ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g98 4/8 ojú ìwé 16-17
  • Òbéjé Lẹ́nu Ọ̀nà Wa

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Òbéjé Lẹ́nu Ọ̀nà Wa
  • Jí!—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìdí Tí A Kì Í Fi Sábà Rí I
  • Ṣé Òbéjé Ni?
  • Ìwọ̀nba Ohun Tí A Mọ̀
  • Ohun Kan Ha Wà fún Wọn Lọ́jọ́ Iwájú Bí?
  • Bí Ẹja Dolphin Ṣe Ń Mọ Ohun Tó Ń Lọ Lábẹ́ Omi
    Ta Ló Ṣiṣẹ́ Àrà Yìí?
  • Ìbápàdé Àràmàǹdà
    Jí!—1996
  • Ìṣẹ̀dá Ń polongo Ògo Ọlọ́run!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
Jí!—1998
g98 4/8 ojú ìwé 16-17

Òbéjé Lẹ́nu Ọ̀nà Wa

LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ AUSTRALIA

ÓFẸ́RÀN omi lílọ́wọ́ọ́wọ́ tí kò jìn ní ilẹ̀ olóoru, yálà oníyọ̀ tàbí èyí tí kò níyọ̀, tí ó rú tàbí tí ó mọ́ kedere. Àgbègbè ibùgbé rẹ̀ jẹ́ láti Ìyawọlẹ̀ Omi Òkun ti Bengal ní Íńdíà dé Erékùṣù Malay dé ìhà àríwá Australia.

Síbẹ̀, ìwọ̀nba ènìyàn díẹ̀—ní pàtàkì àwọn ará Australia, tí ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ etíkun wọn ní ìhà àríwá ni ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ẹranmi wọ̀nyí wà lágbàáyé—ló tíì rí òbéjé Irrawaddy rí tàbí ni wọ́n tí ì gbọ́ nípa rẹ̀ rí. Ìyẹn ha yà ọ́ lẹ́nu bí? Bẹ́ẹ̀ ni, bẹ́ẹ̀ sì kọ́.

Ní ọ̀rúndún kọkàndínlógún, onímọ̀ nípa ẹranko náà, John Anderson, rí ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ òbéjé aláwọ̀ ewé mọ́ àwọ̀ eérú yìí, tí wọ́n ní orí roboto, tí kò ní àgógó, tí wọ́n ń lúwẹ̀ẹ́ nínú Odò Irrawaddy ní Myanmar (tí ń jẹ́ Burma nígbà náà). Ó fún un ní orúkọ náà, òbéjé Irrawaddy.

Ìdí Tí A Kì Í Fi Sábà Rí I

Àwọn òbéjé Irrawaddy ń dàgbà ní àwọn àgbègbè odò, etíkun, àti etídò ilẹ̀ olóoru òun ọlọ́rinrin. Ilé wọn sábà máa ń kún fún ẹrẹ̀, igi ẹ̀gbà, igbó ńlá, ọ̀pọ̀lọpọ̀ yànmùyánmú àti, ní àwọn ibòmíràn, àwọn ọ̀nì pàápàá—kì í ṣe àgbègbè kan tí ó fa ẹ̀dá ènìyàn mọ́ra.

Omi tí ó wà ní àgbègbè yìí sábà ń jẹ́ èyí tí ó rú pẹ̀lú, nítorí náà, àkókò kan ṣoṣo tí o lè rí òbéjé kan ni ìgbà tí ó bá sáré wá sókè láti mí. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, kì í sábà fi ara rẹ̀ hàn. Ẹ̀yìn rẹ̀ ń yọ díẹ̀ síta, lẹbẹ ẹ̀yìn rẹ̀ kéré sí ti àwọn òbéjé mìíràn.

Ṣùgbọ́n ní àwọn ibì kan, àwọn òbéjé Irrawaddy kì í fi bẹ́ẹ̀ pa mọ́ kúrò lójútáyé. Àwọn apẹja àti àwọn awakọ̀ ojú omi tí ń tukọ̀ lórí Odò Irrawaddy ní Myanmar, àti lórí àwọn odò mìíràn ní àgbègbè ibi tí òbéjé wà ní Éṣíà, sábà máa ń rí i tí àwọn ẹranmi náà ń ṣọdẹ ìjẹ, tí wọ́n sì ń ṣeré lọ́nà jíjìn lójú omi, tí wọ́n tilẹ̀ ń tu omi sókè bí ti àwọn orísun omi àtọwọ́dá tàbí bí ère tí a ṣe sáàárín ìkùdù omi.

