Bí Bíbélì Èdè Faransé Ṣe Jìjàkadì Láti Máa Wà Nìṣó
LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ ILẸ̀ FARANSÉ
Ó LÉ ní ọgọ́rùn-ún mílíọ̀nù ènìyàn tí ń sọ èdè Faransé lágbàáyé. Kódà bí o kì í bá ṣe ọ̀kan lára wọn, kíkà nípa bí Bíbélì èdè Faransé ṣe jìjàkadì láti máa wà nìṣó yóò gbádùn mọ́ ọ, lọ́nà kan nítorí ìsopọ̀ tí ó ní pẹ̀lú òmìnira ìsìn. Láti ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún sẹ́yìn, ọ̀pọ̀ Bíbélì èdè Faransé ni àwọn ọ̀tá àti ọ̀rẹ́ èké ti fi ìwà òǹrorò bà jẹ́. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn olùtúmọ̀ àti àwọn òǹtẹ̀wé kojú àwọn ìṣòro tí ń dẹ́rù bani, wọ́n fi ẹ̀mí wọn wewu láti borí nínú ìjàkadì náà.
Láàárín ọ̀rúndún kejìlá, ìtumọ̀ àwọn apá kan lára Bíbélì náà wà lárọ̀ọ́wọ́tó ní àwọn èdè àdúgbò mélòó kan, títí kan èdè Faransé. Àwọn àwùjọ ènìyàn tí Ìjọ Kátólíìkì kà sí aládàámọ̀ ń fúnni ní ìṣírí láti máa lò wọ́n. Ṣùgbọ́n, ọ̀rúndún kọkàndínlógún ni wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ sí í pín Bíbélì èdè Faransé káàkiri dé ibi jíjìnnà réré. Àwọn ọ̀rúndún púpọ̀ tí ó kọjá yìí fi àwọn àdánwò líléwu tí Bíbélì èdè Faransé náà fojú winá rẹ̀ láti máa wà nìṣó hàn gbangba.
Ìwé atúmọ̀ èdè Bíbélì kan tí a ṣe ní nǹkan bí ọdún 900 ṣáájú Sànmánì Tiwa jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìwé tí a kọ́kọ́ ṣe ní èdè Faransé. A ṣe é láti ran àwọn òǹkàwé lọ́wọ́ láti lóye Bíbélì èdè Látìn, èdè tí Ìjọ Kátólíìkì ń lò. Ṣùgbọ́n ní àkókò yẹn, àwọn ènìyàn gbáàtúù, tí wọ́n ń sọ èdè àdúgbò bíi mélòó kan, kò sọ èdè Látìn mọ́. Nípa bẹ́ẹ̀, a kò jẹ́ kí wọ́n mọ̀ nípa Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Èyí jẹ́ ẹ̀tọ́ agbára fún kìkì àwùjọ àlùfáà tí wọ́n kọ́ èdè Látìn dunjú, tí wọ́n lè kà á.
Ní ọdún 842 Sànmánì Tiwa, àkọsílẹ̀ ìjọba tí a kọ́kọ́ kọ ní èdè Faransé jáde. Èyí jẹ́ ẹ̀rí tí ó ṣe kedere tí ó fi hàn pé ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ènìyàn kò sọ èdè Látìn mọ́. Àwọn ewì ìsìn tí a ti kọ ní èdè wíwọ́pọ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í dé ilẹ̀ Faransé ní nǹkan bí ọdún 880 Sànmánì Tiwa. Síbẹ̀síbẹ̀, àwọn ìtumọ̀ Bíbélì kò dé mọ́ fún ọ̀rúndún méjì lẹ́yìn náà. Lára àwọn tó kọ́kọ́ dé ni ìtumọ̀ apá kan Bíbélì sí èdè Faransé ti àwọn Norman, tí a ṣe jáde ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún kejìlá.
