ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g98 5/22 ojú ìwé 4-9
  • Ojú Ọjọ́ Júujùu

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ojú Ọjọ́ Júujùu
  • Jí!—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àìdánilójú Ń Fa Àríyànjiyàn
  • Kí Ni A Ń Ṣe Nípa Rẹ̀?
  • Ohun Tí Ìyípadà Náni
  • Ayé Ń Móoru O!—Ǹjẹ́ Àtúnṣe Kankan Wà?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Báwo Ni Àǹfààní Tí À Ń Rí Nínú Igbó Ṣe Pọ̀ Tó?
    Jí!—2004
  • Kí Ni A Lè Ṣe Láti Dáàbò Bo Àwọn Òkìtì Coral Abẹ́ Òkun?
    Jí!—1996
Jí!—1998
g98 5/22 ojú ìwé 4-9

Ojú Ọjọ́ Júujùu

NÍ ONÍRÚURÚ ọ̀nà, púpọ̀ wa gbára lé àwọn ohun àmúṣagbára eléròjà carbon. A ń wa ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ àti irú àwọn ọkọ̀ mìíràn tí ń lo epo gasoline tàbí diesel. A ń lo iná mànàmáná tí àwọn ẹ̀rọ amúnáwá tí ń lo èédú, gáàsì àdánidá, tàbí ọ́ìlì ń mú wá. A máa ń fi igi, èédú, àti gáàsì àdánidá dáná oúnjẹ tàbí kí a sun wọ́n láti yáná. Gbogbo ìgbòkègbodò wọ̀nyí ń tú gáàsì carbon dioxide sáfẹ́fẹ́. Gáàsì yìí ń sé ooru tí ń wá láti inú oòrùn mọ́.

A tún ń tú àwọn gáàsì amúǹkangbóná mìíràn tí ń sé ooru mọ́ sáfẹ́fẹ́. Gáàsì nitrous oxide láti inú àwọn ajílẹ̀ onígáàsì nitrogen tí a ń lò fún ohun ọ̀gbìn ń tú sáfẹ́fẹ́. Àwọn ilẹ̀ àbàtà tí a ń gbin ìrẹsì sí àti àwọn ilẹ̀ tí màlúù ti ń jẹko ń tú gáàsì methane sáfẹ́fẹ́. Àwọn gáàsì chlorofluorocarbon (CFC) tí ń wá láti inú ìfòfó ike àti àwọn ohun mìíràn tí a ń ṣe ní àwọn ilé iṣẹ́ ẹ̀rọ ń tú sáfẹ́fẹ́. Kì í ṣe pé àwọn gáàsì CFC ń sé ooru mọ́ nìkan ni, àmọ́ wọ́n tún ń ba ìpele ozone tí ó wà ní ibi gíga jù lọ nínú òfuurufú ilẹ̀ ayé jẹ́.

Yàtọ̀ sí àwọn gáàsì CFC, tí a ti díwọ̀n nísinsìnyí, ńṣe ni àwọn gáàsì tí ń sé ooru mọ́ wọ̀nyí ń tú sáfẹ́fẹ́ púpọ̀púpọ̀ sí i. Lápá kan, ohun tó fa èyí ni iye ènìyàn tí ń pọ̀ sí i lórí ilẹ̀ ayé, àti bí ohun àmúṣagbára tí a ń lò, ìgbòkègbodò ilé iṣẹ́ ẹ̀rọ, àti iṣẹ́ àgbẹ̀, ṣe ń gbèrú sí i. Gẹ́gẹ́ bí Ẹ̀ka Ìdáàbòbò Àyíká tí ó fi Washington ṣe ibùjókòó ti sọ, ní báyìí, àwọn ènìyàn ń tú bílíọ̀nù mẹ́fà tọ́ọ̀nù gáàsì carbon dioxide àti àwọn gáàsì amúǹkangbóná mìíràn sáfẹ́fẹ́ lọ́dọọdún. Àwọn gáàsì amúǹkangbóná wọ̀nyí kì í kàn rá sínú afẹ́fẹ́; wọ́n lè wà nínú afẹ́fẹ́ fún ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún.

