Ìgbà Tí Gbogbo Ènìyàn Yóò Nífẹ̀ẹ́ Ara Wọn
NÍNÚ Ìwàásù Jésù Kristi Lórí Òkè, ó sọ nípa ìgbà tí gbogbo ènìyàn yóò nífẹ̀ẹ́ ara wọn. Nínú ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ Jésù, ó fa ọ̀rọ̀ tó wà nínú Sáàmù kẹtàdínlógójì yọ pé: “Ìbùkún ni fún àwọn onínú tútù: nítorí pé wọn óò jogún ilẹ̀ ayé.” Ìwé Sáàmù yẹn tún ṣàpèjúwe bí ipò àgbàyanu yìí yóò ṣe ní ìmúṣẹ, ó wí pé: “A óò ké àwọn aṣebi kúrò; ṣùgbọ́n àwọn tí wọ́n dúró de Jèhófà yóò jogún ilẹ̀ náà.”—Mátíù 5:5; Sáàmù 37:9; American Standard Version.
Ìyípadà ńlá gbáà lèyí yóò jẹ́—kí a mú gbogbo àwọn aṣebi kúrò lórí ilẹ̀ ayé, kí ó wá ṣẹ́ ku kìkì àwọn ènìyàn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ ara wọn! Báwo nìyẹn ṣe lè ṣẹlẹ̀? Jésù fi bí yóò ṣe ṣẹlẹ̀ hàn nínú ìwàásù rẹ̀ nígbà tí ó kọ́ wa bí a óò ṣe máa gbàdúrà pé: “Kí ìjọba rẹ dé. Ìfẹ́ tìrẹ ni kí a ṣe, bí ti ọ̀run, bẹ́ẹ̀ ni ní ilẹ̀ ayé.” (Mátíù 6:10, AS) Kíyè sí ibi tí a óò ti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Kì í ṣe ní ọ̀run nìkan. Àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé ìròyìn The Christian Century tẹnu mọ́ ọn pé: “A gbàdúrà pé, ìfẹ́ tìrẹ ni kí a ṣe ní ayé, bí wọ́n ti ń ṣe ní ọ̀run.”
Nígbà náà, kí ni Ìjọba Ọlọ́run tí Jésù kọ́ wa láti máa gbàdúrà fún? Ní kedere, ó jẹ́ ìjọba gidi kan, èyí tí ń ṣàkóso láti ọ̀run. Ìdí nìyẹn tí a ṣe pè é ní “ìjọba ọ̀run.” (Mátíù 10:7) Ọmọ Ọlọ́run, Jésù Kristi, ni a yàn sípò bí Olùṣàkóso Ìjọba náà.
Tipẹ́tipẹ́ ṣáájú kí Màríà tó bí Jésù, wòlíì Jèhófà náà, Aísáyà, sọ tẹ́lẹ̀ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ ìyanu náà àti ohun tí yóò wá ṣẹlẹ̀ níkẹyìn pé: “A ti bí ọmọ kan fún wa, a ti fi ọmọkùnrin kan fún wa; ìjọba yóò sì wà ní èjìká rẹ̀: a óò sì pe orúkọ rẹ̀ ní Ìyanu Olùdámọ̀ràn, Ọlọ́run Alágbára, Baba Ayérayé, Ọmọ Aládé Àlàáfíà. Ọ̀pọ̀ yanturu ìṣàkóso rẹ̀ àti àlàáfíà kì yóò lópin.” (Aísáyà 9:6, 7, AS) Lẹ́yìn tí Jésù kú, tí ó sì jíǹde, ó jókòó ti Bàbá rẹ̀ ní ọ̀run, ó ń dúró de ìgbà tí a óò fún un láṣẹ láti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso bí Ọba.—Sáàmù 110:1, 2; Hébérù 10:12, 13; Ìṣípayá 11:15.
Kí ni yóò wá ṣẹlẹ̀ sí ayé tí ó kún fún ìkórìíra yìí? Kíyè sí bí Bíbélì ṣe dáhùn ìbéèrè yẹn. Wòlíì Ọlọ́run náà, Dáníẹ́lì, sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Ní ọjọ́ àwọn ọba wọ̀nyẹn, Ọlọ́run ọ̀run yóò gbé ìjọba kan kalẹ̀ èyí tí a kì yóò run láé. Ìjọba náà ni a kì yóò sì gbé fún àwọn ènìyàn èyíkéyìí mìíràn. Yóò fọ́ ìjọba wọ̀nyí túútúú, yóò sì fi òpin sí gbogbo wọn, òun fúnra rẹ̀ yóò sì dúró fún àkókò tí ó lọ kánrin.”—Dáníẹ́lì 2:44.
