Irú Aṣọ Tí A Ń Wọ̀—Ó Ha Já Mọ́ Nǹkan Kan Ní Gidi bí?
“MI Ò mọ ohun tí ń máa wọ̀ o!” Ǹjẹ́ ó ti gbọ́ irú àwáwí yìí rí? Dájúdájú, àwọn ilé oge òde òní ṣetán láti ràn ọ́ lọ́wọ́ ní gbogbo ìgbà—tàbí láti fi ohun tí wọ́n gbé jáde kẹ́yìn dà ọ́ lọ́kàn rú sí i.
Láti mú kí ṣíṣe ìpinnu túbọ̀ ṣòro, lóde òní, wọ́n lè gbà ọ́ níyànjú láti múra lọ́nà yẹpẹrẹ dípò kí o múra dáadáa. Nítorí àwọn àṣà ìwọṣọ tó yí padà ní àwọn ọdún 1990 yìí, olóòtú kan tí ń kọ̀ròyìn nípa oge sọ pé: “A lè mú un dáni lójú pé, kì í ṣe pé mímọ̀ọ́mọ̀ ní ìrísí àgbàlagbà, ti arúgbó, àti pé kí a kàn múra jákujàku lọ́nà kan ṣáá, jẹ́ ohun ìtẹ́wọ́gbà nìkan ni, ó tún jẹ́ ohun tí àwọn ènìyàn ń fẹ́.”
Dájúdájú, ní àwọn ọdún àìpẹ́ yìí, ìpolówó ọjà kíkankíkan, àwọn afìmúra-polówó-ọjà lórí tẹlifíṣọ̀n, àwọn ojúgbà ẹni, pípolówó ara ẹni, àti fífẹ́ láti di gbajúmọ̀ ti nípa lórí irú aṣọ tí àwọn ènìyàn ń wọ̀, ní pàtàkì àwọn ọ̀dọ́. Kódà, àwọn kan lára wọn ń jalè láti lè wọṣọ bí ẹni tó gbọ́ fáàrí.
Ọ̀pọ̀ àṣà ìwọṣọ tí a tẹ́wọ́ gbà ní àwọn ọdún 1990 pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn aláṣerégèé tí wọ́n wà ní àwọn ọdún tó ti kọjá sẹ́yìn, bí irú àwọn abẹ́gbẹ́yodì tó dìde ní Ìwọ̀ Oòrùn ní àwọn ọdún 1960. Wọ́n máa ń dá irùngbọ̀n sí, wọn kì í tọ́jú irun orí wọn tí ó kún ṣìkìtì ṣìkìtì, wọ́n máa ń wọ àkísà tí ń fi hàn pé wọ́n ti kọ ìwà ọmọlúwàbí sílẹ̀. Àmọ́, ìwọṣọ lọ́nà ọ̀tẹ̀ wá tanná ran àṣà àjọgbà tuntun, àṣà ká ṣe ohun tẹ́gbẹ́ ẹni ṣe tuntun.
Aṣọ ti di ohun èlò tó wúlò jù lọ tó sì túbọ̀ ń sọ bí ènìyàn ṣe jẹ́. Àwọn aṣọ, ní pàtàkì ṣẹ́ẹ̀tì alápá péńpé, ti di pátákó ìpolówó-ọjà tí ó rọra ń kéde àwọn eré ìdárayá àti àwọn akọni eléré ìdárayá tó lókìkí, ìpanilẹ́rìn-ín, ìbànújẹ́, ìjà wíwá, ìwà rere—tàbí àìní ìwà rere—àti àwọn ọjà tí a ṣe jáde. Tàbí kí wọ́n dáyà jáni. Ṣàgbéyẹ̀wò àkọlé kan nínú ìwé ìròyìn Newsweek to sọ láìpẹ́ yìí pé: “Ìwà Òkú Òǹrorò Gẹ́gẹ́ Bí Àṣà Tó Lòde fún Àwọn Ọ̀dọ̀.” Àpilẹ̀kọ náà gbé ohun tí ọmọ ọlọ́dún mọ́kànlélógún kan sọ nípa àwọ̀tẹ́lẹ̀ alápá péńpé rẹ̀ jáde pé: “Mo ń wọ̀ ọ́ nítorí pé ó ń jẹ́ kí àwọn ènìyàn mọ ohun tí mo ń rò lọ́wọ́. N kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni máa darí mi, ń kò sì fẹ́ ìyọlẹ́nu kankan.”
