Kí Ló Wà Níwájú fún Àwọn Obìnrin?
“ÌTÀN ìran ènìyàn jẹ́ ìtàn bí àwọn ọkùnrin ṣe ń pa àwọn obìnrin lára àti bí wọ́n ṣe ń fipá lé wọn kúrò nípò léraléra.” Bẹ́ẹ̀ ni Ìkéde Èrò ti Seneca Falls, New York, tí a kọ sílẹ̀ ní Amẹ́ríkà ní 150 ọdún sẹ́yìn ní ìlòdìsí àìṣẹ̀tọ́ fún àwọn obìnrin, ṣe kà.
Láìsíyèméjì, ìmúsunwọ̀n ti wà láti ìgbà náà wá, ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ìtẹ̀jáde The World’s Women 1995 láti ọwọ́ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ṣe sọ, àyè ṣì wà láti túbọ̀ ṣe dáradára sí i. Ó sọ pé: “Lọ́pọ̀ ìgbà, ìgbésí ayé àwọn obìnrin yàtọ̀ sí ti àwọn ọkùnrin, ìgbésí ayé wọn yàtọ̀ ní ti àǹfààní ẹ̀kọ́ kíkọ́ àti iṣẹ́ ṣíṣe, àti ìlera, ààbò ara ẹni àti àkókò ìgbafàájì.”
Mímọ èyí síwájú sí i ti mú kí àwọn orílẹ̀-èdè ṣe àwọn òfin láti dáàbò bo ẹ̀tọ́ àwọn obìnrin. Ṣùgbọ́n òfin kò lè yí ọkàn, ibi tí àìṣẹ̀tọ́ àti ẹ̀tanú ti ta gbòǹgbò, padà. Bí àpẹẹrẹ, gbé ìṣòro àwọn aṣẹ́wó ọmọbìnrin yẹ̀ wò. Ìwé ìròyìn Newsweek sọ nípa ìtìjú àgbáyé yìí pé: “Àwọn òfin tí a pète láti fòpin sí kíkó àwọn ọmọdé nífà ìbálòpọ̀ jẹ́ elérò-rere, ṣùgbọ́n lọ́pọ̀ ìgbà, wọn kì í gbéṣẹ́.” Lọ́nà kan náà, òfin fúnra rẹ̀ kì í dí ìwà ipá lọ́wọ́. Ìwé Human Development Report 1995 sọ pé: “Ẹ̀rí fi hàn pé híhùwà ipá sí àwọn obìnrin jẹ́ ìṣòro tó kárí ayé. Ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn òfin kò kúnjú ìwọ̀n láti fòpin sí irú ìwà ipá bẹ́ẹ̀—àyàfi bí àwọn ohun tí a kà sí pàtàkì ní ti àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ àti ti àwùjọ ẹ̀dá ènìyàn bá yí padà.”—Ìkọ̀wé wínníwínní jẹ́ tiwa.
“Àwọn ohun tí a kà sí pàtàkì ní ti àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ àti ti àwùjọ ẹ̀dá ènìyàn” ni a sábà máa ń gbé karí àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ tó fẹsẹ̀ rinlẹ̀—ohun kan tó ṣòro láti yí padà. Obìnrin kan láti Àáríngbùngbùn Ìlà Oòrùn sọ pé: “Àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ mú kí àwọn ọkùnrin gbà gbọ́ pé ńṣe ló yẹ ká máa lo àwọn obìnrin dípò kí a nífẹ̀ẹ́ wọn, kí a máa fi wọ́n ṣiṣẹ́ dípò kí a máa ṣìkẹ́ wọn. Nítorí náà, ẹnu obìnrin kò gba ọ̀rọ̀, kò ní ẹ̀tọ́ kankan, kò sì ní àǹfààní tó bẹ́ẹ̀ láti mú ipò rẹ̀ sunwọ̀n sí i.”
