Wíwo Ayé
Kíka Bíbélì Ń Ṣàǹfààní
Gẹ́gẹ́ bí ìwádìí kan tí àjọ akọ̀ròyìn Associated Press ròyìn rẹ̀ ti sọ, àwọn ará Amẹ́ríkà tí wọ́n ń ka Bíbélì lẹ́ẹ̀kan lọ́sẹ̀, ó kéré tán, túbọ̀ ń ní ayọ̀, àti ìtẹ́lọ́rùn, wọ́n sì ń nímọ̀lára ète gíga nínú ìgbésí ayé ju àwọn tí kì í fi bẹ́ẹ̀ ka Bíbélì lọ. Nínú ìwádìí kan tí àjọ Market Facts, Inc., ti Illinois, ṣe lọ́dọ̀ àwọn àgbàlagbà káàkiri Amẹ́ríkà, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìpín 90 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn tí wọ́n ń ka Bíbélì déédéé tó sọ pé ọkàn àwọn ń balẹ̀ ní gbogbo ìgbà tàbí ní ìgbà púpọ̀ jù lọ, ní ìfiwéra pẹ̀lú ìpín 58 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn tí kì í ka Bíbélì tó ẹ̀ẹ̀kan lóṣù. Síwájú sí i, ìpín 15 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn tí ń ka Bíbélì déédéé sọ pé àwọn ń ṣàníyàn nípa pé àwọn ẹlòmíràn yóò tẹ́wọ́ gba àwọn, ní ìfiwéra pẹ̀lú ìpín 28 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn tí kì í kà á déédéé. Ìpín 12 péré nínú ọgọ́rùn-ún àwọn tí ń kà á déédéé sọ pé àwọn ń ṣàníyàn lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan tàbí púpọ̀púpọ̀ nípa ikú, ní ìfiwéra pẹ̀lú ìpín 22 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn tí kì í kà á déédéé.
Ohun Tí Àwọn Ọmọ Ọwọ́ Ń Gbọ́
Ìwé agbéròyìnjáde The New York Times sọ pé, ìwádìí lọ́ọ́lọ́ọ́ jẹ́rìí pé ìwọ̀n ọ̀rọ̀ tí ọmọ ọwọ́ kan ń gbọ́ àti bí ó ṣe dún ń nípa lórí agbára rẹ̀ láti ronú lọ́nà tí ó bọ́gbọ́n mu, láti yanjú ìṣòro, àti láti finú wòye nǹkan nípa ohun tí kò ṣeé rí. Ìwádìí kan tí wọ́n ṣe ní Yunifásítì Iowa fi hàn pé àwọn ọmọ tí àwọn òbí wọn jẹ́ amọṣẹ́dunjú ń gbọ́ ìpíndọ́gba 2,100 ọ̀rọ̀ ní wákàtí kọ̀ọ̀kan, nígbà tí àwọn tí àwọn òbí wọn ń ṣiṣẹ́ ọ́fíìsì ń gbọ́ 1,200 ọ̀rọ̀, àwọn ti àwọn òbí wọn ń ṣiṣẹ́ ìfẹ́dàáfẹ́re sì ń gbọ́ 600 péré. Bí ohùn òbí náà ṣe ń dún—ìfúnni-níṣìírí, ìbániwí, ìṣọ̀yàyà, tàbí ìpàṣẹfúnni—ni a tún ṣàkíyèsí. Ìwádìí tí wọ́n fi ọdún méjì ààbọ̀ ṣe náà fi hàn pé ohun yíyàtọ̀síra tí ó ń gbọ́ náà “ní ipa gidigidi lórí agbára ọmọ ọwọ́ kọ̀ọ̀kan láti finú wòye nǹkan nípa ohun tí kò ṣeé rí tí ó bá di ọmọ ọdún 4.” Ọ̀kan lára àwọn olùṣèwádìí náà, Ọ̀mọ̀wé Betty Hart, sọ pé, ọdún mẹ́ta àkọ́kọ́ jẹ́ àrà ọ̀tọ̀ nínú ìgbésí ayé ẹ̀dá ènìyàn nítorí àwọn ọmọ ọwọ́ gbára lé àwọn àgbàlagbà pátápátá fún títọ́ wọn dàgbà àti kíkọ́ wọn lédè.
