ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g98 3/8 ojú ìwé 26-27
  • A Sá fún Bọ́ǹbù—50 Ọdún Lẹ́yìn Náà!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • A Sá fún Bọ́ǹbù—50 Ọdún Lẹ́yìn Náà!
  • Jí!—1998
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • A Wàásù “Ìhìn Rere” Ní Àwọn Erékùṣù Jíjìnnà Réré Ní Àríwá Ọsirélíà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Erékùṣù Cocos—Ìtàn Ìṣúra Abẹ́ Ilẹ̀ Rẹ̀
    Jí!—1997
  • Òkè Ayọnáyèéfín Tẹ́lẹ̀ Rí Di Erékùṣù Tó Pa Rọ́rọ́
    Jí!—2000
  • Kíkéde Ìjọba Ọlọ́run ní Àwọn Erékùṣù Fíjì
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
Jí!—1998
g98 3/8 ojú ìwé 26-27

A Sá fún Bọ́ǹbù—50 Ọdún Lẹ́yìn Náà!

“Àwọn bọ́ǹbù yóò bẹ̀rẹ̀ sí í bú gbàù níhìn-ín láìpẹ́. Kí olúkúlùkù lọ fara pa mọ́!”

ÀWỌN ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn ni ọlọ́pàá kan sọ láti kìlọ̀ fún èmi àti ọkọ mi láti jáde nílé, kí a sì fara pa mọ́ sínú ihò oníkọnkéré kan tó wà nítòsí. Ìkéde náà báni lójijì gidigidi. Ó ṣe tán, a kò sí ní apá ibi tí ogun ti ń jà kíkankíkan lágbàáyé; ńṣe la ń ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ nínú ọ̀kan lára àwọn erékùṣù olómi-láàárín rírẹwà tó jìnnà díẹ̀ sí Erékùṣù Marshall, ní Micronesia.

Ńṣe ni a wá lo ọ̀sẹ̀ kan lọ́dọ̀ ọ̀rẹ́ wa kan àti ọkọ rẹ̀ ní erékùṣù kékeré ti Tõrwã. Ìyàwó ni Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan ṣoṣo tó wà ní erékùṣù náà, a sì fẹ́ láti ràn án lọ́wọ́ láti wàásù fún àwọn ènìyàn tí ń gbé ibẹ̀.

Àwọn ará Marshall jẹ́ ẹlẹ́mìí ọ̀rẹ́ lọ́nà àdánidá, wọ́n sì ń hára gàgà láti sọ̀rọ̀ nípa Bíbélì. Níwọ̀n bí a ti ṣẹ̀ṣẹ̀ mú ìwé Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye jáde ní èdè àdúgbò wọn, a ní àǹfààní láti fi ẹ̀dà mélòó kan sóde. Gbogbo àwọn tí ń fẹ́ láti ní ìwé náà mú un dá wa lójú pé àwọn yóò kà á, àwọn kò sì ní sọ ọ́ di ken karawan kan, tàbí “àwúre oríire” kan láti máa fi lé ẹ̀mí èṣù. Àṣà kan tó wọ́pọ̀ níhìn-ín ni kí àwọn ènìyàn ká abala kan láti inú Bíbélì sínú ìgò, kí wọ́n sì so ó rọ̀ sára igi àjà ilé tàbí sára igi kan ládùúgbò, nítorí pé wọ́n rò pé ìyẹn ń lé àwọn ẹ̀mí búburú.

A ti ń gbádùn wíwà tí a wà níbẹ̀ fún ọjọ́ mélòó kan, ṣùgbọ́n ní Saturday, a wá rí i pé ìyàtọ̀ yóò wà. A bẹ̀rẹ̀ ọjọ́ náà nípa lílúwẹ̀ẹ́ tayọ̀tayọ̀ láàárọ̀ kùtùkùtù nínú omi lílọ́wọ́ọ́wọ́ inú adágún tó mọ́ tónítóní náà. Nígbà tí a ń rìn bọ̀ láti etíkun náà, a rí ọkọ̀ òkun bíbanilẹ́rù kan tó ní àwọ̀ eérú tí ń bọ̀. Láìpẹ́, a mọ ohun tó kó wá. Ọlọ́pàá kan ṣàlàyé pé agbo òṣìṣẹ́ kan tó ní ọmọ ogun méje láti Amẹ́ríkà nínú ti gúnlẹ̀ láti wá fọ́ àwọn ògbólógbòó bọ́ǹbù ní erékùṣù náà. Láti dáàbò bo àwọn ará ìlú, àwọn ènìyàn yóò jáde kúrò nílé, àwọn ará erékùṣù náà yóò sì lo ọjọ́ náà nínú àwọn ihò oníkọnkéré tí àwọn ará Japan ti gbẹ́ nígbà Ogun Àgbáyé Kejì.