Ohun tí wọ́n ń fi hàn ní àyà àti ẹ̀yìn aṣọ ẹnì kọ̀ọ̀kan lè yàtọ̀ síra. Síbẹ̀ ìbáradọ́gba tí a fi ń dá ẹgbẹ́ kan mọ̀ tàbí ipá tí ẹ̀mí ìṣọ̀tẹ̀, ẹ̀mí tèmi làkọ́kọ́, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, tàbí ìwà ipá ní lórí wọn ń hàn kedere. Ọkùnrin aránṣọ kan ń lu ihò sára àwọn aṣọ fún àwọn oníbàárà rẹ bí wọ́n bá ṣe fẹ́ ẹ. Ó sọ pé: “Wọ́n lè yàn ihò tó fẹ̀ tó ojú ìbọn ìléwọ́, ti ìbọn àgbétèjìká, tàbí ti ìbọn arọ̀jò ọta. Ó wulẹ̀ jẹ́ àṣà tó lòde ni.”
Kí Ni Àṣà Tó Lòde Ń Fi Hàn?
Jane de Teliga tó jẹ́ alábòójútó Ibi Ìkóhun-Ìṣẹ̀ǹbáyé-Sí ti Powerhouse ní Sydney, Ọsirélíà, sọ pé: “Ní gbogbo gbòò aṣọ jẹ́ ọ̀nà kan tí o gbà ń fi ara rẹ hàn gẹ́gẹ́ bí ara ẹ̀yà kan pàtó láwùjọ.” Ó fi kún un pé: “O yan ẹ̀yà tí o fẹ́ kí a mọ̀ ọ́ mọ́, o sì ń múra bí tiwọn.” Ọ̀mọ̀wé Dianna Kenny tó jẹ́ olùkọ́ nípa ìrònú àti ìhùwà ní Yunifásítì Sydney sọ pé, aṣọ ṣe pàtàkì bí ìsìn, ọrọ̀, iṣẹ́ ṣíṣe, ìran ẹni, ìmọ̀ ẹ̀kọ́, àti àdírẹ́sì ilé ti ṣe pàtàkì gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà kan láti mọ ibi tí a óò to ènìyàn sí. Ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí ìwé ìròyìn Jet sọ, rògbòdìyàn kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà “bẹ́ sílẹ̀ ní ilé ẹ̀kọ́ kan tí àwọn aláwọ̀ funfun pọ̀ sí jù ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà látàrí pé àwọn ọmọbìnrin aláwọ̀ funfun tí ń lọ sí ilé ẹ̀kọ́ kó àṣà irun dídì, wíwọ aṣọ títóbi, àti àwọn àṣà ìgbàlódé mìíràn nítorí pé wọ́n jẹ́ àṣà tí a mọ̀ mọ àwọn Adúláwọ̀.”
Àṣà kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà tún hàn kedere ní àwọn ọ̀nà mìíràn, bí irú ibi ìwòran orin nípa èyí tí ìwé ìròyìn Maclean’ sọ pé: “Ní ọ̀pọ̀ ìgbà, aṣọ máa ń bá bí orin ṣe rí mu: àwọn olólùfẹ́ orin régè máa ń wọ aṣọ tí ó tàn yòò pẹ̀lú àwọn fìlà ará Jàmáíkà, nígbà tí àwọn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí orin rọ́ọ̀kì onírìísí wúruwùru máa ń dé fìlà tí a fi òwú hun àti ṣẹ́ẹ̀tì abìlà aláwọ̀ mèremère ní èjìká.” Àmọ́, ohunkóhun tí yíyàn náà lè jẹ́, wíwulẹ̀ kó aṣọ kọ́rùn, mímúra yẹpẹrẹ, mímúra láti ní ìrísí ipò òṣì bí ọmọ tí kò nílé, tí kò lọ́nà, àṣà sísọ aṣọ gidi di àkísà láti fi bóde mu, kò sàìnáni lówó.
Kí Ní Ń Ṣẹlẹ̀ Sí Ìlànà Ìwọṣọ?
