Àìfún Ẹ̀sìn Lómìnira Lóde Òní
“Olúkúlùkù ló lẹ́tọ̀ọ́ sí òmìnira ìrònú, ẹ̀rí-ọkàn àti ẹ̀sìn; ẹ̀tọ́ yìí kan òmìnira láti yí ẹ̀sìn tàbí ìgbàgbọ́, àti òmìnira rẹ̀ padà, yálà lóun nìkan tàbí pẹ̀lú àwọn mìíràn láwùjọ àti ní gbangba tàbí níkọ̀kọ̀, láti fi ẹ̀sìn tàbí ìgbàgbọ́ rẹ̀ hàn nínú ẹ̀kọ́, ìṣe, ìjọsìn àti ayẹyẹ.” Apá Kejìdínlógún, Ìpolongo Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn Ti Gbogbo Gbòò, Ọdún 1948.
ǸJẸ́ o ń gbádùn òmìnira ìsìn ní orílẹ̀-èdè rẹ? Ọ̀pọ̀ jù lọ lára orílẹ̀-èdè àgbáyé ló ń fẹnu lásán tẹ̀ lé ìlànà wíwúnilórí yìí, tí a ti kọ sínú àwọn ìpolongo àgbáyé lọ́pọ̀ ìgbà. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, a fojú díwọ̀n pé àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn lónìí ni kò gbádùn òmìnira ìsìn ní àwọn orílẹ̀-èdè tí àìfún ẹ̀sìn lómìnira àti yíya ẹ̀sìn sọ́tọ̀ ti le koko. Yàtọ̀ sí ìyẹn, ọ̀pọ̀ ènìyàn ń gbé àárín àwọn àwùjọ ọlọ́pọ̀ ẹ̀yà, ìbílẹ̀, tàbí ẹ̀sìn níbi tí òfin ti pèsè ìdánilójú pé òmìnira ìsìn wà, tí ó sì jọ pé a ń ṣìkẹ́ fífún ẹ̀sìn lómìnira nínú àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ orílẹ̀-èdè náà.
Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ní àwọn àgbègbè wọ̀nyí pàápàá, òmìnira ìsìn àwọn ènìyàn kan ṣì wà nínú ewu. Angelo d’Almeida Ribeiro, Ajábọ̀ Àpérò Lọ́nà Àkànṣe tẹ́lẹ̀ rí tí Ìgbìmọ̀ Amúṣẹ́ṣe Lórí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Àjọ UN yàn sípò sọ pé: “Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé inú gbogbo ìgbékalẹ̀ ọrọ̀ ajé, àwùjọ ẹ̀dá, àti àkópọ̀ èròǹgbà ètò òṣèlú àti ti ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà àti ní ibi gbogbo lágbàáyé ni a ti ń rí ìyàsọ́tọ̀ nítorí ìsìn tàbí ìgbàgbọ́ tó lágbára.” Nínú ìwé Freedom of Religion and Belief—A World Report, tí olóòtú Kevin Boyle àti Juliet Sheen ṣe ní 1997, wọ́n sọ pé: “Inúnibíni tí a ń ṣe sí àwọn ìsìn tí kò gbajúmọ̀ [àti] dídá tí a ń dẹ́bi fún ohun tí àwọn ènìyàn gbà gbọ́ àti ìyàsọ́tọ̀ tó gbalẹ̀ ti di ìṣẹ̀lẹ̀ ojoojúmọ́ . . . ní ìparí ọ̀rúndún ogún.”
Àmọ́, kì í ṣe àwọn tí ẹ̀sìn wọn kò gbajúmọ̀ nìkan ni ọ̀ràn yíya ẹ̀sìn sọ́tọ̀ kàn. Ọ̀jọ̀gbọ́n Abdelfattah Amor, Ajábọ̀ Àpérò Lọ́nà Àkànṣe Lórí Àìfún Ẹ̀sìn Lómìnira, ti Ìgbìmọ̀ Amúṣẹ́ṣe Lórí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Àjọ UN, ronú pé “kò sí ìsìn tí a kò lè gbógun tì.” Nítorí náà, ó ṣeé ṣe kí àwọn ẹ̀sìn kan máa dojú kọ àìfún ẹ̀sìn lómìnira àti ẹ̀tanú lemọ́lemọ́ níbi tí ìwọ ń gbé.
