ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g98 11/8 ojú ìwé 10-13
  • Báwo Là Bá Ti Ṣe é Láìsí Àwọn Afárá?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Báwo Là Bá Ti Ṣe é Láìsí Àwọn Afárá?
  • Jí!—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Afárá Àtijọ́
  • Àwọn Afárá àti Àwọn Àìní Wa Tí Ń Yí Padà
  • Àwọn Onírúurú Afárá
  • Kí Ni Mo Lè Ṣe Tí Mi Ò Fi Ní Máa Dá Wà?
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì
  • Wíwó Ògiri Palẹ̀ Láti Fi Kọ́ Afárá
    Jí!—1996
  • Ilé Tó Máa Mú Ìyìn Wá Bá Ọ
    “Fi Ayọ̀ Kọrin” sí Jèhófà
  • Ọjọ́ Lọjọ́ Tí Ilé Gogoro Méjì Wó Ní Amẹ́ríkà
    Jí!—2002
Jí!—1998
g98 11/8 ojú ìwé 10-13

Báwo Là Bá Ti Ṣe é Láìsí Àwọn Afárá?

“Yin afárá tí o gùn kọjá.”—George Colman, òǹkọ̀wé eré oníṣe, ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, ní ọ̀rúndún kọkàndínlógún.

ÌGBÀ wo lo gun afárá kọjá kẹ́yìn? Ǹjẹ́ o tilẹ̀ fiyè sí i? Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn ń gun afárá kọjá lójoojúmọ́. A kì í kà wọ́n sí. A ń rìn, a ń gun kẹ̀kẹ́ tàbí kí a wakọ̀ kọjá lórí wọn tàbí lábẹ́ wọn láìfọkàn sí i rárá. Àmọ́, bí wọn kò bá sí níbẹ̀ ńkọ́?

Láti ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún wá, àwọn ènìyàn àti ẹranko ti ń ré kọjá àwọn ibi tí ilẹ̀ ti ní àlàfo, ì báà jẹ́ odò, ọ̀gbun, tàbí àfonífojì tó da gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́, ọpẹ́lọpẹ́ onírúurú afárá. Ó ṣòro láti finú wo bí àwọn ìlú kan ì bá ti rí láìsí àwọn afárá—Cairo, London, Moscow, New York, Sydney, àti ọ̀pọ̀ àwọn mìíràn. Ní tòótọ́, àwọn afárá ti wà tipẹ́.

Àwọn Afárá Àtijọ́

Ní èyí tó ti lé ní 2,500 ọdún sẹ́yìn, Ayaba Nitocris ti ilẹ̀ Bábílónì tẹ́ afárá kan sórí Odò Yúfírétì. Èé ṣe? Òpìtàn ará Gíríìkì náà, Herodotus, sọ pé: “Odò náà pín [Bábílónì] sí ọ̀nà méjì gedegbe. Nígbà tí àwọn ọba ìṣáájú wà lórí oyè, bí ẹnì kan yóò bá ti ìhà kan kọjá sí ìhà kejì, àfi kó wọ ọkọ̀ àjẹ̀ kan; tó jọ pé, ó gbọ́dọ̀ ti jẹ́ ìṣòro gidi kan.” Nitocris fi igi gẹdú, bíríkì sísun, àti búlọ́ọ̀kù olókùúta bí ohun èlò ìkọ́lé, àti irin òun òjé bí àpòpọ̀ sìmẹ́ǹtì, tẹ́ afárá kan sórí ọ̀kan nínú àwọn odò tó lókìkí jù látijọ́.

Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àwọn afárá ti nípa lórí ohun tó ṣẹlẹ̀ nínú ìtàn. Nígbà tí Ọba Dáríúsì Ńlá ti Páṣíà gbéjà ko àwọn ará Síkítíánì, ó fẹ́ gba ọ̀nà orí ilẹ̀ tó yá jù láti Éṣíà dé Yúróòpù. Ìyẹn túmọ̀ sí kíkó ẹgbẹ́ ogun rẹ̀ tó ní 600,000 ọmọ ogun kọjá Ọrùn Omi Bosporus. Ó léwu láti wọ ọkọ̀ àjẹ̀ kọjá ọrùn omi náà nítorí ìrì ńlá àti ìgbì omi eléwu, nítorí náà, Dáríúsì fi okùn so àwọn ọkọ̀ àjẹ̀ pọ̀ títí wọ́n fi di afárá kan tó gùn ní ìwọ̀n 900 mítà. Lónìí, o kò ní láti ṣe wàhálà tó ti Dáríúsì kí o tó ré ọrùn omi náà kọjá. Bí o bá kọjá lórí afárá Bosporus ní Istanbul, Turkey, kò ní gba ìṣẹ́jú méjì tán láti rin ìrìn náà nínú ọkọ̀.

Bí o bá jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, o lè ronú kan àkókò kan tí àìsí afárá nípa lórí ìtàn. Rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà ti Ọba Nebukadinésárì ti Bábílónì gbógun ti ìlú Tírè tó wà ní erékùṣù. Ọdún 13 ló fi gbìyànjú láti ṣẹ́gun ìlú náà, àìsí afárá láàárín erékùṣù náà àti ilẹ̀ gidi jẹ́ ọ̀kan lára ìdí tí kò fi ṣeé ṣe fún un. (Ìsíkíẹ́lì 29:17-20) Ìlú tó wà ní erékùṣù náà kò ṣeé ṣẹ́gun títí di ọ̀ọ́dúnrún ọdún lẹ́yìn náà, nígbà tí Alẹkisáńdà Ńlá tẹ́ ọ̀nà tí a gbé gba òkè láti orí ilẹ̀ dé erékùṣù náà.

Nígbà tó fi di ọ̀rúndún kìíní, ‘ọ̀nà gbogbo ló já sí Róòmù,’ àmọ́ àwọn ará Róòmù nílò afárá àti títì láti so ilẹ̀ ọba náà pọ̀. Wọ́n lo àwọn òkúta tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn tẹ̀wọ̀n tó tọ́ọ̀nù mẹ́jọ, àwọn onímọ̀ ẹ̀rọ ilẹ̀ Róòmù tẹ́ àwọn afárá olóbìrìkìtì, tí wọ́n fi òye iṣẹ́ gíga kọ́, tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn kan nínú wọn fi ṣì wà lẹ́yìn ẹgbàá ọdún. Àwọn ọ̀nà àbásọdá omi àti ọ̀nà àbásọdá kòtò wọn jẹ́ afárá pẹ̀lú.

Ní Sànmánì Ìbẹ̀rẹ̀ Ọ̀làjú, a ń fi àwọn afárá ṣe odi lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Ní ọdún 944 Sànmánì Tiwa, àwọn Saxon fi gẹdú tẹ́ afárá kan sórí Odò Thames ní London kí àwọn ará Denmark má lè gbógun tì wọ́n. Ní nǹkan bí ọ̀ọ́dúnrún ọdún lẹ́yìn náà, wọ́n fi Ògbólógbòó Afárá London, tó lókìkí nínú ìtàn àti orin, rọ́pò afárá onígẹdú yìí.

Nígbà tí Elizabeth Ọbabìnrin Kìíní fi bẹ̀rẹ̀ sí jọba ní England, Ògbólógbòó Afárá London kì í ṣe odi olókùútà kan lásán mọ́. Wọ́n ti kọ́lé sórí afárá náà. Àwọn ṣọ́ọ̀bù ti wà nísàlẹ̀. Kí ni wọ́n ń fi òkè ṣe? Wọ́n ti sọ ọ́ di ibùgbé àwọn ọlọ́lá oníṣòwò àti àwọn òṣìṣẹ́ ààfin pàápàá. Afárá London ti di ojúkò ibi afẹ́ ìlú London. Owó tí wọ́n ń gbà lórí àwọn ṣọ́ọ̀bù àti ibùgbé náà ni wọ́n fi ń bójú tó afárá náà, ní gidi, Afárá London jẹ́ afárá tí ń pawó wọlé!