Ní gbogbogbòò, ohun méjì dá àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì lójú. Àkọ́kọ́ ni pé, ní àwọn ẹ̀wádún àti ọ̀rúndún lọ́ọ́lọ́ọ́, ìwọ̀n gáàsì carbon dioxide àti àwọn gáàsì amúǹkangbóná mìíràn tí ó wà nínú afẹ́fẹ́ ti pọ̀ sí i. Ìkejì ni pé, láàárín ọgọ́rùn-ún ọdún tó kọjá, ìpíndọ́gba ìwọ̀n ìgbóná ilẹ̀ ayé ti fi nǹkan bí ìwọ̀n 0.3 sí 0.6 lórí òṣùwọ̀n Celsius pọ̀ sí i.

Ìbéèrè náà wá dìde pé, Mímú tí ènìyàn ń mú kí àwọn gáàsì amúǹkangbóná pọ̀ sí i ha ní nǹkan láti ṣe pẹ̀lú bí ilẹ̀ ayé ṣe ń móoru bí? Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kan sọ pé ó lè máà ní í ṣe pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n sì sọ pé pípọ̀ tí ìwọ̀n ìmóoru náà ń pọ̀ sí i wà lọ́wọ́ ìyípadà àdánidá àti pé ó lè jẹ́ oòrùn ló fà á. Èyí tó wù kí ó jẹ́, ọ̀pọ̀ àwọn ògbógi nípa ipò ojú ọjọ́ gbà pẹ̀lú ọ̀rọ̀ tó wà nínú ìròyìn kan tí Ìgbìmọ̀ Ọlọ́pọ̀ Orílẹ̀-Èdè Lórí Ìyípadà Ipò Ojú Ọjọ́ kọ. Ó sọ pé, pípọ̀ tí ìwọ̀n ìgbóná ń pọ̀ sí i “lè máà wá lọ́nà àdánidá pátápátá” àti pé, “ẹ̀rí tí ó wà fì síhà pé, a ń rí bí ènìyàn ṣe ń lọ́wọ́ nínú ohun tí ń ṣẹlẹ̀ sí ipò ojú ọjọ́ lágbàáyé.” Síbẹ̀, kò tíì sí ìdánilójú nípa bóyá iṣẹ́ ọwọ́ ẹ̀dá ló ń mú kí pílánẹ́ẹ̀tì máa móoru—ní pàtàkì nípa bí ayé ṣe lè yára móoru tó ní ọ̀rúndún kọkànlélógún àti ohun tí ó lè yọrí sí ní pàtó.

Àìdánilójú Ń Fa Àríyànjiyàn

Nígbà tí àwọn onímọ̀ nípa ipò ojú ọjọ́ sọ tẹ́lẹ̀ nípa ìmáyégbóná tí yóò ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú, wọ́n gbé e karí àwọn àpẹẹrẹ àwòrán ipò ojú ọjọ́ tí wọ́n yẹ̀ wò lórí àwọn kọ̀ǹpútà tí ó yára jù lọ, tí ó sì lágbára jù lọ lágbàáyé. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ìṣiṣẹ́kanra dídíjú kọjá ààlà ti àyípoyípo ilẹ̀ ayé, afẹ́fẹ́ àyíká, àwọn òkun, omi dídì, àwọn àbùdá ilẹ̀, àti oòrùn ni a fi ń pinnu ipò ojú ọjọ́ ilẹ̀ ayé. Níwọ̀n bí ó ti ní ohun púpọ̀ tó bẹ́ẹ̀ nínú, kò ṣeé ṣe fún kọ̀ǹpútà èyíkéyìí láti fi ìdánilójú sọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ ní 50 tàbí 100 ọdún sí àsìkò yìí tẹ́lẹ̀. Ìwé ìròyìn Science sọ láìpẹ́ yìí pé: “Ọ̀pọ̀ àwọn ògbógi nípa ipò ojú ọjọ́ kìlọ̀ pé kò tíì ṣe kedere síbẹ̀ pé àwọn ohun tí ènìyàn ń ṣe ti bẹ̀rẹ̀ sí í mú kí pílánẹ́ẹ̀tì móoru—bẹ́ẹ̀ ni bí ìmúmóoru ilé ewéko yóò ṣe pọ̀ tó nígbà tí ó bá dé kò tíì ṣe kedere.”

