ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g99 2/8 ojú ìwé 12-15
  • Kìnnìún—Olóólàajù Abigọ̀gọ̀ Ti Ilẹ̀ Áfíríkà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kìnnìún—Olóólàajù Abigọ̀gọ̀ Ti Ilẹ̀ Áfíríkà
  • Jí!—1999
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ẹ̀dá Arùfẹ́-Ọkàn-Sókè, Tí Ó Sì Jọni Lójú
  • Simbaa—Olóólàajù Tí Ń Kẹ́gbẹ́ Jẹ̀
  • Ọdẹ
  • Ẹran Ọdẹ
  • Kí Ní Ń sún Wọn Ṣe é?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Ǹjẹ́ O Mọ̀?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • Dáníẹ́lì Nínú Ihò Kìnnìún
    Ìwé Ìtàn Bíbélì
Jí!—1999
g99 2/8 ojú ìwé 12-15

Kìnnìún—Olóólàajù Abigọ̀gọ̀ Ti Ilẹ̀ Áfíríkà

LÁTI ỌWỌ́ AKỌ̀RÒYÌN “JÍ!” NÍ KẸ́ŃYÀ

OÒRÙN ti ràn ní Pẹ̀tẹ́lẹ̀ Serengeti ní Áfíríkà. A jókòó sínú ọkọ̀ Land Rover wa nínú afẹ́fẹ́ atura tí ń fẹ́ lówùúrọ̀, a ń wo àwọn abo kìnnìún àti àwọn ọmọ wọn tí wọ́n ń dà lọ. Ara wọn aláwọ̀ ilẹ̀ títàn rí múlọ́múlọ́, ó sì láwọ̀ wúrà, tó bá ewéko gbígbẹ, tí ó gùn mu. Àwọn ọmọ wọn ya eléréepá, wọ́n sì lókun. Wọ́n ń ta bọ́n-únbọ́n-ún, wọ́n ń fò mọ́ àwọn abo kìnnìún ńlá, tó jọ pé wọn kò fi bẹ́ẹ̀ kọbi ara sí àwọn ọmọ wọn oníwọ́nranwọ̀nran.

Lójijì, agbo àwọn kìnnìún náà dúró láìmira. Gbogbo wọn ń wo ọ̀kánkán. Láti ibi tí a wà, a wo apá ibi tí wọ́n ń bẹjú wò, a sì rí ohun tí ó gba àfiyèsí wọn. A rí akọ kìnnìún ńlá kan nínú ọ̀yẹ̀ òwúrọ̀ náà. Ojú wa ṣe mẹ́rin pẹ̀lú tirẹ̀ bí ó ti ń wò wá. A nímọ̀lára pé ara wa ń gbọ̀n, kì í ṣe pé òtútù òwúrọ̀ náà ló fà á, àmọ́ nítorí pé a mọ̀ pé àwa ló ń wò. Ẹ̀rù rẹ̀ bani, síbẹ̀ ìrísí rẹ̀ jojú ní gbèsè. Ẹranko ńlá onígọ̀gọ̀ aláwọ̀ wúrà tí ìlà dúdú wà ní orí rẹ̀ títóbi. Àwọn ojú rẹ̀ títóbi jẹ́ aláwọ̀ pípọ́n, wọ́n sì ń wò kiri. Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ará ilé rẹ̀ gba àfiyèsí rẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí í wo apá ọ̀dọ̀ wọn díẹ̀díẹ̀, ó sì ń rìn lọ síhà ọ̀dọ̀ wọn.

