Ẹni Tí Jésù Jẹ́ Nísinsìnyí
BÍ Ó tilẹ̀ jẹ́ pé bí Jésù ṣe rí gba àfiyèsí, ó ṣe pàtàkì gan-an láti wádìí ẹni tí ó jẹ́ nísinsìnyí àti ibi tí ó wà. Ipa wo ló ń kó nínú ète Ọlọ́run fún ìdílé aráyé?
A ò lè rí ìdáhùn nínú àwọn ìwé ìtàn. Inú ìwé tí Ọlọ́run ṣe fún àǹfààní àwọn tí ń wá òtítọ́ nìkan ni a ti lè rí i. Ìwé náà sì ni Bíbélì Mímọ́, tàbí Ìwé Mímọ́, ìwé tí a tíì pín kiri jù lọ nínú ìtàn ayé.
Bíbélì kì í ṣe ìwé kan lásán tí àwọn òǹkọ̀wé tí wọ́n jẹ́ ènìyàn kọ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ènìyàn ni Ọlọ́run lò bí akọ̀wé Rẹ̀, òun gan-an ló kọ ọ́: “Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí, ó sì ṣàǹfààní fún kíkọ́ni, fún fífi ìbáwí tọ́ni sọ́nà, fún mímú àwọn nǹkan tọ́, fún bíbániwí nínú òdodo, kí ènìyàn Ọlọ́run lè pegedé ní kíkún, tí a mú gbára dì pátápátá fún iṣẹ́ rere gbogbo.”—2 Tímótì 3:16, 17.
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù mọ ohun tí Ìwé Mímọ́ jẹ́, ìdí nìyẹn tí ó fi kọ̀wé pé: “Nígbà tí ẹ gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, èyí tí ẹ gbọ́ láti ọ̀dọ̀ wa, ẹ tẹ́wọ́ gbà á, kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ ènìyàn, ṣùgbọ́n, gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́ lótìítọ́, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.”—1 Tẹsalóníkà 2:13.
Ọlọ́run ni alágbára gbogbo, Ẹlẹ́dàá àgbáyé tí ó ní ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ tí ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù ìràwọ̀ sì wà nínú ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ kọ̀ọ̀kan. Agbára rẹ̀ má pọ̀ gan-an tó fi lè dá gbogbo nǹkan yẹn o! Dájúdájú, Alágbára Ńlá Gbogbo náà, tí ó dá àgbáálá ayé yíyanilẹ́nu náà, lè ṣe ìwé kan tí yóò jẹ́ atọ́nà tí gbogbo ẹni tí ń wá òtítọ́ lè gbẹ́kẹ̀ lé.
Ohun Tí Bíbélì Sọ
Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tú àṣírí àwọn àbá èrò orí àti àhesọ rẹpẹtẹ tí àwọn ènìyàn ti sọ nípa Jésù. Ṣàkíyèsí díẹ̀ lára àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ tí ó fún wa nípa rẹ̀:
• Jésù ni ẹ̀dá àkọ́kọ́ tí Ọlọ́run nìkan dá láìmọye ọdún sẹ́yìn ní ọ̀run kí ó tó dá àwọn áńgẹ́lì àti ilẹ̀ ayé. Ìdí nìyẹn tí a fi pè é ní “Ọmọ bíbí . . . kan ṣoṣo” ti Ọlọ́run. Nígbà tí Ọmọ yìí, tó jẹ́ “àgbà òṣìṣẹ́” Ọlọ́run, kò tíì wá gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ènìyàn ni a dá gbogbo ìṣẹ̀dá yòókù.—Jòhánù 3:16; 6:38; 8:58; Òwe 8:30; Kólósè 1:16.
• Ní nǹkan bí ẹgbàá ọdún sẹ́yìn, Ọlọ́run tàtaré ẹ̀mí Jésù sínú wúńdíá ọmọ Júù kan, kí ó lè bí i ní ènìyàn. Kódà nísinsìnyí, ènìyàn ń ṣe ohun tí ó jọ ìyẹn nípa fífa àtọ̀ dà sínú ilé ọlẹ̀ obìnrin.—Mátíù 1:18; Jòhánù 1:14.
