Ìdí Tí A Kì Í Fi Í Rí Ìràwọ̀
TA NI kò bojú wo òfuurufú lọ́wọ́ alẹ́ rí, kí ó sì ṣe kàyéfì nípa ẹwà dídángbinrin tí àwọn ìràwọ̀ tí wọ́n wà káàkiri inú gbalasa òfuurufú ní? Bí ó ti wù kí ó rí, ìran àgbàyanu yìí ń pòórá lójú wa díẹ̀díẹ̀. Èé ṣe? Ìmọ́lẹ̀ tí ń ṣèdíwọ́.
Ìmọ́lẹ̀ tí ń ṣèdíwọ́ ni ìrànyòò lílágbárajù, tí ń bù yẹ̀rì wá láti inú àwọn iná ojú pópó, ti ilé, ilé ìtajà, ilé ìjọba, àti ti àwọn pápá ìṣeré tí ènìyàn ṣe. Ó ń tó ìlàjì lára ìmọ́lẹ̀ yìí tí ń lọ sókè sí ojú òfuurufú, tí kì í sì í jẹ́ kí a rí ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn ìràwọ̀ náà. Báwo ni ìṣòro yìí ṣe le tó? Fún àpẹẹrẹ, ní alẹ́ kan tí ó mọ́lẹ̀ rekete ní ìhà àríwá Yúróòpù, a lè fi ojú lásán rí nǹkan bí 2,000 ìràwọ̀. Ṣùgbọ́n fún àwọn tí ń gbé apá ẹ̀yìn ìlú kan, iye yìí dín kù sí 200, àti ní àárín ìlú ńlá kan tí a tan àwọn iná mímọ́lẹ̀ gan-an sí, a lè rí 20 ìràwọ̀ péré. Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ sánmà kan fòyà pé àyàfi bí a bá gbé àwọn ìgbésẹ̀ oníṣọ̀ọ́ratẹ́lẹ̀, a kò ní lè rí ìràwọ̀ kankan mọ́ ni ìhà àríwá Yúróòpù tí ó bá fi máa tó ọdún 25 sí àsìkò yìí.
Òtítọ́ ni pé àwọn iná kan ṣe pàtàkì. Ó ń ṣèdíwọ́ fún ìwà ọ̀daràn, ó sì ń mú kí àwọn onílé tí a lè tètè kọ lù túbọ̀ nímọ̀lára ààbò. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, bí iná tí ń wọlé bá pọ̀ jù, ó ń dá kún àìfararọ, ó sì ń dí ètò oorun sísùn lọ́wọ́. Kì í ṣe àwọn ènìyàn nìkan ló ń dí lọ́wọ́. Iná lè mú kí àwọn ẹyẹ àti àwọn kòkòrò aṣíkiri ṣìnà, ó sì lè dabarú ìṣiṣẹ́ wíwàlétòlétò nínú àwọn irúgbìn.
Kí ni a lè ṣe láti dín ìṣòro náà kù? Ìgbésẹ̀ kan tí ó lè ṣèrànwọ́ ni láti rí i dájú pé a fi nǹkan bo orí àwọn iná tí a tàn síta dáradára, kí a sì yí orí wọn sísàlẹ̀. A lè ṣe é kí àwọn iná tí ó wà fún ààbò máa tàn tí a bá sún mọ́ wọn, dípò kí a tàn wọ́n sílẹ̀. Àgbègbè ẹ̀yìn ìlú kan ní ilẹ̀ Faransé kápá ìṣòro náà nípa lílo àwọn iná ojú pópó lílágbára, tí àwọ̀ wọn jẹ́ funfun mọ́ fàdákà, tí ń mú ìmọ́lẹ̀ tààrà tí ó túbọ̀ ṣe wẹ́kú wá, àti nípa fífi ìbòrí dé àwọn iná ojú pópó tí kò mọ́lẹ̀ jù, tí ó wà, èyí sì ń mú kí ìmọ́lẹ̀ dorí kọlẹ̀. Wọ́n da ọ̀dà dúdú tí ń gba ìmọ́lẹ̀ mọ́ra sí àwọn títì, bí agogo mọ́kànlá alẹ́ bá sì ti kọjá, wọ́n ń pa àwọn iná tí ó wà ní àwọn ilé ìjọba. Kì í ṣe pé èyí fẹ́rẹ̀ẹ́ mú ìdíwọ́ tí ìmọ́lẹ̀ tí ó wà lóròó ń ṣe kúrò, kí ó sì dín ìmọ́lẹ̀ tí ń wọlé kù ní ìdá méjì nínú mẹ́ta nìkan ni, àmọ́ ó mú kí ìpèsè ohun àmúṣagbára fi ìpín 30 nínú ọgọ́rùn-ún gbéṣẹ́ sí i.
Dájúdájú, gbogbo irú ojútùú bẹ́ẹ̀ ń gba àkókò àti owó—àwọn ohun tí ó ṣọ̀wọ́n láti rí lónìí. Ẹ wo bí ó ṣe dára tó láti mọ̀ pé, láìpẹ́, ìṣàkóso Ìjọba Ọlọ́run lọ́wọ́ Ọmọkùnrin rẹ̀, Kristi Jésù, yóò mú oríṣiríṣi ohun ìdíwọ́ kúrò! Nígbà náà, àwọn ọmọ abẹ́ ìjọba rẹ̀ yóò tún lè rí iṣẹ́ ọwọ́ Ẹlẹ́dàá wa, àwọn ọ̀run rírẹwà tí ó kún fún ìràwọ̀, láìsídìíwọ́.—Sáàmù 19:1, 2; Ìṣípayá 11:18.