ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 6/22 ojú ìwé 16-18
  • Àwọn Ohun Iyebíye Etídò

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ohun Iyebíye Etídò
  • Jí!—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bí Lámilámi Ṣe Ń Fò
  • Orí Tí Ó Ní Ọ̀pọ̀ Ojú
  • Ìyípadà Kan Nínú Ọ̀nà Ìgbésí Ayé
  • Ẹ̀rí Lòdì sí Ẹfolúṣọ̀n
  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
    Jí!—1998
  • Ìṣẹ̀dá Ń Jẹ́ Ká Mọ̀ Nípa Ọlọ́run Alààyè
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
  • Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
    Jí!—2010
  • Ibeere Lati Ọwọ́ Awọn Onkawe
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
Àwọn Míì
Jí!—1997
g97 6/22 ojú ìwé 16-18

Àwọn Ohun Iyebíye Etídò

Láti ọwọ́ aṣojúkọ̀ròyìn Jí! ní Sípéènì

NÍGBÀKIGBÀ tí mo bá ń rìn lọ létídò tàbí létí ọ̀gọ̀dọ̀ kan, mo máa ń wá àwọn ohun iyebíye tí mo yàn láàyò—ó lè jẹ́ pupa, aláwọ̀ búlúù, tàbí aláwọ̀ ewé. Nígbà míràn, mo máa ń rí ọ̀kan tí ó wà láìmira lórí ewé kan; mo lè rí òmíràn tí ó dúró sójú kan lórí omi tàbí tí ó tilẹ̀ ń yára fò síhìn-ín sọ́hùn-ún níwájú mi. Ohun iyebíye tí mo ń wá ni lámilámi—“hẹlikópítà” aláwọ̀ mèremère láàárín àwọn kòkòrò.

Àwọn ohun iyebíye tí ń fò wọ̀nyí kọ́kọ́ gba àfiyèsí mi ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn nígbà tí mo ṣèèṣì débi odò ṣíṣàn kan nínú igbó. Àwọn lámilámi mélòó kan tí ń fò síhìn-ín sọ́hùn-ún wọ inú ìtànṣán oòrùn wà níbẹ̀—àwọn kan ní àwọ̀ búlúù atànyanran tó mọ́ rekete, àwọn mìíràn sì ní àwọ̀ ìyeyè fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ tí ń dán yanran. Mo fi wákàtí kan wòran ijó tí wọ́n ń jó nínú afẹ́fẹ́, tí ó sọ àyè inú igbó náà di iyàrá ijó kékeré kan. Láti ìgbà náà wá ni wọ́n ti ń ru mí lọ́kàn sókè.

Bí mo ti ń mọ̀ sí i tó nípa àwọn lámilámi ni mo ń mọyì ẹwà àti ìníyelórí wọn sí i tó. Àwárí tí mo kọ́kọ́ ṣe nípa wọn ni pé, ìyàtọ̀ wà láàárín àwọn lámilámi àti àwọn kòkòrò damselfly. Àwọn lámilámi jẹ́ olùfò lílágbára gan-an, wọ́n sì túbọ̀ máa ń tóbi jù, nígbà tó ṣe pé, àwọn kòkòrò damselfly—gẹ́gẹ́ bí orúkọ wọn ṣe fi hàn—túbọ̀ jẹ́ ẹlẹgẹ́, wọ́n sì ń fò jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́. Ìyàtọ̀ pàtàkì kan ni ti ọ̀nà tí wọ́n fi ń pa ìyẹ́ wọn mọ́ra. Lámilámi tí ń sinmi sábà máa ń na ìyẹ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin sẹ́gbẹ̀ẹ́, nígbà tí kòkòrò damselfly ń pa tirẹ̀ pọ̀ sórí ara rẹ̀.a

Mo bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe kàyéfì nípa bí ó ṣe rọrùn tó bẹ́ẹ̀ fún àwọn lámilámi láti hán yànmùyánmú nínú afẹ́fẹ́. Ní tèmi, ó ṣòro fún mi láti yánwọ́ ba eṣinṣin ńlá kan tí ó bá gẹ́ sára ògiri ilé ìgbọ́únjẹ. Mo wá bi ara mi pé, ‘Kí ni lámilámi kan ní tí èmi kò ní?’ Ohun méjì ni: agbára pátápátá lórí afẹ́fẹ́ àti ojú tí ó gbọ́dọ̀ mú kí ọlọ́dẹ jowú gan-an.

