ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g98 9/8 ojú ìwé 12-15
  • Ọgbọ́n Ìyíniléròpadà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ọgbọ́n Ìyíniléròpadà
  • Jí!—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Tí A Darí Rẹ̀ Sí
  • Àwọn Ohun Ìyíniléròpadà
  • Fífa Ìrònú àti Ìmọ̀lára Ẹni Mọ́ra
  • Àwọn Ìpolówó Ọjà Tí Ń Gbani Lọ́kàn
  • Àpọ̀jù Ìpolówó Ọjà Kò Jẹ́ Ká Lè Ṣèpinnu Tí Ó Tọ́
    Jí!—1998
  • Agbára Tí Ìpolówó Ọjà Ní
    Jí!—1998
  • Báwo Ni Ìmúra Mi Ṣe Rí?
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Iná Mọ́ Àwọn Ilé Iṣẹ́ Tábà
    Jí!—1996
Jí!—1998
g98 9/8 ojú ìwé 12-15

Ọgbọ́n Ìyíniléròpadà

KÍ NI ète ìpolówó ọjà? Àwọn oníṣòwò sọ pé, ìpolówó ọjà àwọn ń ṣe ará ìlú láǹfààní nítorí pé ó ń sọ fún wa nípa àwọn ọjà wọn. Àjọ Ìpolówó Ọjà Lágbàáyé sọ pé: “Láti mọ ohun tí ń lọ, kòṣeémáàní ni ìpolówó ọjà jẹ́ fún àwọn Aláràlò. A ń ra ohun tí ó dára nítorí ìsọfúnni tí a ti rí gbọ́ nípa rẹ̀. Ìpolówó ọjà—ní gbogbo gbòò—ni ọ̀nà tí ìsọfúnni ń gbà dé ọ̀dọ̀ Olùṣe-Ọjà àti Aláràlò.”

Dájúdájú, gbogbo wa la mọ̀ pé irú ìpolówó ọjà bẹ́ẹ̀ ń ṣe ju kí ó jẹ́ kí a mọ̀ nípa nǹkan lọ—nítorí kí a lè ta ọjà ni a ṣe ń ṣe é. Kì í sọ òkodoro ọ̀rọ̀, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣàìpọ̀n sápá kan. Àwọn ìpolówó ọjà máa ń fọgbọ́n gba aláràlò lọ́kàn, ó sì ń sún un láti ra ọjà tí wọ́n polówó.

Síwájú sí i, ìpolówó ọjà ń tà ju ọjà fúnra rẹ̀ lọ; ó ń jẹ́ kí orúkọ ẹ̀yà ọjà tà. Bí o bá ń ṣe ọṣẹ lọ́pọ̀, o kò ní ná àràádọ́ta ọ̀kẹ́ dọ́là sórí ìpolówó ọjà láti fún àwọn ènìyàn níṣìírí láti ra ọṣẹ èyíkéyìí. Wàá fẹ́ kí wọ́n ra ọṣẹ tìrẹ. Wàá fẹ́ ìpolówó ọjà tí yóò mú un dá àwọn ará ìlú lójú pé, irú ọṣẹ tìrẹ dára ju èyíkéyìí mìíràn lọ.

Àwọn Tí A Darí Rẹ̀ Sí

Kí ìpolówó ọjà kan tó lè gbéṣẹ́, a sábà máa ń fìṣọ́ra darí rẹ̀ sí àwùjọ ènìyàn kan, ó lè jẹ́ sí àwọn ọmọdé, àwọn abilékọ, àwọn oníṣòwò, tàbí àwùjọ àwọn mìíràn. Wọ́n ń gbé ìsọfúnni náà kalẹ̀ lọ́nà tí yóò fa ọkàn àwùjọ náà mọ́ra jù lọ. Wọn óò wá gbé ìpolówó ọjà náà jáde ní ilé iṣẹ́ ìròyìn tí wọ́n ń tẹ́tí sí.