Àwọn àìdánilójú mú kí ó rọrùn láti sẹ́ pé ewu kankan wà. Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì tí ń ṣiyè méjì nípa ìmóoru ilẹ̀ ayé, àti àwọn ilé iṣẹ́ ńláńlá tí ọkàn ìfẹ́ wọ́n dá lórí ọrọ̀ ajé láti mú kí ohun tí ń ṣẹlẹ̀ ní lọ́ọ́lọ́ọ́ máa bá a lọ, jiyàn pé ibi tí ìmọ̀ dé báyìí kò dá ohun tí ó lè jẹ́ ìgbésẹ̀ ìṣàtúnṣe tí ó gbówó lórí láre. Wọ́n sọ pé, ó ṣe tán, ọjọ́ iwájú lè má burú tó bí àwọn kan ṣe rò.

Àwọn onímọ̀ nípa àyíká ṣàtakò nípa sísọ pé, kò yẹ kí àwọn àìdánilójú ti ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì mú àwọn aṣòfin kùnà láti fura sí àwọn ewu. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ òtítọ́ pé ipò ojú ọjọ́ lè má burú tó bí àwọn kan ṣe ń bẹ̀rù pé yóò rí lọ́jọ́ iwájú, ipò náà tún lè burú sí i! Wọ́n ronú pé, síwájú sí i, àìmọ ohun tí yóò wá ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú kò túmọ̀ sí pé a kò gbọ́dọ̀ ṣe ohunkóhun láti dín ewu rẹ̀ kù. Fún àpẹẹrẹ, àwọn tí wọ́n ń ṣíwọ́ sìgá mímu kì í kọ́kọ́ béèrè fún ẹ̀rí tí ó bá ìlànà sáyẹ́ǹsì mu tí ó fi hàn pé bí àwọn kò bá ṣíwọ́ sìgá mímu, àwọn yóò ní àrùn jẹjẹrẹ ẹ̀dọ̀fóró ní 30 ọdún tàbí 40 ọdún lẹ́yìn náà. Wọ́n ṣíwọ́ nítorí wọ́n mọ ewu tí ó wà níbẹ̀, wọ́n sì fẹ́ láti dín ewu náà kù tàbí kí wọ́n mú un kúrò.

Kí Ni A Ń Ṣe Nípa Rẹ̀?

Níwọ̀n bí àríyànjiyàn ti pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ nípa bí ìṣòro ìmóoru ilẹ̀ ayé ti pọ̀ tó—àti nípa bóyá ìṣòro kan tilẹ̀ wà rárá pàápàá—kò yani lẹ́nu pé èrò oríṣiríṣi ni ó wà nípa ohun tí a óò ṣe nípa rẹ̀. Àwùjọ àwọn onímọ̀ nípa àyíká ti fi ọ̀pọ̀ ọdún ṣonígbọ̀wọ́ lílo àwọn orísun ohun àmúṣagbára tí kì í sọ àyíká di eléèérí dé àyè tí ó pọ̀. A lè fa agbára láti inú oòrùn, afẹ́fẹ́, odò, àti àwọn ibi tí ń gba ooru àti omi gbígbóná ró tí ó wà lábẹ́lẹ̀.