Ńṣe ló ń dá gọ̀jọgọ̀jọ, bí ọba gan-an. Láìtún bojú wo ọ̀dọ̀ wa, ó gba iwájú ọkọ̀ wa kọjá, ó sì tọ àwọn abo kìnnìún náà àti àwọn ọmọ wọn lọ. Gbogbo wọn gbéra lọ pàdé rẹ̀, wọ́n sì ń fi orí kan igi imú rẹ̀ lílágbára bí ìgbà tí àwọn ẹranko ẹ̀yà ológbò bá ń fimú romú tí wọ́n bá ń kí ara wọn. Bí ó ti dé àárín agbo náà, akọ kìnnìún náà balẹ̀ bàràkàtà bí ẹni tó ti rẹ̀ níbi tó ti ń rìn káàkiri, ó sì fẹ̀yìn lélẹ̀. Àárẹ̀ tó mú un náà ran àwọn yòókù, kò sì pẹ́ tí gbogbo wọn bẹ̀rẹ̀ sí í foorun rẹjú nínú àkọ́yọ ìtànṣán oòrùn òwúrọ̀ tí ń ta yẹ́ẹ́ náà. A rí àwòrán àlàáfíà àti ìtẹ́lọ́rùn láàárín àwọn ewéko aláwọ̀ wúrà, tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ nínú ọ̀dàn gbayawu náà.

Ẹ̀dá Arùfẹ́-Ọkàn-Sókè, Tí Ó Sì Jọni Lójú

Ó jọ pé kò sí ẹranko tí ó tíì ru ìfẹ́-ọkàn ẹ̀dá sókè tó ti kìnnìún. Nígbà láéláé, àwọn ayàwòrán ní Áfíríkà máa ń ya àwòrán àwọn kìnnìún tí ń dọdẹ ẹran ìjẹ sára àpáta. A máa ń fi ère kìnnìún onígọ̀gọ̀, tí a fi òkúta ńlá gbẹ́, ṣe àwọn ààfin àti tẹ́ńpìlì ayé àtijọ́ lọ́ṣọ̀ọ́. Lóde òní, àwọn ènìyàn máa ń rọ́ lọ sí àwọn ọgbà ẹranko láti lọ wo àwọn olóólàajù jíjọnilójú yìí. A ti bá kìnnìún lò bí ẹ̀dá tó gba àfiyèsí pàtàkì nínú àwọn ìwé àti fíìmù, bí Born Free, ìtàn ìgbésí ayé ọmọ kìnnìún tí kò lóbìí tí wọ́n gbé lọ tọ́ níbì kan tó pamọ́, tí wọ́n wá tú sílẹ̀ níkẹyìn. A sì ti ń dúnrùn mọ́ kìnnìún, pé apààyàn ni, nínú àwọn ìtàn—àwọn kan jẹ́ àròsọ, apá kan jẹ́ òtítọ́. Abájọ tí kìnnìún sì fi jẹ́ ẹ̀dá tí ń ru ìfẹ́-ọkàn sókè, tó sì jọni lójú!

Àwọn kìnnìún lè jẹ́ oníkanra gan-an, lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, wọ́n sì lè jẹ́ ẹ̀dá oníwà-pẹ̀lẹ́ tí ó ń ṣeré gan-an bí ọmọ ológbò. Wọ́n máa ń kùn díẹ̀díẹ̀ nígbà tí ara bá tù wọ́n, síbẹ̀, wọ́n lè bú ramúramù gan-an tí a fi lè gbọ́ròó wọn ní kìlómítà mẹ́jọ. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ó máa ń jọ pé wọ́n ya ọ̀lẹ, wọ́n sì lọ́ra, àmọ́ wọ́n ní agbára láti sáré lọ́nà yíyanilẹ́nu. Ènìyàn ti sọ kìnnìún di akíkanjú nítorí ìgboyà rẹ̀, a sì máa ń pe ẹni tó bá gbóyà ní aláyà bíi kìnnìún.

Simbaa—Olóólàajù Tí Ń Kẹ́gbẹ́ Jẹ̀

Kìnnìún jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ẹranko ẹ̀yà ológbò tí ń kẹ́gbẹ́ jẹ̀ jù lọ. Wọ́n máa ń ṣeré bí wọ́n bá wà pọ̀ bí agbo ìdílé kan, níbi tí iye wọn lè jẹ́ láti orí ìwọ̀nba kéréje kan sí èyí tí ó lé ní ọgbọ̀n. Agbo náà máa ń ní ọ̀wọ́ àwọn abo kìnnìún tí wọ́n lè bára tan gan-an. Wọ́n máa ń gbé pọ̀, wọ́n máa ń ṣọdẹ pọ̀, wọ́n sì máa ń bímọ pa pọ̀. Ìdè tímọ́tímọ́ yìí, tí ó lè máa bá a lọ ní gbogbo ìgbésí ayé wọn, ń pèsè ìpìlẹ̀ agbo ìdílé kìnnìún, ó sì ń mú wíwà nìṣó rẹ̀ dájú.