Ìjàkadì Náà Bẹ̀rẹ̀ ní Pẹrẹwu
Ìsapá àkọ́kọ́ tí kò dáwọ́ dúró tí a ṣe láti mú kí Ìwé Mímọ́ wà lárọ̀ọ́wọ́tó fún àwọn ènìyàn ilẹ̀ Faransé ní irú èyí tí wọ́n lè kà wá láti ọ̀dọ̀ Peter Waldo, oníṣòwó kan ní ọ̀rúndún kejìlá tí ó wá láti Lyons, ní àárín gbùngbùn ilẹ̀ Faransé. Waldo gbé iṣẹ́ fún àwọn kan láti túmọ̀ àwọn apá kan Bíbélì sí èdè Provençal, èdè àdúgbò tí wọ́n ń sọ ní gúúsù ìlà oòrùn ilẹ̀ Faransé. Ní 1179, níbi Àpérò Lateran Kẹta, ó gbé ìtumọ̀ apá kan Bíbélì tí ó ṣe lé Póòpù Alexander Kẹta lọ́wọ́.
Lẹ́yìn náà, ṣọ́ọ̀ṣì náà dá Waldo àti àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lẹ́bi gẹ́gẹ́ bí aládàámọ̀, àwọn ọkùnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ànìkàngbé sì dáná sun àwọn ìtumọ̀ tí ó gbé fún àwọn ènìyàn láti ṣe. Láti ìgbà náà lọ, ṣọ́ọ̀ṣì náà ń dènà gbogbo ìsapá láti lè jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dé ọwọ́ àwọn ènìyàn gbáàtúù.
Ṣọ́ọ̀ṣì náà mú kí àwọn ìwéwèé rẹ̀ ṣe kedere ní 1211 nípa sísun àwọn Bíbélì ní ìlú ńlá Metz, ní ìlà oòrùn ilẹ̀ Faransé. Ní 1229, Àpérò Toulouse sọ ìfòfindè rẹ̀ jáde nípa kíka lílo Bíbélì èdè àdúgbò míràn tí a fi èdè èyíkéyìí kọ léèwọ̀ fún àwọn ọmọ ìjọ. Ti Àpérò Tarragona, Sípéènì, tẹ̀ lé e ní 1234, èyí tí ó fòfin de níní Bíbélì tí wọ́n fi èyíkéyìí lára àwọn èdè Romance (èdè tí a fà yọ láti inú èdè Látìn) kọ, kódà àwọn àlùfáà kò gbọ́dọ̀ ní in lọ́wọ́.
Lójú irú àtakò tí kò dẹwọ́ bẹ́ẹ̀, ìtumọ̀ Bíbélì tí a kọ́kọ́ parí ní èdè Faransé dé ní apá ìlàjì kejì ọ̀rúndún kẹtàlá. Ìwọ̀nba kéréje ni a pín kiri lára Bíbélì tí a kò kọ orúkọ àwọn tí ó túmọ̀ rẹ̀ sí náà. Lákòókò yí, àwọn ènìyàn gbáàtúù kò ní irú Bíbélì kankan lọ́wọ́. Ńṣe ni wọ́n ń fi ọwọ́ dà á kọ. Owó rẹ̀ tí ó ga àti àìní èyí tí ó pọ̀ tó lọ́wọ́ mú kí níní Bíbélì fẹ́rẹ̀ẹ́ mọ sọ́dọ̀ àwọn ọ̀tọ̀kùlú àti àwùjọ àlùfáà.