Àwọn alágbàwí ire àyíká ènìyàn tún ti pàrọwà fún àwọn ìjọba láti ṣe àwọn òfin láti dín títú àwọn gáàsì tí ń sé ooru mọ́ sáfẹ́fẹ́ jáde kù. Àwọn ìjọba ti fọwọ́ sí àwọn ìwé àdéhùn. Fún àpẹẹrẹ, ní 1992, níbi Àpérò Lórí Ọ̀ràn Ilẹ̀ Ayé ní Rio de Janeiro, Brazil, àwọn aṣojú nǹkan bí 150 orílẹ̀-èdè fọwọ́ sí ìwé àdéhùn kan tí ń fìdí ẹ̀jẹ́ ìmúratán wọn láti dín títú àwọn gáàsì amúǹkangbóná, pàápàá gáàsì carbon dioxide, sáfẹ́fẹ́ kù, múlẹ̀. Góńgó wọ́n ni pé tí ó bá máa di ọdún 2000, àwọn gáàsì tí ń sé ooru mọ́, tí àwọn orílẹ̀-èdè onílé-iṣẹ́ ẹ̀rọ ńláńlá ń tú sáfẹ́fẹ́ yóò dín kù di ìwọ̀n tí ó wà ní 1990. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn díẹ̀ ti ṣe dáradára nínú ọ̀ràn yìí, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n lọ́rọ̀ kò tilẹ̀ sún mọ́ pípa ẹ̀jẹ́ tí kò tó nǹkan náà mọ́. Dípò kí àwọn orílẹ̀-èdè náà dín in kù, ńṣe ni ọ̀pọ̀ jù lọ lára wọn ń ṣèmújáde àwọn gáàsì amúǹkangbóná púpọ̀ sí i ju ti ìgbàkigbà rí lọ! Fún àpẹẹrẹ, ní United States, a ronú pé tí ó bá máa di ọdún 2000, ìwọ̀n gáàsì carbon dioxide tí wọ́n ń tú sáfẹ́fẹ́ lè ti fi ìpín 11 nínú ọgọ́rùn-ún pọ̀ ju bí ó ṣe tó ní 1990 lọ.

Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, a ti gbé àwọn ìgbésẹ̀ láti “mú” àwọn àdéhùn àgbáyé “ṣẹ lọ́nà gbígbéṣẹ́.” Dípò mímú kí dídín ìwọ̀n tí wọ́n ń tú sáfẹ́fẹ́ kù jẹ́ àfínnúfíndọ̀ṣe bí ó ṣe wà nínú àdéhùn ti 1992, wọ́n ti pe ìpè láti gbé àwọn góńgó tí a fi dandan lé kalẹ̀ lórí ìwọ̀n àwọn gáàsì tí ń sé ooru mọ́ tí a ń tú sáfẹ́fẹ́.

Ohun Tí Ìyípadà Náni

Àwọn aṣáájú olóṣèlú ń fẹ́ kí a wo àwọn bí ọ̀rẹ́ ilẹ̀ ayé. Àmọ́ wọ́n tún ń ṣàníyàn nípa àwọn ohun tí ìyípadà lè mú wá bá ètò ọrọ̀ ajé. Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn The Economist ti sọ, níwọ̀n bí ìpín 90 nínú ọgọ́rùn-ún àgbáyé ti sinmi lé àwọn ohun àmúṣagbára eléròjà gáàsì carbon, láti má lò ó mọ́ yóò mú àwọn ìyípadà ńlá wá; iye tí ìyípadà yóò sì náni ń fa àríyànjiyàn gbígbónájanjan.