Oríṣiríṣi Ìyàsọ́tọ̀
Yíya ẹ̀sìn kan sọ́tọ̀ lè wá lóríṣiríṣi ọ̀nà. Àwọn orílẹ̀-èdè kan wulẹ̀ ń yan ẹ̀sìn kan péré láàyò, wọn ó sì wá sọ ọ́ di ìsìn Orílẹ̀-èdè. Ní àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, ńṣe ni wọ́n ń ṣe àwọn òfin kan tí ń ká ìgbòkègbodò àwọn ẹ̀sìn kan lọ́wọ́ kò. Àwọn orílẹ̀-èdè kan ti ṣe àwọn òfin tí a ti ṣì lóye. Ṣàgbéyẹ̀wò ibi tí a ṣi agbára lò dé lórí òfin kan tí a wéwèé ní Ísírẹ́lì láti fìyà jẹni fún kíkó àwọn ìwé pẹlẹbẹ tàbí ìwé “tí a ṣe láti yíni lọ́kàn padà sí ẹ̀sìn kan” wọ̀lú, títẹ̀ wọ́n, pípín wọn kiri, tàbí níní wọn lọ́wọ́. Kò yani lẹ́nu nígbà tí ìwé ìròyìn International Herald Tribune sọ pé: “A ti dí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́wọ́, a sì ti kọ lu wọ́n ní Ísírẹ́lì.” Wọ́n já wọ Gbọ̀ngàn Ìjọba Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan ní Lod lẹ́ẹ̀mẹta, àwọn aláṣejù onítara ìsìn lọ́nà àṣerégèé sì bà á jẹ́ lẹ́ẹ̀mejì. Àwọn ọlọ́pàá kò sì dá sí i.
Ìwé Freedom of Religion and Belief mẹ́nu kan àwọn àpẹẹrẹ àìfún ẹ̀sìn lómìnira pé: “Àdámọ̀ àti àwọn aládàámọ̀ nìkan kọ́ ni èròǹgbà tó ti wà tipẹ́. . . . Ìkọnisílẹ̀, inúnibíni àti yíya àwọn tí wọ́n tọ ọ̀nà mìíràn sọ́tọ̀ ṣì jẹ́ lájorí okùnfà àìfún ẹ̀sìn lómìnira. Àwọn Amadíyà ní Pakistan àti àwọn [Baha’is] ní Íjíbítì, Iran, àti Malaysia jẹ́ àpẹẹrẹ àwọn ẹ̀sìn díẹ̀ bíi ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní àwọn orílẹ̀-èdè mélòó kan ní Ìlà Oòrùn Yúróòpù, ní Gíríìsì àti Singapore.” Ó ṣe kedere pé òmìnira ìsìn wà nínú ewu ní apá ibi púpọ̀ lágbàáyé.
Lójú èyí, Federico Mayor, olùdarí àgbà Àjọ Ètò Ẹ̀kọ́, Ìmọ̀ Ìjìnlẹ̀, àti Àṣà Ìbílẹ̀ ti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè, sọ pé sànmánì tí yóò wọlé dé láìpẹ́ “kò fún ìtara-ọkàn aláìlábòsí níṣìírí. . . . Ńṣe ni òmìnira tuntun tí àwọn ènìyàn ní ń tanná ran ìkórìíra.” Nígbà tí olùdarí Ibùdó Tí Ń Rí sí Ọ̀ràn Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ní Yunifásítì Essex, United Kingdom, ń jẹ́rìí sí àwọn ohun tí ń bani lẹ́rù náà, ó wí pé: “Gbogbo ẹ̀rí ló tọ́ka sí ìparí èrò náà pé ìwà àìfún ẹ̀sìn lómìnira . . . ń pọ̀ sí i dípò kí ó máa dín kù ní ayé òde òní.” Irú àìfún ẹ̀sìn lómìnira bẹ́ẹ̀ tí ń pọ̀ sí i ń hu òmìnira ìsìn léwu, ó sì lè kan òmìnira ìsìn tìrẹ. Ṣùgbọ́n kí ló dé tí òmìnira ìsìn fi ṣe pàtàkì tó bẹ́ẹ̀?
