Àrùn RSD—Àrùn Ríronilára Kan Tí Ń Rúni Lójú
Láti ọwọ́ aṣojúkọ̀ròyìn Jí! ní Kánádà
ÀRÙN ÌṢIṢẸ́GBÒDÌ IṢAN AMÚNIMỌ̀RORA (RSD) jẹ́ “ọ̀kan lára àwọn àmì àrùn tí ń rúni lójú jù lọ nínú ìmọ̀ ìṣègùn àti ọ̀kan lára àwọn tí ń roni lára ju lọ tí ó sì lè sọni di aláìlágbára,” ni Allison Bray kọ nínú ìwé agbéròyìnjáde Winnipeg Free Press. Anna Alexander, tí àrùn náà ń ṣe, sọ nínú ìwé ìròyìn British Medical Journal pé, àrùn RSD “máa ń wà lára aláìsàn tí a yẹ̀ wò, a kì í sì í mọ̀ kìkì nítorí pé a kò mọ ohun tí ó pọ̀ tó nípa rẹ̀.” Ìwé ìròyìn kan náà sọ pé, bóyá a kì í dá àrùn náà mọ̀ dáradára tó lára àwọn ọmọdé ni. Fún ọ̀pọ̀ ọdún, àwọn dókítà tilẹ̀ rò pé ìrora náà jẹ́ ti èrò orí òun èrò ìmọ̀lára.
Àwọn tí àrùn àràmàǹdà yí ń ṣe ń ní ìrora tí kì í dáwọ́ dúró àti nínú àwọn ọ̀ràn kan, agbára káká ni wọ́n fi ń rántí pé àwọn ti ṣe ohun kan tí ó lè fa ìrora gógó náà. Sarah Arnold kọ nínú ìwé ìròyìn Accent on Living pé: “Ìfarapa tàbí ọgbẹ́ ní ẹ̀yà ara kan tí ọ̀pọ̀ iṣan parí sí, bí ọwọ́ tàbí ẹsẹ̀, ni ń fa àrùn náà. Ìfarapa náà lè jẹ́ fífi abẹ́rẹ́ gúnni lásán tàbí èyí tí ó le gan-an bíi ti iṣẹ́ abẹ. Àmì àkọ́kọ́ tí àrùn náà ń gbé wá ni ìrora tí kò tètè dẹwọ́ tí ó le koko ju bí ìfarapa náà ti mọ lọ. Àwọn àmì àrùn náà le gan-an, ìrora gógó ní apá kan pàtó nínú ara, kí ara máa kọ ooru àti ìmọ́lẹ̀ lọ́nà gíga, irun àti èékánná tí ń yí pa dà àti awọ ara tí ń pàwọ̀ dà.”
Àrùn náà ń la ìpele ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ kọjá. Lákọ̀ọ́kọ́, apá ibi tí ó mú ń wú, ó sì ń pupa, irun ń hù níbi tí a kò rí i kí ó hù sí tẹ́lẹ̀. Èyí lè pẹ́ tó oṣù kan sí mẹ́ta. Lẹ́yìn náà, apá ibẹ̀ ń ní àwọ̀ búlúù, ó sì ń tutù; ìrora náà ń pọ̀ sí i, ìdè oríkèé egungun àti àwọn oríkèé ara sì ń le gbandi sí i. Àrùn àìlágbára egungun lè tibẹ̀ wọ̀ ọ́. Níkẹyìn, àwọn iṣan tí ó ṣẹlẹ̀ sí ń joro, àwọn iṣan ara tí ó so pọ̀ mọ́ egungun ń sún kì, ẹsẹ̀ tàbí apá tí ó sì ṣe ń rọ.
Gẹ́gẹ́ bí Dókítà Howard Intrater, olùdarí ibi ìṣètọ́jú ìrora ní Ilé Ìwòsàn Ìṣètọ́jú Àrùn ní Winnipeg, ti sọ, a lè ṣèdíwọ́ fún ìpalára tí kò ṣeé yí pa dà. A ní láti dí iṣan amúnimọ̀rora mọ́ kí ó má baà máa fi àwọn àmì ìrora ránṣẹ́.a Ìwé agbéròyìnjáde tí wọ́n ń ṣe ní Winnipeg náà ròyìn pé, “oríṣiríṣi ìtọ́jú wà láti orí fífi ìhùmọ̀ abánáṣiṣẹ́ tani jí sí lílo àwọn egbòogi tí ń dènà gbígba ìmọ̀lára ní ìhà beta, títí kan àwọn ìhùmọ̀ atanijí lóde awọ nínípọn tí ó bo ọpọlọ (níbi tí a ti gbé ìhùmọ̀ tí ń gba ìgbì iná sára sínú okùn ògooro ẹ̀yìn láti ta ibi tí nǹkan ń ṣe náà jí) sí gígún abẹ́rẹ́ láti dí àwọn iṣan amúnimọ̀rora mọ́.” A ń lo ìṣètọ́jú ara pa pọ̀ pẹ̀lú ìṣètọ́jú ní lílo akupọ́ńṣọ̀ láti dín ìrora kù, kí a sì mú agbára rírìn sunwọ̀n sí i. Ìwé ìròyìn British Medical Journal sọ pé, “àpapọ̀ fífi ìhùmọ̀ abánáṣiṣẹ́ jí mélòó kan, fífi kẹ́míkà sé àwọn iṣan amúnimọ̀rora mọ́, ṣíṣètọ́jú lọ́nà ti èrò orí, àti ìtọ́jú ara láìlo egbòogi tí a tẹra mọ́ wà lára àwọn ìtọ́jú tí ó gbéṣẹ́.”
Ó ṣe kedere pé títètè dá àrùn náà mọ̀ ṣàǹfààní. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, nígbà tí àwọn dókítà ń kọ̀wé nínú ìwé ìròyìn The American Journal of Sports Medicine, wọ́n sọ pé, àwọn àbájáde ìtọ́jú tí wọ́n ṣe fún àwọn aláìsàn tí wọ́n rí àwọn àmì àrùn náà lára wọn fún àkókò tí kò tó oṣù 6, tàbí láti oṣù 6 sí 12, tàbí fún àkókò tí ó lé ní oṣù 12, “fẹ́rẹ̀ẹ́ dọ́gba. Àwárí yìí ta ko èrò tí a ní lọ́wọ́ báyìí pé bí àmì àrùn bá wà fún àkókò tí ó ju ọdún kan lọ kí a tó ṣètọ́jú rẹ̀, ó jẹ́ àmì àfihàntẹ́lẹ̀ tí kò dára.”
A ṣèrètí pé bí ìmọ̀ ìṣègùn ti ń jinlẹ̀ sí i, a óò túbọ̀ lóye àrùn RSD dáradára sí i, a óò sì lè rí ìtọ́jú tí ó túbọ̀ gbéṣẹ́ fún un.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fún kúlẹ̀kúlẹ̀ ìjíròrò lórí kókó ọ̀rọ̀ ìrora, wo àwọn ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ tí ó ní àkọlé náà “Ìwàláàyè Láìsí Ìrora Ha Ṣeéṣe Bí?” nínú Jí!, ìtẹ̀jáde June 22, 1994.