Wíwo Ayé
Àṣà Oògùn Lílò Tí Ń Náni Lówó
Ìròyìn kan tí ìjọba United States ṣe fojú bù ú pé àwọn ará Amẹ́ríkà ná bílíọ̀nù 57.3 dọ́là sórí oògùn tí kò bófin mu ní 1995. Kokéènì kó ìpín méjì nínú mẹ́ta, nígbà tí heroin, marijuana, àti àwọn oògùn tí kò bófin mu mìíràn para pọ̀ kó ìpín tó kù. Àjọ akóròyìnjọ Associated Press ròyìn pé olùdarí Ọ́fíìsì Ìlànà Ìkápá Egbòogi Lórílẹ̀-Èdè ní Ibùjókòó Ìjọba Àpapọ̀ United States, Barry McCaffrey, sọ pé iye owó tí wọ́n ná sórí oògùn wọ̀nyí ti lè gbọ́ bùkátà ẹ̀kọ́ ọlọ́dún-mẹ́rin ní kọ́lẹ́ẹ̀jì lórí àádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn tàbí kí ó ra bílíọ̀nù 83 lítà wàrà láti fi bọ́ àwọn ọmọ ọwọ́ tí kò jẹunre kánú. Síwájú sí i, iye yìí kò ní ohun tó ná àwùjọ ènìyàn nínú, bí ìwà ọ̀daràn tó pọ̀ sí i, dídabarú ìgbésí ayé ẹni àti ti ìdílé, àti títàn tí àwọn àrùn bí àrùn mẹ́dọ̀wú àti àrùn AIDS tàn kálẹ̀.
Òfin Tí A Ti Gbàgbé
Mélòó nínú Òfin Mẹ́wàá inú Bíbélì ni o lè rántí? Ìwádìí kan ní Rio de Janeiro rí i pé, ó lé ní ìpín 1 nínú 4 àwọn ará Brazil tí kò lè sọ ọ̀kankan nínú wọn! Ìwé ìròyìn Veja sọ pé, lára àwọn tí wọ́n mọ ọ̀kan nínú àwọn òfin náà, ó kéré tán, ìpín 42 nínú ọgọ́rùn-ún mẹ́nu ba “Má pànìyàn” tàbí “Má jalè.” Àwọn mìíràn rántí “Má ṣojúkòkòrò aya ẹnì kejì rẹ” (ìpín 38 nínú ọgọ́rùn-ún), “Bọ̀wọ̀ fún baba àti ìyá [rẹ]” (ìpín 22 nínú ọgọ́rùn-ún), àti “Má ṣe jẹ́rìí èké” (ìpín 14 nínú ọgọ́rùn-ún). Ìpín 13 péré nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn tó dáhùn ìbéèrè náà ló rántí òfin kẹta: “Má pe orúkọ mímọ́ Ọlọ́run lásán.”
Àyẹ̀wò Ìpíndọ́gba Ìwọ̀n Làákàyè fún Àwọn Ọmọdé Níbẹ̀rẹ̀ Ìgbésí Ayé
Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì tí ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa làákàyè ẹ̀dá ènìyàn gbà gbọ́ nísinsìnyí pé ọpọlọ ọmọ ọwọ́ kan ń la àkókò ìdàgbàsókè tó ṣe pàtàkì jù nínú ìgbésí ayé rẹ̀ kọjá láàárín ìgbà tí a bí i sí ìgbà tó bá di ọmọ ọdún mẹ́ta. Wọ́n tún rò pé, ní ìhùwàpadà sí títa èrò orí jí, a ń ṣàgbékalẹ̀ àwọn ìsokọ́ra pípẹ́títí nínú ọpọlọ láàárín àkókò yìí. Ìwé ìròyìn Modern Maturity sọ pé, nípa bẹ́ẹ̀, àwọn òbí kan ti bẹ̀rẹ̀ sí fún àwọn ọmọ wọn ní àwọn àyẹ̀wò ìpíndọ́gba ìwọ̀n làákàyè tipẹ́tipẹ́ ṣáájú kí wọ́n tó wọ ilé ẹ̀kọ́ jẹ́léósinmi, láti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti rọ́wọ́ mú nínú ìdíje. Bí ó ti wù kí ó rí, Dókítà Barry Zuckerman, alága ẹ̀ka ẹ̀kọ́ ìṣègùn nípa ìtọ́jú àrùn àwọn ọmọdé ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìṣègùn ti Yunifásítì Boston, ṣàníyàn nípa àwọn òbí tó rò pé “àwọn wà lábẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe láti ‘pèsè ìsúnniṣe’ fún ọmọ wọn kékeré léraléra” ní gbígbìyànjú láti sọ ọ́ di “ọmọdé tó ta yọ.” Richard Weinberg, tó jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n ìmọ̀ ìrònú òun ìhùwà ọmọdé, fi kún un pé: “Títi àwọn ọmọdé láti máa díje nígbà tí wọ́n kéré jù máa ń dá wàhálà sílẹ̀ níkẹyìn. Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọ yín gbádùn ìgbà ọmọdé wọn.”
