Wíwo Ayé
Kádínà Ṣe Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Àlàyé Lórí Àwọn Ọ̀rọ̀ Póòpù
Ní àfikún sí ọ̀rọ̀ tí Póòpù John Paul sọ pé àbá èrò orí ẹfolúṣọ̀n “ju ọ̀rọ̀ àbá ìpìlẹ̀ lásán lọ,” Kádínà O’Connor ti New York ti dábàá pé ó ṣeé ṣe kí Ádámù àti Éfà ti jẹ́ “irú oríṣi ẹ̀dá mìíràn,” kì í ṣe ọkùnrin àti obìnrin. Gẹ́gẹ́ bí ìwé agbéròyìnjáde New York Daily News ṣe sọ ọ́, O’Connor wí pé: ‘Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì múra tán láti ṣàgbéyẹ̀wò àwọn àbájáde ìwádìí sáyẹ́ǹsì, ìyẹn sì rí bẹ́ẹ̀ ní ti ẹfolúṣọ̀n àwọn ohun alààyè.’ Nínú ìwàásù kan tí ó ṣe ní Kàtídírà Patrick Mímọ́, kádínà náà sọ pé: “Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ pé, nígbà tí a dá àwọn ẹni méjì tí a ń sọ̀rọ̀ nípa wọn gẹ́gẹ́ bí Ádámù àti Éfà, wọ́n jẹ́ irú oríṣi ẹ̀dá mìíràn, Ọlọ́run sì mí èémí ìyè sínú wọn, ó mí ọkàn kan sínú wọn—ìyẹn jẹ́ ìbéèrè kan, tí ó bá ìlànà sáyẹ́ǹsì mu.” Àkọlé ìròyìn kan nínú ìwé agbéròyìnjáde arọ̀mọ́pìlẹ̀ ti Ítálì náà, Il Giornale, sọ̀rọ̀ láìfi bọpobọyọ̀ pé: “Póòpù Wí Pé Ó Ṣeé Ṣe Kí Ènìyàn Jẹ́ Àtìrandíran Ọ̀bọ.”
Ìmọ̀ràn fún Póòpù
Akọ̀ròyìn ará Ítálì, tí ó tún jẹ́ ọmọ ìjọ Kátólíìkì náà, Vittorio Messori, gbà gbọ́ pé àwọn mẹ́ńbà alákòóso Ìjọ Kátólíìkì òde òní ti ń sọ̀rọ̀ jù. Ó dábàá pé kí wọ́n máa ‘pààlà ọ̀rọ̀ wọn, kí wọ́n sì máa ṣe ṣókí’ nínú ìhìn iṣẹ́ wọn. Nínú ìfọ̀rọ̀wáni-lẹ́nuwò kan tí ẹ̀ka ìròyìn Kátólíìkì náà, Adista, gbé jáde, ó wí pé: “Ìṣirò àsáréṣe kan fi hàn pé, ní gbogbo àyè, ọ̀rọ̀ tí ìjọ náà sọ láàárín 20 ọdún tó kọjá ju èyí tí ó ti sọ láàárín 20 ọ̀rúndún tó ṣáájú lọ. Bí ọ̀rọ̀ tí ẹnì kan ń sọ bá ṣe ń pọ̀ tó ni àwọn ènìyàn kì í ṣe fetí sí i tó. Mo ti dábàá ìsinmi ọlọ́dún méje kan, nínú èyí tí ìjọ náà kò gbọ́dọ̀ gbin pínkín, bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ olùrànlọ́wọ́ àlùfáà ìjọ àdúgbò títí dé ọ̀dọ̀ Póòpù. . . . Gbogbo àsọọ̀sọtán ọ̀rọ̀ àti àkọọ̀kọtán lẹ́tà sí àwọn bíṣọ́ọ̀bù wọ̀nyí . . . Mo ń kà wọ́n, ṣùgbọ́n ṣé àwọn tó kù ń ṣe bẹ́ẹ̀? A gbọ́dọ̀ pa dà sí àṣà àwọn póòpù ẹ̀wádún mélòó kan sẹ́yìn. Ó pọ̀ jù lọ, wọ́n ń kọ lẹ́tà mẹ́ta péré sí àwọn bíṣọ́ọ̀bù.”