Àwọn ihò oníkọnkéré wọ̀nyẹn, tí ń gbàfiyèsí àlejò tó bá wọ Tõrwã lọ́gán, jẹ́ ẹ̀rí ìṣẹ̀lẹ̀ bíbanilẹ́rù tó tí ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn. Bí a bá ń wo erékùṣù náà lókèèrè, ó dà bíi párádísè ilẹ̀ olóoru kan ní gbogbo ọ̀nà, àmọ́, bí a bá sún mọ́ ọn, ó ṣe kedere pé àwọn àpá ogun kan tó parí ní nǹkan bí 50 ọdún sẹ́yìn ti ba ẹwà Tõrwã jẹ́. Erékùṣù náà, tó jẹ́ ibùdó ẹgbẹ́ ọmọ ogun òfuurufú ilẹ̀ Japan nígbà kan rí, kún fún àwọn ohun ìránnilétí Ogun Àgbáyé Kejì. Níbi gbogbo, àwọn àlòkù ohun èlò ogun tí ń bà jẹ́ lọ wà káàkiri—àwọn ọkọ̀ òfuurufú ológun, àwọn ìbọn tí a gbé sípò, àti àwọn ẹ̀rọ tí ń fọ́ ọkọ̀ ojú omi yángá—tí àwọn ewéko ilẹ̀ olóoru ti hù bò.

Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn bọ́ǹbù tó ṣẹ́ kù náà ló ń bani lẹ́rù jù. Nígbà ogun náà, àwọn ológun United States ju ohun tí ó lé ní 3,600 tọ́ọ̀nù bọ́ǹbù, àwọn bọ́ǹbù oníná, àti àwọn rọ́kẹ́ẹ̀tì, sí Tõrwã, àwọn ará Japan sì ní ìtòpelemọ bọ́ǹbù àti àwọn ohun ìjà mìíràn níbẹ̀. Nígbà tí kò jọ pé bọ́ǹbù tó ti pé 50 ọdún lè bú gbàù, nígbà gbogbo ni wọ́n jẹ́ orísun ewu, èyí tó ṣàlàyé ìdí tí àwọn agbo òṣìṣẹ́ tí ń palẹ̀ bọ́ǹbù mọ́ ti fi ṣèbẹ̀wò sí erékùṣù náà nígbà márùn-ún, ó kéré tán, láti 1945, ọdún tí ogun náà parí.

A ṣe kàyéfì bóyá ìkìlọ̀ náà jẹ́ òótọ́ ní gidi, nítorí náà, a rìn lọ sí ibi tí agbo àwọn òṣìṣẹ́ tó wá palẹ̀ bọ́ǹbù mọ́ náà gúnlẹ̀ sí, a sì bá wọn sọ̀rọ̀. Wọ́n sọ pé, kì í ṣe pé ìkìlọ̀ náà jẹ́ òtítọ́ nìkan ni, ṣùgbọ́n láàárín wákàtí náà gan-an ni àwọn bọ́ǹbù yóò bẹ̀rẹ̀ sí í bú gbàù! Wọ́n sọ fún wa pé, bí a kò bá ní fara pa mọ́ sínú ihò oníkọnkéré kan, a óò ní láti fi erékùṣù náà sílẹ̀ lójú ẹsẹ̀.

Ọ̀rẹ́ wa pinnu láti wà ní Tõrwã, òun àti àwọn ìdílé mélòó kan sì fara pamọ́ sì inú ihò oníkọnkéré ńlá kan ti wọ́n gbé ìbọn ẹlẹ́rọ kan sí nígbà ogun. Ó sọ fún wa níkẹyìn pé kìkì àyè ẹnu ìbọn ló jẹ́ fèrèsé inú ihò oníkọnkéré náà, àti pé, inú rẹ̀ lọ́hùn-ún móoru gan-an, ó sì há. Lílo ọjọ́ náà níbẹ̀ mú kí ó rántí àwọn ọdún àkókò ogun, ó sì jẹ́wọ́ pé, nígbà tí ìró ìbúgbàù àwọn bọ́ǹbù náà dùn mọ́ òun nígbà tí òun jẹ́ ọmọdé, ó jọ pé wọ́n ń ba òun lẹ́rù gidigidi nísinsìnyí.

