ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g98 4/8 ojú ìwé 30
  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
  • Jí!—1998
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Apilẹ̀ Àbùdá Ha Ní Ń Pinnu Àyànmọ́ Wa Bí?
    Jí!—1996
  • Ẹ̀bi Ta Ni—Ṣé Ẹ̀bi Rẹ Ni Àbí Ti Apilẹ̀ Àbùdá Rẹ?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
    Jí!—1998
  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
    Jí!—1998
Àwọn Míì
Jí!—1998
g98 4/8 ojú ìwé 30

Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa

Ẹfolúṣọ̀n ní Ìdojúkọ Ìṣẹ̀dá Ẹ gbé àwọn ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ náà, “Báwo La Ṣe Déhìn-ín? Nípasẹ̀ Èèṣì Ni Tàbí Nípasẹ̀ Àpilẹ̀ṣe?” (May 8, 1997), jáde lọ́nà tí ó ṣe kedere, tí ó rọrùn, tí ó sì bọ́gbọ́n mu délẹ̀délẹ̀. Inú mi dùn láti ka ọ̀pọ̀ ojú ewé tí ó ní àwọn ẹ̀rí tí ó bá ìlànà sáyẹ́ǹsì mu nípa ìṣẹ̀dá. Àwọn àwòrán ibẹ̀ tẹ́ni lọ́rùn. Ní pàtàkì, mo gbádùn kíkà nípa sẹ́ẹ̀lì àti gbogbo àwọn ẹ̀yà rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i. N kò jókòó ronú nípa ìṣiṣẹ́ ẹran ara mitochondrion àti Golgi láti ìgbà tí mo ti fi ilé ẹ̀kọ́ sílẹ̀, mo sì gbádùn rẹ̀ dáradára.

J. S., United States

Gẹ́gẹ́ bí amọṣẹ́dunjú nínú ẹ̀kọ́ nípa ohun alààyè àti ẹnì kan tí ó ti gbà gbọ́ pé Ọlọ́run-kò-ṣeé-mọ̀ láti ìgbà kékeré wá, mo fẹ́ láti dúpẹ́ lọ́wọ́ yín fún àwọn àpilẹ̀kọ náà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn àpilẹ̀kọ náà ní àwọn ìmúrọrùn-kọjá-àyè . . . , síbẹ̀síbẹ̀ wọ́n pe àfiyèsí sí ojúlówó ìṣòro kan tí àbá èrò orí ẹfolúṣọ̀n lọ́ọ́lọ́ọ́ ní: ìrònú àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì nípa ìjójúlówó ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n nípa àṣàyàn àdánidá tí ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ kárí ayé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìṣòro púpọ̀ wà nínú ẹ̀rí náà. Ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì gbọ́dọ̀ máa fàyè gba àwọn aláìnídàáni-lójú láti ṣàyẹ̀wò rẹ̀ bí a óò bá pè é ní ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì ní gidi. Ní pípe àfiyèsí sí àwọn àṣìṣe inú àbá ẹ̀kọ́ Darwin Tuntun, kì í ṣe pé ẹ ń pèsè ẹ̀rí tí a fi ní láti ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà nìkan ni àmọ́, ẹ tún ń ṣe iṣẹ́ lórí ọjọ́ ọ̀la ìwádìí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì. Ẹ ṣeun.

A. S., United States

Kíkólọ Mo mọrírì àpilẹ̀kọ náà, “Ṣírò Ohun Tí Kíkó Lọ Yóò Ná Ọ!” (May 8, 1997), gan-an. Ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn ohun tí ẹ kọ nípa rẹ̀ ló ń ṣe mí. Níwọ̀n bí mo ti kó lọ sí Yúróòpù láti Áfíríkà, léraléra ni mo ń kojú ìṣòro lílekoko ti ọ̀ràn ẹ̀yà, èdè, àwọ̀ àti, lékè gbogbo rẹ̀, ẹ̀tanú. Àwọn ilé iṣẹ́ agbéròyìnjáde tí ó lókìkí ti sọ ohun tí kò dára nípa àwọn ará Áfíríkà àti nípa àwọn àjèjì lápapọ̀.