Àwọn Amóríyá Tí Ń Pani
Fífo ìfò bungee, pípọ́nkè láìlo ohun èlò ìpọ́nkè, fífòbọ́ láti inú ọkọ̀ òfuurufú ní fífarapitú ṣáájú rírọ̀ mọ́ okùn, fífòbọ́sílẹ̀ láti ibi gíga fíofío ní rírọ̀mọ́ ṣóńṣó orí okùn kan—àwọn eré amóríyá—ti di olókìkí ní ilẹ̀ Faransé. Ìwé agbéròyìnjáde ti Paris náà, Le Monde, wádìí lórí ìdí tí àwọn eré amóríyá fi di olókìkí bẹ́ẹ̀ ní ilẹ̀ Faransé lọ́wọ́ àwọn ògbóǹkangí. Alain Loret, olùdarí ibùdó ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdásílẹ̀ eré ìdárayá, sọ pé, ìdí kan ni pé àwọn eré ìdárayá àbáláyé, pẹ̀lú àwọn òfin, ìbáwí, àti ìdánilẹ́kọ̀ọ́, tí wọ́n nílò, kò bá ohun tí àwọn èwe ìwòyí, tí wọ́n fi ìjẹ́pàtàkì sórí wíwà lómìnira àti ìmóríyá ju àìní fún ìbáwí lọ, kà sí pàtàkì mu mọ́. Gẹ́gẹ́ bí onímọ̀ ìbágbépọ̀-ẹ̀dá, tí ó tún jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Faransé náà, David Le Breton, ṣe wí, “gbígbilẹ̀ tí òkìkí eré ìdárayá líléwu púpọ̀ ń gbilẹ̀ sí i jẹ́ ìgbéyọ ìforígbárí tí ó wà láàárín àwọn ìhùwàsí tí a kà sí pàtàkì. Ní ti gidi, a kò mọ ohun tí a wà láàyè fún mọ́. Àwùjọ wa kò sọ fún wa pé ìwàláàyé tóyeyẹ fún gbígbé. Nítorí náà, wíwá ìmóríyá . . . ṣeé lóye bí ọ̀nà kan láti mú kí ìgbésí ayé nítumọ̀.” Bí ó ti wù kí ó rí, púpọ̀ sí i àwọn èwe ń fi ìwàláàyè wọn wewu, wọ́n sì ń pàdánù rẹ̀.
A Tún Ṣèbẹ̀wò sí Alẹkisáńdíríà Ìgbàanì
Lákọ̀ọ́kọ́, àwọn awalẹ̀pìtàn kéde pé wọ́n ti ṣàwárí Pharos, ilé iná atọ́nà àwọn atukọ̀ òkun, tí ọjọ́ orí rẹ̀ jẹ́ 2,200 ọdún, ọ̀kan nínú àwọn ohun ìyanu méje ti ayé ìgbàanì, nínú omi nítòsí Alẹkisáńdíríà, Íjíbítì. Nísinsìnyí, gẹ́gẹ́ bí ìwé agbéròyìnjáde The Vancouver Sun ṣe wí, wọ́n ní wọ́n ti rí “àwókù àgbàlá ti Alẹkisáńdíríà lábẹ́ omi tí ó jìn ní nǹkan bíi mítà mẹ́fà [20 ẹsẹ̀ bàtà] níhà ìlà oòrùn ògbólógbòó èbúté ti Alẹkisáńdíríà.” Gẹ́gẹ́ bí Franck Goddio, ọmọ ilẹ̀ Faransé, tí ń walẹ̀ abẹ́ omi fi pìtàn, ti sọ, wọ́n rí àwọn àwókù ilé àti tẹ́ńpìlì Mark Antony, àwọn ti ààfin Cleopatra, títí kan àwọn àgé wáìnì, àwọn òpó tí a fi akọ òkúta ṣe, àwọn títì olókùúta, àti àwọn àfọ́kù míràn láti inú ìlú ńlá ìgbàanì náà. Goddio sọ pé, àwọn olùwádìí náà rí “èbúté rírẹwà kan, tí a fi ògiri gígùn kan, tí kò bà jẹ́ lẹ́yìn 2,000 ọdún sé mọ́, ṣùgbọ́n tí ó wà lábẹ́ omi.” Wọ́n fi orúkọ ọba Alexander Ńlá, ẹni tí ó pinnu pé ibẹ̀ gbọ́dọ̀ jẹ ibùdó ìlú ńlá kan, nígbà tí ó rí èbúté ọlọ́lá ńlá náà ní ọdún 332 ṣááju Sànmánì Tiwa, sọ ìlú Alẹkisáńdíríà. Ó wá di ibùdó àṣà àti ìṣòwò tí ń bá Áténì àti Róòmù figa gbága. Ibẹ̀ ni ibi ìkówèésí ti Alẹkisáńdíríà lílókìkí náà wà. Àmọ́ nígbà Sànmánì Agbedeméjì, apá púpọ̀ jù lọ nínú ìlú ńlá ìgbàanì náà ti pòórá, àwọn ìsẹ̀lẹ̀ àti iná ti bà á jẹ́, òkun sì ti bò ó.