Bí Lámilámi Ṣe Ń Fò

Pípe lámilámi ní hẹlikópítà—orúkọ ìnagijẹ́ kan tí ó wọ́pọ̀ ní Sípéènì—jẹ́ àfiwéra arẹnisílẹ̀. Bí wọ́n ṣe ń fara pitú lófuurufú yára kánkán tó bẹ́ẹ̀ tí kò ṣeé fojú bá lọ nígbà míràn. Ní kíá tí wọ́n bá gbéra sọ, àwọn irú ọ̀wọ́ kan lè dé ìwọ̀n ìsáré tí ó tó kìlómítà 96 láàárín wákàtí kan. Wọ́n tún lè dúró sójú kan tàbí kí wọ́n fò síwá, sẹ́yìn, tàbí sẹ́gbẹ̀ẹ́ ní kíámọ́sá. Síwájú sí i, nígbà tí lámilámi bá yí pa dà bìrí nínú afẹ́fẹ́, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ṣírò rẹ̀ pé, ó gbọ́dọ̀ ti kojú ìwọ̀n agbára tí ó pọ̀ tó 2.5 G.

Àwọn lámilámi ń ní ìyẹ́ mẹ́rin tó ṣeé yára ká kò, tó sì fara jọ léèsì. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìrísí ìyẹ́ wọ̀nyí ṣe ẹlẹgẹ́, wọ́n lè lù tó ìgbà 40 láàárín ìṣẹ́jú àáyá kan, kí wọ́n má sì bà jẹ́ púpọ̀ bí nǹkan bá gbá wọn. Onímọ̀ nípa ohun alààyè, Robin J. Wootton, ṣàpèjúwe wọn bí “àgbà iṣẹ́ ìhùmọ̀ kéékèèké.”

Ó ṣàfikún pé: “Bí a bá ṣe lóye dáradára sí i tó nípa ìṣiṣẹ́ ìyẹ́ àwọn kòkòrò, ni ọnà ìgbékalẹ̀ wọn ń jọ ti ìhùmọ̀, tí ó sì ń rẹwà sí i tó. . . . Ìmọ̀ ẹ̀rọ tí ó bá wọn dọ́gba kò tó nǹkan, ìyẹn ni bí ó bá wà rárá.” Kò yani lẹ́nu pé, àwọn onímọ̀ ẹ̀rọ nípa bí nǹkan ṣe ń fò ń ṣèwádìí lọ́wọ́lọ́wọ́ lórí bí lámilámi ṣe ń fò.

Orí Tí Ó Ní Ọ̀pọ̀ Ojú

Bí ọ̀nà tí àwọn lámilámi gbà ń fò bá jẹ́ àrà ọ̀tọ̀, ọ̀nà tí wọ́n gbà ń ríran jẹ́ àrà ọ̀tọ̀ bákan náà. Ojú ńlá kòǹgbàkòǹgbà méjì fẹ́rẹ̀ẹ́ gba gbogbo agbárí lámilámi tán. Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ojú wọ̀nyí ní iye tí ó tó 30,000 ẹ̀ka onígun mẹ́fàmẹ́fà tí ó jọ ojú kéékèèké nínú ojú kan ṣoṣo, nítorí pé ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní ń gbé ìsọfúnni ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lọ sínú ọpọlọ. Bí ó ti wù kí ó rí, ìyẹn kò túmọ̀ sí pé lámilámi kan ń rí ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìran ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lẹ́ẹ̀kan náà. Kàkà kí ó máa rí ìran lódindi, bí àwa ṣe ń ṣe, ó ń nímọ̀lára ìrìnsí, bátànì, ìyàtọ̀síra, àti ìrísí.