Woody Hochswender tí ó jẹ́ akọ̀ròyìn sọ pé: “Òdìkejì gbogbo ohun tí a fọkàn sí la ń rí. Ìmúra àwọn ọkùnrin tó ti fìgbà kan rí ní ìlànà pàtó kan tí kì í yẹ̀ ti di ti ewèlè . . . Kí gbogbo rẹ̀ ṣá ti rí bí èyí tí a kàn gbé kọ́ ọrùn ṣáá.” Bí ó ti wù kí ó rí, ìtẹ̀sí yìí lè fi ìwà àìbìkítà hàn. Tàbí kí ó fi àìní iyì ara ẹni tàbí ọ̀wọ̀ fún àwọn ẹlòmíràn hàn.
Nínú àpilẹ̀kọ kan lórí èrò àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ nípa àwọn olùkọ́, ìwé ìròyìn Perceptual and Motor Skills ṣàlàyé pé, “bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé olùkọ́ tó ń wọ jíǹsì ni a ń rí bí olùkọ́ tí ń mú kí orí yá nínú iyàrá ìkẹ́kọ̀ọ́, wọn kì í fi bẹ́ẹ̀ ka ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí dan-indan-in, òun ni wọ́n sì sábà máa ń tọ́ka sí bí olùkọ́ tí kò dà bí pé ó mọ nǹkan kan.” Ìwé ìròyìn náà tún sọ pé, “a sábà máa ń wo olùkọ́ obìnrin tó wọ jíǹsì bí amóríyá, ẹni tó ṣeé súnmọ́, tí kò ní ìmọ̀ ní ti gidi, tí kò sì fi bẹ́ẹ̀ lọ́wọ̀ lára, tí kò jọ olùkọ́, òun ni a sì sábà ń fẹ́ràn jù.”
Ní báyìí ná, a tún ní ọ̀rọ̀ kan fún àṣà tó lòde lágbo àwọn òṣìṣẹ́ tí a pè ní: fúnwọntán. Ní àwọn ọdún àìpẹ́ yìí, ọ̀pọ̀ obìnrin ló ń fẹ́ ká gbé àwọn sípò gíga níbi iṣẹ́. Marie, tó jẹ́ ọ̀gá ní ilé iṣẹ́ ìtẹ̀wé kan, sọ pé: “Mo ń wọṣọ láti mórí gbóná ni.” Ó fi kún un pé: “Mo fẹ́ dá yàtọ̀. Mo fẹ́ fara hàn bí ẹni tó wà pa.” Òtítọ́ ni Marie sọ pé òun ń darí gbogbo àfiyèsí sọ́dọ̀ ara òun.
Wọ́n ti kó àṣà tó lòde wọ ṣọ́ọ̀ṣì pẹ̀lú. Àwọn kan tí àṣà tó lòde ká lára pàápàá ti sọ ṣọ́ọ̀ṣì di ibi tí wọ́n ti ń fi aṣọ tí wọ́n bá ṣẹ̀ṣẹ̀ rán hàn. Síbẹ̀, lónìí, nígbà tí àwọn àlùfáà bá ró dẹ́dẹ́ nínú aṣọ oyè wọn gbàgìẹ̀-gbàgìẹ̀, wọ́n sábà máa ń rí i láti orí àga ìwàásù pé jíǹsì àti bàtà káńfáàsì tàbí aṣọ àṣà ìgbàlódé ní àwọn ọmọ ìjọ wọ̀.
Èé Ṣe Tí Ìrísí Ẹni àti Ìdánimọ̀ Fi Ń Gba Àwọn Ènìyàn Lọ́kàn Tó Bẹ́ẹ̀?
Àwọn afìṣemọ̀rònú sọ pé, ìwọṣọ ìgbàlódé—pàápàá láàárín àwọn èwe—jẹ́ apá kan àṣà ìjọra ẹni lójú, nítorí pé ó ń fi ìfẹ́-ọkàn láti pe àfiyèsí sí ara ẹni hàn. Wọ́n ṣàpèjúwe rẹ̀ bí, “èrò tí ó ti di bárakú fún àwọn aṣẹ̀ṣẹ̀bàlágà láti máa rò pé àwọn ni àwọn ẹlòmíràn ń wò.” Láìsí àní-àní, ó ń sọ pé: “Mo rò pé mo gbà ọ́ lọ́kàn bí mo ṣe rò nípa ara mi.”—American Journal of Orthopsychiatry.