Ìgbèjà Bíbélì Súnni Ṣiṣẹ́
Pẹ̀lú ìhùmọ̀ ẹ̀rọ ìtẹ̀wé tí ó sì jẹ́ irú èyí tí àwọn lẹ́tà rẹ̀ ṣeé tún tò tí Johannes Gutenberg ṣe ní nǹkan bí 1450, ìyípadà tegbòtigaga nínú ìwé títẹ̀ ní ilẹ̀ Yúróòpù náà ní ipa lórí ilẹ̀ Faransé. Àwọn ìlú ńlá mẹ́ta ní ilẹ̀ Faransé—Paris, Lyons, àti Rouen—wá di ibùdó pàtàkì fún ìwé títẹ̀, ìtìlẹ́yìn lílágbára nínú ìgbèjà Bíbélì.a
Kí ìjàkadì náà tó dé ìpele yìí, a ti gbé àwọn ìtumọ̀ Bíbélì ní èdè Faransé karí ìtumọ̀ Vulgate ti èdè Látìn. Àkọsílẹ̀ ti èdè Látìn náà ni a ti fi onírúurú àṣìṣe bà jẹ́ lẹ́yìn ẹgbẹ̀rún ọdún tí wọ́n ti ń ṣàdàkọ rẹ̀ léraléra, àmọ́ ṣọ́ọ̀ṣì náà rọ̀ mọ́ ìtumọ̀ Vulgate. Síbẹ̀síbẹ̀, Kátólíìkì ọmọ ilẹ̀ Faransé náà, Jacques Lefèvre d’Étaples, pinnu láti mú kí Bíbélì wà lárọ̀ọ́wọ́tó àwọn ènìyàn. Ní 1530, ó ṣe ìtumọ̀ Vulgate náà sí èdè Faransé, ó sì ṣàtúnṣe díẹ̀ lára àwọn àṣìṣe inú rẹ̀ nípa wíwo àwọn ìwé àfọwọ́kọ èdè Hébérù àti Gíríìkì tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé nígbà náà. Ó tún mú àwọn àlàyé ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn tí ń ṣini lọ́nà tí ṣọ́ọ̀ṣì náà ti fi sínú àkọsílẹ̀ náà kúrò.
Kíá ni ìtumọ̀ tí Lefèvre ṣe ko àtakò. Wọ́n ní láti lọ tẹ àwọn ìtumọ̀ kan lẹ́yìn odi ilẹ̀ Faransé. A ka àwọn wọ̀nyí mọ́ àwọn ìwé tí ṣọ́ọ̀ṣì náà fòfin dè. Fún àkókò kan, Lefèvre ní láti sá di Strasbourg, tí ó jẹ́ ìlú ńlá ilẹ̀ ọba olómìnira kan tí ó wà ní ìhà ìlà oòrùn ilẹ̀ Faransé. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ìtumọ̀ tí ó ṣe kẹ́sẹ járí.
Ọdún 1535 ni a tẹ Bíbélì èdè Faransé tí a kọ́kọ́ túmọ̀ láti inú àkọsílẹ̀ ti èdè tí wọ́n fi kọ ọ́ ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ jáde. Ẹni tí ó túmọ̀ rẹ̀ ni Pierre-Robert Olivétan, ọmọ ilẹ̀ Faransé tí ó jẹ́ Pùròtẹ́sítáǹtì, mọ̀lẹ́bí Alátùn-únṣe náà, John Calvin. Nítorí àtakò ṣọ́ọ̀ṣì náà, wọn kò lè tẹ̀ ẹ́ ní ilẹ̀ Faransé, nítorí náà, wọ́n tẹ ìtumọ̀ yí ní Neuchâtel, Switzerland, àwùjọ tuntun ti àwọn Pùròtẹ́sítáǹtì. Ìtumọ̀ Bíbélì èdè Faransé tí Olivétan ṣe jẹ́ èyí tí a fi díwọ̀n ọ̀pọ̀ àwọn àtúnṣe tí a ṣe àti àwọn Bíbélì tí a túmọ̀ sí àwọn èdè míràn.
Ìjàkadì Tí Ó Léwu
Ní ilẹ̀ Faransé, àwọn onígboyà òǹtẹ̀wé kan bí Étienne Dolet ní 1546, ni wọ́n sun lórí igi nítorí pé wọ́n tẹ Bíbélì. Àpérò Trent, ní 1546, tún fìdí “ìjójúlówó” ìtumọ̀ Vulgate múlẹ̀, láìka àwọn àṣìṣe inú rẹ̀ sí, láti ìgbà náà sì ni ṣọ́ọ̀ṣì náà ti ń mú ipò fífìdímúlẹ̀ gbọn-ingbọn-in lòdì sí àwọn ìtumọ̀ ti èdè àdúgbò. Ní 1612, Ìwádìí Láti Gbógun Ti Àdámọ̀ ní Sípéènì dáwọ́ lé ìgbétáásì oníjàgídí-jàgan kan láti mú àwọn Bíbélì èdè àdúgbò kúrò.