P. A., Germany

Ohun Àṣenajú Ẹ ṣeun fún àpilẹ̀kọ náà, “Kí Ló Ti Ṣẹlẹ̀ sí Ohun Àṣenajú?” (May 22, 1997) Ọmọ ọdún 12 ni mí, mo sì ń wo tẹlifíṣọ̀n gan-an lásìkò tí mo wà ní ọlidé. Àpilẹ̀kọ náà ràn mí lọ́wọ́ láti rí i pé àwọn ohun àṣenajú mìíràn wà tí mo lè ṣe.

J. L., England

Wíwàásù ní Àwọn Àrọko Ilẹ̀ Áfíríkà N óò fẹ́ láti dúpẹ́ lọ́wọ́ yín fún àpilẹ̀kọ náà, “Ohun Tí Adìyẹ Ń Lé Kiri Nínú Òjò . . .” (May 22, 1997) Mo fẹ́ràn ìfọkànsìn àti ìfaradà onífara-ẹni-rúbọ tí àwọn ará wa ní Nàìjíríà ní. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ní láti kojú ejò, ọ̀nì, àti ọ̀sọ̀sọ̀, ìfẹ́ tí wọ́n ní fún àwọn ènìyàn ń ru wọ́n sókè. Ìgbà mìíràn tí mo bá tún jáde lọ wàásù tí ooru bá ń mú mi tàbí tí o bá rẹ̀ mí, n óò ronú nípa àwọn ará wa ọ̀wọ́n ní Nàìjíríà.

S. S., United States

Àṣà Ìbálòpọ̀—Ìṣarasíhùwà Tí Ń Yí Padà Mo fẹ́ láti fi tọkàntọkàn dúpẹ́ fún àwọn ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ náà, “Àṣà Ìbálòpọ̀—Ohun Tí Ìṣarasíhùwà Tí Ń Yí Pa Dà Túmọ̀ Sí.” (June 8, 1997) Ó fún ìgbàgbọ́ mi lókun gan-an. Ọkùnrin kan ládùúgbò wa wí fún mi [obìnrin kan] pé, ‘ara mi kò pé’ nítorí pé mo ti pé ọmọ ọdún 19, mo sì jẹ́ wúńdíá síbẹ̀. Inú mi dùn pé mo jẹ́ kí ó mọ̀ pé, lójú Jèhófà, ara mi àti ipò tẹ̀mí mi pé.

W. M. C. C., Zimbabwe

Ohun tí ẹ tọ́ka sí lójú ìwé 10 nípa ‘àwọn apilẹ̀ àbùdá ìṣekúṣe’ kò tọ̀nà. Gẹ́gẹ́ bí akẹ́kọ̀ọ́ ọlọ́dún kẹrin, tí kò tí ì gboyè jáde nínú ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì nípa ìwàláàyè, mo lè sọ fún yín pé, ‘àwọn apilẹ̀ àbùdá ìṣekúṣe’ ń tọ́ka sí àwọn apilẹ̀ àbùdá inú chromosome tí ń káàkiri inú chromosome náà tàbí tí ó bọ̀ sínú chromosome tuntun kan. Kò ní nǹkan kan láti ṣe pẹ̀lú ìhùwà.

L. P., Kánádà

Ọ̀rọ̀ náà pé, Ọlọ́run kò dá ‘àwọn apilẹ̀ àbùdá ìṣekúṣe’ mọ́ wa, ní ti gidi, jẹ́ ìtọ́ka sí ọ̀rọ̀ kan tí bíṣọ́ọ̀bù ìjọ Áńgílíkà ti Edinburgh, Scotland, sọ, tí a fa apá kan rẹ̀ yọ lójú ìwé 4 ìtẹ̀jáde “Jí!” yẹn. Bíṣọ́ọ̀bù náà sọ pé, “Ọlọ́run . . . ti fún wa ní apilẹ̀ àbùdá ìṣekúṣe”—ó ṣe kedere pé èyí jẹ́ ìgbìyànjú láti wí àwíjàre nípa ìwà pálapàla. Àpilẹ̀kọ wa tú àṣírí àṣìṣe tí ó wà nínú irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀.—Olùyẹ̀wòṣàtúnṣe.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́