Àwọn ọlọ́gbọ́n èrò orí tí wọ́n ka ènìyàn sí pàtàkì tí wọn kò sì ka Ọlọ́run sí ohunkóhun tún ti ń gbé èrò náà (tí wọ́n sábà ń gbé jáde nínú ìṣòwò) lárugẹ pé, ìwọ, gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan, ni ó ṣe pàtàkì jù lọ ní gbogbo àgbáálá ayé. Ohun tí ń bani nínú jẹ́ níbẹ̀ ni pé, àwọn ènìyàn tí ó ‘ṣe pàtàkì jù lọ’ wọ̀nyí ti ń lọ sí nǹkan bí bílíọ̀nù mẹ́fà báyìí. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ nínú ẹ̀sìn Kirisẹ́ńdọ̀mù ló ti fara wọn sábẹ́ ìkọlù ìfẹ́ ọrọ̀-àlùmọ́ọ́nì, tí wọ́n ń tiraka láti gbé “ìgbésí ayé tó dára gan-an nísinsìnyí.” (Fi wé 2 Tímótì 3:1-5.) Bákan náà, ìṣọ̀kan ìdílé àti ojúlówó ìfẹ́ ń mẹ́hẹ, kò sì yani lẹ́nu pé ọ̀pọ̀ ènìyàn, ní pàtàkì àwọn ọ̀dọ́, ń dáwọ́ lé ohunkóhun kí wọ́n ṣáà lè di ẹni tí a dá mọ̀ tí ó sì ni ìfọ̀kànbalẹ̀.
Àmọ́, àwọn tí wọ́n ń ṣàníyàn nípa bí ìmúra wọn ṣe kan ìdúró wọn níwájú Ọlọ́run sábà máa ń béèrè pé: Dé àyè wo ni mo gbọ́dọ̀ mú kí ìmúra mi bá ọ̀nà ìwọṣọ tí ń yí padà dọ́gba tó? Báwo ni mo ṣe lè mọ̀ bóyá aṣọ mi bójú mu? Ṣé ó ń dani lọ́kàn rú ni tàbí ó tilẹ̀ ń jẹ́ kí a ní èrò òdì nípa mi pàápàá?
Mo Ha Múra Lọ́nà Tó Bójú Mu Bí?
Ohun tí a wọ̀ jẹ́ ọ̀ràn ara ẹni ní pàtàkì jù lọ. Ohun tí ó wu olúkúlùkù yàtọ̀ síra, bí orísun tí owó ti ń wọlé fún wa ṣe yàtọ̀ síra. Àṣà sì yàtọ̀ láti ibì kan sí ibòmíràn, láti orílẹ̀-èdè sí orílẹ̀-èdè, àti láti ẹkùn ilẹ̀ kan sí òmíràn. Àmọ́, ipòkípò tí o lè wà, ní èrò yìí lọ́kàn pé: “Ohun gbogbo ni àkókò wà fún, àti ìgbà fún gbogbo ọ̀ràn lábẹ́ ọ̀run.” (Oníwàásù 3:1, Revised Standard Version) Kí a sọ́ lọ́nà mìíràn, múra bá àyíká ipò mu. Ní ọ̀nà kejì, “jẹ́ ẹni tí ó mẹ̀tọ́mọ̀wà ní bíbá Ọlọ́run rẹ rìn.”—Míkà 6:8.
Ìyẹn kò túmọ̀ sí pé kí o múra jákujàku, kàkà bẹ́ẹ̀, múra ní ọ̀nà tí ó “wà létòletò” tó sì ń fi “ìyèkooro èrò inú” hàn. (1 Tímótì 2:9, 10) Lọ́pọ̀ ìgbà, ó wulẹ̀ túmọ̀ sí kíkó ara ẹni níjàánu, ànímọ́ kan tí ìwé ìròyìn Working Woman so pọ̀ mọ́ ṣíṣe yíyàn tó dára àti ẹwà. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí ìrírí fi hàn pé ó dára, má ṣe jẹ́ kí aṣọ rẹ jẹ́ èyí tí àwọn ènìyàn kọ́kọ́ ń kíyè sí, tí yóò sì gba àfiyèsí àwọn ẹlòmíràn nígbà tí o bá wọnú ilé kan. Ìwé ìròyìn Working Woman sọ pé: “Múra . . . ní ọ̀nà tí àwọn ènìyàn yóò fi wò ọ́ kọjá aṣọ tí o wọ̀ tí wọn óò sì rí ọ bí ẹni tó níyì lára.”