Inúnibíni máa ń ṣamọ̀nà sí àwọn ìhùmọ̀ àfòyeṣe nígbà míràn. A gbé àwọn Bíbélì “inú irun ṣùkú,” tàbí “irun tí a ṣù ní kókó sórí” jáde, èyí kéré gan-an tó láti tọ́jú sínú irun tí obìnrin kan ṣù ní kókó sórí. Nígbà tí ó sì di 1754, a tẹ àwọn àṣàyàn apá kan láti inú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù àti Gíríìkì jáde nínú ìwé kan tí ó gùn ní sẹ̀ǹtímítà mẹ́ta tí ó sì fẹ̀ ní sẹ̀ǹtímítà márùn-ún.
Jíjàpadà
Bí ó ti wù kí ó rí, bí àkókò ti ń lọ, ọwọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ náà yí pa dà. Lẹ́yìn tí Bíbélì ti kojú ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún àtakò lílekoko, a jà pa dà fún un. Àwọn èrò tuntun àti òmìnira ìjọsìn, tí a fún àwọn ènìyàn lẹ́yìn Ìyípadà Tegbòtigaga ní ilẹ̀ Faransé, pe àwọn ẹni jàǹkànjàǹkàn inú ṣọ́ọ̀ṣì náà tí ń ṣàtakò níjà. Nítorí náà, ní 1803, wọ́n tẹ Májẹ̀mú Tuntun ti Pùròtẹ́sítáǹtì jáde ní ilẹ̀ Faransé, àkọ́kọ́ irú rẹ̀ láàárín ọdún 125!
Àwọn ẹgbẹ́ tí ń ṣe Bíbélì ṣèrànwọ́ pẹ̀lú. Ní 1792, wọ́n dá Ẹgbẹ́ Bíbélì Èdè Faransé sílẹ̀ ní London, England, “láti gba Bíbélì èdè Faransé, bí ó bá ti lè ṣeé ṣe tó, fún àwọn ọmọ ilẹ̀ Faransé tí wọn kò ní ọrọ̀ àtọ̀runwá yìí ní èdè tí ó lè yé wọn.” Àwọn ẹgbẹ́ tí ń ṣe Bíbélì míràn dara pọ̀ nínú ìjàkadì náà. Góńgó wọn láti ṣe Bíbélì jáde ní èdè Faransé kí wọ́n sì pín in kiri kẹ́sẹ járí.
Ìgbéjàkoni Tí Ó Yanjú Ọ̀rọ̀
Ìjọ Kátólíìkì dènà ìyípadà èyíkéyìí nínú àwọn ọgbọ́n tí ó ń lò, ṣùgbọ́n kò lè borí nínú ìjàkadì náà. Jálẹ̀jálẹ̀ ọ̀rúndún kọkàndínlógún, àwọn póòpù gbé oríṣiríṣi àṣẹ jáde tí ń ṣòdì sí Bíbélì èdè àdúgbò láìdábọ̀. Títí di ìgbà tí ó pẹ́ tó 1897, Póòpù Leo Kẹtàlá tún tẹnu mọ́ ọn pé, “gbogbo ìtumọ̀ àwọn Ìwé Mímọ́ èyíkéyìí tí òǹkọ̀wé tí kì í ṣe Kátólíìkì ṣe, tí ó sì wà ní èdè wíwọ́pọ̀ èyíkéyìí ni a kà léèwọ̀, ní pàtàkì àwọn tí àwọn ẹgbẹ́ tí ń ṣe Bíbélì ṣe jáde, tí Póòpù ti Róòmù ti bẹnu àtẹ́ lù lọ́pọ̀ ìgbà.”