Agbo kìnnìún kọ̀ọ̀kan ní akọ kìnnìún kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ tí wọ́n ti dàgbà dáadáa, tí ń káàkiri, tó ń fi òórùn sàmì ìpínlẹ̀ agbo náà. Láti orí imú dúdú àwọn ẹranko ńlá yìí dé ṣóńṣó ìrù wọn ṣíṣù, wọ́n lè gùn tó mítà mẹ́ta, wọ́n sì lè wọ̀n ju kìlógíráàmù igba ó lé mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn akọ ló ń jọba lé agbo lórí, àwọn abo ló máa ń mú ipò aṣáájú. Àwọn abo kìnnìún ló máa ń kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ nǹkan, bí lílọ sí ibòòji tàbí bíbẹ̀rẹ̀ ṣíṣọdẹ ẹran.

Àwọn abo kìnnìún sábà máa ń bímọ lọ́dún méjì-méjì. Àwọn kìnnìún kéékèèké kì í lè ṣe nǹkan kan. Títọ́ ọmọ kìnnìún dàgbà jẹ́ iṣẹ́ gbogbo agbo náà lápapọ̀, gbogbo àwọn abo ni yóò sì máa dáàbò bo ọmọ náà, tí wọn ó sì máa tọ́jú rẹ̀. Àwọn ọmọ kìnnìún máa ń yára dàgbà; tí wọ́n bá fi máa di ọmọ oṣù méjì, wọ́n ti ń sáré kiri, tí wọn ó sì máa ṣeré. Bí wọ́n ti ń yí kiri láàárín ara wọn bí ọmọ ológbò, wọ́n máa ń jìjàkadì, wọ́n máa ń wa àwọn alájọṣeré wọn mú, wọ́n sì máa ń fò kiri láàárín ewéko gíga. Ohunkóhun tó bá ń lọ láti ibì kan sí ibòmíràn máa ń fà wọ́n mọ́ra, wọ́n máa ń fò mọ́ labalábá, wọ́n máa ń lé kòkòrò, wọ́n sì máa ń bá ọ̀pá àti àjàrà jìjàkadì. Èyí tí ó jẹ́ àrímáleèlọ jù lọ ni bí ìrù ìyá wọn ṣe ń jù, èyí tí ó máa ń dìídì jù síwá sẹ́yìn, láti fi pè wọ́n wá ṣeré.

Agbo kọ̀ọ̀kan máa ń gbé ìpínlẹ̀ tí a pààlà sí kedere tí fífẹ̀ rẹ̀ lè jẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ hẹ́kítà. Àwọn kìnnìún fẹ́ràn àwọn àgbègbè tó ga níbi tí omi gbé pọ̀, tí ibòòji sì máa ń wà nínú oòrùn ọ̀sán gangan tó mú ganrínganrín. Àárín àwọn erin, àgùnfọn, ẹfọ̀n, àti àwọn ẹranko mìíràn nínú ọ̀dàn náà ni wọ́n ń gbé. Ìgbésí ayé kìnnìún kan pín sí ìsọ̀rí wákàtí gígùn tí ó fi ń sùn àti àkókò kúkúrú tí ó fi ń dọdẹ ẹran tí ó sì fi ń gùn. Òtítọ́ ibẹ̀ ni pé, a lè rí àwọn kìnnìún níbi tí wọ́n ti ń sinmi, tí wọ́n ti ń sùn, tàbí tí wọ́n jókòó sí fún ogún wákàtí tan-n-tán lóòjọ́. Bí wọ́n bá ti sùn lọ, wọ́n máa ń jọ ẹranko oníwàpẹ̀lẹ́ tí a mú dọ́sìn. Bí ó ti wù kí ó rí, má ṣe jẹ́ kí ìyẹn tàn ọ́ jẹ—ọ̀kan lára ẹranko rírorò jù lọ nínú igbó ni kìnnìún jẹ́!