Àwọn Kòkòrò Àrà Ọ̀tọ̀
Pákí ni lájorí oúnjẹ nǹkan bí 200 mílíọ̀nù ènìyàn ní Áfíríkà. Nísinsìnyí ẹ̀wẹ̀, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ kòkòrò kékeré tí ń jẹ́ Typhlodromalus aripo, tí ń jẹ àwọn kòkòrò mìíràn, pákí púpọ̀púpọ̀ sí i ti wà ti yóò tó gbogbo ènìyàn. Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn New Scientist ti sọ, wọ́n gbé kòkòrò T. aripo náà wá láti Brazil láti gbógun ti ọ̀kan lára àwọn kòkòrò tí ń ba pákí jẹ́ jù lọ lágbàáyé, kòkòrò spider mite aláwọ̀ ewé, tí ó ba nǹkan bí ìdámẹ́ta pákí ilẹ̀ Áfíríkà jẹ́. Àwọn olùṣèwádìí ṣàwárí pé ìhà àríwá ìlà oòrùn Brazil, tí pákí ti pọ̀, ní ìṣòro díẹ̀ tí kòkòrò spider mite aláwọ̀ ewé náà fà. Wọ́n ṣàwárí pé àwọn kòkòrò tí ń jẹ àwọn kòkòrò mìíràn náà, T. aripo, jókòó sí etí irúgbìn náà tí wọ́n ń dúró de àwọn kòkòrò mite aláwọ̀ ewé náà láti fara hàn, kí wọ́n sì jẹ wọ́n. Ìwé ìròyìn náà sọ pé, kì í ṣe pé T. aripo pa nǹkan bí ìpín 90 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn kòkòrò spider mite aláwọ̀ ewé náà nìkan ni, àmọ́ wọ́n tún ran àwọn àgbẹ̀ lọ́wọ́ láti má lo àwọn oògùn apakòkòrò, tí ọ̀pọ̀ lára wọn kò rówó rà.
Ẹni Méjì Sàn Ju Ẹnì Kan Lọ
Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn New Scientist ti Britain ti sọ, àwọn ènìyàn ní àṣeyọrí tí ó pọ̀ sí i nínú gbígbìyànjú láti ṣàmúlò ọ̀nà ìgbésí ayé tí ó túbọ̀ sunwọ̀n nígbà tí wọ́n bá ní alábàáṣègbéyàwó tí ń ṣe bákan náà. Èyí ni ìparí èrò tí a dé nínú ìwádìí kan tí a ṣe lọ́dọ̀ àwọn 1,204 tọkọtaya, èyí tí a ròyìn nípa rẹ̀ nínú ìwé Archives of Family Medicine. Stephen Pyke, láti Ilé Ẹ̀kọ́ Ìmọ́tótó àti Ìṣègùn Ilẹ̀ Olóoru ti London, sọ pé: “Ó ṣeé ṣe púpọ̀ pé kí àwọn ènìyàn jáwọ́ nínú mímu sìgá, kí wọ́n dín èròjà cholesterol tí wọ́n ń jẹ kù, kí wọ́n má sì sanra jọ̀kọ̀tọ̀ bí tọkọtaya náà bá tẹ̀ lé ìmọ̀ràn náà.”
