Kò Kólòlò Mọ́!
Ó FẸ́RẸ̀Ẹ́ tó ọgọ́rin ọdún tí Jí! ti ń ran àwọn tí ń kà á lọ́wọ́ láti kojú àwọn ìṣòro tí ń jẹ yọ lójoojúmọ́. Nígbà mìíràn, ó ń jẹ́ kí wọ́n mọ̀ nípa àwọn ìgbésẹ̀ tuntun àti ìhùwà tuntun nínú ìlànà ìṣègùn, tó lè kan ìgbésí ayé wọn gbọ̀ngbọ̀n, bí ìṣẹ̀lẹ̀ tí ẹ ó kà nísinsìnyí ṣe fi hàn.
Wọ́n bí Matthew ní 1989 ní àríwá England. Kò sí ohun tó ṣàjèjì nípa rẹ̀ títí tí ó fi pé ọmọ ọdún méjì. Lójijì, nígbà tó wà nísinmi, ó bẹ̀rẹ̀ sí kólòlò gan-an.
Ìyá rẹ̀, Margaret, sọ pé: “Èmi àti ọkọ mi kàn sí ẹ̀ka ìtọ́jú àrùn àìlèsọ̀rọ̀-jágaara tó wà ládùúgbò wa, wọ́n sì sọ fún wa pé kò sí ohun tí àwọn lè ṣe ṣáájú ìgbà tó bá di ọmọ ọdún méje, nítorí pé àwọn ọmọdé ń dàgbà tó bẹ́ẹ̀ kí wọ́n tó lè dá ṣàkóso tán-án-ná wọn. Àmọ́ nígbà tí Matthew bẹ̀rẹ̀ sí lọ sílé ìwé, kò rọrùn fún un láti kojú bí àwọn ọmọ mìíràn ṣe ń fi ṣẹ̀sín, ìkólòlò rẹ̀ sì burú sí i. Kì í fẹ́ wà láàárín àwùjọ, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí wà láìbẹ́gbẹ́ṣe. Kódà, lílọ sí àwọn ìpàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba di ìṣòro fún un.
“Nígbà náà ni a rí àpilẹ̀kọ ‘Ìrètí fún Àwọn Akólòlò,’ nínú ẹ̀ka ‘Wíwo Ayé,’ nínú ìtẹ̀jáde Jí! ti April 8, 1995. Ó ṣàlàyé ṣókí nípa iṣẹ́ tí àwùjọ àwọn oníṣègùn àìlèsọ̀rọ̀-jágaara kan, tí wọ́n ti kẹ́sẹ járí nídìí wíwo àwọn ọmọdé tí ń kólòlò sàn, ṣe ní Sydney, Ọsirélíà.
“A kọ̀wé sí Yunifásítì Sydney, a sì gba èsì tó fi ìgbatẹnirò han láti ọ̀dọ̀ Dókítà Mark Onslow, tó sọ pé ká kàn sí òun lórí tẹlifóònù. Nítorí pé ìkángun kejì ayé sí àwùjọ àwọn oníṣègùn àìlèsọ̀rọ̀-jágaara tí ń bá a ṣiṣẹ́ la ń gbé, wọ́n gbìyànjú láti dán ‘ìlànà ìṣètọ́jú láti ọ̀nà jíjìn’ wò. Wọ́n lo tẹlifóònù, ẹ̀rọ aṣàdàkọ ìsọfúnni, àti kásẹ́ẹ̀tì ìgbohùnsílẹ̀ láti kọ́ àwa, tí a jẹ́ òbí Matthew, ní ọ̀nà tí àwùjọ náà gbà ń ṣèwòsàn. Wọ́n mú ọ̀nà ìṣèwòsàn náà bá àwọn ipò ti Matthew fúnra rẹ̀ mu. Mo máa ń jókòó tì í, mo sì máa ń ràn án lọ́wọ́ ní tààrà láti pe àwọn ọ̀rọ̀ tí ń kọ́ ọ lẹ́nu dáadáa, lọ́nà tó tura, tí a kò sì ṣètò àrà ọ̀tọ̀ fún. Mo máa ń yìn ín gan-an, mo sì máa ń fún un lẹ́bùn nígbà tó bá sọ̀rọ̀ tó ‘já gaara.’
“Lóṣù mẹ́fà sí i, Matthew ti ń bẹ́gbẹ́ ṣe, kì í dá ṣe lóun nìkan mọ́, ó ti di ọ̀dọ́ tó láyọ̀, tí kò sì yàtọ̀ sí àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀. Ní báyìí, ó ń dáhùn ní àwọn ìpàdé ìjọ, ó sì ń gbádùn kíka Bíbélì ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Ó tún ń kópa dáradára nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ ilé dé ilé. Ó ń sọ̀rọ̀ bó ti yẹ gan-an!
“Ìsọfúnni ìròyìn kékeré, tí Jí! gbé jáde, tó sì ti yí ìgbésí ayé ọmọ wa padà yẹn mà dùn mọ́ wa gan-an ò!”—A kọ ọ́ ránṣẹ́.