Àwọn Adàwékọ Oníṣọ̀ọ́ra
Ọ̀mọ̀wé Barbara Aland, ọ̀gá Ilé Ẹ̀kọ́ Ìwádìí Nípa Májẹ̀mú Tuntun, ní Münster, Germany, wí pé, a ti fara balẹ̀ da àwọn ọ̀rọ̀ tó para pọ̀ di Ìwé Mímọ́ Lédè Gíríìkì nínú Bíbélì kọ, a sì ti tàtaré wọn tìṣọ́ratìṣọ́ra. Ìwé agbéròyìnjáde Westfälische Nachrichten ròyìn pé: “Àwọn àṣìṣe tàbí àwọn ìyípadà tí ẹ̀kọ́ ìsìn ń fà pàápàá ṣọ̀wọ́n.” Láti 1959 wá, ilé ẹ̀kọ́ náà ti ṣàyẹ̀wò àwọn ẹ̀dà àfọwọ́kọ tó lé ní 5,000, tí wọ́n ti wà láti Sànmánì Agbedeméjì àti àwọn àkókò ṣáájú ìgbà yẹn. A ti gba nǹkan bí ìpín 90 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ẹ̀dà àfọwọ́kọ náà sórí fọ́tò onífíìmù tíntìntín. Èé ṣe tí àwọn aṣàdàkọ-Bíbélì náà fi lo ìṣọ́ra púpọ̀ tó bẹ́ẹ̀ láti má ṣe àṣìṣe? Ìwé agbéròyìnjáde náà sọ pé, ó jẹ́ nítorí pé wọ́n “ka ara wọn sí ‘aṣàdàkọ,’ kì í ṣe òǹkọ̀wé.”
Ṣé Lóòótọ́ La Dín Èròjà Kaféènì Rẹ̀ Kù?
Àwọn tí èròjà kaféènì kò bá lára mu sábà máa ń yíjú sí ohun mímu tí a dín èròjà kaféènì rẹ̀ kù bí àfirọ́pò. Ṣùgbọ́n dé àyè wo lo fi lè rí kọfí tí a dín èròjà kaféènì rẹ̀ kù ní tòótọ́ bí o bá béèrè fún un? Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn kan tí ìwé agbéròyìnjáde The New York Times gbé jáde ṣe fi hàn, ó jẹ́ nǹkan bí ìpín 1 nínú 3. Àjọ Àbójútó Oúnjẹ àti Oògùn ní United States túmọ̀ kọfí tí a ti dín èròjà kaféènì rẹ̀ kù gẹ́gẹ́ bí èyí tó ní mílígíráàmù méjì sí márùn-ún èròjà kaféènì nínú. Ṣíṣàyẹ̀wò kọfí nílé ìtakọfí 18 ní New York City fi hàn pé ìwọ̀n èròjà kaféènì inú ife kọfí oníwọ̀n 150 mìlímítà yàtọ̀ síra gan-an, láti 2.3 mílígíráàmù sí 114 mílígíráàmù! Gẹ́gẹ́ bí Ẹgbẹ́ Àwọn Oníṣòwò Kọfí Lórílẹ̀-Èdè ṣe sọ, ife kọfí kan tí a lè mú ṣàpẹẹrẹ ń ní èròjà kaféènì ní ìwọ̀n 60 sí 180 mílígíráàmù nínú.
