkókò ewu” kan. Ìwé agbéròyìnjáde náà sọ pé ìwé ọ̀hún “rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí ṣọ́ọ̀ṣì náà pé kí ó ṣèwòsàn àwọn ìpínyà gidigidi tí ó wà nínú rẹ̀.” Ìwádìí èròǹgbà àwọn ènìyàn fi hàn pé, ọ̀pọ̀ lára 60 mílíọ̀nù àwọn Kátólíìkì ní United States kò fara mọ́ àwọn ẹ̀kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì bíi wíwà láìgbéyàwó àwọn àlùfáà àti fífi òfin de ìfobìnrinjoyè. Níbi ìpàdé pẹ̀lú àwọn oníròyìn tí wọ́n ti gbé ìwé náà jáde, olóògbé kádínà Joseph Bernardin sọ àníyàn rẹ̀ jáde nípa “ìpínsọ́tọ̀ọ̀tọ̀ tí ń pọ̀ sí i nínú ṣọ́ọ̀ṣì náà àti, lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ìmọtara-ẹni-nìkan lílágbára” tí ń ṣèdíwọ́ fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ ṣọ́ọ̀ṣì náà. Ó wí pé: “Gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí rẹ̀, ìṣọ̀kan ṣọ́ọ̀ṣì náà wà nínú ewu. Àwọn olóòótọ́ mẹ́ńbà ṣọ́ọ̀ṣì náà ń káàárẹ̀, a sì ń fi ẹ̀rí wa níwájú ìjọba, ẹgbẹ́ àwùjọ ènìyàn àti àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ báni dọ́rẹ̀ẹ́.”

Ìtẹ̀síwájú Nípa Bíbojúwẹ̀yìn

Ṣáájú àwọn ẹ̀rọ rédíò, àwọn túùbù oníhò ṣíṣófo ti wà. Ní báyìí, àwọn olùwádìí ń bojú wẹ̀yìn. Onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ohun àdánidá, Griff L. Bilbro, ti Yunifásítì Ìpínlẹ̀ Àríwá Carolina, sọ pé: “A ń ṣàtúnyẹ̀wò àwọn túùbù oníhò ṣíṣófo tí a lò ní àwọn ọdún 1940. Ṣùgbọ́n nísinsìnyí, a ń lo àwọn èròjà tuntun àti àwọn ohun èlò ìṣiṣẹ́ ẹ̀rọ kọ̀ǹpútà láti pinnu bí wọn yóò ti ṣe sí ní ìwọ̀n ìyára gíga, kí a lè lò wọ́n nínú àwọn fóònù onírédíò àti alágbèérìn.” Ìyàtọ̀ kan láàárín àwọn túùbù àtijọ́ àti tuntun ni ìtóbi wọn. Àwọn túùbù tuntun náà kéré, wọ́n sì wà ní ìtòjọ bí orí ìṣáná. Ìwé ìròyìn Science News sọ pé, “àwọn electrode ni a ń sé mọ́ inú dáyámọ́ńdì, tí a wá ń fẹ́ afẹ́fẹ́ náà kúrò nínú wọn. Ìyàtọ̀ ńlá kan láàárín àwọn túùbù oníhò onídáyámọ́ńdì tuntun náà àti àwọn onígíláàsì ńláńlá ti 50 ọdún sẹ́yìn ni ooru. Àwọn túùbù àtijọ́ náà gbọ́dọ̀ gbóná, kí wọ́n pọ́n dẹ̀dẹ̀, kí wọ́n tó lè mú electron jáde. Àwọn túùbù tuntun ń mú agbára jáde ní ìwọ̀n ìgbóná inú iyàrá.” Láfikún sí pé àwọn túùbù tuntun náà lálòpẹ́ ju àwọn ohun èlò agbanámọ́ra tí kì í fi bẹ́ẹ̀ gbóná àti àwọn ègé pẹlẹbẹ agbanámọ́ra ti kọ̀ǹpútà lọ, wọ́n tún dára jù wọ́n lọ ní ti ìwọ̀n ìgbóná òun ìtutù, ìwọ̀n agbára iná tí wọ́n lè gbà mọ́ra, àti ìwọn agbára iná tí wọ́n lè mú jáde.