• Kì í ṣe pé Jésù jẹ́ ènìyàn rere nìkan ni. Nígbà tó dàgbà, ó ṣàgbéyọ ànímọ́ onífẹ̀ẹ́, oníyọ̀ọ́nú, olódodo ti Bàbá rẹ̀ ọ̀run, Jèhófà Ọlọ́run, lọ́nà pípé.—Jòhánù 14:9, 10; Hébérù 1:3; 1 Jòhánù 4:7-11, 20, 21.
• Gẹ́gẹ́ bí aṣojú Ọlọ́run lórí ilẹ̀ ayé, Jésù ṣaájò àwọn aláìní àti àwọn tí a ń ni lára, síbẹ̀ kò ya àwọn ọlọ́rọ̀ sọ́tọ̀. Pẹ̀lú ìtìlẹ́yìn ẹ̀mí mímọ́ alágbára ti Ọlọ́run, Jésù mú àwọn aláìsàn lára dá, ó tilẹ̀ gbé àwọn òkú dìde lọ́nà iṣẹ́ ìyanu. Nípa ṣíṣe irú iṣẹ́ ìyanu bẹ́ẹ̀, ó fi ohun tí yóò ṣe jákèjádò ayé hàn ní ráńpẹ́ lẹ́yìn tí ó bá jíǹde kúrò ní ipò òkú sí ìyè ní ọ̀run, tí ó sì di Ọba Ìjọba Ọlọ́run ti ọ̀run.—Mátíù 11:4-6; Lúùkù 7:11-17; Jòhánù 11:5-45.
• Ìjọba Ọlọ́run ti ọ̀run yẹn ni Jésù kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti máa gbàdúrà fún, kí wọ́n sì fi sí ipò kìíní nínú ìgbésí ayé wọn. Nígbà tí Ìjọba yẹn bá fìdí múlẹ̀ dáadáa, “yóò fọ́ ìjọba wọ̀nyí [tí ó wà lónìí] túútúú, yóò sì fi òpin sí gbogbo wọn, òun fúnra rẹ̀ yóò sì dúró fún àkókò tí ó lọ kánrin.” Lẹ́yìn náà, Ìjọba yẹn nìkan ni yóò máa ṣàkóso lórí ilẹ̀ ayé. Òun ni ìrètí kan ṣoṣo tí ìran ènìyàn tí ń dààmú ní.—Dáníẹ́lì 2:44; Mátíù 6:9, 10.
• Ọlọ́run ni Bàbá Jésù, Jésù sì ṣe olóòótọ́ sí Ọlọ́run. Nípa bẹ́ẹ̀, ẹni pípé ni Jésù nígbà tí a pa á. Ó fínnúfíndọ̀ fi ìwàláàyè pípé rẹ̀ lé Ọlọ́run lọ́wọ́ bí ẹbọ ìràpadà láti gba ohun tí Ádámù gbé sọnù nígbà tí ó ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run padà. Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, Jésù ṣí ọ̀nà ìyè ayérayé sílẹ̀ fún olúkúlùkù ẹni tó bá lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀.—Jòhánù 3:16; Róòmù 3:23, 24; 1 Jòhánù 2:2.
• Gẹ́gẹ́ bí Ọba tí Ọlọ́run yàn sípò ní ọ̀run, Jésù yóò ṣàṣepé ète Ọlọ́run láti mú ìwà ibi kúrò lórí ilẹ̀ ayé àti láti sọ àwọn ènìyàn onígbọràn di pípé ní èrò inú àti ara. Aráyé yóò wá máa gbé lálàáfíà àti ayọ̀ nínú párádísè orí ilẹ̀ ayé, gbogbo wọn yóò sì ní ilé tó dára àti ọ̀pọ̀ yanturu oúnjẹ. Àrùn, ìbànújẹ́, àti ikú kì yóò sí mọ́. Kódà, a óò jí àwọn òkú dìde, wọn óò sì ní àǹfààní láti wà láàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé.—Jẹ́nẹ́sísì 1:26-28; 2:8; Sáàmù 37:10, 11, 29; Òwe 2:21, 22; Aísáyà 25:6; 65:21-23; Lúùkù 23:43; Ìṣe 24:15; Ìṣípayá 21:3, 4.
Nítorí náà, Bíbélì sọ fún wa kedere pé, Jésù kó ipa pàtàkì nínú ète Ọlọ́run láti gbé ayé tuntun òdodo kalẹ̀ síhìn-ín lórí ilẹ̀ ayé. Nítorí ipa pàtàkì tí Jésù kó ni ó fi lè sọ lọ́nà ẹ̀tọ́ pé: “Èmi ni ọ̀nà àti òtítọ́ àti ìyè. Kò sí ẹni tí ń wá sọ́dọ̀ Baba bí kò ṣe nípasẹ̀ mi.”—Jòhánù 14:6; 2 Pétérù 3:13.