Nígbà tí àwọn ará Yúróòpù ń fi gẹdú àti òkúta ṣe afárá, àwọn Inca tí ń gbé Gúúsù Amẹ́ríkà ń fi okùn ṣe é. Àpẹẹrẹ kan tó lókìkí ni afárá San Luis Rey, tó wà lórí Odò Apurímac, ní Peru. Àwọn Inca mú àwọn fọ́nrán igi kan, wọ́n sì lọ́ wọn pọ̀ di okùn tó ṣe gìdìgbà tó odindi ènìyàn. Wọ́n so àwọn okùn náà sórí àwọn òpó olókùúta, wọ́n wá nà wọ́n kọjá orí odò. Lẹ́yìn tí wọ́n ti so àwọn okùn ọ̀hún ní ìkángun méjèèjì, wọ́n to àwọn pákó lé orí okùn náà bí títì. Ọdún méjìméjì ni àwọn òṣìṣẹ́ alátùn-únṣe ń pààrọ̀ àwọn okùn náà. Wọ́n tẹ́ afárá yìí dáradára, wọ́n sì ń ṣàtúnṣe rẹ̀, tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi wà fún ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ọdún!

Àwọn Afárá àti Àwọn Àìní Wa Tí Ń Yí Padà

Kò yẹ kí ìsẹ̀lẹ̀, ìjì líle, àti ìyípadà nínú ìwọ̀n ìgbóná òun ìtutù ba afárá jẹ́. Bí a ti sọ tẹ́lẹ̀, gẹdú, bíríkì, tàbí òkúta ni àwọn onímọ̀ ẹ̀rọ fi ń tẹ́ afárá títí di ẹnu àìpẹ́ yìí. Nígbà tí a bẹ̀rẹ̀ sí lo ọkọ̀ ìrìnnà ní ìparí ọ̀rúndún kọkàndínlógún, ó di dandan kí a mú àwọn afárá tó wà sunwọ̀n sí i, kí a sì fẹ̀ wọ́n sí i, kí àyè lè gba àwọn ohun ìrìnnà tó túbọ̀ tóbi.

Ìhùmọ̀ ọkọ̀ ojúurin pẹ̀lú tún mú kí a tẹ́ afárá púpọ̀ sí i, kí a sì mú ọnà wọn sunwọ̀n sí i. Ọ̀nà ojúurin tó rọrùn jù sábà máa ń kọjá lórí odò tàbí ọ̀gbun jíjìn. Ǹjẹ́ a lè tẹ́ afárá tó gùn tó, tó sì lágbára tó, láti gba ọ̀pọ̀ ọkọ̀ tí a ń ṣe? Àwọn afárá alápòpọ̀ irin líle ni a lò fún àkókò kan. Ọ̀kan nínú àwọn afárá tó lókìkí jù níbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún kọkàndínlógún ni afárá alásokọ́ orí Ọrùn Omi Menai ní Àríwá Wales, tí onímọ̀ ẹ̀rọ ará Scotland náà, Thomas Telford, tẹ́ parí ní 1826. Ó gùn ní mítà 176, a sì ṣì ń lò ó di báyìí! Ṣùgbọ́n ó jọ pé àpòpọ̀ irin líle máa ń tètè ṣẹ́, àwọn afárá sì tètè máa ń já nígbà náà. Níkẹyìn, ní apá ìparí àwọn ọdún 1800, a bẹ̀rẹ̀ sí ṣe irin lílẹ̀. Èyí rí bó ti yẹ wẹ́kú fún fífi tẹ́ àwọn afárá tó túbọ̀ gùn, tí kò sì léwu tó bẹ́ẹ̀.

