ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g98 3/8 ojú ìwé 3-4
  • Báwo Ni O Ṣe Lè Gbẹ́kẹ̀ Lé Sáyẹ́ǹsì Tó?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Báwo Ni O Ṣe Lè Gbẹ́kẹ̀ Lé Sáyẹ́ǹsì Tó?
  • Jí!—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bí Sáyẹ́ǹsì Ṣe Rọ́wọ́ Mú
  • Mímú Ìmọ̀ Sáyẹ́ǹsì àti Ìsìn Ṣọ̀kan
    Jí!—2002
  • Ṣé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ka Sáyẹ́ǹsì Sí?
    Àwọn Ìbéèrè Táwọn Èèyàn Sábà Máa Ń Béèrè Nípa Ẹlẹ́rìí Jèhófà
  • Ìròyìn Nípa Sáyẹ́ǹsì—Etí Wo Lo Fi Ń Gbọ́ Ọ?
    Jí!—1998
  • Báwo Ni Àgbáálá Ayé àti Ìwàláàyè Ṣe Bẹ̀rẹ̀?
    Jí!—2002
Àwọn Míì
Jí!—1998
g98 3/8 ojú ìwé 3-4

Báwo Ni O Ṣe Lè Gbẹ́kẹ̀ Lé Sáyẹ́ǹsì Tó?

LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ AUSTRALIA

Ọ̀PỌ̀ ènìyàn ló ń gbóṣùbà fún sáyẹ́ǹsì ní gidi, nítorí ọ̀pọ̀ àṣeyọrí rẹ̀ nínú ìṣègùn, ìmọ̀ ẹ̀rọ, ètò ìbánisọ̀rọ̀, àti àwọn ẹ̀ka ìmọ̀ mìíràn. Àwọn àwárí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì ti nípa lórí ìgbésí ayé ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn tó wà láàyè lónìí. Ọ̀pọ̀ onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti fi gbogbo ìgbésí ayé wọn jin sáyẹ́ǹsì, ó sì yẹ kí a gbóríyìn fún àwọn ìsapá aláìlábòsí ti ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì tí ó wà fún mímú ìgbésí ayé sunwọ̀n. Ní gidi, òǹkọ̀wé Tony Morton lọ jìnnà gan-an láti sọ pé “láìsíyèméjì, sáyẹ́ǹsì jẹ́ ọ̀kan lára òpó tó ń múlé ọ̀làjú òde òní ró.”

Àmọ́, nínú gbogbo ẹ̀ka ìgbésí ayé, ó yẹ láti wà déédéé ní dídíyelé ìníyelórí tòótọ́, kò sì yọ ẹ̀ka ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì sílẹ̀. Láti ràn wá lọ́wọ́, kí a lè ní irú èrò wíwàdéédéé bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ kí a ṣàyẹ̀wò ohun tí òǹkọ̀wé mìíràn, ẹni tí kò fi bẹ́ẹ̀ gbóríyìn fún ipa tí sáyẹ́ǹsì ń kó nínú ìgbésí ayé wa, sọ. Nínú ìwé The Unnatural Nature of Science tí Lewis Wolpert kọ, ó wí pé: “Àwọn ìwádìí fi hàn pé àwọn ènìyàn ní ọkàn ìfẹ́ púpọ̀ nínú sáyẹ́ǹsì, wọ́n gbóṣùbà fún un, wọ́n sì ní ìgbàgbọ́ tí kò tọ̀nà nínú rẹ̀ pé ó lè yanjú gbogbo ìṣòro; ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn kan tún ní ìbẹ̀rù àti ìkórìíra tó lágbára . . . Wọ́n ka àwọn tí ń ṣiṣẹ́ lórí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì sí àwọn ògbógi onímọ̀ tí kì í túra ká, tí a kì í dá mọ̀, tí kì í sì í bìkítà.”

Bí Sáyẹ́ǹsì Ṣe Rọ́wọ́ Mú

Nígbàkúùgbà tí àwọn ìwádìí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì bá gbé ohun tuntun jáde, nǹkan eléwu kan sábà máa ń wà níbẹ̀. Ṣùgbọ́n bí àwọn àwárí tuntun bá ṣe ń fi hàn pé nǹkan eléwu náà níye lórí ni ìgbẹ́kẹ̀lé tí ará ìlú ní nínú sáyẹ́ǹsì ń pọ̀ sí i. Nítorí náà, ní fífi ògo àṣeyọrí àtẹ̀yìnwá ṣe fọ́nńté, sáyẹ́ǹsì ti túbọ̀ gbé àwọn ìgbésẹ̀ eléwu dé àyè kan, ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ẹnu yà, tí wọ́n sì ní ìtara ọkàn, ti wá ń wo sáyẹ́ǹsì bíi gbogboǹṣe tí yóò tán àwọn ìṣòro aráyé. Èyí ti mú kí ọ̀pọ̀ ènìyàn so àwọn ọ̀rọ̀ náà, “sáyẹ́ǹsì” àti “ti sáyẹ́ǹsì,” pọ̀ mọ́ òtítọ́ tí kò kù síbì kankan.