Ìtọ́jú Ohùn
Ìwé agbéròyìnjáde The Toronto Star sọ pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá ń lo ohùn rẹ̀ jù, bí olùkọ́, wà nínú ewu lílo ohùn rẹ̀ kọjá àlà, kí ó sì há. Bákan náà, kíkérara léraléra kí a lè gbọ́ni ní àyíká ibi tí ariwo ti pọ̀ lè ba àwọn okùn ohùn jẹ́. Onímọ̀ nípa àwọn àìsàn ọ̀rọ̀ sísọ àti èdè náà, Bonnie Mann, sọ pé, sísúfèé àti sísọ híhakẹ̀lẹ̀bẹ̀ di àṣà pẹ̀lú ń ba ohùn rẹ jẹ́. Ó gbaninímọ̀ràn láti má ṣe dúró di ìgbà tí ìṣòro náà bá di ńlá kí a tó ṣe nǹkan sí i, ó sì fún ipò ìrísí ara dídára níṣìírí kí iṣan ọrùn àti èjìká lè dẹ̀. Ó fi kún un pé: “Pàápàá jù lọ, ó ṣe pàtàkì kí o máà jẹ́ kí ọ̀fun rẹ gbẹ.” Bí o bá ní láti lo ohùn rẹ̀ púpọ̀púpọ̀, Mann dámọ̀ràn sísófèrè omi ní gbogbo ọjọ́.
Ṣíṣọ́ Ojú Ọjọ́ Ilẹ̀ Tibet
Ìwé ìròyìn New Scientist ròyìn pé, orílẹ̀-èdè mẹ́wàá ní àgbègbè Éṣíà òun Pàsífíìkì ti ṣètò àṣeyẹ̀wò kan láti ṣèwádìí nípa ẹ̀fúùfù. Iṣẹ́ àgbẹ̀ ní àwọn àgbègbè púpọ̀ ní Éṣíà gbára lé òjò tí ẹ̀fúùfù náà ń mú wá, àmọ́ ẹ̀rí fi hàn pé ìwọ̀nyí lè yàtọ̀ gan-an lọ́dọọdún. Àwọn awojú-ọjọ́-sàsọtẹ́lẹ̀ gbà gbọ́ pé òkè olórí títẹ́jú ti Tibet ni lájorí okùnfà òjò ẹlẹ́fùúùfù náà, àmọ́ ìsọfúnni oníṣirò tí ó wá láti Tibet kò tí ì sí lọ́wọ́ láti ṣàyẹ̀wò kúlẹ̀kúlẹ̀ rẹ̀. Lẹ́yìn ṣíṣàdéhùn pẹ̀lú China, wọ́n ti gbé àwọn ẹ̀rọ tí ènìyàn kò sí nídìí rẹ̀ sí Tibet láti máa ṣọ́ ìwọ̀n ìgbóná òun ìtutù, ọ̀rinrin, ẹ̀fúùfù, àti àwọn kókó abájọ mìíràn tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ojú ọjọ́ ní Himalaya. Àwọn olùṣèwádìí nírètí pé ìsọfúnni oníṣirò tí wọn yóò rí kó jọ yóò mú kí wọ́n túbọ̀ lóye sí i nípa àwọn ẹ̀fúùfù ní Éṣíà.
Wọ́n Wa Ibùjókòó Ìjọba Róòmù Jáde Nílẹ̀ Ísírẹ́lì
Ìròyìn Reuters kan sọ pé, àwọn awalẹ̀pìtàn ní Ísírẹ́lì ti wa ọgbà ibùjókòó ìjọba Róòmù kan, tí ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ ààfin adájọ́ Róòmù níbi tí wọ́n ti fi àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sẹ́wọ̀n ní Kesaréà, jáde nílẹ̀. Yosef Porath, olórí Àjọ Amúṣẹ́ṣe Nípa Ohun Ìṣẹ̀ǹbáyé Ísírẹ́lì ní Kesaréà, sọ pé àwọn awalẹ̀pìtàn tí wọ́n wà ní àgbègbè náà ti wa àwọn àwòrán tí ó ní àkọlé ọ̀rọ̀ èdè Látìn náà tí ń tọ́ka pé ó ṣeé ṣe kí ọ́fíìsì kan níbẹ̀ ti jẹ́ ilé iṣẹ́ ààbò ìlú. Porath sọ pé: “Àkọlé yìí báni yanjú ìṣòro tí ó wà nípa ibi tí wọn ti gbọ́ ẹjọ́ Pọ́ọ̀lù Mímọ́ níwájú gómìnà Róòmù tí a ṣàpèjúwe nínú Májẹ̀mú Tuntun.” Ó sọ pé àgbègbè náà ni ibùjókòó ìjọba Róòmù kan ṣoṣo tí a tí ì wà jáde nínú ilẹ̀ ní Ísírẹ́lì, òun sì ni ọ̀kan lára àwọn díẹ̀ tí ó wà ní àgbègbè Róòmù ìgbàanì.