Kíkọ́ Àwọn Ọkọ àti Baba Lẹ́kọ̀ọ́
Ìkéde Ìpinnu Ìmúṣẹ́ṣe tí ìpàdé àpérò àgbáyé kan tí wọ́n ṣe nípa àwọn obìnrin ní 1995 dábàá rẹ̀ ní Beijing, China, polongo pé, kìkì “ìgbésẹ̀ àjùmọ̀ṣe gbogbogbòò lọ́gán” ló lè ṣàṣeyọrí “ìgbésí ayé alálàáfíà, yíyẹ, tó sì gba tẹlòmíràn rò,” tí yóò mú kí a bọlá fún àwọn obìnrin.
Ìgbésẹ̀ èyíkéyìí láti mú kí ìgbésí ayé àwọn obìnrin túbọ̀ ‘lálàáfíà, kó yẹ, kó sì ní ìgbatẹnirò,’ gbọ́dọ̀ bẹ̀rẹ̀ láti inú ilé, lọ́dọ̀ àwọn ọkọ àti àwọn baba. Nípa èyí, ó dá Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lójú pé, ẹ̀kọ́ Bíbélì ni kókó pàtàkì tí yóò mú àṣeyọrí wá. Wọ́n ti rí i pé ní gbàrà tí àwọn ọkùnrin bá ti kẹ́kọ̀ọ́ pé Ọlọ́run retí pé kí àwọn fi ọ̀wọ̀ àti ìgbatẹnirò bá àwọn ìyàwó àti àwọn ọmọbìnrin àwọn lò, wọn yóò fi sọ́kàn, wọn yóò sì ṣe é.
Ní Àáríngbùngbùn Áfíríkà, Pedro, baálé ọlọ́mọ mẹ́rin kan, ń fiyè sí àwọn àìní ìyàwó rẹ̀ ní báyìí. Ó ń bá a bójú tó àwọn ọmọ, ó sì tilẹ̀ ń bá a bu oúnjẹ fún àwọn àlejò tí wọ́n bá ń bá ìdílé náà jẹun pọ̀. Irú ìṣarasíhùwà onígbatẹnirò bẹ́ẹ̀ ṣọ̀wọ́n ní orílẹ̀-èdè rẹ̀. Kí ló mú kó mọyì ìyàwó rẹ̀, kó sì máa bá a fọwọ́ sowọ́ pọ̀?
Pedro ṣàlàyé pé: “Nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, mo kọ́ nípa àwọn ìlànà pàtàkì méjì tó kan ipa ti ọkọ. Wọ́n ti nípa gidigidi lórí ojú tí mo fi ń wo ìyàwó mi. Èkíní, nínú 1 Pétérù 3:7, ó ṣàlàyé pé ó yẹ kí ọkọ máa fi ọlá fún aya rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí “ohun èlò tí ó túbọ̀ jẹ́ aláìlera, ọ̀kan tí ó jẹ́ abo.” Èkejì, ní Éfésù 5:28, 29, sọ pé kí ọkọ máa nífẹ̀ẹ́ aya rẹ̀ ‘gẹ́gẹ́ bí ara òun fúnra rẹ̀.’ Láti ìgbà tí mo ti ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn yẹn, a ti túbọ̀ sún mọ́ra tímọ́tímọ́. Nítorí náà, àwa ọkùnrin gbọ́dọ̀ so ìjẹ́pàtàkì títóbi mọ́ ìmọ̀ràn Ọlọ́run ju àwọn àṣà ìbílẹ̀ lọ.”
Michael, tó wá láti Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà jẹ́wọ́ pé kí òun tó bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú Àwọn Ẹlẹ́rìí, òun kì í hùwà sí ìyàwó òun bó ṣe yẹ. Ó jẹ́wọ́ pé: “Mo tilẹ̀ máa ń lù ú nígbà tí inú bá bí mi. Ṣùgbọ́n Bíbélì kọ́ mi pé mo gbọ́dọ̀ yí ìwà mi padà. Ní báyìí, mo ń gbìyànjú gan-an láti káwọ́ ìbínú mi àti láti nífẹ̀ẹ́ aya mi bí ara èmi fúnra mi. Àwa méjèèjì sì túbọ̀ láyọ̀.” (Kólósè 3:9, 10, 19) Aya rẹ̀, Comfort, kín in lẹ́yìn pé: “Ní báyìí, Michael túbọ̀ ní ọ̀wọ̀ àti ìfẹ́ni fún mi ju bí ó ti jẹ́ àṣà ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn ọkọ ní àwùjọ wa lọ. A lè jọ sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìṣòro wa, kí a sì ṣiṣẹ́ pọ̀ bí agbo òṣìṣẹ́ kan.”