Nínú òkun tí ó kan ilẹ̀ Australia, àwọn òbéjé Irrawaddy wà ní etíkun ìhà ìwọ̀ oòrùn, lókè kọ́ńtínẹ́ǹtì náà, àti ní etíkun ìhà ìlà oòrùn nísàlẹ̀. A sábà máa ń rí wọn pọ̀ ní iye tí kì í dín sí 6, àmọ́ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, wọ́n máa ń tó 15. Láìdàbí ọmọ ìyá wọn ní Éṣíà, a kò mọ ọ̀wọ́ àwọn ti ìsàlẹ̀ lọ́hùn-ún náà pẹ̀lú àṣà kí wọ́n máa tu omi lẹ́nu bí àwọn orísun omi àtọwọ́dá.

Ṣé Òbéjé Ni?

Ìtòsí ilẹ̀ ni àwọn òbéjé Irrawaddy ń gbé, wọn kì í sì í yára lúwẹ̀ẹ́ bí tí àwọn ìbátan wọn alára-fífẹ́-nílẹ̀, tí ń gbé inú omi tí kò rú tó bẹ́ẹ̀. Síbẹ̀, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti ní ìṣòro nínú ìwádìí nípa wọn. Àgbègbè ibùgbé wọn tí kò fani mọ́ra jẹ́ okùnfà pàtàkì kan. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, wọ́n ti ṣèwádìí nípa àwọn òòyẹ̀ òbéjé Irrawaddy ní Ibi Ọ̀sìn Ẹ̀dá Òkun ti Jaya Ancol, ní Djakarta, Indonesia.

Nítorí pé a kò mọ púpọ̀ nípa àwọn òbéjé Irrawaddy, ẹnu àìpẹ́ yìí ni àwọn onímọ̀ nípa ohun alààyè ṣẹ̀ṣẹ̀ ní ìdánilójú nípa ìsọ̀rí tí àwọn yóò fi wọ́n sí nínú àwòrán ìlà ìdílé àbùùbùtán òun òbéjé. Ó hàn kedere pé ohun púpọ̀ jọra lára àwọn àti àwọn òbéjé. Síbẹ̀, ní ìrísí, kì í ṣe ní àwọ̀ (wọ́n ní oríṣiríṣi àwọ̀ láti orí èyí tí ó rí ràkọ̀ràkọ̀ sí àwọ̀ eérú mọ́ àwọ̀ búlúù), wọ́n fẹ́rẹ̀ẹ́ rí bí ẹ̀yà àbùùbùtán beluga, tàbí àbùùbùtán funfun tí ó túbọ̀ kéré ní Arctic. Kódà, ọrùn wọn tí ó ṣeé yí síhìn-ín sọ́hùn-ún lọ́nà àrà ọ̀tọ̀ jọ ti beluga gan-an. Nítorí náà, kí ni wọ́n jẹ́—irú beluga ti ibi ìlà agbedeméjì òbìrí ayé tàbí òbéjé gidi?

Ọ̀nà kan tí a lè gbà mọ̀ ni nípa ṣíṣàyẹ̀wò oríṣiríṣi ìgbékalẹ̀ ara àti apilẹ̀ àbùdá wọn, kí a sì wo ìhà ibi tí wọ́n pọ̀n sí jù. Ó jọ pé ẹ̀rí tí ó fìdí múlẹ̀ tọ́ka pé wọ́n pọ̀n sí ìhà ti òbéjé jù.

Ìwọ̀nba Ohun Tí A Mọ̀

Bí wọ́n bá ṣẹ̀ṣẹ̀ bí òbéjé Irrawaddy, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ gùn tó mítà kan, ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ tóbi tó kìlógíráàmù 12. Tí akọ bá dàgbà tán, ó máa ń tó nǹkan bí 2.75 mítà, abo sì ń kéré díẹ̀ jù ú lọ. Wọ́n lè lo ọdún 28.

A rí oúnjẹ bí ẹran oníkarawun, edé, ọ̀kàṣà, àti ẹja—ní pàtàkì àwọn ẹja tí ń gbé ìsàlẹ̀ omi—nínú àgbẹ̀du òkú àwọn òbéjé Irrawaddy náà. Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kan méfò pé àṣà títu omi jáde lẹ́nu lọ́nà tí ń pàfiyèsí tí àwọn òbéjé ilẹ̀ Éṣíà ń dá lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti pa ẹja nínú àwọn omi rírú.