Ìpagbórun Kárí Ayé
Ìwé agbéròyìnjáde Jornal da Tarde ròyìn pé: “A ti ba ìdá méjì nínú ìdá mẹ́ta gbogbo igbó ojú ilẹ̀ ayé jẹ́.” Nínú àpapọ̀ ìwọ̀n 80 mílíọ̀nù kìlómítà níbùú lóròó tó jẹ́ igbó ní ilẹ̀ ayé tẹ́lẹ̀, ìwọ̀n 30 mílíọ̀nù ló ṣẹ́ kù. Àjọ Akówójọ fún Ìdáàbòbò Ohun Alààyè Inú Ìgbẹ́ Lágbàáyé (WWF) ti rí i pé Éṣíà ni kọ́ńtínẹ́ǹtì tí a ti pa igbó run jù, a ti pa ìpín 88 nínú ọgọ́rùn-ún igbó tó ní nípilẹ̀ṣẹ̀ run. Ní Yúróòpù, iye náà jẹ́ ìpín 62 nínú ọgọ́rùn-ún, ìpín 45 nínú ọgọ́rùn-ún ni ní Áfíríkà, ìpín 41 nínú ọgọ́rùn-ún ni ní Látìn Amẹ́ríkà, ó sì jẹ́ ìpín 39 nínú ọgọ́rùn-ún ní Àríwá Amẹ́ríkà. Amazonia, tó jẹ́ àgbègbè tí a ti rí igbó kìjikìji títóbijù ní ilẹ̀ olóoru ṣì ní ìpín 85 nínú ọgọ́rùn-ún igbó tó ní nípilẹ̀ṣẹ̀. Ìwé agbéròyìnjáde O Estado de S. Paulo fa ọ̀rọ̀ Garo Batmanian ti Àjọ WWF yọ pé: “Brazil ní àǹfààní láti yẹra fún ṣíṣe àṣìṣe kan náà tí wọ́n ti ṣe ní àwọn igbó mìíràn.”
Wọ́n Jí Àwọn Ìṣúra Kó
Ìwé ìròyìn World Press Review sọ pé ìròyìn kan tí wọ́n gbé jáde ní Kánádà láìpẹ́ yìí kéde pé, “àwọn ẹgbẹ́ ọ̀daràn ọlọ́pọ̀ orílẹ̀-èdè ń fojú sun àwọn ìṣúra àgbègbè Mesopotámíà, tó ti wà láìláàbò láti ìgbà ìbẹ̀rẹ̀ ogun Ìyawọlẹ̀ Omi Páṣíà ní 1991.” Ní 1996, àwọn olè rúnlẹ̀ wọ Ibi Ìkóhun-Ìṣẹ̀ǹbáyé-Sí ti Bábílónì lọ́sàn-án gangan, wọ́n sì kó àwọn ọ̀pá alámọ̀ rìbìtì àti àwọn wàláà tí a gbẹ́ ọ̀rọ̀ sí. A fojú díwọ̀n rẹ̀ pé àwọn ohun ìṣẹ̀ǹbáyé tó ṣọ̀wọ́n náà, tí àwọn kan lára wọn ti wà nígbà ìṣàkóso Nebukadinésárì Kejì, níye lórí ju 735,000 dọ́là lọ lọ́jà iṣẹ́ ọnà àgbáyé. Àgbègbè mìíràn tí àwọn olè náà fojú sùn ni ìlú ńlá ìgbàanì náà, Al-Hadhr. Nínú ìgbìyànjú láti dáàbò bo àwọn ìṣúra tó kù, ìwé ìròyìn náà sọ pé, ìjọba ti mọ bíríkì dí gbogbo ilẹ̀kùn àti ọ̀nà àbákọjá ìlú náà pa.
Ìjọ Kátólíìkì Ń Tọrọ Ìdáríjì
Ìjọ Roman Kátólíìkì ilẹ̀ Faransé ti gbé “Ìkéde Ìrònúpìwàdà” kan tí a fàṣẹ sí jáde, tí ń tọrọ ìdáríjì lọ́wọ́ Ọlọ́run àti àwọn Júù nítorí “ìwà àgunlá” tí Ìjọ Kátólíìkì hù nígbà inúnibíni tí ìjọba Vichy ṣe sí àwọn Júù ní àkókò ogun ilẹ̀ Faransé. Láàárín 1940 sí 1944, wọ́n fàṣẹ ọba mú àwọn Júù tó lé ní 75,000, wọ́n sì kó wọn lọ sí àgọ́ ikú ti Nazi, láti ilẹ̀ Faransé. Ìwé agbéròyìnjáde ilẹ̀ Faransé náà, Le Monde, ròyìn pé, nínú ọ̀rọ̀ kan tí Bíṣọ́ọ̀bù-Àgbà Olivier de Berranger kà, ìjọ náà gbà pé òun ti jẹ́ kí àwọn ìdàníyàn tara òun “ṣíji bo àṣẹ inú Bíbélì láti bọ̀wọ̀ fún gbogbo ẹ̀dá ènìyàn tí a dá ní àwòrán Ọlọ́run.” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn àlùfáà ará Faransé mélòó kan sọ̀rọ̀ ní ìgbèjà àwọn Júù, ògìdìgbó wọn ló ti ìjọba Vichy àti àwọn ìlànà rẹ̀ lẹ́yìn. Ìkéde náà sọ lápá kan pé: “Ìjọ náà gbọ́dọ̀ gbà pé, ní ti inúnibíni àwọn Júù, àti ní pàtàkì, ní ti onírúurú ìgbésẹ̀ tí àwọn aláṣẹ Vichy pàṣẹ rẹ̀ lòdì sí àwọn Júù, ìdágunlá bo ìbínú mọ́lẹ̀ gidigidi. Àìfọhùn ló gbòde kan, sísọ̀rọ̀ ní ìgbèjà àwọn tí ìyà ń jẹ náà kò sì wọ́pọ̀. . . . Lónìí, a jẹ́wọ́ pé àṣìṣe ni àìfọhùn yìí. A sì tún gbà pé ìjọ náà ní ilẹ̀ Faransé kùnà nínú iṣẹ́ rẹ̀ bí olùkọ́ ẹ̀rí ọkàn àwọn ènìyàn.”