Gbogbo ohun tó ń rí yìí nílò ìfọ́síwẹ́wẹ́. Nípa bẹ́ẹ̀, ìpín 80 nínú ọgọ́rùn-ún nínú ọpọlọ lámilámi ni a yà sọ́tọ̀ fún ṣíṣàtúpalẹ̀ ìsọfúnni nípa ìríran. Ìwọ̀n ìgbékalẹ̀ ìríran mélòó kan ló lágbára tó bẹ́ẹ̀—lámilámi kan lè rí yànmùyánmú tó wà ní nǹkan bí 20 mítà sí i. Kódà ní àríniìmọni, nígbà tí ìmọ́lẹ̀ kò pọ̀ tó bẹ́ẹ̀, tí ènìyàn kò sì lè fi bẹ́ẹ̀ rí eṣinṣin kékeré kan, àwọn lámilámi ilẹ̀ olóoru ń mu wọn nírọ̀rùn.

Bí lámilámi ṣe ń yára fò lójijì, kíákíá kọjá láàárín ìgbẹ́ etídò ń gba ìpinnu àfìkánjúṣe gan-an. Ó lè dá bírà yí nítorí pé ó lè rí nǹkan ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí ó pọ̀ tó ọgọ́rùn-ún ní ìṣẹ́jú àáyá kan, ó lé ní ìlọ́po márùn-ún ohun tí a lè rí. Nípa bẹ́ẹ̀, lójú lámilámi kan, sinimá kan, tí ń gbé àwòrán 24 jáde ní ìṣẹ́jú àáyá kan, yóò wulẹ̀ dà bí àwọn fọ́tò tí kò kúrò lójú kan.

Ìyípadà Kan Nínú Ọ̀nà Ìgbésí Ayé

Nígbà tí lámilámi kan bá bẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀, kì í sí àmì kan tí ń tọ́ka sí i pé yóò wá di olùfò aláṣeyọrí tí ó ń dà níkẹyìn. Lẹ́yìn tí ẹyin náà bá pa, kògbókògbó tí ń gbé inú omi náà yóò wà bákan láìmira nínú ọ̀gọ̀dọ̀ tàbí odò kan, tí ó ń dúró láti mú oúnjẹkóúnjẹ tó bá wá sí àrọ́wọ́tó rẹ̀. Lẹ́yìn ìpààrọ̀ awọ lọ́pọ̀ ìgbà—lọ́pọ̀ oṣù tàbí ọdún nínú ọ̀ràn àwọn irú ọ̀wọ́ mélòó kan—kògbókògbó náà ń gòkè wá sórí esùsú kan. Níbẹ̀ ni ìyírapadà àrà ọ̀tọ̀ kan ti ń ṣẹlẹ̀.

Awọ náà ń là lọ́gan-anran àyà, lámilámi tí ó ti gbó kan sì ń jáde wá. Bíi ti labalábá, àgbà lámilámi tó ṣẹ̀ṣẹ̀ yọ náà ní láti dúró fún wákàtí mélòó kan kí ìyẹ́ rẹ̀ tó lágbára, kí ó sì bẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé tuntun. Láàárín ọjọ́ díẹ̀, ọgbọ́n àdánidá rẹ̀ ń mú kí ó máa ṣọdẹ láṣeyọrí, kí ó sì mọ gbogbo ọgbọ́n ìfòkiri.

Láìpẹ́, ọ̀dọ́ lámilámi náà yóò di ògbógi nídìí híhán àwọn eṣinṣin àti yànmùyánmú bí ó ṣe ń fò lọ. Nípa jíjẹ àwọn kòkòrò tí ó tẹ̀wọ̀n tó òun fúnra rẹ̀ lójoojúmọ́, ó ń ṣe iṣẹ́ tí kò ṣeé díwọ̀n kan. Láti máa rí ìpèsè oúnjẹ tó dájú, ọ̀pọ̀ akọ lámilámi ń dá gba àgbègbè ìpínlẹ̀ kékeré kan, tí wọ́n ń dáàbò bò ó tìtaratìtara.

Àwọn irú ọ̀wọ́ lámilámi kan ń dọdẹ àwọn kòkòrò tí ń mu oje igi tàbí ọ̀bọ̀n-ùnbọn-ùn, àwọn mìíràn ń mú àwọn àkèré kéékèèké, kòkòrò damselfly kan nílẹ̀ olóoru tilẹ̀ ń jẹ aláǹtakùn. Ó ń dúró sójú kan nítòsí ilé aláǹtakùn ńlá kan, ó sì ń hán àwọn aláǹtakùn kéékèèké tí ń wá jí oúnjẹ tí aláǹtakùn ńlá bá fi sílẹ̀ jẹ.