Kí ni yóò náni láti dín títú àwọn gáàsì tí ń sé ooru mọ́ sáfẹ́fẹ́ kù sí ìwọ̀n tí ó fi ìpín 10 nínú ọgọ́rùn-ún dín sí ti ọdún 1990 tí ó bá máa di ọdún 2010? Ìdáhùn sí ìbéèrè yẹn sinmi lórí ẹni tí o bá bi. Ṣàgbéyẹ̀wò àwọn èrò láti United States, orílẹ̀-èdè tí ń tú àwọn gáàsì amúǹkangbóná tí ó pọ̀ ju ti orílẹ̀-èdè èyíkéyìí mìíràn lọ sáfẹ́fẹ́. Àwùjọ àwọn aṣèwádìí nípa onírúurú ẹ̀ka ìmọ̀ tí àwọn ilé iṣẹ́ ẹ̀rọ ṣonígbọ̀wọ́ kìlọ̀ pé, irú dídín àwọn gáàsì tí ń sé ooru mọ́ kù bẹ́ẹ̀ yóò ná United States ní ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù dọ́là lọ́dọọdún, yóò sì sọ 600,000 ènìyàn di aláìníṣẹ́. Ní ìyàtọ̀, àwọn alágbàwí ire àyíká sọ pé ṣíṣàṣeyọrí góńgó kan náà lè gba ètò ọrọ̀ ajé náà lọ́wọ́ níná ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù dọ́là lọ́dọọdún, kí ó sì mú kí 773,000 iṣẹ́ tuntun wà.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwùjọ àwọn alágbàwí ire àyíká ń pe ìpè fún gbígbégbèésẹ̀ ojú ẹsẹ̀, àwọn ilé iṣẹ́ ńláńlá—àwọn tí ń ṣe ọkọ̀ ìrìnnà, àwọn ilé iṣẹ́ elépo, àti àwọn tí ń ṣe èédú, kí a dárúkọ díẹ̀—wà, tí ń lo owó àti ipá ìdarí púpọ̀ tí wọ́n ní láti bu ìjẹ́pàtàkì ewu tí ó wà nínú mímóoru ilẹ̀ ayé kù àti láti sàsọdùn nípa ipa bíburú tí yíyí kúrò nínú lílo ohun àkẹ̀kù bí epo yóò ní lórí ètò ọrọ̀ ajé.

Àríyànjiyàn ń bá a lọ. Bí àwọn ènìyàn bá tilẹ̀ ń yí ipò ojú ọjọ́ padà, tí wọn kò sì ṣe nǹkan kan nípa rẹ̀ àyàfi kí wọ́n máa sọ̀rọ̀ ṣáá, òwe tí ó sọ pé, gbogbo ènìyàn ń sọ̀rọ̀ ṣáá nípa ojú ọjọ́, àmọ́ kò sí ẹni tó ṣe nǹkan kan nípa rẹ̀ yóò ní ìtumọ̀ tuntun kan tí ó jẹ́ atọ́ka ìṣẹ̀lẹ̀ ibi.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 5]

Àdéhùn ti Kyoto Lórí Ipò Ojú Ọjọ́

Ní December 1997, ó lé ní 2,200 àyànṣaṣojú láti orílẹ̀-èdè 161 tí wọ́n ṣèpàdé ní Kyoto, Japan, láti ṣe àdéhùn kan láti wá nǹkan ṣe sí ewu ìmóoru ilẹ̀ ayé. Lẹ́yìn tí wọ́n ti fi ohun tí ó lé ní ọ̀sẹ̀ kan jíròrò, àwọn àyànṣaṣojú náà dórí ìpinnu pé, tí ó bá fi máa di ọdún 2012, àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti gòkè àgbà gbọ́dọ̀ dín ìwọ̀n àwọn gáàsì amúǹkangbóná tí wọ́n ń tú jáde kù sí ìpíndọ́gba tí ó fi ìpín 5.2 nínú ọgọ́rùn-⁠ún dín sí ìwọ̀n ti 1990. Wọn óò pinnu ìyà tí wọn óò fi jẹ àwọn tí wọ́n bá tẹ àdéhùn náà lójú nígbà tó bá yá. Ká ní gbogbo orílẹ̀-èdè rọ̀ mọ́ àdéhùn náà, ipa wo ni dídín ìwọ̀n gáàsì tí a ń tú jáde kù ní ìpín 5.2 nínú ọgọ́rùn-⁠ún yóò ní? Dájúdájú, kò lè tó nǹkan. Ìwé ìròyìn Time sọ pé: “Yóò gba dídín ìwọ̀n gáàsì tí a ń tú jáde kù ní ìpín 60 nínú ọgọ́rùn-⁠ún láti lè dín àwọn gáàsì amúǹkangbóná, tí ó ti ń kóra jọ sínú afẹ́fẹ́ láti ìbẹ̀rẹ̀ ìgbà ìyípadà sí sànmánì iṣẹ́ ẹ̀rọ, kù lọ́nà tó já mọ́ nǹkan.”