Kí Ní Ń Fì Dùgbẹ̀dùgbẹ̀?
Onímọ̀ ìbágbépọ̀ ẹ̀dá, Bryan Wilson, sọ nínú ìwé rẹ̀ Human Values in a Changing World, pé: “Kí a tó lè sọ pé ẹgbẹ́ àwùjọ kan wà lómìnira, ó gbọ́dọ̀ ní òmìnira ìsìn. . . . Láìsí òmìnira ìsìn àti ẹ̀tọ́ láti tan ìgbàgbọ́ ẹni kálẹ̀, kò lè sí òmìnira ẹ̀rí-ọkàn, bẹ́ẹ̀ ni kò lè sí ìjọba tiwa-n-tiwa tí ó pójú owó.” Bí ilé ẹjọ́ kan ní ilẹ̀ Faransé ṣe mọ̀ láìpẹ́ yìí, “òmìnira ìgbàgbọ́ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn kókó pàtàkì nínú fífún ará ìlú lómìnira.” Nítorí náà, yálà o lẹ́mìí ìsìn tàbí o kò ní in, ó yẹ kí o nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀ràn dídáàbòbo òmìnira ìsìn.
Ìṣarasíhùwà orílẹ̀-èdè kan nípa òmìnira ìsìn tún ń nípa púpọ̀ gan-an lórí ìfùsì àti bí àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn yóò ṣe gbà á gbọ́ sí. Wọ́n sọ nínú ìròyìn kan tí a kà ní 1997 níbi ìpàdé kan tí àwọn orílẹ̀-èdè mẹ́rìnléláàádọ́ta tí wọ́n jẹ́ mẹ́ńbà Àjọ Ààbò àti Àjọṣe Ilẹ̀ Yúróòpù ṣe pé: “Òmìnira Ìsìn jẹ́ ọ̀kan lára ìlànà gíga jù lọ nínú àkójọ àwọn ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn, tí ó jẹ́ pàtàkì lára ohun tí ń gbé ẹ̀dá níyì. Kò sí ìgbékalẹ̀ kan tí ń tẹ irú ẹ̀tọ́ bẹ́ẹ̀ lójú, tàbí tí ń fàyè gba títẹ̀ ẹ́ lójú léraléra, tí ó lè fi ẹ̀tọ́ sọ pé òun wà lára àwùjọ àwọn orílẹ̀-èdè tí ó dúró ṣánṣán, tí wọ́n jẹ́ alátìlẹ́yìn ìjọba tiwa-n-tiwa, tí wọ́n bọ̀wọ̀ fún àwọn ìpìlẹ̀ ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn.”
Ńṣe ni òmìnira ìsìn dà bí apá kan ìpìlẹ̀ ilé. Orí rẹ̀ ni a kọ́ àwọn òmìnira mìíràn—ti ará ìlú, ìṣèlú, àṣà ìbílẹ̀, àti ètò ọrọ̀ ajé—lé. Bí a bá gbẹ́ ìdí ìpìlẹ̀ ilé, gbogbo ilé yóò di ẹgẹrẹmìtì. Láìfọ̀rọ̀ bọpobọyọ̀, Ọ̀jọ̀gbọ́n Francesco Margiotta-Broglio sọ ọ́ báyìí pé: “Ìgbàkigbà tí a bá tẹ òmìnira [ìsìn] lójú, àwọn òmìnira mìíràn yóò wá fara gbá nínú ìṣòro náà.” Bí a óò bá dáàbò bo àwọn òmìnira mìíràn, a ní láti kọ́kọ́ dáàbò bo òmìnira ìsìn.
Láti mọ bí a ṣe lè dáàbò bo ohun kan dáadáa, ó ṣe pàtàkì láti lóye rẹ̀. Kí ni gbòǹgbò òmìnira ìsìn? Báwo ni a ṣe fìdí rẹ̀ múlẹ̀, kí ni ó sì gbà?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]
Àṣà àìfún ẹ̀sìn lómìnira ti wà tipẹ́