Alákòóso Tí Ó Yọ́nú
Àwọn onírẹ̀lẹ̀ ènìyàn fẹ́ kí Jésù jẹ́ alákòóso wọn nínú ayé tuntun náà, ẹ sì wo irú alákòóso àrà ọ̀tọ̀, tí ó gbádùn mọ́ni tí òun yóò jẹ́! Ọ̀nà kan tó gbà fi èyí hàn jẹ́ nípa àwọn iṣẹ́ ìwòsàn yíyanilẹ́nu tí ó ṣe nígbà tó wà láyé. (Mátíù 15:30, 31) Àmọ́, tún ṣàkíyèsí irú alákòóso tí yóò jẹ́.
Kọ́kọ́ gbé àwọn àkọsílẹ̀ nípa àwọn alákòóso ayé yìí yẹ̀ wò. Ìtàn fi hàn pé ní ọ̀pọ̀ ọdún tó ti kọjá, wọ́n ti jẹ́ òǹrorò àti aláìláàánú, wọ́n sì ti mú kí àwọn ènìyàn wọn lọ́wọ́ nínú ogun, ìwà ìkà bíburújáì, ìwádìí láti gbógunti àdámọ̀, àti ìpakúpa tí kò lóǹkà. Nínú ọ̀rúndún ogún yìí nìkan, ó lé ní ọgọ́rùn-ún mílíọ̀nù ènìyàn tí ogun ti pa.
Fi ìṣesí àti àkọsílẹ̀ tí àwọn alákòóso ayé yìí ní wéra pẹ̀lú èyí tí a kọ nípa ọ̀nà tí Jésù gbà bá àwọn aláìní, àwọn tí a ń ni lára, àwọn mẹ̀kúnnù lò pé: “Nígbà tí ó rí àwọn ogunlọ́gọ̀, àánú wọn ṣe é, nítorí a bó wọn láwọ, a sì fọ́n wọn ká bí àwọn àgùntàn tí kò ní olùṣọ́ àgùntàn.” Nítorí náà, ó wí fún wọn pé: “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣe làálàá, tí a sì di ẹrù wọ̀ lọ́rùn, dájúdájú, èmi yóò sì tù yín lára. Ẹ gba àjàgà mi sọ́rùn yín, kí ẹ sì kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ mi, nítorí onínú tútù àti ẹni rírẹlẹ̀ ní ọkàn-àyà ni èmi, ẹ ó sì rí ìtura fún ọkàn yín. Nítorí àjàgà mi jẹ́ ti inú rere, ẹrù mi sì fúyẹ́.”—Mátíù 9:36; 11:28-30.
Ẹ wo bí Jésù ṣe yọ́nú sí àwọn ènìyàn tó! Ó fi èyí jọ Bàbá rẹ̀ ọ̀run ni. Jésù ni àpẹẹrẹ ìfẹ́ gan-an, ó sì kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti fi ìfẹ́ tòótọ́, tí a gbé karí ìlànà hàn sí ara wọn lẹ́nì kìíní-kejì. Wọn kò ní tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́ kí ẹ̀yà, orílẹ̀-èdè, bí wọ́n ṣe lówó sí, ìsìn wọn àtijọ́, tàbí ohunkóhun mìíràn ṣèdíwọ́ fún ìṣọ̀kan tí wọ́n ní jákèjádò ayé. (Jòhánù 13:34, 35; Ìṣe 10:34, 35) Ní gidi, Jésù nífẹ̀ẹ́ àwọn ènìyàn gan-an tí ó fi fẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ fún wọn. (Éfésù 5:25) Òun ni irú alákòóso tí aráyé ń fẹ́, wọn ó sì rí i.