Kí wọ́n tó ṣètò ìpolówó ọjà kan, wọn óò ti ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwádìí nípa àwùjọ ènìyàn tí ó ṣeé ṣe jù lọ kí wọ́n ra ọjà tí wọ́n ń polówó náà kí wọ́n sì lò ó. Àwọn olùpolówó ọjà ní láti mọ irú àwọn tí wọ́n lè ra ọjà wọn, bí wọ́n ṣe ń ronú, tí wọ́n sì ń hùwà, ohun tí wọ́n fẹ́. Amọṣẹ́dunjú olùpolówó ọjà kan kọ̀wé pé: “A jẹ́ kí mímọ irú àwọn ènìyàn pàtó tí ìpolówó ọjà wa yóò dé ọ̀dọ̀ wọn jẹ́ olórí iṣẹ́ wa. Ẹni tí wọ́n jẹ́, ibi tí wọ́n ń gbé, irú ohun tí wọ́n máa ń rà. Àti ìdí tí wọ́n fi ń rà á. Mímọ gbogbo èyí jẹ́ ohun tí a nílò láti gbé ìpolówó ọjà lọ́nà tí yóò sún wọn rà á kalẹ̀. Àwọn tí a darí rẹ̀ sí yóò hùwà padà sí rírọ̀ tí a ń rọ̀ wọ́n náà; wọn kì yóò hùwà padà sí ìpolówó ọjà tí ó jẹ́ ti ìṣefọ́ńté, ti ire ara wa, tàbí tí ó jọ ọfà tí a ń ta sáfẹ́fẹ́ léraléra.”

Àwọn Ohun Ìyíniléròpadà

Nígbà tí a bá bẹ̀rẹ̀ ìgbékalẹ̀ ìpolówó ọjà, ó máa ń ṣe pàtàkì láti ṣàṣàyàn ọ̀rọ̀ tí a óò lò. Ó wọ́pọ̀ kí a máa gbéni gẹṣin aáyán. Wọ́n sọ nípa oúnjẹ àárọ̀ kan pé “ọba oúnjẹ ni,” ilé iṣẹ́ kan tí ó sì ń ṣe káàdì ìkíni sọ pé ìgbà tí àwọn ènìyàn bá “fẹ́ fi èyí tí ó dára jù lọ ránṣẹ́” ni wọ́n máa ń ra káàdì òun. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í fi bẹ́ẹ̀ rọrùn láti mọ ìyàtọ̀ láàárín ìgbénigẹṣin-aáyán àti ẹ̀tàn àpilẹ̀ṣe, àwọn olùpolówó ọjà ní láti ṣọ́ra kí wọ́n máà máa sọ àwọn ohun tí a lè já irọ́ ìdí rẹ̀ bí a bá ṣe ìwádìí. Àwọn ìjọba kan ṣe òfin tí ń ka irú àbòsí bẹ́ẹ̀ léèwọ̀, àwọn ilé iṣẹ́ sì máa ń tètè pe ẹjọ́ bí àwọn ìpolówó ọjà ẹlẹ́tàn tí ilé iṣẹ́ abánidíje kan ṣe bá wu ire iṣẹ́ wọn léwu.

Bí ọjà kan bá fẹ́rẹ̀ẹ́ jọ àwọn mìíràn gan-an, ìwọ̀nba ni olùpolówó ọjà kan lè dánnu mọ, nítorí náà, ọ̀rọ̀ kì í sábà pọ̀ tàbí kí ó má tilẹ̀ sí rárá. Ọ̀pọ̀ máa ń lo àwọn ọ̀rọ̀ amóríwú láti polówó ọjà wọ́n. Àwọn àpẹẹrẹ kan nìyí: “Ìwọ sáà rà á” (irú bàtà kan tí wọ́n fi ń sáré), “Oúnjẹ àárọ̀ fún àwọn olùborí” (irú oúnjẹ àárọ̀ kan tí wọ́n fi ọkà ṣe), “Fi owó rẹ ra nǹkan gidi” (irú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ kan), àti “Àwọn ènìyàn gidi lo bá dòwò pọ̀” (ilé iṣẹ́ ìbánigbófò kan).