Àwọn Kòkòrò Tí Ń Ṣèbàjẹ́
Láti ìgbà tí kòkòrò jọ̀pẹjọ̀pẹ ti dé sí àgbègbè Ìyawọlẹ̀ Omi Arébíà ní èyí tí kò pé 20 ọdún sẹ́yìn, kòkòrò kékeré yìí ti wọnú ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọ̀pẹ date, ó sì ti ṣèbàjẹ́ tí kò ṣeé fẹnu sọ. Ìwé ìròyìn The Economist sọ pé: “Ẹ̀rù tilẹ̀ ń bani pé ọ̀pẹ date—‘èso ìyè’ ilẹ̀ Arébíà láti 5,000 ọdún wá—lè di ohun tí kò sí mọ́.” Kòkòrò náà, tó gùn ní sẹ̀ǹtímítà márùn-ún péré, ń gbẹ́ ọ̀pọ̀ ihò sínú igi ọ̀pẹ, ó sì ń pa igi náà díẹ̀díẹ̀. Àwọn oògùn apakòkòrò kò fi bẹ́ẹ̀ rí kòkòrò náà gbé ṣe, ó sì yára ń pọ̀ sí i jákèjádò àgbègbè náà.
Àǹfààní Àwọn Òṣìṣẹ́ Ọlọ́jọ́lórí
Ìwé agbéròyìnjáde The Times ti London ròyìn pé àwọn òṣìṣẹ́ tí ọjọ́ orí wọn lé ní ọdún 47 túbọ̀ ń wà lójúfò, wọ́n sì ń jáfáfá ní àárọ̀ ju àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn tí kò lọ́jọ́ lórí tó wọn lọ. Níwọ̀n bí èyí ti máa ń yí padà lẹ́yìn náà, Tom Reilly, láti Yunifásítì John Moores ní Liverpool, dábàá pé kí àwọn agbanisíṣẹ́ ṣètò pé kí àwọn òṣìṣẹ́ ọlọ́jọ́lórí máa ṣiṣẹ́ àárọ̀ kùtù hàì, kí àwọn tí kò lọ́jọ́ lórí tó bẹ́ẹ̀ máa gba iṣẹ́ lọ́wọ́ wọn ní ọ̀sán àti ìrọ̀lẹ́. Àwọn olùbánisọ̀rọ̀ lórí dídàgbà, níbi àpérò Ẹgbẹ́ Àwọn Oníṣègùn Ilẹ̀ Britain, tún fi hàn pé àwọn ilé ìtajà ńlá àti àwọn ibi ìtajà mú-un-fúnra-rẹ sábà máa ń fẹ́ gba àwọn ọlọ́jọ́lórí síṣẹ́. Èé ṣe? Nítorí pé wọ́n máa ń ṣaájò àwọn oníbàárà gan-an, wọ́n sì ń fi ìmọ̀ nípa bí a ṣe lè ṣe nǹkan láìsí ìtọ́ni tí a kọ sílẹ̀ nípa rẹ̀ hàn. Ìwé agbéròyìnjáde náà sọ pé, wọ́n tún máa ń rọ̀ mọ́ “àwọn ọ̀pá ìdiwọ̀n ìwà rere tí ó ṣeé ṣe kí ilé iṣẹ́ kan ti máa sú lọ kúrò nínú rẹ̀.”