“Arẹwà” Ọba Ni Jésù Nísinsìnyí
Ọ̀rọ̀ alásọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run ràn wá lọ́wọ́ láti lóye pé Ọba ńlá ni Jésù jẹ́ lọ́run nísinsìnyí. Onísáàmù náà sọ tẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀ pé: “Ní tòótọ́, ìwọ rẹwà ju àwọn ọmọ ènìyàn. . . . Nínú ọlá ńlá rẹ, kí o tẹ̀ síwájú dé àṣeyọrí sí rere; máa gẹṣin lọ nítorí òtítọ́ àti ìrẹ̀lẹ̀ àti òdodo . . . Ìwọ nífẹ̀ẹ́ òdodo, o sì kórìíra ìwà burúkú. Ìdí nìyẹn tí Ọlọ́run, àní Ọlọ́run rẹ, fi fòróró ayọ̀ ńláǹlà yàn ọ́ ju àwọn alájọṣe rẹ.”—Sáàmù 45:2, 4, 7.
Gẹ́gẹ́ bí Ọba ọ̀run tí Ọlọ́run fòróró yàn, ó yan Jésù láti fi ìfẹ́ tí ó ní fún òdodo hàn kí ó sì fi ìkórìíra tí ó ní fún ìwà burúkú hàn. Ìdí nìyẹn tí a fi ṣàpèjúwe rẹ̀ nínú Bíbélì bí aṣẹ́gun tí kò lè kú, “Ọba àwọn ọba,” tí yóò pa gbogbo ọ̀tá Ọlọ́run láìpẹ́. Síwájú sí i, yóò sọ ilẹ̀ ayé di párádísè, yóò sì sọ àwọn ènìyàn tí ó ṣeé rà padà di pípé.—Ìṣípayá 19:11-16.
Ipa tuntun tí Jésù ń kó kì í ṣe ti ‘Mèsáyà tí ń jìyà,’ tí àwọn aṣòdì fi ṣẹ̀sín, tí wọ́n nà, tí wọ́n sì pa. Kàkà bẹ́ẹ̀, ipa tuntun tí ó ń kó jẹ́ ti “Ọlọ́run Alágbára Ńlá,” alákòóso ilẹ̀ ayé. (Aísáyà 9:6) Ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn alákòóso ayé kò nífẹ̀ẹ́ sí ìròyìn yìí, nítorí pé a óò fọ́ àwọn ìjọba wọn túútúú láìpẹ́, bí Dáníẹ́lì 2:44 ṣe sọ tẹ́lẹ̀. Nípa fífi Kristi ṣe amúdàájọ́ṣẹ rẹ̀, Ọlọ́run “yóò fọ́ àwọn ọba sí wẹ́wẹ́ dájúdájú ní ọjọ́ ìbínú rẹ̀. Òun yóò mú ìdájọ́ ṣẹ ní kíkún láàárín àwọn orílẹ̀-èdè.”—Sáàmù 110:5, 6.
Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé nípa ṣíṣe èyí, Kristi yóò “mú ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ta gìrì. Àwọn ọba yóò pa ẹnu wọn dé sí i.” Èé ṣe? “Nítorí pé ohun tí a kò tíì ròyìn lẹ́sẹẹsẹ fún wọn [láti ẹnu àwọn agbaninímọ̀ràn nínú ìsìn wọn] ni wọn yóò rí ní tòótọ́, ohun tí wọn kò tíì gbọ́ sì ni wọn yóò yí ìrònú wọn sí.”—Aísáyà 52:15.
‘Kíkórè Ààjà’
Aísáyà sàsọtẹ́lẹ̀ nípa bí àwọn aṣáájú ìsìn yóò ṣe pa iṣẹ́ wọn tì. Fún àpẹẹrẹ, wọn kì í fi òtítọ́ Bíbélì kọ́ àwọn ọmọ ìjọ wọn bí kò ṣe àwọn ẹ̀kọ́ tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu nípa ìdálóró ayérayé ní ọ̀run àpáàdì, mẹ́talọ́kan, àti àìleèkú ọkàn—tí gbogbo wọn pilẹ̀ ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn kèfèrí. Àwùjọ àlùfáà ṣètìlẹ́yìn fún gbogbo ogun tí ó ṣẹlẹ̀ ní orílẹ̀-èdè wọn, kódà nígbà tí ó bá béèrè pé kí wọ́n pa àwọn tí wọ́n jọ ń ṣe ìsìn kan náà. Èyí jẹ́ rírú àwọn òfin Ọlọ́run ní tààràtà.—1 Jòhánù 2:3, 4; 3:10-12; 4:8, 20, 21.