Àwọn àwòrán tí a ń fi polówó ọjà, yálà nínú ìwé ìròyìn tàbí lórí tẹlifíṣọ̀n, ń ní àwọn ìtọ́kasí tí ó lágbára ju ohun tí a sọ nípa ọjà náà gan-an lọ. Ọ̀nà tí a gbà gbé ìpolówó ọjà kan kalẹ̀ lè gbé àwọn èrò bí ìwọ̀nyí jáde, ‘Bí o bá ra agogo yìí, àwọn ènìyàn yóò bọ̀wọ̀ fún ọ’ tàbí ‘Irú ṣòkòtò jeans yìí yóò mú kí ẹ̀yà òdì kejì túbọ̀ máa gba tìrẹ’ tàbí ‘Ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ yìí yóò mú kí àwọn aládùúgbò rẹ jowú.’ Ní ọ̀kan lára àwọn ilé iṣẹ́ ìpolówó ọjà tí a mọ̀ jù lọ, tí ó sì rí ṣe jù lọ, ilé iṣẹ́ kan tí ń ṣe sìgá so àwọn tí ń da màlúù mọ́ ọjà rẹ̀. A fi àwọn tí ń da màlúù náà hàn bí alágbára, tí ó taagun, tí àkóso wà lọ́wọ́ wọn. Ọ̀rọ̀ tí a kò sọ jáde náà ni pé: Mu sìgá wa, ìwọ yóò sì dà bí àwọn ọkùnrin alágbára tí ayé gba tiwọn wọ̀nyí.

Ní àfikún sí àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn àti àwòrán tí a rí, orin ṣe pàtàkì nínú ìpolówó ọjà orí tẹlifíṣọ̀n àti rédíò. Ó ń wọnú ara lọ, ó ń mú ìpolówó ọjà sunwọ̀n sí i, kì í jẹ́ kí a gbàgbé rẹ̀, ó sì ń mú kí ìṣarasíhùwà àwọn aláràlò dára sí ọjà náà.

Ìwé ìròyìn World Watch sọ pé: “Àwọn ìpolówó ọjà tí a gbé kalẹ̀ lọ́nà tí ó dára jù lọ jẹ́ àgbàyanu—tí ó ní àwòrán kíkàmàmà, àṣeyọrí tí ń tuni lára, àti àwọn ọ̀rọ̀ agbàfiyèsí tí ó kan àwọn tí a bẹ̀rù àti ohun tí a fẹ́ràn. Àwọn ìpolówó ọjà tí a máa ń ṣe lọ́wọ́ ìrọ̀lẹ́ nígbà tí ọ̀pọ̀ ènìyàn máa ń wo tẹlifíṣọ̀n ní àwọn orílẹ̀-èdè onílé-iṣẹ́ ńláńlá máa ń dá ọ̀pọ̀lọpọ̀ àbá láàárín ìṣẹ́jú kan péré ju ohunkóhun mìíràn tí a tíì hùmọ̀ lọ.”

Fífa Ìrònú àti Ìmọ̀lára Ẹni Mọ́ra

A ń fìṣọ́ra gbé àwọn ìpolówó ọjà kalẹ̀ láti fa àwọn ìfẹ́-ọkàn àti ohun tí ó jẹ àwọn tí a darí rẹ̀ sí lógún mọ́ra. Bóyá ìpolówó ọjà kan yóò mú kí ọkàn ẹni kan fà sí gbígbádùn ara rẹ̀, fífẹ́ ààbò, tàbí fífẹ́ kí àwọn ẹlòmíràn tẹ́wọ́ gbani. Bóyá ìpolówó ọjà náà yóò darí ara rẹ̀ sípa wíwọ àwọn ènìyàn lọ́kàn, láti mọ́ tónítóní, tàbí gbígbàfiyèsí. Àwọn ìpolówó ọjà kan ń gbé àwọn ọjà wọn lárugẹ nípa sísọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tí a bẹ̀rù. Fún àpẹẹrẹ, ilé iṣẹ́ kan tí ń ṣe ọṣẹ ìfọyín kìlọ̀ nípa ewu tí ó wà nínú kí ẹnu máa rùn pé: “Ọ̀rẹ́ rẹ tímọ́tímọ́ jù lọ pàápàá kò ní sọ fún ọ” àti pé, “Ó sábà máa ń ṣẹlẹ̀ pé bí ẹnu rẹ bá ń rùn, o kò lè rọ́kọ fẹ́.”

Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ó máa ń rọrùn láti wo ìpolówó ọjà kan kí a sì ṣe ìfọ́síwẹ́wẹ́ bí ó ṣe fani mọ́ra. A darí àwọn ìpolówó ọjà kan ní tààràtà sí àwọn apá èrò inú tí ó wà lójúfò, tí ń ronú jinlẹ̀, tí ó kún fún ọgbọ́n. Wọ́n ń gbé àwọn ìsọfúnni pàtó nípa ọjà kan jáde. Àpẹẹrẹ kan ni ti àmì ìsọfúnni kan tí ń wí fún ọ pé ìlàjì iye owó tí ẹja jẹ́ ni a ń tà á nísinsìnyí. Ọ̀nà mìíràn tí wọ́n máa ń gbà ṣe é ni láti sọ ohun tí ó lè yíni lérò padà. Irú ìpolówó ọjà báyìí lè ṣàlàyé pé, kì í ṣe pé ẹja tí a ń tà ní ìlàjì iye owó rẹ̀ yóò dín owó tí ìwọ yóò ná kù nìkan ni, àmọ́, yóò dùn lẹ́nu rẹ, yóò sì ṣe ara ìwọ àti ìdílé rẹ lóore.

Wọ́n ṣètò àwọn ìpolówó ọjà mìíràn láti sọ nípa ìmọ̀lára wa. Fún àpẹẹrẹ, àwọn ìpolówó ọjà tí ń wọni lára máa ń fani mọ́ra nípa síso àwòrán gbígbádùnmọ́ni mọ́ ọjà náà. Àwọn tí ń ṣe èròjà ìṣaralóge, sìgá, àti ọtí máa ń lo ọ̀nà ìyọsíni yìí gan-an. Àwọn ìpolówó ọjà mìíràn máa ń lo àsọtúnsọ. Ọ̀nà ìtajà aláṣejù yìí ni a gbé karí ìrètí náà pé bí àwọn ènìyàn bá gbọ́ ìpolówó ọjà kan lọ́pọ̀ ìgbà, wọn óò gbà á gbọ́, wọ́n óò sì máa ra ọjà náà, bí wọ́n bá tilẹ̀ kórìíra ìpolówó ọjà náà! Ìdí nìyí tí a fi sábà máa ń rí i tí àwọn ìpolówó ọjà máa ń dámọ̀ràn ọjà kan náà léraléra. Àwọn ilé iṣẹ́ tí ń ṣe oògùn tí dókítà kò kọ fúnni sábà máa ń ṣe èyí.

Bákan náà ni àwọn ìpolówó ọjà tí ń pàṣẹ fúnni máa ń fa ìmọ̀lára wa mọ́ra. Àwọn ìpolówó ọjà wọ̀nyí ń wí fún wa tààràtà pé kí a ṣe ohun kan: “Mu kinní yìí!” “Rà á nísinsìnyí!” A ronú pé àwọn ìpolówó ọjà tí ń pàṣẹ fúnni máa ń ṣiṣẹ́ dáradára fún àwọn ọjà tí àwọn ènìyàn ti mọ̀ tẹ́lẹ̀, tí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ sí. Ọ̀pọ̀ àwọn ìpolówó ọjà ló tún wà lára ìsọ̀rí mìíràn. Ìwọ̀nyí ni àgbélẹ̀rọ, tàbí èyí tí a fi ń jẹ́rìí ìjójúlówó ọjà. Àwọn ọjà wọ̀nyí ń ṣàgbéyọ àwọn olókìkí tàbí àwọn tí ìrísí wọ́n ń fani mọ́ra, tí ń lo ọjà tí olùpolówó ọjà ń fẹ́ kí a rà tàbí kí ó máa júwe rẹ̀ fún wa. A gbé irú ìfanimọ́ra yìí karí èrò náà pé a fẹ́ láti dà bí àwọn ènìyàn tí a gba tiwọn. Ẹni tí ń da màlúù tí ń mu sìgá jẹ́ àpẹẹrẹ irú ìpolówó ọjà yìí.