A Fi Èèrà Ṣe Egbòogi
Nígbà ogun kan ní 1947, ó pọn dandan fún oníṣẹ́ abẹ fún ẹgbẹ́ ọmọ ogun ilẹ̀ China náà, Wu Zhicheng, láti dá àkóràn tí ń wọnú egbò àwọn tí wọ́n fara pa dúró, àmọ́ egbòogi tí ó ní ti tán. Bí àìnírètí ti fẹ́rẹ̀ẹ́ bò ó mọ́lẹ̀ tán, ó tọ adáhunṣe kan ládùúgbò lọ, ẹni tí ó júwe egbòogi ìbílẹ̀ ti China fún un—fífi omi tí a fi se èèrà fọ ojú egbò náà àti egbòogi tí a fi irú àwọn èèrà àkànṣe kan ṣe. Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn China Today ti sọ, ìyọrísí rẹ̀ fúnni níṣìírí gan-an tí Dókítà Wu fi dáwọ́ lé ìwádìí kan, tí ó gba àkókò gígùn, nípa ìlò àwọn èèrà bí egbòogi. Ó gbà gbọ́ pé egbòogi tí a fi èèrà ṣe ń ṣèrànwọ́ láti mú ìgbékalẹ̀ adènà àrùn wà déédéé, ó sì wí pé: “Èèrà jẹ́ ilé ìkóǹkansí kóńkó ti ohun ìṣaralóore. Ó ní ju 50 èròjà tí ara ẹ̀dá ènìyàn nílò lọ, èròjà ásíìdì amino 28 àti oríṣiríṣi èròjà mineral àti àpòpọ̀ oníkẹ́míkà.”
“Àìsàn Tí Iṣẹ́ Ọ́fíìsì Ń Fà”
Gẹ́gẹ́ bí ìwádìí kan tí Ọ̀jọ̀gbọ́n Maurizio Ricciardi, olùdarí ibùdó ìṣọwọ́jókòó ní Yunifásítì Siena, ṣe, ti sọ, ó lé ní ìpín 80 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ará Ítálì tí ń nírìírí ìṣòro ìṣọwọ́jókòó nítorí ìgbésí ayé ìjókòó-sójúkan. Ìwé agbéròyìnjáde Il Messaggero sọ pé, ó lé ní ìdajì lára àwọn tí wọ́n ní ìṣòro “àìsàn tí iṣẹ́ ọ́fíìsì ń fà” yí tó tún ń sọ pé àwọn ohun bí ẹ̀yìn ríro, ẹ̀fọ́rí, ìrìndọ̀, òòyì àti ìṣòro ìséraró, àìdúró-sójúkan ìwọ̀n ìfúnpá, ìgbẹ́ gbuuru, inú kíkún, ìwúlé ìfun ńlá, àti àrùn ìwúlé awọfẹ́lẹ́ inú àpòlúkù ń ṣe àwọn. Ricciardi sọ pé: “Lẹ́yìn wákàtí kọ̀ọ̀kan lẹ́nu iṣẹ́, àwọn ará Japan àti àwọn ará China máa ń ṣe àwọn eré ìmárale tí ó rọrùn” láti bá ìṣòro wọ̀nyí jà, àmọ́ ní ti wa, ìṣíwọ́ ráńpẹ́ tí a ń ní jẹ́ láti mu kọfí.”