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

A Ṣàpèjúwe Ìmáyégbóná

Ìmáyégbóná: Afẹ́fẹ́ àyíká ilẹ̀ ayé, bí àwọn dígí tí a gé dí ilé ewéko kan, ń sé ooru tí ń tinú oòrùn wá mọ́. Ìtànṣán oòrùn ń mú ilẹ̀ ayé móoru, àmọ́ ooru tí ó ń mú wá—tí ìtànṣán aláìṣeéfojúrí ń gbé—kò lè tètè kúrò nínú afẹ́fẹ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn gáàsì amúǹkangbóná ń dí ìtànṣán náà, wọ́n sì ń darí díẹ̀ lára rẹ̀ padà sí ilẹ̀ ayé, èyí sì ń fi kún ìmóoru àyíká ilẹ̀ ayé.

1. Oòrùn

2. Ìtànṣán aláìṣeéfojúrí tí a sé mọ́

3. Àwọn gáàsì amúǹkangbóná

4. Ìtànṣán tí ń tú jáde

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8, 9]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

Àwọn Ipá Tí Ń Ṣàkóso Ojú Ọjọ́

Bí a bá fẹ́ lóye àríyànjiyàn nípa ìmóoru ilẹ̀ ayé tí ń lọ lọ́wọ́, a ní láti lóye díẹ̀ lára àwọn ipá amúniṣekàyéfì tí ń mú kí ojú ọjọ́ wa rí bó ṣe rí. Ẹ jẹ́ kí a gbé àwọn díẹ̀ tí ó ṣe pàtàkì yẹ̀ wò.

1. Oòrùn—Orísun Ooru àti Ìmọ́lẹ̀

Ìwàláàyè lórí ilẹ̀ ayé gbára lé ìléru kíkàmàmà náà tí a ń pè ní oòrùn. Bí oòrùn ti tóbi ju ilẹ̀ ayé lọ nígbà àádọ́ta ọ̀kẹ́, ó ń pèsè ooru àti ìmọ́lẹ̀ tí ó ṣeé gbíyè lé nígbà gbogbo. Bí ohun tí oòrùn ń gbé jáde bá dín kù, omi dídì yóò bo pílánẹ́ẹ̀tì wa; bí ó bá sì pọ̀ sí i, yóò sọ ilẹ̀ ayé di gbígbónájanjan bí páànù tí a fi ń dín nǹkan. Níwọ̀n bí ibi tí ayé wà sí oòrùn tí ó ń yí po ti jẹ́ 150 mílíọ̀nù kìlómítà, ó ń gba ìdajì péré lára ìdá kan nínú bílíọ̀nù agbára tí ń jáde lára oòrùn. Bí ó ti wù kí ó rí, ìwọ̀n tí ó tó láti mú kí ipò ojú ọjọ́ tí nǹkan ti lè wà láàyè wà nìyí.

2. Afẹ́fẹ́ Àyíká —Kúbùsù Mímóoru ti Ilẹ̀ Ayé

Kì í ṣe oòrùn nìkan ní ń pinnu ìwọ̀n ìgbóná ilẹ̀ ayé; afẹ́fẹ́ àyíká wa pẹ̀lú kó ipa pàtàkì nínú rẹ̀. Bí ilẹ̀ ayé àti òṣùpá ṣe jìnnà sí oòrùn jẹ́ ọgbọọgba, nítorí náà, ìwọ̀n ooru tí àwọn méjèèjì ń gbà láti ara oòrùn fẹ́rẹ̀ẹ́ dọ́gba. Síbẹ̀síbẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìpíndọ́gba ìdíwọ̀n ìgbóná ilẹ̀ ayé jẹ́ ìwọ̀n 15 lórí òṣùwọ̀n Celsius, ìpíndọ́gba ìdíwọ̀n ìtutù òṣùpá jẹ́ ìwọ̀n 18 sísàlẹ̀ oódo lórí òṣùwọ̀n Celsius. Kí ló dé tí wọ́n yàtọ̀ síra? Ilẹ̀ ayé ní afẹ́fẹ́ àyíká; òṣùpá kò ní in.