Nígbà Wo Ni Ẹgbẹ̀rúndún Náà Ń Bẹ̀rẹ̀?
Ní àárín òru December 31, 1999, ọ̀pọ̀ ènìyàn kárí ayé yóò ṣayẹyẹ ìbẹ̀rẹ̀ ẹgbẹ̀rúndún tuntun kan, àwọn ìṣètò àwẹ̀jẹwẹ̀mu onínàá àpà sì ti wà ní sẹpẹ́ báyìí. Ṣùgbọ́n, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ kan tí Ibi Ìdúrówosánmà ti Aláyélúwà, ní Cambridge, England, gbé jáde, “ní pàtó, a óò máa ṣayẹyẹ 2,000 ọdún, tàbí ọdún tó kẹ́yìn ẹgbẹ̀rúndún kan, kì í ṣe ìbẹ̀rẹ̀ ẹgbẹ̀rúndún tuntun náà.” Ìdàrúdàpọ̀ náà ṣẹlẹ̀ nítorí bí Bede, òpìtàn kan ní ọ̀rúndún keje, tí ó tún jẹ́ ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn, tí ó sapá láti ṣàkọsílẹ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú ìbí Jésù ṣe pinnu ìrésọdá láti àwọn ọdún ṣááju Sànmánì Tiwa sí àwọn ọdún Sànmánì Tiwa. Kò sí ọdún kòṣekukòṣẹyẹ kankan, nítorí náà, àkókò tí ó wà láàárín ọjọ́ kìíní nínú ọdún 1 ṣááju Sànmánì Tiwa àti ọjọ́ kìíní nínú ọdún 1 Sànmánì Tiwa jẹ́ ọdún kan péré. Lójú ìwòye èyí, ẹgbẹ̀rúndún kìíní bẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ kìíní nínú ọdún 1 Sànmánì Tiwa, ó sì parí ní ọjọ́ tó kẹ́yìn nínú ọdún 1000 Sànmánì Tiwa. Ẹgbẹ̀rúndún kejì bẹ̀rẹ̀ ní January 1, 1001. Àwọn olùwádìí náà sọ pé: “Nípa bẹ́ẹ̀, ó ṣe kedere pé ìbẹ̀rẹ̀ ẹgbẹ̀rúndún tuntun náà yóò jẹ́ ọjọ́ kìíní, oṣù January, ọdún 2001.” Bí ó ti wù kí ó rí, a óò gbé ayẹyẹ náà karí kàlẹ́ńdà ti Gregory, kì í ṣe lórí ọjọ́ tí a bí Jésù gan-an, tí a wá mọ̀ nísinsìnyí pé, a ti bí ní àkókò díẹ̀ ṣáájú, ní ti gidi.