Ó ṣe kedere pé àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì yìí ń tọ́ka sí ìyípadà ńlá kan nínú àlámọ̀rí ènìyàn. Odindi ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan yìí, tí ó ní àwọn ènìyàn ìran yìí nínú, tí wọ́n fi orí kunkun kọ̀ láti tẹrí ba fún ìṣàkóso Ọlọ́run, ni a óò mú kúrò lórí ilẹ̀ ayé! Wo ohun tí yóò rọ́pò rẹ̀.
Ìgbésí Ayé Nínú Ayé Tuntun Òdodo
Nígbà tí ayé ògbólógbòó yìí bá wá sí òpin rẹ̀, àwọn kan yóò là á já. Bíbélì ṣàlàyé pé: “Ayé ń kọjá lọ, bẹ́ẹ̀ sì ni ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni yóò dúró títí láé.” (1 Jòhánù 2:17) Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn tí wọ́n bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run yóò là á já sínú ayé tuntun kan, gẹ́gẹ́ bí Nóà àti ìdílé rẹ̀ ṣe la òpin ayé àkókò wọn já. Àpọ́sítélì Pétérù kọ̀wé pé: “Àwọn ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun wà tí a ń dúró dè ní ìbámu pẹ̀lú ìlérí [Ọlọ́run], nínú ìwọ̀nyí ni òdodo yóò sì máa gbé.”—2 Pétérù 3:5-7, 11-13.
Ní ti àkókò tí Ìjọba Ọlọ́run nìkan yóò máa ṣàkóso, Bíbélì ṣèlérí pé: “Àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.” (Sáàmù 37:29) Àwọn olódodo yóò gbádùn ìwàláàyè ní ilẹ̀ ayé tí a ti fọ̀ mọ́. Àkókò ológo gbáà ni ìgbà yẹn yóò jẹ́! Bí o kò bá tíì ṣàyẹ̀wò àwọn ìbùkún tí a ṣàpèjúwe nínú Bíbélì, tí a fi àwòrán ṣàpèjúwe rẹ̀ ní ojú ewé tí ó ṣáájú èyí, jọ̀wọ́ ṣe bẹ́ẹ̀.
Inú rẹ ha dùn láti mọ̀ pé Ẹlẹ́dàá wa ṣèlérí irú ohun àgbàyanu bẹ́ẹ̀ fún àǹfààní àwọn tí ń sìn ín bí? Dájúdájú, ète Ọlọ́run nìyẹn nígbà tí ó dá tọkọtaya àkọ́kọ́, tí ó sì fi wọ́n sínú Párádísè ilẹ̀ ayé! Kíyè sí ohun tí Ọlọ́run wí fún wọn: “Ẹ máa so èso, kí ẹ sì di púpọ̀, kí ẹ sì kún ilẹ̀ ayé, kí ẹ sì ṣèkáwọ́ rẹ̀, kí ẹ sì máa jọba lórí ẹja òkun àti àwọn ẹ̀dá tí ń fò ní ojú ọ̀run àti olúkúlùkù ẹ̀dá alààyè tí ń rìn lórí ilẹ̀ ayé.”—Jẹ́nẹ́sísì 1:27, 28.
Ádámù àti Éfà yóò bímọ, bí àwọn ọmọ wọn bá sì ṣe ń dàgbà, wọn óò nípìn-ín nínú iṣẹ́ gbígbádùnmọ́ni ti bíbójútó Párádísè ilẹ̀ ayé. Ronú nípa ayọ̀ tí ó wà nínú mímú kí ọgbà Édẹ́nì gbòòrò sí i bí ìdílé ènìyàn ṣe ń pọ̀ sí i! Ó ṣe kedere pé, ète Ọlọ́run ni pé kí gbogbo ilẹ̀ ayé di Párádísè. Ète yẹn yóò ha ní ìmúṣẹ láé bí? Dájúdájú yóò ní ìmúṣẹ, nítorí Ọlọ́run ló sọ ọ́! Ó ṣèlérí pé: “Mo ti sọ ọ́; . . . Èmi yóò ṣe é pẹ̀lú.”—Aísáyà 46:11; 55:11.