Àwọn Ìpolówó Ọjà Tí Ń Gbani Lọ́kàn

Ǹjẹ́ o ti ṣàkíyèsí pé irú òórùn tàbí ariwo kan tí o máa ń gbọ́ ní gbogbo ìgbà lè ti bá ọ lára mu débi pé agbára káká ni ìwọ yóò fi ṣàkíyèsí rẹ̀? Ohun kan náà ní ń ṣẹlẹ̀ nínú ìpolówó ọjà.

Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn Business Week ti sọ, ọmọ ilẹ̀ Amẹ́ríkà kan tí a lè mú bí àpẹẹrẹ le wo nǹkan bí 3,000 ìpolówó ọjà lójúmọ́. Báwo ni àwọn ènìyàn ṣe ń hùwà padà? Wọn kì í fọkàn sí i, wọ́n sì lè yíjú síbòmíràn. Ọ̀pọ̀ ènìyàn wulẹ̀ ń fún ìpolówó ọjà ní àfiyèsí díẹ̀ lásán ni.

Láti borí ẹ̀mí ìdágunlá àwọn òǹwòran, àwọn ìpolówó ọjà gbọ́dọ̀ gba àfiyèsí wa. Àwọn ìpolówó ọjà orí tẹlifíṣọ̀n máa ń fi àwọn àwòrán kíkàmàmà hàn. Wọ́n máa ń gbìyànjú láti dáni lára yá, láti gbàfiyèsí, láti pani lẹ́rìn-ín láti rúni lójú, tàbí ru ìmọ̀lára ẹni sókè. Wọ́n máa ń fi àwọn gbajúgbajà àti àwọn àwòrán àfiṣènìyàn tí ó gbádùn mọ́ni hàn. Ọ̀pọ̀ ń lo èrò ìmọ̀lára láti gba àfiyèsí wa, bóyá nípa dídarí àfiyèsí sí ológbò, ọmọ ajá, tàbí ìkókó.

Gbàrà tí olùpolówó ọjà náà bá ti gba àfiyèsí wa, ó gbọ́dọ̀ gbá ọkàn-ìfẹ́ wa mú tó láti mú kí a mọ̀ nípa ọjà tí wọ́n ń polówó. Àwọn ìpolówó ọjà tí ó kẹ́sẹ járí kì í dáni lára yá lásán; wọ́n máa ń gbìyànjú láti sọ̀rọ̀ tí yóò mú kí a rà á.

Ní ṣókí, bí ìpolówó ọjà ṣe ń ṣiṣẹ́ nìyẹn. Wàyí o, a óò gbé agbára tí ó ní yẹ̀ wò.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 14]

Ọmọ ilẹ̀ Amẹ́ríkà kan tí a lè mú bí àpẹẹrẹ le wo nǹkan bí 3,000 ìpolówó ọjà lójúmọ́

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 13]