Ẹja Dolphin Ń Dáàbò Bo Ìwàláàyè

Ìtẹ̀jáde Journal of Commerce sọ pé, ó ṣeé ṣe kí àwùjọ àwọn ẹja dolphin kan ti gba ọkùnrin kan tí ń lúwẹ̀ẹ́ nínú Òkun Pupa là. Mark Richardson, láti Britain, ń lúwẹ̀ẹ́ létíkun ilẹ̀ Íjíbítì náà nígbà tí ẹja ekurá kan gbéjà kò ó. Lẹ́yìn tí ó ti bù ú jẹ lẹ́gbẹ̀ẹ́ àti lápá, àwọn ẹja dolphin onímú bí ìgò mẹ́ta yí i ká, wọ́n sì ń ju apá àti ìrù wọn láti lé ẹja ekurá náà lọ.” Àwọn ẹja dolphin náà wá “ń dòòyì ká Ọ̀gbẹ́ni Richardson títí tí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ fi wá ràn án lọ́wọ́.” Gẹ́gẹ́ bí àtẹ̀jáde Journal náà ṣe sọ, “irú ìṣesí bẹ́ẹ̀ wọ́pọ̀ láàárín àwọn ẹja dolphin nígbà tí àwọn ìyá bá ń dáàbò bo àwọn ọmọ wọn kéékèèké.”

Ara Olúwa “Nínú Ike”

Ìwé ìròyìn Christianity Today ròyìn pé, oníléeṣẹ́ ará America kan, Jim Johnson, ń ṣe àwọn sákírámẹ́ǹtì tí a dì sínú ike, láti lò fún ìsìn Gbígba Ara Olúwa ní ṣọ́ọ̀ṣì. Àwọn ife oníke kéékèèké elésè àlùkò náà, tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ ní ìwọ̀n ìtóbi àti ìrísí ohun ìkóǹkansí tí ó gba ife kọfí kan tán, ń ní omi èso grape tàbí wáìnì díẹ̀ nínú lápá kan. Wọ́n tún ń ní àkàrà aláìwú nínú lápá kejì. Gẹ́gẹ́ bí Johnson ṣe sọ, ohun àṣejáde náà ṣàǹfààní ní ti pé ó ṣeé yára ṣe kí a sì yára palẹ̀ rẹ̀ mọ́, kò gbówó lórí gọbọi, ó sì ní ìmọ́tótó. Ó lé ní 4,000 ṣọ́ọ̀ṣì tí ó ti ń lo ohun àṣejáde tuntun yìí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ènìyàn ti ń ráhùn lórí “ṣíṣe ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ” Ara Olúwa jáde yìí. Johnson ṣàtakò pé: “Jésù pèsè oúnjẹ àsáréṣe kìíní nígbà tí ó bọ́ àwọn ògìdìgbó.”

Àwọn Ẹyẹlé Tí Ń Wọkọ̀

Ìwé ìròyìn New Scientist sọ pé, àwọn ènìyàn ti ṣàkíyèsí tipẹ́ pé àwọn ẹyẹlé ń wọkọ̀ abẹ́lẹ̀ lọ́fẹ̀ẹ́ ní London. Láfikún sí i, àwọn ènìyàn kan sọ pé àwọn ẹyẹ náà tilẹ̀ mọ ibùdókọ̀ tí ó yẹ kí wọ́n ti sọ̀. Ní ìdáhùn sí ìkésíni kan láti ọ̀dọ̀ ìwé ìròyìn náà, àwọn òǹkàwé mélòó kan kọ̀wé ránṣẹ́ lórí àwọn ìrírí tiwọn fúnra wọn nípa àwọn arìnrìn-àjò abìyẹ́ náà. Bí àpẹẹrẹ, ọkùnrin kan kọ̀wé pé: “Láàárín 1974 sí 1976, mo ń bá ẹyẹlé aláwọ̀ pupa fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ kan pàdé, tí ó máa ń wọkọ̀ abẹ́lẹ̀ láti Paddington, tí ó sì ń sọ̀ ní ibùdókọ̀ tí ó tẹ̀ lé e.” Ọkùnrin mìíràn kan ṣàkíyèsí ohun jíjọra kan lẹ́yìn lọ́hùn-ún ní 1965. Ó jọ pé àwọn ẹyẹlé ti ń wọkọ̀ láìsanwó nínú ìṣètò ìwọkọ̀ London fún nǹkan bí 30 ọdún!