Bákan náà, àwùjọ àlùfáà ń fi àwọn ohun tí ń fa ojú mọ́ra bí àwòrán ìsìn, aṣọ oyè àlùfáà gbàgìẹ̀gbàgìẹ̀, ilé ìjọsìn olówó ńlá, àti àwọn àwòrán tí a ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ pẹ̀lú èrò ìbọ̀rìṣà lọ́kàn, títí kan ìmọ́lẹ̀ roboto ti òrìṣà oòrùn fa àwọn ọmọ ìjọ wọn mọ́ra ṣùgbọ́n ìwọ̀nyí kò já mọ́ nǹkan lójú Ọlọ́run. Wọ́n ń ṣe èyí bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run pàṣẹ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé: “Ẹ yí padà, ẹ yí padà, ẹ jáde kúrò níbẹ̀, ẹ má fọwọ́ kan ohun àìmọ́ kankan . . . , ẹ̀yin tí ń gbé àwọn nǹkan èlò Jèhófà.”—Aísáyà 52:11; 2 Kọ́ríńtì 6:14-18.
Àwọn tí wọ́n ní àwọn ń ṣojú fún Ọlọ́run ṣùgbọ́n tí wọ́n ń rú àwọn òfin rẹ̀, tí wọ́n sì ń kọ́ àwọn ẹlòmíràn láti máa ṣe bákan náà yóò kórè ohun tí wọ́n ń gbìn. A óò dá wọn lẹ́bi, wọn óò sì jìyà rẹ̀ nígbà tí a bá pa ètò àwọn nǹkan yìí run. Bí wòlíì Hóséà ṣe sọ, “wọ́n ti gbin ẹ̀fúùfù, wọn ó sì ká ààjà.”—Hóséà 8:7, King James Version; wo Ìṣípayá 17:1-3, 15, 16.
Àwọn Aláìlábòsí-Ọkàn Ń Kẹ́kọ̀ọ́ Òtítọ́
Kíkọ́ tí àwùjọ àlùfáà ń kọ́ àwọn ènìyàn lẹ́kọ̀ọ́ òdì nípa Ọlọ́run àti Jésù kò lè dí àwọn aláìlábòsí-ọkàn lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nípa Jésù. Ní ọ̀rúndún kìíní, kò dí wọn lọ́wọ́, nítorí pé bí Paul Barnett ṣe kọ ọ́ nínú ìwé The Two Faces of Jesus, “Kì í ṣe pé Kristi kàn já bọ́ láti ojú sánmà, láìsí ìsọfúnni nípa rẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni, nígbà náà lọ́hùn-ún, àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ‘polongo’ Mèsáyà lọ́nà pípéye, ó sì fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ adúróṣinṣin ní ìdánilójú pé ó ń bọ̀. Lónìí, ẹ̀rí púpọ̀ sí i wà tí ń polongo òtítọ́ náà pé Ọlọ́run ti fún Jésù ní agbára láti ṣàkóso bí ológo, “Ọba àwọn ọba” ní ọ̀run.—Mátíù 24:3-13; 2 Tímótì 3:1-5, 13.
Ní gidi, “a ó . . . wàásù ìhìn rere ìjọba [Ọlọ́run tí Kristi yóò ṣàkóso rẹ̀] ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; nígbà náà ni òpin yóò sì dé.” (Mátíù 24:14) Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tí iye wọn lé ní mílíọ̀nù márùn-ún jákèjádò ayé ń ṣe bẹ́ẹ̀. Nítorí náà, àwọn tí wọ́n fẹ́ mọ Jésù gan-an lè ṣe bẹ́ẹ̀. (Jòhánù 10:14; 1 Jòhánù 5:20) Bákan náà, mímọ̀ ọ́n àti ṣíṣègbọràn sí i ṣe pàtàkì fún ẹni tó bá fẹ́ la “ìpọ́njú ńlá” tí yóò wá fọ ilẹ̀ ayé mọ́ já.—Ìṣípayá 7:9-14; Jòhánù 17:3; 2 Tẹsalóníkà 1:6-10.
Nítorí náà, inú Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò dùn láti ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣàgbéyẹ̀wò àlàyé fífanimọ́ra tí Bíbélì ṣe nípa Ọmọ Ọlọ́run.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Kristi yóò fi agbára Ìjọba mú ìwà burúkú kúrò
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Lábẹ́ ìṣàkóso onífẹ̀ẹ́ ti Kristi, ilẹ̀ ayé yóò di párádísè