Àwọn Tí Kò Fẹ́ Gbọ́ Ìpolówó Ọjà

Ìhùmọ̀ ìdarí tẹlifíṣọ̀n jẹ́ ohun tí a fi ń bá ìpolówó ọjà jà. Ọ̀pọ̀ ènìyàn ló máa ń tẹ ohun tí ń mú ohùn tẹlifíṣọ̀n lọ, kí wọ́n má bàa gbọ́ ìpolówó ọjà tí ń lọ lọ́wọ́. Àwọn mìíràn máa ń gba eré sílẹ̀ sínú kásẹ́ẹ̀tì fídíò, tí wọ́n bá sì fẹ́ tún un wò, wọ́n máa ń fo àwọn ìpolówó ọjà nípa títẹ ohun tí ń mú kí ẹ̀rọ sáré fo ibi tí ìpolówó ọjà wà. Àwọn mìíràn sì máa ń yí tẹlifíṣọ̀n wọn sí àwọn ìkànnì mìíràn láìdáwọ́dúró kí wọ́n má bàa wo àwọn ìpolówó ọjà. Àwọn tí wọ́n já fáfá nínú yíyí tẹlifíṣọ̀n káàkiri ìkànnì mọ iye ìṣẹ́jú tí wọ́n fi máa ń ṣe ìpolówó ọjà kan, tí ìpolówó ọjà náà bá sì tán, wọn óò yí i padà síbẹ̀ láti máa wo eré tí wọ́n ń wò tẹ́lẹ̀ lọ.

Àwọn olùpolówó ọjà ń gbìyànjú láti máa polówó ọjà lọ́nà tí àwọn ènìyàn kò ní máà fẹ́ gbọ́ ọ nípa gbígbé àwọn ìpolówó ọjà tí ó ní agbára láti mú kí ó wuni láti gbọ́—àwọn tí ń fa ọkàn-ìfẹ́ òǹwòran mọ́ra lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, tí kò sì ní ṣàìfẹ́ gbọ́ ọ. Ìdẹkùn gbígbé àwọn ìpolówó ọjà tí ó pinminrin jáde ni pé àwọn ènìyàn lè rántí ìpolówó ọjà náà àmọ́ wọn kò ní rántí ọjà tí a ń polówó.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 14]

Ìpolówó Ọjà Tí Kò Kún Rẹ́rẹ́

Ní apá ìparí àwọn ọdún 1950, James Vicary sọ pé òún ṣe ìwádìí kan ní ilé sinimá kan ní New Jersey, U.S.A., níbi tí a ti gbé ọ̀rọ̀ náà “Máa Mu Coca-Cola” àti “Máa Jẹ Gbúgbúrú” yọ lára ògiri ìwòran nígbà tí sinimá ń lọ lọ́wọ́. Àkókò tí ìpolówó ọjà náà fi fara hàn kò tó ìṣẹ́jú àáyá kan, àkókò náà kéré gan-an débi tí kò lè tẹ ohunkóhun mọ́ ẹni tí ó wò ó lọ́kàn. Síbẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Vicary ṣe sọ, wọ́n mú kí Coca-Cola àti gbúgbúrú túbọ̀ tà. Ohun tí ó sọ yìí mú kí àwọn ènìyàn níbi gbogbo gbà gbọ́ pé àwọn olùpolówó ọjà lè sún àwọn ènìyàn ra nǹkan nípa gbígbé àwọn ìpolówó ọjà “tí a kò rí” yọ lára ibi tí wọ́n ti ń wo sinimá. Ìròyìn fi hàn pé, lẹ́yìn tí Ọ̀gbẹ́ni Vicary fọwọ́ sí àdéhùn mílíọ̀nù 4.5 dọ́là pẹ̀lú àwọn olùpolówó ọjà tí ó tóbi jù lọ ní Amẹ́ríkà, ńṣe ni ó pòórá pátápátá. Gbájú-ẹ̀ ni ó lò fún àwọn olùpolówó ọjà náà.

Ìwádìí tí wọ́n ṣe lẹ́yìn náà fi irọ́ tí ó wà nínú ohun tí Vicary sọ hàn. Ọ̀gá kan tí ó ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìpolówó ọjà sọ pé: “Ìpolówó ọjà tí kò kún rẹ́rẹ́ kì í kẹ́sẹ járí. Bí ó bá ń kẹ́sẹ járí ni, à bá ti lò ó.”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Wọ́n ń gbé àwọn ìpolówó ọjà kalẹ̀ lọ́nà tí yóò fi gba àfiyèsí wa

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́