Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
Èèṣì Tàbí Àpilẹ̀ṣe? Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ parí kíka ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ náà, “Báwo La Ṣé Déhìn-ín? Nípasẹ̀ Èèṣì Ni Tàbí Nípasẹ̀ Àpilẹ̀ṣe?” (May 8, 1997) Ó wọ̀ mí lọ́kàn nítorí àwọn ìdí mélòó kan wọ̀nyí: (1) Ọ̀nà rírọrùn tí ẹ gbà gbé irú kókó ọ̀ràn lílọ́júpọ̀, tó jinlẹ̀ bí ẹfolúṣọ̀n kalẹ̀, àti ìdánilójú tí ẹ fi gbèjà èrò Bíbélì nípa bí a ṣe pilẹ̀. (2) Àwọn àpèjúwe tí ẹ lò láti rọ́wọ́ tẹ ìlépa yín tó yẹ fún ìgbóríyìn. Mo jẹ́ olùwádìí àti akẹ́kọ̀ọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ ìbánisọ̀rọ̀ títóbi kan. Irú àwọn àpilẹ̀kọ bẹ́ẹ̀ jẹ́ ẹ̀rí pé NÍGBÀ GBOGBO ni ẹ ń fara balẹ̀ wádìí jinlẹ̀ kí ẹ tó tẹ nǹkan jáde. Ó dájú pé ìyẹn ni ìdí tí gbogbo akọ̀ròyìn, olùyẹ̀wòṣàtúnṣe, àti olùwádìí bíi tèmi fi máa ń ka Jí! déédéé, tí wọ́n sì ń gbádùn rẹ̀.
D. S. T., Cameroon
Èrèdí Ṣíṣàìsàn Tó Bẹ́ẹ̀? Gbogbo ìmọ̀lára tí Jason sọ nínú àpilẹ̀kọ náà, “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . Èé Ṣe Tí Mo Fi Ń Ṣàìsàn Tó Bẹ́ẹ̀?” (April 22, 1997), ni mo ti nírìírí rẹ̀. Gbogbo ìgbà tí mo bá ń ka àpilẹ̀kọ náà ni mo ń nímọ̀lára bíi pé mo ń bá ẹnì kan tó lóye ipò mi, tó mọ̀ ọ́n, tó sì bìkítà nípa rẹ̀ fọ̀rọ̀ jomi toro ọ̀rọ̀. Ẹ ṣeun púpọ̀ fún dídín ẹrù ìnira mi kù. Mo mọ̀ pé Jèhófà ń bìkítà, àti pé yóò mú gbogbo àrùn kúrò, ní àkókò tí òun yàn.
O. A., Gánà
Ní ọ̀sẹ̀ méjì kí àpilẹ̀kọ yìí tó jáde, wọ́n ṣàwárí pé gìrì ń bá mi jà. Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ di ọmọ ọdún 18 ni, àìsàn sì ti dín gbogbo òmìnira tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ gbà láìpẹ́ kù. Ọ̀pọ̀ èèwọ̀ ni mo ní àti ọ̀pọ̀ egbòogi tí mo gbọ́dọ̀ máa rántí láti lò. Ó ti nípa lórí àwọn òbí mi pẹ̀lú, tí ọmọ wọn méjì mìíràn ti kú. Àpilẹ̀kọ náà wọ̀ mí lọ́kàn ní tòótọ́ lọ́nà kan tó mú mi sunkún. Ó sọ̀rọ̀ nípa àwọn èrò tí mo ti ń tẹ̀ rì, ara mi sì dá lọ́nà kan ṣáá. Mo lè rí i pé àwọn ẹlòmíràn tún wà tí wọ́n ní ìṣòro àti hílàhílo tó jọ tèmi. Jèhófà ń tẹ ìsọfúnni tí mo nílò láti máa lókun nìṣó jáde nípasẹ̀ ètò àjọ rẹ̀.
D. S., United States
Nígbà tí mo ka àpilẹ̀kọ náà, mo mọ̀ pé àìsàn mi ń fa ìrora fún àwọn òbí mi ju ẹnikẹ́ni mìíràn lọ. Wọ́n sọ fún mi pé mo jogún àìsàn mi ni, èyí sì ń mú wọn sorí kọ́. Nígbà tí mo bá rí i tí wọ́n sorí kọ́, àánú wọn máa ń ṣe mí.
Y. H., Japan
Ara mi dá ṣáṣá nígbà tí mo wà lọ́mọdé. Ṣùgbọ́n nígbà ìbàlágà, mo ń ṣàìsàn léraléra ni. Mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún, n kò sì lè bá góńgó mi láàárín oṣù méjì àkọ́kọ́ nítorí àìlera. Mo sorí kọ́ gan-an, ní ríronú (lọ́nà òdì) pé mo ti ṣe ohun búburú kan lójú Jèhófà, ó sì ń fìyà jẹ mí nípasẹ̀ àìsàn. Àpilẹ̀kọ náà ti ràn mí lọ́wọ́ láti mú ara mi bá ipò mi mu bó ṣe yẹ, kí n sì mọ́kàn.
C. K., Gánà
Ọmọbìnrin mi ọlọ́dún mẹ́sàn-án ní ìṣòro àìlèkẹ́kọ̀ọ́ kan àti ìbàjẹ́ ọpọlọ níhà tí ń darí ìséraró àti ìsọ̀rọ̀. Ó jáfáfá gan-an, ó sì mọ̀ pé àbùkù tí òun ní ń pààlà sí àwọn ìgbòkègbodò tó yẹ kí òun máa ṣe. Láìka ti pé ó ní ìṣarasíhùwà ìtúraká àti aláyọ̀ sí, èyí máa ń mú un sorí kọ́ díẹ̀. Àpilẹ̀kọ yìí àti àwọn ìjíròrò alaalẹ́ tí bàbá rẹ̀ ń bá a ṣe nípa Párádísè ọjọ́ ọ̀la, níbi tí yóò ti dà bí àwọn ọmọdé mìíràn, ń fún un níṣìírí.
Y. P., United States
Nǹkan bí ọdún mẹ́wàá ni mo ti fi ń bá ‘àrùn tí kò hàn síta’ kan, tí ń dààmú ìgbékalẹ̀ oúnjẹ dídà nínú mi, yí. Nítorí rẹ̀, mo ti ní láti fi iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún sílẹ̀. Nígbà tí mo kọ́kọ́ ń ka àpilẹ̀kọ yìí, mo lérò pé ẹnì kan lóye ohun tí mo ń bá yí. Ó tù mí lára láti mọ̀ pé èmi nìkan kọ́. Ńṣe ló dà bíi pé a sọ ẹrù ìnira ńlá kan kalẹ̀ lórí mi. Ẹnu mi kò gba ọpẹ́. Àwọn àpilẹ̀kọ tí ń fúnni níṣìírí, tó sì ń bọ́ sákòókò wọ̀nyí, ń fún wa lókun nínú ètò ìgbékalẹ̀ ògbólógbòó yìí.
L. C., Kánádà