Àwọn Onírúurú Afárá

Oríṣi afárá méje ló wà ní pàtàkì. (Wo àpótí tó wà lókè.) Níhìn-ín, a ó sọ̀rọ̀ ṣókí nípa méjì nínú wọn.

Àwọn afárá onítìí ń ní òpó ńláńlá méjì ní ìhà méjèèjì odò. Wọ́n ń so ìtí igi mọ́ òpó ńláńlá kọ̀ọ̀kan, bí pákó àtẹ̀wọdò tí wọ́n ń ṣe sí adágún omi ìwẹ̀. Láti parí afárá náà, wọ́n wá ń fi igi ìgbátí kan so àwọn ìtí náà pọ̀ láàárín.

Níbi tí odò bá ti máa ń ru gan-an, tàbí tí ilẹ̀ odò ti rọ̀ jù, a sábà máa ń lo afárá onítìí nítorí pé, kò sí pé a ń ri òpó mọ́lẹ̀ láàárín odò. Nítorí bí àwọn afárá onítìí ṣe ń lágbára gan-an, wọ́n dára fún ọ̀nà ohun ìrìnnà tó wúwo gan-an bí ọkọ̀ ojú irin.

Bóyá o ti rí afarapitú kan tí ń rìn lórí okùn títa kan. Ǹjẹ́ o mọ̀ pé orí afárá ló ti ń rìn yẹn—afárá alásokọ́? Àwọn afárá alásokọ́ kan tí a ń lò lónìí kò fi nǹkan kan yàtọ̀ sí okùn títa lásán. Ó lè jẹ́ okùn kan tí a so kọ́ lẹ́gbẹ̀ẹ́ méjèèjì, tí a sì so apẹ̀rẹ̀ kan rọ̀ mọ́ ni. Ẹni tó fẹ́ kọjá náà ń jókòó sínú apẹ̀rẹ̀ ọ̀hún, ó sì ń yí ara rẹ̀ ní ìwọ̀n títẹ̀ sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan títí ó fi ń dé ìhà kejì. Kárí ayé ni àwọn ènìyàn ti ń lo àwọn afárá olókùn nígbà gbogbo.

Dájúdájú, yóò ṣòro fún ọ láti ronú pé o ń wa ọkọ̀ kọjá lórí afárá kan tí a fokùn ṣe. Lẹ́yìn tí a hùmọ̀ àwọn ọ̀gbàrà ẹ̀wọ̀n tí a fi irin so kọ́ra àti àwọn wáyà onírin lílẹ̀, ó wá ṣeé ṣe láti tẹ́ àwọn afárá alásokọ́ tó ṣeé gbé ẹrù wíwúwo. Àwọn afárá alásokọ́ òde òní lè gùn tó 1,200 mítà tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ. Afárá alásokọ́ kan sábà máa ń ní òpó àárín méjì, tí a fi irin lílẹ̀ ṣe, tí ọ̀kọ̀ọ̀kan ń fún òpó gogoro kọ̀ọ̀kan lágbára. Àwọn okùn onírin lílẹ̀, tí a fi ẹgbẹẹgbẹ̀rún wáyà ṣe, ni a ń dè mọ́ àwọn òpó gogoro náà àti títì tó wà nísàlẹ̀. Àwọn okùn wọ̀nyẹn ni ojúlówó ohun tó gbé ohun ìrìnnà àti títì náà gan-an ró. Bí a bá ṣe é dáradára, afárá alásokọ́ jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn afárá tí ewu rẹ̀ kéré jù lágbàáyé.

O ti lè má ka àwọn afárá sí tẹ́lẹ̀. Àmọ́, nígbà tí o bá tún kọjá lórí afárá kan tí o mọ̀ dunjú, bi ara rẹ pé: ‘Kí ni mo mọ̀ nípa afárá yìí? Nígbà wo ni wọ́n tẹ́ ẹ?’ Wò ó láwòfín. Ṣé onítìí ni àbí alásokọ́, àbí oríṣi afárá mìíràn? Kí ló dé tó fi jẹ́ oríṣi yìí?