Àkọsílẹ̀ Tí A Kò Fọkàn Fẹ́ Rárá
Ìwé agbéròyìnjáde The New York Times sọ pé: “Ìgbìmọ̀ àwọn ògbóǹkangí kan nípa ìlera [sọ pé] United States ló ní ìwọ̀n gíga jù lọ àrùn tí ìbálòpọ̀ ń ta látaré ní àwọn orílẹ̀-èdè tó ti gòkè àgbà lágbàáyé, tí kò sì ní ìgbékalẹ̀ orílẹ̀-èdè tí ó gbéṣẹ́ tó láti gbógun ti àjàkálẹ̀ àrùn náà.” Gẹ́gẹ́ bí ìgbìmọ̀ kan nínú Àjọ Ìṣègùn, ẹ̀ka Ilé Ẹ̀kọ́ Orílẹ̀-Èdè fún Ìmọ̀ Sáyẹ́ǹsì, ṣe sọ, àìlóǹkà àrùn tí ìbálòpọ̀ ń ta látaré, tí àwọn ará America ní, ni ó ṣeé dènà, síbẹ̀ tí wọ́n ṣì ń fa àwọn ìṣòro ìlera lílekoko, irú bí àrùn jẹjẹrẹ, àti ikú ẹgbẹẹgbẹ̀rún ènìyàn lọ́dọọdún. Lẹ́yìn ìwádìí olóṣù 18 kan, ìgbìmọ̀ ẹlẹ́ni 16 náà rí i pé, lára ìpíndọ́gba dọ́là 43 tí a ń ná lórí ìtọ́jú àrùn àti àwọn ìnáwó mìíràn, dọ́là 1 péré ni a ń ná láti dènà àwọn àrùn náà. Ìròyìn tí wọ́n ṣe sọ pé ìdá mẹ́rin lára ìfojúbù ìṣẹ̀lẹ̀ àrùn tuntun tí a ṣírò sí mílíọ̀nù 12 lọ́dọọdún ni ó kan àwọn aṣẹ̀ṣẹ̀bàlágà. Bí a bá fi wọ́n sílẹ̀ láìtọ́jú, àwọn àrùn náà—tí ó ní àrùn herpes, àrùn mẹ́dọ̀wú oríṣi B, àrùn chlamydia, àtọ̀sí, àti àrùn rẹ́kórẹ́kó—lè fa àìlèbímọ, bíbí ọmọ alárùn, ìṣẹ́nú, àrùn jẹjẹrẹ, àti ikú. Ó kéré tán, àwọn àrùn wọ̀nyí ń ná orílẹ̀-èdè náà ní bílíọ̀nù 10 dọ́là lọ́dọọdún, láìṣírò iye tí a ń ná lórí fáírọ́ọ̀sì HIV, fáírọ́ọ̀sì tí ń fa àrùn AIDS, mọ́ ọn.
Wíwá Antarctic Tí Kò Léèérí Kiri
Láìka ìwọ̀n ojú ọjọ́ ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn tí ó jẹ́ ẹẹ́wàá péré lábẹ́ òòfo lórí òṣùwọ̀n Celsius sí, àwọn olùbẹ̀wò tí ń lọ sí Antarctica ti di ìlọ́po méjì láàárín ọdún mẹ́wàá tó kọjá. Ẹgbàarùn-ún ènìyàn ló gbàyè ìsinmi tí ó náni tó 9,000 dọ́là láti lọ wo àgbáálá ilẹ̀ ìhà gúúsù jíjìnnà réré yìí àti àwọn ẹyẹ penguin, àwọn kìnnìún òkun, àti ohun ìyanu ilẹ̀ dídì tí ó fẹ̀ ní mílíọ̀nù 13 kìlómítà níbùú lóròó, tí ó wà níbẹ̀. Ṣùgbọ́n, ìwé agbéròyìnjáde The Independent, ti London, sọ pé, kíákíá ni àwọn onígboyà arìnrìn-àjò wọ̀nyí máa ń ráhùn lórí àwọn pàǹtírí tí àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti lọ ṣiṣẹ́ níbẹ̀ fi sílẹ̀ lọ—àwọn ahéré, goro epo, ìdọ̀tí, àti àwọn ògbólógbòó kọ̀ǹpútà pàápàá, tí a pa tì síbẹ̀. Ọ̀mọ̀wé Bernard Stonehouse, láti Ilé Ẹ̀kọ́ Scott Nípa Ìpẹ̀kun Ayé, ní Cambridge, ilẹ̀ England, tí ó ṣe ìwé ìfinimọ̀nà àkọ́kọ́ fún àgbègbè náà jáde, sọ nípa àwọn olùṣèbàjẹ́ wọ̀nyí pé: “Wọn kò wulẹ̀ ń ṣèyọnu láti palẹ̀ ìdọ̀tí mọ́ látijọ́, ṣùgbọ́n a ti ń mú kí wọ́n ṣèyọnu nísinsìnyí. Àwọn arìnrìn-àjò afẹ́ àti àwọn olùṣèbẹ̀wò ti ń ráhùn pé, àkìtàn kọ́ ni àwọn sanwó láti wá wo.”