Pedro àti Michael kọ́ láti bọ̀wọ̀ fún àwọn aya wọn, kí wọ́n sì ṣìkẹ́ wọn, nítorí pé wọ́n fi àwọn ìtọ́ni inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tó mú un ṣe kedere pé àìṣẹ̀tọ́ fún àwọn obìnrin kò dùn mọ́ Ẹlẹ́dàá wa nínú rárá, sọ́kàn.
Àníyàn Ọlọ́run Nípa Àwọn Obìnrin
Nígbà gbogbo ni Ọlọ́run ti ń ṣàníyàn nípa àwọn obìnrin àti ire wọn. Bí ó tilẹ̀ sọ fún àwọn òbí wa àkọ́kọ́ pé, nítorí ìṣọ̀tẹ̀ wọn, àìpé yóò mú kí àwọn obìnrin di ẹni tí a ‘jọba lé lórí,’ èyí kò fìgbà kankan jẹ́ ète Ọlọ́run. (Jẹ́nẹ́sísì 3:16) Ó dá Éfà bí “àṣekún” Ádámù àti bí alájọṣepọ̀ kan fún un. (Jẹ́nẹ́sísì 2:18) Nínú Òfin Mósè, tí a fi fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ìgbàanì, Jèhófà dẹ́bi pàtó fún fífìyàjẹ-àwọn-opó, ó sì pàṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti hùwà inú rere sí wọn, kí wọ́n sì ràn wọ́n lọ́wọ́.—Ẹ́kísódù 22:22; Diutarónómì 14:28, 29; 24:17-22.
Ní ṣíṣàfarawé Baba rẹ̀ ọ̀run, Jésù kò tẹ̀ lé àṣà àtọwọ́dọ́wọ́, tí ń pẹ̀gàn àwọn obìnrin, tó gbilẹ̀ nígbà ayé rẹ̀. Ó bá àwọn obìnrin—kódà, àwọn tí ìwà wọn kò dára—sọ̀rọ̀ pẹ̀lú inú rere. (Lúùkù 7:44-50) Síwájú sí i, ó dùn mọ́ Jésù nínú láti ran àwọn obìnrin tó ní àìlera lọ́wọ́. (Lúùkù 8:43-48) Nígbà kan, tí ó rí opó kan tí ń ṣọ̀fọ̀ ọmọkùnrin kan ṣoṣo tó bí, tó ṣẹ̀ṣẹ̀ kú, ó lọ síbi ìtòlọ́wọ̀ọ̀wọ́ ìsìnkú náà lọ́gán, ó sì jí ọ̀dọ́kùnrin náà dìde.—Lúùkù 7:11-15.
Àwọn obìnrin wà lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù níbẹ̀rẹ̀, àwọn ni wọ́n sì kọ́kọ́ ṣẹlẹ́rìí àjíǹde rẹ̀. Bíbélì sọ̀rọ̀ rere nípa àwọn obìnrin bí Lìdíà, Dọ̀káàsì, àti Pírísíkà gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ aájò àlejò, ìyọ́nú, àti ìgboyà. (Ìṣe 9:36-41; 16:14, 15; Róòmù 16:3, 4) A sì kọ́ àwọn Kristẹni ìjímìjí lẹ́kọ̀ọ́ láti bọ̀wọ̀ fún àwọn obìnrin. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ fún míṣọ́nnárì ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, Tímótì, pé kí ó máa hùwà sí “àwọn àgbà obìnrin gẹ́gẹ́ bí ìyá, àwọn ọ̀dọ́bìnrin gẹ́gẹ́ bí arábìnrin pẹ̀lú gbogbo ìwà mímọ́.”—1 Tímótì 5:2.
