ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g98 4/22 ojú ìwé 16
  • A Fi Orúkọ Ọlọ́run Ṣe Àwọn Ilé Lọ́ṣọ̀ọ́ ní Czech

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • A Fi Orúkọ Ọlọ́run Ṣe Àwọn Ilé Lọ́ṣọ̀ọ́ ní Czech
  • Jí!—1998
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Orúkọ Ọlọ́run Lára Àwọn Ilé Àtayébáyé
    Jí!—2004
  • A4 Orúkọ Ọlọ́run Nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Jí!—1998
g98 4/22 ojú ìwé 16

A Fi Orúkọ Ọlọ́run Ṣe Àwọn Ilé Lọ́ṣọ̀ọ́ ní Czech

Láti ọwọ́ aṣojúkọ̀ròyìn Jí! ní Orílẹ̀-èdè Olómìnira Czech

NÍBI púpọ̀ lágbàáyé, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nìkan ni a mọ orúkọ Jèhófà mọ̀. Ó lè yà ọ́ lẹ́nu láti mọ̀ pé ní Orílẹ̀-èdè Olómìnira Czech, àwọn ọ̀ṣọ́ ara àwọn ilé àmúpìtàn ní Tetragrammaton, lẹ́tà Hébérù mẹ́rin (יהוה), tí ó para pọ̀ di orúkọ àtọ̀runwá náà, Jèhófà, lára.

Bóyá àpẹẹrẹ Lẹ́tà Hébérù Mẹ́rin náà tó lókìkí jù ni ti ara Afárá Charles, tí a ṣe ní 1357 sórí àgbàyanu Odò Vltava, nítòsí Ògbólógbòó Ìlú Prague. Wọ́n fi àwọn ọnà gbígbẹ́ sí ara afárá yìí lẹ́gbẹ̀ẹ́ méjèèjì, ọ̀kan sì fẹ́rẹ̀ẹ́ máa gbàfiyèsí gbogbo ẹni tí ń kọjá lọ. Ó jẹ́ ère Jésù Kristi lórí àgbélébùú kan, tí a fi wúrà dídányanran kọ àwọn lẹ́tà lédè Hébérù—tó ní Lẹ́tà Hébérù Mẹ́rin náà nínú—yí i ká, tó kà pé “Mímọ́, mímọ́, mímọ́ ni Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun.”

Báwo ni gbólóhùn yìí, tí ó wà nínú Bíbélì, nínú Aísáyà 6:3, ṣe wá dé ara ère yìí? Ìkọ̀wé kan nísàlẹ̀ rẹ̀ sọ nípa Júù kan tó kọjá níbẹ̀ lọ́jọ́ kan ní 1696, tí a sì gbọ́ pé ó sọ̀rọ̀ àbùkù nípa àgbélébùú náà. Nítorí èyí, wọ́n mú un lọ síwájú Ilé Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn ti Aláyélúwà, wọ́n sì bu owó ìtanràn lé e. Ó pèsè ohun ọ̀wọ̀ rìbìtì tí a fi wúrà tẹ́ inú rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ tí a fà yọ lókè yìí fún àgbélébùú náà, gẹ́gẹ́ bí owó ìtanràn.

Nítòsí ni Sínágọ́gù Ògbólógbòó òun Ọ̀tun àti itẹ́ àwọn Júù tó ti pẹ́ jù lọ ní Yúróòpù wà. Nínú Sínágọ́gù yìí, àga aṣáájú ẹgbẹ́ akọrin ní Lẹ́tà Hébérù Mẹ́rin náà tí a fi fàdákà kọ lára. Ṣùgbọ́n kì í ṣe nínú àwọn ilé àwọn Júù nìkan ni a ti lè rí Lẹ́tà Hébérù Mẹ́rin náà. Ní ìhà Ìlà Oòrùn Gúúsù Prague, níbi ilẹ̀ olókè tó ta gọngọ ní ìdojúkọ Odò Sázava, ni ilé ńlá olódi Český Šternberk wà. Lórí pẹpẹ tó wà nínú ilé ìsìn inú ilé ńlá olódi náà ni àwọn lẹ́tà mẹ́rin tí a fi wúrà kọ—Lẹ́tà Hébérù Mẹ́rin náà—gbé wà. Ó dà bí pé inú afẹ́fẹ́ lófuurufú ni àwọn lẹ́tà náà wà nítorí pé wáyà la fi so wọ́n rọ̀. Iná kan ń tàn yòò lẹ́yìn wọn—ṣùgbọ́n kì í ṣe iná àtùpà! Ìmọ́lẹ̀ láti òfuurufú, tí a kò lè rí láti inú, ń tàn yòò sórí pẹpẹ funfun náà, lórí èyí tí Lẹ́tà Hébérù Mẹ́rin náà ti ń fì dirodiro.

A tún rí Lẹ́tà Hébérù Mẹ́rin náà nínú àwọn àwòrán àlẹ̀mógiri nínú àwọn ilé mìíràn ní Czech. Wọ́n ń jẹ́rìí síwájú sí i pé ọ̀pọ̀ ènìyàn níhìn-ín ló ti dojúlùmọ̀ orúkọ Ọlọ́run nígbà kan rí. Lónìí, ní Orílẹ̀-èdè Olómìnira Czech àti ní àwọn ilẹ̀ mìíràn tó lé ní 200, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láyọ̀ láti mọ orúkọ àtọ̀runwá náà àti láti fi kọ́ àwọn ẹlòmíràn. (Aísáyà 43:10-12) Síwájú sí i, ìwé Aísáyà nínú Bíbélì sọ nípa àkókò tí a óò sọ orúkọ Ọlọ́run—àti àwọn ànímọ́ rẹ̀, ète rẹ̀, àti àwọn ìgbòkègbodò rẹ̀—“di mímọ̀ ní gbogbo ilẹ̀ ayé.”—Aísáyà 12:4, 5.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́