Ọdẹ

Nígbà tí ó di ọwọ́ ìrọ̀lẹ́, àwọn ilẹ̀ oníkoríko tí oòrùn ti pa dáadáa bẹ̀rẹ̀ sí í tutù. Àwọn abo kìnnìún mẹ́ta tó wà lára agbo tí a ń wò bẹ̀rẹ̀ sí í lajú láti ojú oorun ọ̀sán wọn. Ebi ti bẹ̀rẹ̀ sí í pa àwọn olóólàajù náà, wọ́n wá rìn káàkiri, wọ́n ń gbóòórùn inú afẹ́fẹ́, wọ́n sì ń bẹjú wo gbogbo inú ọ̀dàn tí ó láwọ̀ ràkọ̀ràkọ̀ náà. Ó jẹ́ àkókò tí àwọn ẹtu ń ṣí kiri, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ẹtu tí ìrísí wọn kò báradé wọ̀nyí ń jẹ̀ lọ sí ìhà gúúsù lálàáfíà. Àwọn olóólàajù mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà wá lọ sápá ibẹ̀. Wọ́n pínyà sọ́tọ̀ọ̀tọ̀, wọ́n yọ́ kẹ́lẹ́ la àárín ilẹ̀ wúruwùru náà já. A fẹ́rẹ̀ẹ́ má lè rí àwọn olóólàajù aláwọ̀ ilẹ̀ títàn yìí láàárín àwọn ewéko gígùn náà, wọ́n sì sún mọ́ ọ̀wọ́ àwọn ẹran tí kò fura náà tó nǹkan bí ọgbọ̀n mítà. Ìgbà yẹn ní àwọn olóólàajù náà pinnu láti gbá yá wọn. Pẹ̀lú eré tó le gan-an, wọ́n já wọ àárín agbo àwọn ẹtu tí jìnnìjìnnì bò náà. Ọ̀wọ́ àwọn ẹtu tí jìnnìjìnnì bò náà bẹ̀rẹ̀ sí í sáré sókè sódò, ojú wọn ranko bí wọ́n ṣe ń sá fún ẹ̀mí wọn. Ọgọ́rọ̀ọ̀rún pátákò tí ń kilẹ̀, wọ́n sì ń ku eruku lálá. Bí eruku ti ń rọlẹ̀, a rí àwọn abo kìnnìún mẹ́ta náà tí wọ́n dá dúró, tí wọ́n ń mí hẹlẹhẹlẹ gan-an. Ẹran lọ mọ́ wọn lọ́wọ́. Bóyá àǹfààní àtiṣọdẹ yóò tún wà lọ́wọ́ alẹ́, ó sì lè máà rí bẹ́ẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kìnnìún lè fò síhìn-ín sọ́hùn-ún tí wọ́n sì yára, ìdá ọgbọ̀n nínú gbogbo ìgbà tí wọ́n bá ṣọdẹ ni wọ́n máa ń rí ẹran pa. Àìróúnjẹjẹ wá tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára ohun tí ń halẹ̀ mọ́ àwọn kìnnìún jù lọ.