Àwọn Obìnrin Tí Wọ́n Ti Rí Ọ̀wọ̀
Bí o bá jẹ́ Kristẹni ọkùnrin, ìwọ yóò fi ọ̀wọ̀ kan náà yẹn hàn fún àwọn obìnrin. O kò ní fi àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ kẹ́wọ́ láti hùwà búburú sí wọn. Síwájú sí i, híhùwà tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ sí àwọn obìnrin lè jẹ́rìí ketekete sí ìgbàgbọ́ rẹ. (Mátíù 5:16) Salima, ọ̀ṣọ́ọ́rọ́ obìnrin kan láti Áfíríkà, ṣàpèjúwe bí ó ṣe jàǹfààní láti inú rírí àwọn ìlànà Kristẹni lẹ́nu iṣẹ́.
“Mo dàgbà ní àyíká kan, tí a ń hùwà sí àwọn àgbàlagbà obìnrin àti àwọn ọmọbìnrin lọ́nà tí kò dára. Wákàtí 16 ni ìyá mi fi ń ṣiṣẹ́ lóòjọ́, ṣùgbọ́n ìráhùn lásán ló ń gbọ́ bí ohun kan bá kù tí kò ṣe. Èyí tó burú jù ni pé, nígbà tí baba mi bá mutí yó tán, ó máa ń lu ìyá mi. Àwọn obìnrin mìíràn ní àgbègbè wa ń jìyà bákan náà. Ṣùgbọ́n mo mọ̀ pé irú ìṣarasíhùwà bẹ́ẹ̀ kò dára—pé ó ń fi ìjákulẹ̀ àti àìláyọ̀ kún inú ìgbésí ayé wa. Síbẹ̀síbẹ̀, ó jọ pé kò sí ọ̀nà kankan láti yí ipò àwọn nǹkan yìí padà.
“Bí ó ti wù kí ó rí, nígbà tí mo wà ní ọ̀dọ́langba, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí bá mi ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Nígbà tí mo ka àwọn ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Pétérù, tó sọ pé kí a máa bọlá fún àwọn obìnrin, ó wọ̀ mí lọ́kan gan-an. Àmọ́, mo ronú pé, ‘kò jọ pé àwọn ènìyàn yóò lo ìmọ̀ràn yìí, ní pàtàkì, lójú àṣà ìbílẹ̀ àdúgbò wa.’
“Bí ó ti wù kí ó rí, nígbà tí mo lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba, níbi tí Àwọn Ẹlẹ́rìí ti ń ṣe àwọn ìpàdé wọn, tọkùnrin-tobìnrin ló fi inú rere hàn sí mi. Èyí tó túbọ̀ yà mí lẹ́nu ni pé, àwọn tó jẹ́ ọkọ láàárín wọn bìkítà ní gidi fún àwọn aya wọn. Bí mo ti túbọ̀ ń mọ àwọn ènìyàn náà dáradára sí i, mo mọ̀ pé èyí jẹ́ ohun kan tí a retí pé kí gbogbo Ẹlẹ́rìí máa ṣe. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan lára àwọn ọkùnrin náà ti wá láti inú ipò àtẹ̀yìnwá tó jọ tèmi, wọ́n ń bọ̀wọ̀ fún àwọn obìnrin nísinsìnyí. Mo fẹ́ láti jẹ́ ara ìdílé ńlá yìí.”