Afẹ́fẹ́ àyíká wa—afẹ́fẹ́ oxygen, nitrogen, àti àwọn gáàsì mìíràn tí ó wé ilẹ̀ ayé pọ̀—ń gba díẹ̀ lára ìmóoru oòrùn mọ́ra, ó sì ń jẹ́ kí àwọn yòókù dà nù. A sábà máa ń fi ìlànà náà wé ilé ewéko. Bóyá ẹ mọ̀ pé ilé ewéko jẹ́ ilé kan tí ó ní ògiri àti òrùlé tí wọ́n fi dígí tàbí ike ṣe. Ìtànṣán oòrùn ń fìrọ̀rùn wọlé, ó sì ń mú inú rẹ̀ gbóná. Lákòókò kan náà, òrùlé àti ògiri rẹ̀ kì í jẹ́ kí ooru lè tètè jáde.

Lọ́nà kan náà, afẹ́fẹ́ àyíká wa ń jẹ́ kí ìtànṣán oòrùn gba àárín rẹ̀ kọjá láti mú ilẹ̀ ayé móoru. Ilẹ̀ ayé náà yóò wá dá ooru padà sínú afẹ́fẹ́ bí ìtànṣán aláìṣeéfojúrí. Ọ̀pọ̀ lára àwọn ìtànṣán wọ̀nyí kì í lọ sínú òfuurufú ní tààràtà nítorí pé àwọn gáàsì kan tí ó wà nínú afẹ́fẹ́ ń gbà á sára, wọ́n sì ń darí rẹ̀ padà sí ilẹ̀ ayé, tí èyí sì ń fi kún ìmóoru ilẹ̀ ayé. Ìlànà ooru yìí ni a ń pè ní ìmáyégbóná. Bí afẹ́fẹ́ àyíká wa kò bá sé ooru tí ń tinú oòrùn wá mọ́ lọ́nà yìí, kò ní sí ohun alààyè kan lórí ilẹ̀ ayé bí kò ṣe sí nínú òṣùpá.

3. Oruku Omi —Gáàsì Tí Ó Ṣe Pàtàkì Jù Lọ ní Ilé Ewéko

Ìpín 99 nínú ọgọ́rùn-ún lára afẹ́fẹ́ àyíká wa ni ó ní gáàsì méjì nínú: nitrogen àti oxygen. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn gáàsì wọ̀nyí kó ipa pàtàkì nínú àyípoyípo dídíjú tí ń ti ìwàláàyè lẹ́yìn lórí ilẹ̀ ayé, wọ́n fẹ́rẹ̀ẹ́ máà kó ipa tààràtà kan nínú ṣíṣètò bí ojú ọjọ́ yóò ṣe rí. Iṣẹ́ ṣíṣètò ojú ojọ́ wà lọ́wọ́ ìpín 1 nínú ọgọ́rùn-ún tó ṣẹ́ kù nínú afẹ́fẹ́, àwọn gáàsì amúǹkangbóná tí ń sé ooru mọ́, tí ó ní oruku omi, gáàsì carbon dioxide, nitrous oxide, methane, chlorofluorocarbon, àti ozone, nínú.