Ọkọ rẹ̀ ti gbà láti fi ọkọ̀ ojú omi kékeré kan tó ní ẹ̀rọ ìtukọ̀ tù wá lọ sí Erékùṣù Wollet, tí ó wà ní kìlómítà mẹ́jọ sí ibẹ̀. A ṣẹ̀ṣẹ̀ tukọ̀ lọ fún ìṣẹ́jú mélòó kan nígbà tí a gbọ́ ìró ìbúgbàù ńlá kan. Nígbà tí a bojú wo Tõrwã lẹ́yìn, a rí ọwọ̀n èéfín tí ń ga sókè nítòsí àgbègbè tí àwọn ènìyàn ń gbé ní erékùṣù náà. Láìpẹ́, a tún gbọ́ ìró ìbúgbàù mìíràn, àti ẹ̀kẹta tí ó tóbi jù gan-an.

A fi ọjọ́ náà wàásù ní Wollet, ó sì jẹ́ ọjọ́ kan tí a ń gbọ́ ìró ìbúgbàù bọ́ǹbù látòkèèrè. Wọ́n ti ṣàwárí àwọn ògbólógbòó bọ́ǹbù náà lóṣù mélòó kan ṣáájú, wọ́n sì ti sàmì sí ibi tí wọ́n wà. Àwọn ohun abúgbàù wà níbi gbogbo—ní àwọn etíkun, ní ilẹ̀ tó jìn sí etíkun níbi tí ọkọ̀ òfuurufú ti ń balẹ̀, kódà, ní ẹ̀yìnkùlé àwọn ènìyàn pàápàá! Láti dín iye ìbúgbàù náà kù, agbo òṣìṣẹ́ tí ń palẹ̀ bọ́ǹbù mọ́ náà ti gbá àwọn bọ́ǹbù kéékèèké mélòó kan jọ sójú kan, wọ́n sì fọ́ wọn yángá lápapọ̀.

Ọjọ́ ti fẹ́rẹ̀ẹ́ rọ̀ nígbà tí a fi padà dé Tõrwã. Bí a ti sún mọ́ erékùṣù náà, a kíyè sí i pé kò sí èéfìn iná ìseúnjẹ tí ó wọ́pọ̀ níbẹ̀. A mọ̀ pé ohun búburú kan ń ṣẹlẹ̀. Lójijì, ọkọ̀ àjẹ̀ kékeré kan sáré wá sọ́dọ̀ wa, láti kìlọ̀ fún wa pé kí a má ṣe sún mọ́ erékùṣù náà jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ó ṣì ku bọ́ǹbù ńlá kan tí a rì sínú omi tí wọ́n fẹ́ fọ́ yángá nítòsí òkìtì iyanrìn etíkun náà. Nípa bẹ́ẹ̀, bí a ti ń sún lọ kúrò létíkun náà ní ọwọ́ alẹ́, a rí ohun kan tí ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn tó wà láàyè lónìí kò rí rí—ìbúgbàù bọ́ǹbù Ogun Àgbáyé Kejì kan lábẹ́ omi, tó tú ìrútúú omi àti èéfín gígùn gbọọrọ tó ọgọ́rọ̀ọ̀rún mítà sáfẹ́fẹ́!

A láyọ̀ pé, kò sí ẹnì kankan tó fara pa ní erékùṣù Tõrwã lọ́jọ́ náà. Ǹjẹ́ àwọn agbo òṣìṣẹ́ tí ń palẹ̀ bọ́ǹbù mọ́ náà ti palẹ̀ gbogbo bọ́ǹbù tó kù ní erékùṣù náà mọ́ níkẹyìn báyìí? Ó ṣeé ṣe kó máà jẹ́ bẹ́ẹ̀. Aṣáájú agbo òṣìṣẹ́ náà sọ pé òun retí pé kí àwọn ará erékùṣù náà tún rí àwọn ògbólógbòó ohun abúgbàù sí i lọ́jọ́ iwájú. Dájúdájú, ìyẹn fún wa ní kókó ọ̀rọ̀ wíwọnilọ́kàn mìíràn láti bá àwọn ènìyàn jíròrò lé lórí bí a ti ń parí iṣẹ́ ìwàásù wa ní Tõrwã. Ó jẹ́ àǹfààní gidi kan láti sọ fún àwọn ará erékùṣù yìí nípa àkókò tí Ìjọba Jèhófà yóò “mú kí ogun kásẹ̀ nílẹ̀ títí dé ìkángun ilẹ̀ ayé.”—Sáàmù 46:9.

Gẹ́gẹ́ bí Nancy Vander Velde ṣe sọ ọ́

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]

Bọ́ǹbù kan tí kò bú gbàù

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́