Bí o bá ti ń kọjá lórí rẹ̀, wo ilẹ̀, kí o sì bi ara rẹ pé, ‘Báwo ni ǹ bá ti ṣe é, láìsí i?’

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]

ÀWỌN ORÍṢI AFÁRÁ

1. AFÁRÁ GÁDÀ ni a sábà ń lò fún títì. Àwọn gádà náà máa ń wà lórí àwọn òpó àárín tí a rì mọ́lẹ̀. Àwọn afárá wọ̀nyí lè gùn tó 300 mítà.

2. AFÁRÁ ALÁKÀNPỌ̀ PÁKÓ ni àwọn tí a ń fi àwọn pákó tí a ṣe ní onígun mẹ́ta gbé ró. Àwọn afárá wọ̀nyí, tí a sábà ń fi ṣe ọ̀nà ojú irin, ni a ń tẹ́ sórí àwọn àfonífojì olómi, odò, àti àwọn nǹkan ìdènà mìíràn.

3. Nínú AFÁRÁ OLÓBÌRÌKÌTÌ, ìpín kọ̀ọ̀kan rí bìrìkìtì. Èyí jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn oríṣi afárá tó ti wà tipẹ́tipẹ́. Irú òbìrìkìtì yìí ni àwọn ará Róòmù ṣe ni àwọn ibi ọ̀nà àbásọdá omi àti ọ̀nà àbásọdá kòtò wọn, tí wọ́n sì fi àwọn òkúta tí wọ́n gbẹ́ so pọ̀ mọ́ra. Ọ̀pọ̀ nínú wọn ló ṣì wà di ìsinsìnyí.

4. AFÁRÁ ÀFOKÙNGBÉRÓ dà bí àwọn afárá alásokọ́, kìkì pé a so àwọn okùn náà mọ́ àwọn òpó gogoro náà ní tààràtà.

5. A lè gbé AFÁRÁ ÀṢEÉṢÍNÍPÒ sókè tàbí kí a yí wọn po, kí àwọn ọkọ̀ òkun lè ráyè kọjá. Àpẹẹrẹ tí a mọ̀ dunjú ni Afárá Tower tó wà ní London.

6. A sọ̀rọ̀ lórí AFÁRÁ ONÍTÌÍ nínú àpilẹ̀kọ gan-an.

7. A sọ̀rọ̀ lórí AFÁRÁ ALÁSOKỌ́ nínú àpilẹ̀kọ gan-an.—World Book Encyclopedia, 1994.

[Àtẹ Ìsọfúnnni tó wà ní ojú ìwé 13]

ÀWỌN AFÁRÁ OLÓKÌKÍ MÉLÒÓ KAN

ALÁSOKỌ́

Storebaelt Denmark 1,624 mítà

Brooklyn U.S.A. 486 mítà

Golden Gate U.S.A. 1,280 mítà

Jiangyin Yangtze China 1,385 mítà

ONÍTÌÍ

Forth (alápá Scotland 521 mítà lápá

gbígbòòrò méjì) kọ̀ọ̀kan

Quebec Kánádà 549 mítà

Odò Mississippi U.S.A. 480 mítà

OLÓBÌRÌKÌTÌ TÍ A FI IRIN LÍLẸ̀ ṢE

Àpápá Sydney Ọsirélíà 500 mítà

Birchenough Zimbabwe 329 mítà

ÀFOKÙNGBÉRÓ

Pont de Normandie Ilẹ̀ Faransé 856 mítà

Skarnsundet Norway 530 mítà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Afárá gádà ìgbàlódé tó wà lókè afárá olóbìrìkìtì ní Almería, Sípéènì

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Afárá Brooklyn, New York, U.S.A. (alásokọ́)

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Afárá Tower, London, England (àṣeéṣínípò)

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Afárá Àpápá Sydney, Ọsirélíà (olóbìrìkìtì)

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Seto Ohashi, Japan (àfokùngbéró)

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́