Ìgbà Tí Òkú Kú Ní Gidi
“Ààyè ajá sàn ju òkú kìnnìún lọ. Nítorí àwọn alààyè mọ̀ pé àwọn yóò kú; ṣùgbọ́n ní ti àwọn òkú, wọn kò mọ nǹkan kan rárá, wọn kò sì ní owó ọ̀yà mọ́, nítorí pé a ti gbàgbé ìrántí wọn.” —Oníwàásù 9:4, 5.
Ọ̀PỌ̀ ènìyàn ní ìgbàgbọ́ tí kò ṣe gúnmọ́ nípa ọkàn kan tí ń wà láàyè lọ lẹ́yìn tí ènìyàn bá kú, tàbí tí ń yíra padà nínú onírúurú àkókò àtúnwáyé. Àwọn kan tilẹ̀ gbà gbọ́ pé ẹnì kan lè padà wá sí ìyè lẹ́yìn tí ó ti kú. Láìpẹ́ yìí, wọ́n bi Thomas Lynch, òṣìṣẹ́ ìpalẹ̀mọ́ òkú àti ètò ayẹyẹ ìsìnkú kan, léèrè ohun tí ó rò sí ọ̀ràn ìwàláàyè lẹ́yìn ikú. Ó sọ pé: “Àwọn ènìyàn tí wọ́n ń ṣìrànǹrán àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ wọ̀nyẹn kò jí dìde rárá—a wulẹ̀ ń kà wọ́n sí òkú nítorí pé ó kọjá agbára wa láti díwọ̀n àwọn àmì ìwàláàyè wọn ni. Ìdí ni pé, ẹnì kan jẹ́ ‘òkú’ nígbà tí kò bá jí sáyé mọ́.”—The New York Times Magazine.
Bíbélì ti sọ òtítọ́ tó wà níbẹ̀ láti ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún wá. “Ààyè ajá sàn ju òkú kìnnìún lọ. Nítorí àwọn alààyè mọ̀ pé àwọn yóò kú; ṣùgbọ́n ní ti àwọn òkú, wọn kò mọ nǹkan kan rárá, wọn kò sì ní owó ọ̀yà mọ́, nítorí pé a ti gbàgbé ìrántí wọn.” (Oníwàásù 9:4, 5) Wíwulẹ̀ ṣèbẹ̀wò sí itẹ́ àtayébáyé kan yóò tètè fìdí òtítọ́ yẹn múlẹ̀.
Ǹjẹ́ ìyẹn túmọ̀ sí pé kò sí ìrètí kankan fún àwọn òkú ni? Ó dájú pé Bíbélì kò fúnni ní ìdí kankan láti gbà gbọ́ pé ọkàn kan tí kò lè kú ń wà nìṣó lẹ́yìn tí ènìyàn bá ti kú. (Jẹ́nẹ́sísì 2:7; Ìsíkíẹ́lì 18:4, 20) Bí o ti wù kí ó rí, Jésù Kristi wàásù nípa àjíǹde sí ìyè lórí ilẹ̀ ayé tí a sọ di párádísè sípò. Júù ọmọlẹ́yìn rẹ̀ náà, Màtá, tí arákùnrin rẹ̀, Lásárù, ṣẹ̀ṣẹ̀ kú nígbà náà, gbà gbọ́ pé àjíǹde wà, nítorí tí ó sọ nípa Lásárù pé: “Mo mọ̀ pé yóò dìde nínú àjíǹde ní ọjọ́ ìkẹyìn.” (Jòhánù 11:24) Jésù fèsì sí èyí pé: “Èmi ni àjíǹde àti ìyè. Ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú mi, bí ó tilẹ̀ kú, yóò yè; àti olúkúlùkù ẹni tí ń bẹ láàyè, tí ó sì ń lo ìgbàgbọ́ nínú mi, kì yóò kú láé. Ìwọ ha gba èyí gbọ́ bí?” (Jòhánù 11:25, 26) Ó ti sọ ṣáájú pé: “Kí ẹnu má yà yín sí èyí, nítorí pé wákàtí náà ń bọ̀, nínú èyí tí gbogbo àwọn tí wọ́n wà nínú ibojì ìrántí yóò gbọ́ ohùn rẹ̀, wọn yóò sì jáde wá, àwọn tí wọ́n ṣe ohun rere sí àjíǹde ìyè, àwọn tí wọ́n sọ ohun búburú dàṣà sí àjíǹde ìdájọ́.” Ṣùgbọ́n, kíyè sí i pé Jésù kò mẹ́nu ba ọkàn kan tí kò lè kú!—Jòhánù 5:28, 29; Lúùkù 23:43.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 31]
“Ẹnì kan jẹ́ ‘òkú’ nígbà tí kò bá jí sáyé mọ́.” Thomas Lynch, òṣìṣẹ́ ìpalẹ̀mọ́ òkú àti ètò ayẹyẹ ìsìnkú