Bí ti àwọn òbéjé mìíràn, àwọn òbéjé Irrawaddy máa ń ta ẹnu lọ́nà tí ó hàn ketekete. Ọ̀mọ̀wé Peter Arnold, láti Ibi Ìkóhun-Ìṣẹ̀ǹbáyé-Sí Ilẹ̀ Olóoru Queensland, wí fún Jí! pé, “gẹ́gẹ́ bí ìwádìí tí wọ́n ṣe nínú Ibi Ọ̀sìn Ẹ̀dá Òkun ní Jaya Ancol ṣe fi hàn, òbéjé Irrawaddy lè lo ẹnu tí ó ń ta láti mọ ibi tí ẹran ìjẹ rẹ̀ wà bí ti àwọn òbéjé mìíràn.”

Ohun Kan Ha Wà fún Wọn Lọ́jọ́ Iwájú Bí?

Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kò mọ iye òbéjé Irrawaddy tó wà lágbàáyé. Ṣùgbọ́n àníyàn ń pelemọ sí i látàrí pé wọ́n wà nínú ewu àkúrun. Iye wọn ti ń dín kù ní àwọn apá ibì kan ní Ìlà Oòrùn Gúúsù Éṣíà, a kò sì rí wọn mọ́ rárá ní àwọn apá ibòmíràn.

Lọ́pọ̀ ìgbà, èyí máa ń jẹ́ nítorí gẹdú gígé àti ìbàyíkájẹ́ tí ó so pọ̀ mọ́ ọn àti dída ẹrẹ̀ sínú àwọn odò. Ní Australia, púpọ̀ lára àgbègbè ibùgbé àwọn òbéjé Irrawaddy ni àwọn ènìyàn kò fi bẹ́ẹ̀ sí. Ṣùgbọ́n ní àwọn àgbègbè tí ó túbọ̀ fani mọ́ra ní etíkun ìhà ìlà oòrùn, sísọ ìlú di ńlá àti rírìnrìn-àjò afẹ́ ti ṣe ìpalára. Àwọn kan lára àwọn òbéjé Irrawaddy kú sínú àwọ̀n ìpẹja, àwọn kan sì kú sínú àwọ̀n ìpẹja àbùùbùtán tí a nà sítòsí àwọn etíkun láti dáàbò bo àwọn òmùwẹ̀. Pípa àwọn ẹja tí àwọn òbéjé Irrawaddy ń jẹ lápajù pẹ̀lú ń dá kún dídín tí wọ́n ń dín kù.

Síbẹ̀, ewu ọjọ́ iwájú tí ó le jù lọ lè jẹ́ iye àwọn ohun aṣèbàjẹ́ tí ń pọ̀ sí i tí ń ṣàn wọ inú àwọn odò àti ẹnu odò. Àwọn àpòpọ̀ àgbélẹ̀rọ èròjà oníkẹ́míkà, bí àwọn biphenyl ọlọ́pọ̀ èròjà chlorine (PCB), tí kì í tètè kúrò ní àyíká, wà lára àwọn tí ó burú jù lọ. A ti lo àwọn PCB nínú àwọn ẹ̀yà ohun abánáṣiṣẹ́, ọ̀dà, gírísì, ọ̀dà tí a fi ń kun pákó àti irin, àti àwọn ohun mìíràn.

Ní ti ìhà dídára rẹ̀, Ẹgbẹ́ Ìdáàbòbò Ìṣẹ̀dá ti Australia, sọ nínú àkọsílẹ̀ wọn náà, The Action Plan for Australian Cetaceans, pé: “Púpọ̀ lára àgbègbè ibùgbé [àwọn òbéjé Irrawaddy] ní Queensland wà lábẹ́ àbójútó Ọgbà Ìtura Ẹ̀dá Òkun Àpáta Great Barrier Reef; nítorí náà, ó dára pé ó ṣeé ṣe láti bójú tó wọn nínú àwọn omi Queensland.”

Gẹ́gẹ́ bí ìgbésẹ̀ mìíràn sípa àbójútó lọ́nà tí ó sàn jù, ẹgbẹ́ náà dámọ̀ràn pé kí a fi òbéjé Irrawaddy sára irú àwọn ọ̀wọ́ onípò kìíní, bí ti àbùùbùtán oníké, àbùùbùtán right ti ìhà gúúsù, àti òbéjé onímú-ìgò, nínú àwọn ètò ìpàfiyèsí àwọn ará ìlú. Ìyẹn yóò ṣàǹfààní fún òbéjé Irrawaddy—àti àwa náà.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 17]

Àwọn fọ́tò: Nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda onínúure Dókítà Tony Preen

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́