Arabaríbí ni okun tí kìnnìún tó ti dàgbà dáadáa ní. Ní àwọn ìgbà tí wọ́n bá ṣọdẹ pọ̀ bí agbo kan, a ti rí i pé wọ́n máa ń ṣá àwọn ẹranko tó tẹ̀wọ̀n ju ẹ̀ẹ́dégbèje [1,300] kìlógíráàmù balẹ̀, tí wọn á sì pa á. Bí kìnnìún bá kọ́kọ́ gbéra ìlépa ẹran, ó lè sáré tó kìlómítà mọ́kàndínlọ́gọ́ta láàárín wákàtí kan, àmọ́ wọ́n kò lè ṣe bẹ́ẹ̀ sáré fún àkókò gígùn. Nítorí èyí, wọ́n máa ń lo ọgbọ́n ìyọ́kẹ́lẹ́ àti ìfarapamọ́ láti rí ẹran pa. Àwọn abo kìnnìún ló máa ń ṣe èyí tó pọ̀ jù lára ọdẹ ṣíṣe náà, àmọ́ àwọn akọ tí wọ́n túbọ̀ tóbi ló sábà máa ń jẹ èyí tó pọ̀ jù bí wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí í jẹun. Bí àwọn kìnnìún kò bá fi bẹ́ẹ̀ rí ẹran pa, nígbà mìíràn, ebi máa ń pa wọ́n débi pé wọ́n óò lé àwọn ọmọ wọn dànù kí wọ́n má bàa jẹ nínú ẹran tí wọ́n pa.

Ẹran Ọdẹ

Nígbà láéláé, kìnnìún olóólàajù rìn gbéregbère káàkiri gbogbo ilẹ̀ Áfíríkà àti àwọn apá ibì kan ní Éṣíà, Yúróòpù, Íńdíà, àti Palẹ́sìnì. Nítorí pé ó jẹ́ ọdẹ, ó máa ń figa gbága pẹ̀lú ènìyàn. Nítorí pé kìnnìún jẹ́ ewu fún ohun ọ̀sìn, tí ó sì máa ń ṣe ènìyàn léṣe, ó ti di ẹ̀dá tí a ní láti yìn níbọn tí a bá fojú kàn án. Bí ènìyàn ṣe ń pọ̀ sí i ni ibùgbé àdánidá kìnnìún ń kéré sí i. Lẹ́yìn odi ilẹ̀ Áfíríkà, ìwọ̀nba kìnnìún tó ṣẹ́ kù nínú igbó kò ju ọgọ́rùn-ún bíi mélòó kan péré lọ lónìí. Nísinsìnyí, bí àwọn kìnnìún bá wà ní àárín àgbègbè tí a dáàbò bò àti àwọn ọgbà ohun alààyè nìkan ni ẹ̀mí wọ́n dè.

Lọ́nà tó múni láyọ̀, àwọn ìyípadà wà nípamọ́ fún ẹranko ńlá yìí. Bíbélì ṣàpèjúwe ọjọ́ ọ̀la kan nígbà tí kìnnìún yóò máa gbé lálàáfíà pẹ̀lú ènìyàn. (Aísáyà 11:6-9) Ẹlẹ́dàá wa onífẹ̀ẹ́ yóò mú èyí ṣẹ láìpẹ́. Nígbà yẹn, onígọ̀gọ̀ olóólàajù Áfíríkà yóò máa gbé ní ìṣọ̀kan àti àlàáfíà pẹ̀lú àwọn ìṣẹ̀dá mìíràn.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Simba ni “kìnnìún” lédè Swahili.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 15]

Nígbà Tí Kìnnìún Bá Ń BÚ RAMÚRAMÙ

KÌNNÌÚN ní ìfùsì agbára ìbúramúramù aláìlẹ́gbẹ́ tí a lè gbọ́ láti ibi tó jìnnà gan-an. A ti ka ìbúramúramù kìnnìún sí ọ̀kan lára “ìró àdánidá tí ń nípa lórí ẹni jù lọ.” Kìnnìún sábà máa ń bú lákòókò tí ilẹ̀ kò tíì mọ́ lọ́wọ́ ìdájí. Takọtabo kìnnìún ló máa ń bú, lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àṣehàn máa ń mú kí wọ́n bú pa pọ̀ lẹ́ẹ̀kan náà.

Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì tí wọ́n ṣèwádìí nípa kìnnìún dábàá pé bíbú tí wọ́n ń bú máa ń jẹ́ kí wọ́n ṣe ohun púpọ̀. Àwọn akọ kìnnìún máa ń bú láti kéde ibi tí ààlà ibùgbé wọn dé àti láti fi ìwà ògbójú kìlọ̀ fún àwọn akọ kìnnìún mìíràn tí ó ṣeé ṣe kí wọ́n wọ àyíká ibùgbé wọn. Lọ́nà tí ó bá a mu, Bíbélì pe àwọn ògbójú, onígbèéraga, àti oníwọra tí ń ṣàkóso Ásíríà àti Bábílónì ní “ẹgbọrọ kìnnìún onígọ̀gọ̀” tí ń fipá ta ko àwọn ènìyàn Ọlọ́run tí ó sì ń pa wọ́n jẹ.—Aísáyà 5:29; Jeremáyà 50:17.

Bíbú tí wọ́n ń bú ń jẹ́ kí àwọn tí wọ́n jọ wà nínú agbo kan náà lè rí ara wọn nígbà tí wọ́n bá jìnnà síra tàbí tí òkùnkùn bá ṣú. Lẹ́yìn pípa ẹran kan, ìró ohùn yìí yóò ta àwọn yòókù lólobó nípa ibi tí ẹran ìjẹ náà wà. Bíbélì sọ nípa ànímọ́ yìí pé: “Ẹgbọrọ kìnnìún onígọ̀gọ̀ yóò ha fọhùn láti ibi ìfarapamọ́ rẹ̀ bí kò bá tíì mú nǹkan kan rárá?”—Ámósì 3:4.

Ó yani lẹ́nu pé nígbà tí kìnnìún bá ń ṣọdẹ àwọn ẹran igbó, kì í lo ìkéramúramù bí ọgbọ́n ìṣọdẹ láti dẹ́rù ba ẹran ọdẹ. Nínú ìwé tí Richard Estes kọ náà, The Behavior Guide to African Mammals, ó sọ pé, “kò sí ẹ̀rí pé kìnnìún ń ṣàdéédé ké ramúramù láti lé àwọn ẹran ọdẹ wọnú ibùba (nínú ọ̀pọ̀ ìṣẹ̀lẹ̀, àwọn ẹ̀yà ẹran ọdẹ sábà máa ń kọtí ikún sí ìkéramúramù kìnnìún).”

Nígbà náà, kí ló dé tí Bíbélì fi tọ́ka sí Sátánì bí ‘kìnnìún tí ń ké ramúramù, tí ń wá ọ̀nà láti pani jẹ’? (1 Pétérù 5:8) Bí ó tilẹ̀ jọ pé ìkéramúramù kìnnìún kò lè kó àwọn ẹranko ìgbẹ́ láyà jẹ, èyí kò rí bẹ́ẹ̀ ní ti ènìyàn àti àwọn ẹran ọ̀sìn. Ìbúramúramù tí ń múni gbọ̀nrìrì tí ń jáde lẹ́nu kìnnìún, tí ń dún àdúntúndún nínú òkùnkùn lálẹ́, yóò dẹ́rù ba ẹnikẹ́ni tí ó wà níta gbangba, yóò sì kó o láyà jẹ. Tipẹ́tipẹ́ sẹ́yìn ni ẹnì kan ti sọ pé: “Kìnnìún kan wà tí ó ti ké ramúramù! Ta ni kì yóò fòyà?”—Ámósì 3:8.

Sátánì jáfáfá nínú fífi ìbẹ̀rù kó àwọn ènìyàn láyà jẹ kí wọ́n lè rẹ̀wẹ̀sì. Kí a dúpẹ́ pé àwọn ènìyàn Ọlọ́run ní olùgbèjà tó lágbára. Pẹ̀lú ìgbàgbọ́ tó lágbára nínú ìtìlẹ́yìn Jèhófà, wọ́n lè dènà “kìnnìún tí ń ké ramúramù” tó lágbára yìí. A rọ àwọn Kristẹni láti ‘mú ìdúró wọn lòdì sí i, ní dídúró gbọn-in nínú ìgbàgbọ́.’—1 Pétérù 5:9.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́