Ìpínlẹ̀ Australia Fòfin Gbe Fífikú Bàṣírí Olókùnrùn Lẹ́yìn

Ìwé agbéròyìnjáde The New York Times ròyìn pé, ọkùnrin kan ní Ẹkùn Ìpínlẹ̀ Àríwá Australia ni ẹnì kíní tí ó kú lábẹ́ òfin tuntun orílẹ̀-èdè náà tí ó fàyè gba ìpara-ẹni tí dókítà kúnni lọ́wọ́ ṣe. Ọkùnrin náà ti lé ní 60 ọdún, ó sì ní àrùn jẹjẹrẹ inú ẹṣẹ́ tí ń pèsè omi tí ń gbé sẹ́ẹ̀lì àtọ̀, tí a kà sí pé yóò pa á níkẹyìn. Dókítà Philip Nitschke, tí ó fún ọkùnrin náà ní èròjà barbiturate tí ó pọ̀ tó láti pa á, sọ pé: “Èyí ni ìgbà kíní tí ẹnì kan gba ẹ̀mí ara rẹ̀ lọ́nà tó bófin mu.” Nitschke ṣàlàyé pé: “Wọ́n so àwọn túùbù àti wáyà láti ara ẹ̀rọ kan mọ́ ara ọkùnrin náà, ó sì fún un láyè láti bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ ikú ara rẹ̀ nípa títẹ bọ́tìnnì kan lórí ẹ̀rọ kọ̀ǹpútà àgbélétan tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ bẹ́ẹ̀dì rẹ̀.” Bí ó ti wù kí ó rí, òfin tuntun náà ń kojú àtakò gbígbóná janjan. Ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin orílẹ̀-èdè náà ń ṣàgbéyẹ̀wò ṣíṣe òfin tí yóò pa òfin náà rẹ́, àwọn dókítà àti ṣọ́ọ̀ṣì kan sì ti ń pẹjọ́ lórí òfin ọ̀hún.

Wọ́n Yí Ṣọ́ọ̀ṣì Pa Dà

Gẹ́gẹ́ bí ìwé agbéròyìnjáde Dutch náà, Het Overijssels Dagblad, ṣe wí, nǹkan bí 300 ṣọ́ọ̀ṣì ní ilẹ̀ Netherlands ni wọ́n ti yí pa dà di ilé ìtajà ńlá, ilé ibùgbé, gbọ̀ngàn àfihàn, àti ilé ọ́fíìsì. Nítorí pé iye àwọn tí ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì ní Netherlands ti dín kù ní ìwọ̀n ìpín 50 nínú ọgọ́rùn-ún láàárín ọdún 15 tó kọjá, ó dùn mọ́ ọ̀pọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì nínú pé wọ́n rí ẹni ra àwọn ilé náà, tí ẹrù ìnáwó àbójútó sì kúrò léjìká wọn. Wọ́n ti ta àwọn ṣọ́ọ̀ṣì kan lówó pọ́ọ́kú, guilder kan (nǹkan bí 60 sẹ́ǹtì ilẹ̀ United States)! Bí ó ti wù kí ó rí, sísọ ṣọ́ọ̀ṣì àtijọ́ kan di ilé ìṣòwò ń fa ìrora ọkàn, ní pàtàkì, láàárín àwọn àgbàlagbà. Ìwé ìtọ́kasí kan sọ pé: “Wọ́n ti fi ọ̀pọ̀ ọdún lọ jọ́sìn níbẹ̀. Wọ́n ṣe batisí àti ìgbéyàwó níbẹ̀, wọ́n sì ń rí i nísinsìnyí tí àwọn ènìyàn ń ṣe àwọn nǹkan ṣákálá níbẹ̀ . . . kódà, tí wọ́n ń ṣépè.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́