Àwọn Ọ̀dọ́ Òǹkàwé Ará Brazil
Ìwé ìròyìn Exame sọ pé, ìmọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà àti iye ọdún tí àwọn àkẹ́kọ̀ọ́ ń lò ní ilé ẹ̀kọ́ ń pọ̀ sí i ní ilẹ̀ Brazil. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àyè púpọ̀ ṣì wà láti mú ipò nǹkan sunwọ̀n sí i, bí Àjọ Nípa Ayé àti Ohun Inú Rẹ̀ àti Àkọsílẹ̀ Oníṣirò ti Brazil ṣe sọ, láàárín 1991 sí 1995, àìmọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà nínú ọ̀wọ́ àwọn ọmọ ọdún 7 sí 14 fi ìpín 36 nínú ọgọ́rùn-ún lọ sílẹ̀. Ìpíndọ́gba iye ọdún tí wọ́n ń lò ní ilé ẹ̀kọ́ fi ìpín 10 nínú ọgọ́rùn-ún pọ̀ sí i láàárín 1990 sí 1995. Ọkàn ìfẹ́ tí ń pọ̀ sí i tí àwọn èwe ilẹ̀ Brazil ń ní nínú ìwé kíkà lè fara hàn nínú bí iye àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n lọ síbi ìpàtẹ ìwé kan tí ó wáyé ní Rio de Janeiro láìpẹ́ yìí ṣe fi nǹkan bí ìpín 40 nínú ọgọ́rùn-ún pọ̀ sí i. Ìwé agbéròyìnjáde O Estado de S. Paulo sọ pé, àwọn ìwé tó tà jù lọ níbi ìpàtẹ náà—tí ó jẹ́ ìpín 24 nínú ọgọ́rùn-un lára gbogbo ohun tí wọ́n tà níbẹ̀—ni àwọn ìwé tí a kọ fún àwọn ọ̀dọ́.
Àwọn Ará Punjab àti Ohun Dídì Nínú Kíndìnrín
Ìwé ìròyìn India Today International sọ pé, àwọn ará ìpínlẹ̀ Punjab àti àgbègbè rẹ̀ ní Íńdíà lè tètè ní ohun dídì nínú kíndìnrín ju ẹgbẹ́ àwùjọ èyíkéyìí mìíràn lágbàáyé lọ. Ìròyìn náà sọ pé, a mọ àwọn ará Punjab sí ẹni tí ń ṣiṣẹ́ kára, tí ó sì ń jẹun gan-an, àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà, wọn kì í mu omi tí ó pọ̀ tó ní àwọn oṣù ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn tí ó máa ń le gan-an. Nítorí ìdí yìí, níbi àpérò àgbáyé kan lórí àwọn ẹ̀yà ara tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ìtọ̀ tí wọ́n ṣe láìpẹ́ yìí, wọ́n ṣàpèjúwe àgbègbè wọn bí “àgbègbè olóhun dídì nínú kíndìnrín” lágbàáyé. Ìpíndọ́gba ìwọ̀n ohun dídì nínú kíndìnrín kan níbẹ̀ jẹ́ láàárín sẹ̀ǹtímítà méjì sí mẹ́ta [nǹkan bí íǹṣì kan], ní ìfiwéra pẹ̀lú sẹ̀ǹtímítà kan [tí kò tó ìlàjì íǹṣì kan] ní Yúróòpù àti United States. Ìròyìn náà so ìṣẹ̀lẹ̀ yìí mọ́ ìtẹ̀sí ṣíṣàìkọbi-ara sí àwọn ìrora pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ tàbí sísún ìgbàtọ́jú síwájú tí ọ̀pọ̀ àwọn ará Íńdíà ní. Àwọn onímọ̀ nípa ẹ̀yà ara tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ìtọ̀ sọ pé àwọn ènìyàn tí ara wọn le gbọ́dọ̀ máa mu, ó kéré tán, lítà méjì omi mímọ́tónítóní lójoojúmọ́.