Lẹ́tà ìròyìn American Studies sọ pé: “Bẹ̀rẹ̀ láti àwọn ọdún 1920, tí ó sì pọ̀ sí i ní àwọn ọdún 1930, onímọ̀ sáyẹ́ǹsì tí ń wọ aṣọ àwọ̀lékè funfun níyàrá ìwádìí ń fún àwọn arajàlò ní ìdánilójú àìṣẹ̀tàn pé ohun kan tí òun ṣe jáde dára ‘lọ́nà ti sáyẹ́ǹsì’ ju àwọn tí ń bá a díje lọ. Ọ̀rọ̀ olóòtú kan nínú ìwé ìròyìn Nation ní 1928 kédàárò pé, ‘ní gbogbogbòò, gbólóhùn tí ó bá ti bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú “Sáyẹ́ǹsì wí pé” ni yóò yanjú àríyànjiyàn èyíkéyìí níbi àpéjọ ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà, tí yóò sì jẹ́ kí ọjà èyíkéyìí tà, láti orí ọṣẹ ìfọyín dé orí ẹ̀rọ fìríìjì.’”

Àmọ́ ṣé lóòótọ́ ni sáyẹ́ǹsì ń jẹ́ òtítọ́ tí kò kù síbì kankan nígbà gbogbo? Jálẹ̀jálẹ̀ ìtàn ni àwọn àwárí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì ti ń ní alátakò gidi. Àwọn àtakò kan tí ń yọjú kì í lẹ́sẹ̀ nílẹ̀; ó sì jọ pé àwọn mìíràn ń lẹ́sẹ̀ nílẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, àwọn àwárí tí Galileo ṣe, mú kí Ìjọ Kátólíìkì bínú ní gbangba. Àwọn àbá èrò orí tí ó bá ìlànà sáyẹ́ǹsì mu nípa bí ènìyàn ṣe pilẹ̀ ṣẹ̀ fa ìhùwàpadà kíkorò lórí ìpìlẹ̀ ti sáyẹ́ǹsì àti ti Bíbélì lápapọ̀. Nítorí náà, kò yani lẹ́nu pé àwárí kọ̀ọ̀kan tí sáyẹ́ǹsì ń ṣe ń ní àwọn tó fara mọ́ ọn àti àwọn tó ta kò ó.

Látijọ́, òwe Látìn kan sọ pé: “Aláìmọ̀kan nìkan ni ọ̀tá sáyẹ́ǹsì [tàbí, ìmọ̀].” Àmọ́, èyí kì í ṣe òtítọ́ mọ́, nítorí pé a ti gbógun ti sáyẹ́ǹsì lónìí ju ti ìgbàkúùgbà rí lọ—kì í sì í ṣe láti ọ̀dọ̀ àwọn aláìmọ̀kan. Ó jọ pé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ènìyàn ti ka sáyẹ́ǹsì sí ohun tí kò ṣeé gbógun tì rí, àwọn alátìlẹ́yìn rẹ̀ nígbà kan rí ló ń gbógun tì í nísinsìnyí. Iye tí ń pọ̀ sí i lára àwọn tí ń tẹ̀ lé e lẹ́yìn ni a lè sọ pé wọ́n ti wá di adájọ́, olùgbẹ́jọ́, àti aṣekúpani rẹ̀. Àwọn ibùdó ìkẹ́kọ̀ọ́ sáyẹ́ǹsì tó lókìkí ti wá di ojúde ìforígbárí lọ́pọ̀ ìgbà. Ìdí kan tí ó fi ń kojú ìṣòro wọ̀nyí ni pé, àwọn ẹ̀tàn àti ìwà ìbàjẹ́ tí àwọn ògbógi onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti hù sẹ́yìn ti ń hàn sí gbangba.

Nípa bẹ́ẹ̀, ìbéèrè tí a ń béèrè léraléra ju ti ìgbàkúùgbà rí lọ náà ni pé, Ǹjẹ́ a lè gbẹ́kẹ̀ lé gbogbo ohun tí sáyẹ́ǹsì bá gbé jáde? Àpilẹ̀kọ tó kàn yóò mẹ́nu ba díẹ̀ lára àwọn ìdí tí àwọn ènìyàn tí iye wọn ń pọ̀ sí i fi ń béèrè ìbéèrè yìí.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 4]

Ṣé nígbà gbogbo ni sáyẹ́ǹsì ń jẹ́ òtítọ́ tí kò kù síbì kankan ni?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́