Ojútùú Pípẹ́títí Kan
Ọ̀wọ̀ tí Salima kíyè sí kì í ṣe èèṣì. Ó jẹ́ ìyọrísí ètò ìkọ́ni kan, tí a gbé karí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí ń ran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ láti mọyì ara wọn bí Ọlọ́run ti ṣe. Èyí jẹ́ ìtọ́ka kan sí ohun tí a lè ṣe nísinsìnyí pàápàá, ó sì ń tọ́ka sí ohun tí a óò ṣe níbi gbogbo nígbà tí Ìjọba Ọlọ́run bá ń ṣàkóso lórí gbogbo ilẹ̀ ayé. (Dáníẹ́lì 2:44; Mátíù 6:10) Ìjọba ọ̀run yìí yóò mú gbogbo àìṣẹ̀tọ́ kúrò. Bíbélì mú kí ó dáni lójú pé: “Nígbà tí àwọn ìdájọ́ bá ti ọ̀dọ̀ rẹ [Jèhófà] wá fún ilẹ̀ ayé, òdodo ni àwọn olùgbé ilẹ̀ eléso yóò kọ́ dájúdájú.”—Aísáyà 26:9.
Àní nísinsìnyí pàápàá, ẹ̀kọ́ nínú òdodo ń yí ọ̀nà ìrònú àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn padà. Nígbà tí gbogbo ẹ̀dá ènìyàn tó wà láàyè bá jẹ́ ọmọ abẹ́ Ìjọba Ọlọ́run, ẹ̀kọ́ yìí yóò máa bá a nìṣó kárí ayé, yóò sì fòpin sí ìwà ìgbonimọ́lẹ̀ tí àwọn ọkùnrin ń hù sí àwọn obìnrin, tí ó jẹ́ ìyọrísí ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù. Jésù Kristi, Ọba tí Ọlọ́run yàn, kì yóò fàyè gba àìṣẹ̀tọ́ sí àwọn obìnrin láti ba ìṣàkóso rẹ̀ jẹ́. Nígbà tí Bíbélì ń ṣàpèjúwe ìṣàkóso Kristi yẹn, ó wí pé: “Òun yóò dá òtòṣì tí ń kígbe fún ìrànlọ́wọ́ nídè, ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ pẹ̀lú, àti ẹnì yòówù tí kò ní olùrànlọ́wọ́. Òun yóò káàánú ẹni rírẹlẹ̀ àti òtòṣì, yóò sì gba ọkàn àwọn òtòṣì là. Yóò tún ọkàn wọn rà padà lọ́wọ́ ìnilára àti lọ́wọ́ ìwà ipá.”—Sáàmù 72:12-14.
Ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ yìí ti pọkàn pọ̀ sórí àwọn ìṣòro tí àwọn obìnrin ń ní. Bí ó ti wù kí ó rí, a mọ̀ pé a ti hùwà búburú sí ọ̀pọ̀ ọkùnrin pẹ̀lú. Jálẹ̀jálẹ̀ ìtàn ni àwọn alágbára àti olubi ọkùnrin ti hùwà ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ tí ẹnu kò ṣeé ròyìn sí àwọn ọkùnrin àti àwọn obìnrin. Àwọn obìnrin díẹ̀ ti ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ nípa ìtàjẹ̀-aláìṣẹ̀-sílẹ̀ láti ọwọ́ àwọn olubi obìnrin bí Jésíbẹ́lì, Ataláyà, àti Hẹrodíà.—1 Àwọn Ọba 18:4, 13; 2 Kíróníkà 22:10-12; Mátíù 14:1-11.
Nípa bẹ́ẹ̀, gbogbo aráyé nílò ayé tuntun ti Ọlọ́run, lábẹ́ ìṣàkóso Ìjọba rẹ̀. Láìpẹ́, nígbà tí ọ̀yẹ̀ ọjọ́ yẹn bá là, ìsọkùnrin-ìṣobìnrin kì yóò nírìírí ìyàsọ́tọ̀ tàbí ìfìyàjẹni mọ́ láé. Kàkà bẹ́ẹ̀, ọjọ́ kọ̀ọ̀kan yóò máa jẹ́ ti “inú dídùn kíkọyọyọ” fún ẹni gbogbo.—Sáàmù 37:11.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Àwọn ọkọ tó jẹ́ Kristẹni ń tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì, wọ́n ń bọ̀wọ̀ fún àwọn aya wọn, wọ́n sì ń bọlá fún wọn