Gáàsì amúǹkangbóná tí ó ṣe pàtàkì jù lọ—oruku omi—ni a kì í fìgbà gbogbo ronú pé ó jẹ́ gáàsì páàpáà, níwọ̀n bí ó ti mọ́ wa lára láti máa ronú nípa omi bí ohun ṣíṣàn. Síbẹ̀, èérún oruku omi kọ̀ọ̀kan tí ó wà nínú afẹ́fẹ́ ní agbára olóoru nínú. Fún àpẹẹrẹ, bí oruku omi tí ó wà nínú kùrukùru bá tutù, tí ó sì dì, yóò tú ooru jáde, èyí yóò sì mú kí ìgbì ìtúkiri rẹ̀ lágbára jọjọ. Ìtúkiri gbígbéṣẹ́ oruku omi nínú afẹ́fẹ́ àyíká wa kó ipa pàtàkì tí ó sì díjú nínú pípinnu bí ojú ọjọ́ yóò ṣe rí.

4. Gáàsì Carbon Dioxide —Ó Ṣe Pàtàkì fún Ìwàláàyè

Gáàsì carbon dioxide ni a sábà máa ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nígbà tí a bá ń jíròrò nípa ìmóoru ilẹ̀ ayé. Ó jẹ́ ìṣinilọ́nà láti bẹnu àtẹ́ lu gáàsì carbon dioxide pé ó jẹ́ kìkì asọ-àyíká-deléèérí. Gáàsì carbon dioxide jẹ́ èròjà pàtàkì nínú ìlànà photosynthesis, ìlànà tí àwọn ewéko fi ń pèsè oúnjẹ fún ara wọn. Àwọn ènìyàn àti ẹranko ń mí afẹ́fẹ́ oxygen sínú, wọ́n sì ń mí gáàsì carbon dioxide síta. Àwọn ewéko ń gba gáàsì carbon dioxide sára, wọ́n sì ń tú afẹ́fẹ́ oxygen jáde. Ní gidi, ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìpèsè tí Ẹlẹ́dàá ṣe, tí ń mú kí nǹkan lè wà láàyè lórí ilẹ̀ ayé.a Àmọ́, bí gáàsì carbon dioxide bá pọ̀ jù nínú afẹ́fẹ́, ó dájú pé yóò dà bí fífi kúbùsù mìíràn kún èyí tó ti wà lórí bẹ́ẹ̀dì. Ó lè mú kí nǹkan túbọ̀ móoru sí i.

Ọ̀wọ́ Dídíjú Ti Àwọn Ipá Agbára

Oòrùn àti afẹ́fẹ́ àyíká nìkan kọ́ ní ń pinnu bí ojú ọjọ́ yóò ṣe rí. Àwọn òkun àti àwọn òkìtì omi dídì lófuurufú, àwọn èròjà àyíká ilẹ̀ ayé àti àwọn ewéko, ìbáṣepọ̀ àwọn ohun alààyè pẹ̀lú àyíká ilẹ̀ ayé wọn, àwọn ọ̀wọ́ ìlànà ìbáṣepọ̀ àwọn kẹ́míkà ilẹ̀ ayé pẹ̀lú irúgbìn àti ẹranko alààyè ní àgbègbè kan, àti ipa tí àwọn ohun tí ń yí ilẹ̀ ayé po ń ní, ń ṣe nínú rẹ̀ pẹ̀lú. Ìwádìí nípa ipò ojú ọjọ́ fẹ́rẹ̀ẹ́ kó gbogbo ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì nípa ilẹ̀ ayé mọ́ra.

Oòrùn

Afẹ́fẹ́ àyíká

Oruku omi (H20)

Gáàsì carbon dioxide (CO2)

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ohun alààyè orí ilẹ̀ ayé ní ń gba agbára láti àwọn orísun tí ó ní gáàsì carbon nínú, tí èyí sì ń mú wọn gbára lé ìtànṣán oòrùn ní tààràtà tàbí láìṣetààràtà. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, àwọn ohun alààyè kan wà tí ń gbọ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀ nínú òkùnkùn lábẹ́ òkun nípa gbígba agbára láti inú àwọn kẹ́míkà kòṣẹ̀fọ́kòṣẹran. Dípò kí àwọn ohun alààyè wọ̀nyí lo ìlànà photosynthesis, ìlànà kan tí a ń pè ní chemosynthesis ni wọ́n ń lò.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́