Ìwọ yóò ha fẹ́ láti gbádùn gbígbé títí láé nínú Párádísè ilẹ̀ ayé tí a ṣàpèjúwe nínú Ìwé Mímọ́, bí a ṣe fi àwòrán ṣàpèjúwe rẹ̀ ní ojú ewé tí ó ṣáájú èyí bí? Bí a ṣe lè retí rẹ̀, kì í ṣe gbogbo ènìyàn ni a óò gbà láyè láti gbé ibẹ̀ títí láé. Àwọn ohun kan wà tí a béèrè. Kí ni àwọn ohun náà?
Títóótun Láti Wà Láàyè Títí Láé
Lákọ̀ọ́kọ́, àwọn tí yóò gbé inú ayé tuntun Ọlọ́run gbọ́dọ̀ kọ́ láti nífẹ̀ẹ́ ara wọn, gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ṣe kọ́ wa láti ṣe. Bíbélì sọ pé: “Ọlọ́run ti kọ́ ẹ̀yin fúnra yín láti nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́nì kìíní-kejì.” (1 Tẹsalóníkà 4:9) Báwo ni Ọlọ́run ṣe ń kọ́ wa ní èyí?
Ní pàtàkì, ó jẹ́ nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí a kọ sílẹ̀, Bíbélì. Èyí túmọ̀ sí pé láti wà láàyè títí láé, a gbọ́dọ̀ tẹ́wọ́ gba àwọn ẹ̀kọ́ Ọlọ́run tí ó wà nínú Bíbélì. Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan ní Ìlà Oòrùn Ayé sọ pé: “Mo ń wọ̀nà fún ìgbà tí Bíbélì ṣèlérí pé, gbogbo ènìyàn yóò nífẹ̀ẹ́ ara wọn.”
Nínú àdúrà tí Jésù gbà sí Bàbá rẹ̀, ó tọ́ka sí ohun pàtàkì kan tí a ń béèrè fún. Ó wí pé: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú, àti ti ẹni tí ìwọ rán jáde, Jésù Kristi.” (Jòhánù 17:3) Ìwé pẹlẹbẹ olójú-ewé 32 náà, Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa?, yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti gba ìmọ̀ yìí. Bí o bá fẹ́ ìsọfúnni nípa bí o ṣe lè rí ẹ̀dà kan gbà, kọ̀wé kún fọ́ọ̀mù tó wà lójú ìwé 32, kí o sì fi ránṣẹ́ sí Watch Tower, P.M.B. 1090, Benin City, Edo State, Nigeria, tàbí sí àdírẹ́sì tí ó yẹ lójú ìwé 5.
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22-24]
Àwọn Ohun Tí Ọlọ́run Ṣèlérí
Ẹgbẹ́ Àwọn Ará Onífẹ̀ẹ́ Jákèjádò Ayé
“Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú, ṣùgbọ́n ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, tí ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún un.”—Ìṣe 10:34, 35.
Ìwà Ọ̀daràn Tàbí Ogun Kò Sí Mọ́
“Ní ti àwọn ẹni burúkú, a óò ké wọn kúrò lórí ilẹ̀ ayé gan-an.”—Òwe 2:22.
“[Ọlọ́run] mú kí ogun kásẹ̀ nílẹ̀ títí dé ìkángun ilẹ̀ ayé.”—Sáàmù 46:9.
Oúnjẹ Àtàtà Tó Pọ̀ Rẹpẹtẹ
“Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ọkà yóò wá wà lórí ilẹ̀; àkúnwọ́sílẹ̀ yóò wà ní orí àwọn òkè ńlá.”—Sáàmù 72:16.
Àlàáfíà Láàárín Àwọn Ènìyàn àti Ẹranko
“Ìkookò yóò sì máa gbé ní ti tòótọ́ fún ìgbà díẹ̀ pẹ̀lú akọ ọ̀dọ́ àgùntàn, àmọ̀tẹ́kùn pàápàá yóò sì dùbúlẹ̀ ti ọmọ ewúrẹ́, . . . àní ọmọdékùnrin kékeré ni yóò sì máa dà wọ́n.”—Aísáyà 11:6.
A Mú Àìsàn, Ọjọ́ Ogbó, àti Ikú Kúrò
“[Ọlọ́run] yóò . . . nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.”—Ìṣípayá 21:4.
Jíjí Àwọn Olùfẹ́ Tí Wọ́n Ti Kú Dìde Sórí Ilẹ̀ Ayé
“Wákàtí náà ń bọ̀, nínú èyí tí gbogbo àwọn tí wọ́n wà nínú ibojì ìrántí yóò gbọ́ ohùn [Jésù] wọn yóò sì jáde wá.”—Jòhánù 5:28, 29.