Ẹ̀rí Lòdì sí Ẹfolúṣọ̀n

Ọ̀pọ̀ onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti ẹfolúṣọ̀n ka àwọn lámilámi sí àwọn kòkòrò tí ó kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í fò. Àkẹ̀kù kan tí wọ́n rí ní ilẹ̀ Faransé ní àmì ìrísí àwọn ìyẹ́ lámilámi kan tí ó fẹ̀ tó sẹ̀ǹtímítà 75 bí ó bá na ìyẹ́ tán! Òun ni kòkòrò títóbi jù lọ tí a mọ̀, ó sì tóbi ju ìlọ́po mẹ́ta bí lámilámi èyíkéyìí tí ń bẹ láàyè ṣe tóbi tó lọ.

Mo bi ara mi pé, ‘Báwo ló ṣe lè ṣeé ṣe kí ọ̀kan lára àwọn ìhùmọ̀ tí ènìyàn mọ̀ pé ó ń fò, wulẹ̀ fara hàn ní pípé pérépéré?’ Ìwé náà, Alien Empire—An Exploration of the Lives of Insects, gbà pé: “Kò sí àkẹ̀kù àwọn kòkòrò tí ó wà láàárín ipò àìníyẹ̀ẹ́ àti ipò oníyẹ̀ẹ́.” Ó ṣe kedere pé, iṣẹ́ ọwọ́ Àgbà Olùṣàgbékalẹ̀ kan tí ó ní làákàyè ni àwọn lámilámi.

Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo apá ilẹ̀ ayé ni àwọn lámilámi ti ṣàṣeyọrí ní mímú ilé sí. Wọ́n ń rí ibùgbé tó bá wọn lára mu ní ẹ̀bá àwọn adágún olókè, irà ibi ìlà agbedeméjì òbìrí ayé, tàbí níbi ìkùdu ìlúwẹ̀ẹ́ àrọko pàápàá.

Mo ti wòran ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ lámilámi ní etíkun ilẹ̀ olóoru ní Áfíríkà, mo sì ti wo lámilámi ọlọ́ba tí ń dá wà bí wọ́n ṣe ń lọ tí wọ́n sì ń bọ̀ láìsinmi níbi ọ̀gọ̀dọ̀ ilẹ̀ Europe tí wọ́n yàn láàyò. Nígbà tí mo sì rìnrìn àjò la òkè àfonífojì olómi tí ewé yí ká ní Philippines já, àwọn kòkòrò damselfly dídányanran ń sìn mí sọ́nà, kódà, wọ́n ń bà lé apá mi tí n kò faṣọ bò.

Nígbà tí àwọn lámilámi lè wà lára àwọn ohun tí ń rìn kiri nínú afẹ́fẹ́, tí ó díjú pọ̀, lórí ilẹ̀ ayé, ọlá ńlá wọn àti ẹwà wọn sábà máa ń wọ̀ mí lọ́kàn ju agbára tí wọ́n ní láti fò lọ. Wíwà tí wọ́n wà ń fi ìtànyanran àrà ọ̀tọ̀ kan kún àwọn ọ̀gọ̀dọ̀ wa àti àwọn etídò wa. Wọ́n jẹ́ ohun iyebíye pípé—wọ́n wà níbẹ̀ nígbà gbogbo kí a lè jẹ̀gbádùn wọn.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àwọn lámilámi máa ń tẹ ìyẹ́ wọn wálẹ̀, wọ́n sì ń gbé ara wọn sókè sí oòrùn. Wọ́n máa ń wà ní ipò yí kí ara wọn lè balẹ̀, níwọ̀n bí ó ti máa ń jẹ́ kí ìhà tí ń ṣí sílẹ̀ sí oòrùn nínú ara mọ níwọ̀n.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16, 17]

Àwọn lámilámi, tí ń na ìyẹ́ sẹ́gbẹ̀ẹ́, sábà máa ń tóbi ju àwọn kòkòrò “damselfly,” tí ń pa ìyẹ́ tiwọn pọ̀ sórí ara wọn lọ

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́