Pípa Ara Ẹni—Ìṣòro Wíwọ́pọ̀ Láàárín Àwọn Ọ̀dọ́
BÍ PÉ ogun, ìpànìyàn, àti ìwà ìkà búburú tó wà kò tó láti sọ àwọn ọ̀dọ́ wa di aláìnírètí, ìpara-ẹni-run kan tún kárí ayé nísinsìnyí, ní ti àwọn ọ̀dọ́ tí ń pa ara wọn. Oògùn olóró àti ìmutípara ń ba ọkàn àti ara àwọn èwe jẹ́, ó sì ń mú kí ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ kú. Àkọlé ara sàréè tí ń wọ́pọ̀ sí i ni pé àlòjù oògùn, bóyá tí òkú náà mọ̀ọ́mọ̀ lò tàbí tí ó ṣèèṣì lò, ló pa á.
Ìwé ìròyìn Morbidity and Mortality Weekly Report fún April 28, 1995, sọ pé, “pípa ara ẹni ló gba ipò kẹta nínú àwọn ohun tí ń pa àwọn ọ̀dọ́langba ọlọ́dún 15 sí 19 ní United States.” Dókítà J. J. Mann kọ̀wé nínú ìwé The Decade of the Brain pé: “Ó lé ní 30,000 [iye náà jẹ́ 31,284 ní 1995] ará Amẹ́ríkà tí ń pa ara rẹ̀ lọ́dọọdún. Lọ́nà tó bani nínú jẹ́, àwọn èwe ló sábà ń ṣẹlẹ̀ sí . . . Iye tó fi ìlọ́po mẹ́wàá ju 30,000 yẹn lọ ló ń gbìdánwò láti pa ara wọn, ṣùgbọ́n tí wọ́n ń là á já. . . . Ìṣòro kíkàmàmà tí ń kojú ètò ìṣègùn ni bí a ṣe lè dá àwọn tó wà nínú ewu pípa ara ẹni mọ̀, nítorí pé kò rọrùn fún àwọn oníṣègùn láti mọ àwọn aláìsàn tó ní ìsoríkọ́ gidigidi débi tí wọn yóò gbìyànjú láti pa ara wọn yàtọ̀ sí àwọn tí kò ní ṣe bẹ́ẹ̀.”
Simon Sobo, ọ̀gá ẹ̀ka ìtọ́jú àrùn ọpọlọ ní Ilé Ìwòsàn New Milford, Connecticut, U.S.A., sọ pé: “Àwọn ìgbìdánwò láti pa ara ẹni tí ó ṣẹlẹ̀ nígbà ìrúwé yìí [1995] pọ̀ ju gbogbo èyí tí mo ti rí láàárín ọdún 13 tí mo ti wà níbí lọ.” Ní United States, ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọ̀dọ́langba ló ń gbìdánwò láti pa ara wọn lọ́dọọdún. Ìgbìdánwò kọ̀ọ̀kan jẹ́ kíké gbàjarè fún ìrànlọ́wọ́ àti àfiyèsí. Ta ni yóò ṣèrànwọ́ kó tó pẹ́ jù?
Ìṣòro Tó Kárí Ayé
Ipò náà kò fi bẹ́ẹ̀ yàtọ̀ ní ibi púpọ̀ lágbàáyé. Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn India Today ṣe wí, nǹkan bí 30,000 ọ̀dọ́ ló pa ara wọn ní Íńdíà lọ́dún 1990. Ní Kánádà, Finland, ilẹ̀ Faransé, Ísírẹ́lì, ilẹ̀ Netherlands, New Zealand, Sípéènì, Switzerland, àti Thailand, iye àwọn ọ̀dọ́ tí ń pa ara wọn ti pọ̀ sí i. Ìròyìn kan tí Àjọ Àkànlò Owó Ti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè fún Àwọn Ọmọdé (UNICEF) gbé jáde fún ọdún 1996 sọ pé ní Finland, Latvia, Lithuania, New Zealand, Rọ́ṣíà, àti Slovenia ni àwọn ọ̀dọ́ ti ń pa ara wọn jù.
Ọ̀kan lára àwọn ibi tí àwọn ọ̀dọ́ ti ń pa ara wọn jù lágbàáyé ni Ọsirélíà. Bí ìwé ìròyìn The Canberra Times ṣe wí, ní 1995, ìpín 25 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọ̀dọ́kùnrin tó kú, àti ìpín 17 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọ̀dọ́bìnrin tó kú ní orílẹ̀-èdè yìí, ló pa ara wọn. Iye àwọn ọmọkùnrin ilẹ̀ Ọsirélíà tó “kẹ́sẹ járí” ní pípa ara wọn fi nǹkan bí ìlọ́po márùn-ún pọ̀ ju ti àwọn ọmọbìnrin lọ. Ìpíndọ́gba tó jọra wà ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè.