Síbẹ̀síbẹ̀, nítorí pé àwọn Bíbélì Pùròtẹ́sítáǹtì tí kò wọ́n, tí àwọn ẹgbẹ́ tí ń ṣe Bíbélì ṣe, wà lárọ̀ọ́wọ́tó, Ìjọ Kátólíìkì gba àwọn ọ̀mọ̀wé tó jẹ́ Kátólíìkì láyè láti túmọ̀ Bíbélì sí èdè Faransé. Ìtumọ̀ tí Augustin Crampon ṣe, tí a kọ́kọ́ tẹ̀ jáde ní ìdìpọ̀ méje (1894 sí 1904) àti lẹ́yìn náà ní ìdìpọ̀ kan (1904), ni ìtumọ̀ àkọ́kọ́ ti Kátólíìkì ní èdè Faransé láti inú èdè tí wọ́n fi kọ ọ́ ní ìpilẹ̀ṣẹ̀. Ọ̀pọ̀ yanturu àkíyèsí ẹsẹ̀ ìwé tí a fi òye ìmọ̀ ìwé gbé kalẹ̀ àti òtítọ́ náà pé Crampon lo orúkọ Ọlọ́run, Jéhovah, bí wọ́n ṣe ń pè é ní èdè Faransé dáadáa, gba àfiyèsí.
Ní yíyóhùnpadà nínú lẹ́tà tí Vatican kọ sí àwọn bíṣọ́ọ̀bù náà, Divino Afflante Spiritu, ní 1943, nígbẹ̀yìngbẹ́yín, ó gbé ìlànà ìtọ́sọ́nà kan kalẹ̀ fún títúmọ̀ Bíbélì sí àwọn èdè àdúgbò. Ọ̀pọ̀ àwọn ìtumọ̀ ti Kátólíìkì ni wọ́n ti ṣe jáde láti ìgbà náà wá, títí kan Jerusalem Bible tí ó gbajúmọ̀ náà, tí wọ́n kọ́kọ́ ṣe jáde ní èdè Faransé àti lẹ́yìn náà tí wọ́n wá túmọ̀ sí onírúurú àwọn èdè míràn, títí kan Gẹ̀ẹ́sì.
Bíbélì kan tí ó ti ran àwọn ènìyàn tí ń sọ èdè Faransé lọ́wọ́ jákèjádò ayé ni ẹ̀dà New World Translation of the Holy Scriptures ní èdè Faransé. A kọ́kọ́ ṣé e jáde lódindi ní 1974, a ṣàtúnṣe rẹ̀ ní 1995. Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ èdè tí a ti ṣe é jáde títí di báyìí, New World Translation fi ìyìn fún Olùpilẹ̀ṣẹ̀ Bíbélì nípa dídá orúkọ rẹ̀, Jèhófà, pa dà sí àyè rẹ̀ nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù àti, níbi tí ó bá tọ́, nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Gíríìkì. Títí di báyìí, ó lé ní mílíọ̀nù márùn-ún ẹ̀dà rẹ̀ tí a ti tẹ̀ jáde ní èdè Faransé. Láìsí àní-àní, Bíbélì ti borí ìjàkadì tí ó jà láti máa wà nìṣó ní èdè Faransé.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ìwé títẹ̀ lédè Faransé náà kẹ́sẹ járí débi pé nígbà tí Ìwádìí Láti Gbógun Ti Àdámọ̀ ní Sípéènì náà pàṣẹ kíkó àwọn Bíbélì àjèjì jọ ní 1552, ilé ẹjọ ti Seville ròyìn pé nǹkan bí ìpín 90 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn tí a gbẹ́sẹ̀ lé ni a ti tẹ̀ jáde ní ilẹ̀ Faransé!
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Bíbélì Lefèvre d’Étaples ti 1530
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Bíbélì Olivétan ti 1535
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Àpẹẹrẹ “Bíbélì ọ̀rúndún Kẹtàlá” kan tí kò wọ́pọ̀
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 17]
Àwọn Bíbélì: Bibliothèque Nationale de France