Tẹ́tẹ́ Oríire Ta Ṣọ́ọ̀ṣì Yọ
Àjọ Akóròyìnjọ Ìjọ Baptist sọ pé, àwọn ará America ń náwó sórí tẹ́tẹ́ oríire ju bí wọ́n ṣe ń dáwó sí ṣọ́ọ̀ṣì wọn lọ. Bí wọ́n ṣe ròyìn rẹ̀ nínú ìwé ìròyìn Christian Century, àfiwéra iye kan tí ìròyìn Àjọ Ìkànìyàn Ilẹ̀ United States gbé jáde pẹ̀lú èyí tí ìwé ọdọọdún Yearbook of American and Canadian Churches gbé jáde fi hàn pé ní 1994, àwọn ará America ná bílíọ̀nù 26.6 dọ́là lórí àwọn tẹ́tẹ́ oríire tí ìjọba ṣe onígbọ̀wọ́ rẹ̀, síbẹ̀ wọ́n dá bílíọ̀nù 19.6 dọ́là péré ní àwọn ṣọ́ọ̀ṣì wọn.
Kò Sí fún Yànmùyánmú
Iná apakòkòrò, àwọn ìhùmọ̀ oníná mànàmáná tí a ń gbé kọ́ síta, tí ń fa àwọn kòkòrò mọ́ra lálẹ́, tí ó sì ń pariwo bí ó ti ń pa wọ́n, kì í pa yànmùyánmú. George B. Craig, Kékeré, ọ̀jọ̀gbọ́n ìmọ̀ nípa kòkòrò sọ pé: “Àwọn ìhùmọ̀ wọ̀nyí kò wúlò ní gidi.” Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn yànmùyánmú ni iná náà kì í fà mọ́ra, nígbà tí wọ́n bá sì ń bà lé oúnjẹ wọn, àwọn abo—tí ń géni jẹ náà—ń wá afẹ́fẹ́ ammonia, afẹ́fẹ́ carbon dioxide, ooru, àti àwọn ohun mìíràn tí ń tinú awọ ara jáde tí àwọn iná apakòkòrò náà kì í mú jáde. Bí wọn kò bá rí ìwọ̀nyí, wọn á fò lọ. Yàtọ̀ sí ìyẹn, Ọ̀mọ̀wé Craig sọ pé, gbígbìyànjú láti fi iná apakòkòrò pa yànmùyánmú dà bíi “gbígbìyànjú láti fi ṣíbí ìmùkọ gbọ́n omi òkun gbẹ.” Abo yànmùyánmú kan lè mú irú ọmọ tí ó jẹ́ abo tí ó lé ní 60,000 jáde láàárín oṣù mélòó kan péré. Ìwádìí olóṣù mẹ́ta kan fi hàn pé, ní ìpíndọ́gba alẹ́ kan, kìkì ìpín 3 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn kòkòrò tí àwọn iná apakòkòrò ń pa ló ń jẹ́ abo yànmùyánmú. Craig sọ nípa iná apakòkòrò náà pé, “ẹ̀ka ìtajà ohun ìdárayá inú ilé ló yẹ kí wọ́n ti máa tà á, kì í ṣe ẹ̀ka ìtajà ohun èlò iṣẹ́ inú ọgbà ọ̀gbìn.”