Ṣe èyí túmọ̀ sí pé ó wọ́pọ̀ kí àwọn ọmọkùnrin gbìyànjú láti pa ara wọn ju àwọn ọmọbìnrin lọ ni? Dandan kọ́. Àwọn ìsọfúnni oníṣirò tó wà lárọ̀ọ́wọ́tó fi hàn pé kò fi bẹ́ẹ̀ sí ìyàtọ̀ láàárín bí àwọn ẹ̀yà méjèèjì ṣe ń gbìyànjú láti pa ara wọn tó. Bí ó ti wù kí ó rí, “gẹ́gẹ́ bí iye tí àjọ WHO [Àjọ Ìlera Àgbáyé] gbe jáde kẹ́yìn ṣe fi hàn, nǹkan bí ìlọ́po mẹ́rin iye àwọn ọ̀dọ́bìnrin tí ń pa ara wọn ni iye àwọn ọ̀dọ́kùnrin tí ń pa ara wọn.”—The Progress of Nations, tí Àjọ UNICEF gbé jáde.
Àmọ́ àkọsílẹ̀ oníṣirò bíbanilẹ́rù wọ̀nyí pàápàá lè ṣàìfi bí ìṣòro náà ṣe tó hàn. Àwọn ìsọfúnni oníṣirò tí a fi èdè ìṣègùn àti alálàyé kọ nípa àwọn èwe tí ń pa ara wọn dùn kà gan-an. Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ohun tí ìsọfúnni oníṣirò kọ̀ọ̀kan tí kò kanni kì í gbé jáde ni àwọn ìdílé tí ń fọ́ yángá àti ìbànújẹ́, ìsoríkọ́, ìrora, àti àìnírètí tí àwọn tó kù ń ní bí wọ́n ṣe ń ronú lórí ìdí tó fi ṣẹlẹ̀.
Nítorí náà, ǹjẹ́ a lè ṣèdíwọ́ fún àwọn ọ̀ràn ìbànújẹ́ bí ti àwọn ọ̀dọ́ tí ń pa ara wọn? A ti dá àwọn kókó pàtàkì kan mọ̀, wọ́n sì lè wúlò fún dídènà ipò ìbànújẹ́ yìí.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 5]
Àwọn Ohun Tí Ń Múni Pa Ara Ẹni
Ọ̀pọ̀ àbá ló ti wà nípa àwọn ohun tí ń múni pa ara ẹni. “Pípa ara ẹni jẹ́ àbáyọrí ìhùwà ẹnì kan sí ìṣòro tó jọ pé kò ṣeé yanjú, bí èrò àìbẹ́gbẹ́mu, ikú olólùfẹ́ kan (ní pàtàkì, ọkọ tàbí aya), ìdílé tó tú ka nígbà tí a wà lọ́mọdé, àìsàn lílekoko, dídarúgbó, àìríṣẹ́ṣe, àìlówólọ́wọ́, àti ìjoògùnyó.”—The American Medical Association Encyclopedia of Medicine.
Gẹ́gẹ́ bí onímọ̀ ìbágbépọ̀ ẹ̀dá, Emile Durkheim, ṣe wí, oríṣi pípa ara ẹni mẹ́rin pàtàkì ló wà:
1. Elérò àdáṣe—Èyí “ni a rò pé ó ń ṣẹlẹ̀ nítorí pé ẹnì kan kò lè bá àwùjọ ṣe. Nítorí tí wọ́n ń dá wà, àwọn tí ń pa ara wọn báyìí kì í bá àwùjọ ṣe, wọn kì í sì í gbára lé àwùjọ.” Wọ́n máa ń nìkan ṣe gbogbo nǹkan.
2. Ajàfáwùjọ—“Irú ẹni yìí máa ń fara mọ́ àwùjọ jù débi tí ó fi ń rò pé kò sí ohun tí ó yẹ kí òun má lè pàdánù.” Àwọn àpẹẹrẹ tí a fúnni ni ti àwọn ológun òfuurufú ilẹ̀ Japan nígbà Ogun Àgbáyé Kejì àti àwọn agbawèrèmẹ́sìn tí wọ́n ṣe tán láti pa ara wọn nígbà tí wọ́n ba ń pa àwọn tí wọ́n kà sí alátakò wọn. Àwọn àpẹẹrẹ mìíràn ni ti àwọn tí wọ́n kú nípa ìmọ̀ọ́mọ̀-fara-ẹni-rúbọ láti pàfiyèsí sí ọ̀ràn kan tí wọ́n kà sí pàtàkì.
3. Aláìronújinlẹ̀—“Ẹni tó pa ara rẹ̀ ní ọ̀nà àìronújinlẹ̀ ni ẹni tí kò lè kojú ipò ìṣòro lọ́nà onírònú, tó sì yàn láti pa ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ojútùú ìṣòro kan. [Èyí] ń ṣẹlẹ̀ nígbà tí àjọṣe inú àwùjọ tí onítọ̀hún ti fi kọ́ra tẹ́lẹ̀ bá yí padà lójijì, lọ́nà tí ń gboni jìgìjìgì.”
4. Aláròpin—Èyí ni “a rò pé àpọ̀jù ìlànà tí àwùjọ gbé kalẹ̀, tó pààlà sí òmìnira ẹnì kan ní gidi, ń fà.” Irú àwọn tí ń pa ara wọn báyìí “rò pé kò sí ìrètí pé ọjọ́ ọ̀la lè dára fún àwọn.”—Adolescent Suicide: Assessment and Intervention, láti ọwọ́ Alan L. Berman àti David A. Jobes.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Díẹ̀ lára àwọn ìwà eléwu tó lè yọrí sí kí ọ̀dọ́ pa ara rẹ̀