Ìwé ìròyìn Perceptual and Motor Skills sọ pé: “Àkójọ ìtàn alákọsílẹ̀ tó ṣàgbéyẹ̀wò èrò tí aṣọ ń tẹ̀ mọ́ni lọ́kàn nípa ẹni tó wọ̀ ọ́ àti ohun tó ń sọ nípa ẹni náà láìfọhùn fi hàn pé aṣọ jẹ́ àmì pàtàkì kan tí ń mú kí a lè sọ bí àwọn ẹlòmíràn ṣe jẹ́ nígbà àkọ́kọ́.” Nítorí èyí, obìnrin kan tí ó ti lé ní ọmọ ogójì ọdún tí ó ti máa ń yọ̀ ṣìnkìn tẹ́lẹ̀ rí nípa bí ó ṣe máa ń fi ìmúra rẹ̀ fa àwọn ènìyàn mọ́ra, sọ pé: “Ó fa ìṣòro ńlá fún mi, nítorí pé kò jẹ́ kí a mọ ìyàtọ̀ láàárín ìgbà tí mo bá wà lẹ́nu iṣẹ́ àti ìgbà tí mo bá wà láyè ara mi. Àwọn ọkùnrin máa ń kàn sí mi ní gbogbo ìgbà láti gbé mi jáde lọ jẹun.” Obìnrin kan, oluṣírò owó, tó ṣàpèjúwe ọ̀nà ìṣeǹkan mìíràn tí ó yàtọ̀, sọ pé: “Mo ti máa ń wo bí àwọn ọkùnrin ṣe ń hùwà sí àwọn obìnrin tí ń múra yẹpẹrẹ, tàbí tí wọ́n ń múra bí tọkùnrin gẹ́lẹ́. Wọ́n máa ń kà wọ́n sí oníjàgídíjàgan obìnrin tí ó ṣe tán láti ṣèpalára fún ẹni tí kò ṣọ́ra, àwọn ọkùnrin sì máa ń fojú wọn rí màbo.”
Ọmọdébìnrin ọ̀dọ́ kan tí ń jẹ́ Jeffie rí i pé òun ń fún àwọn ènìyàn ní àwọn àmì kan tí ń dani lọ́kàn rú nígbà tí òun gẹ irun òun ní ọ̀nà àṣà ìgbàlódé. Ó sọ pé: “Mo kàn rò pé ó mú kí ìrísí mi ‘yàtọ̀’ ni. Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn bẹ̀rẹ̀ sí bi mí pé, ‘Ṣé ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ọ́ ní tòótọ́?’ ìyẹn sì ń dójú tì mí.” Jeffie ní láti bi ara rẹ̀ ní àwọn ìbéèrè àtọkànwá kan. Ní ti gidi, ǹjẹ́ kì í ṣe òótọ́ ni pé “lára ọ̀pọ̀ yanturu tí ń bẹ́ nínú ọkàn-àyà” ni kì í ṣe pé ẹnu wa nìkan bí kò ṣe àwọn aṣọ àti ìmúra wa pẹ̀lú ń sọ jáde? (Mátíù 12:34) Kí ni aṣọ rẹ ń fi hàn—ọkàn-àyà tí ó ní ìtẹ̀sí láti pe àfiyèsí sí Ẹlẹ́dàá ni tàbí sí ara rẹ?
Lílo “Ìyèkooro Èrò Inú” Nígbà Tí A Bá Ń Múra
Tún ṣàgbéyẹ̀wò ipa tí àwọn aṣọ rẹ ní lórí rẹ. Agbára tí ìwọṣọ láti fúnwọntán tàbí ìmúra àṣerégèé ní lè sọ ọ́ di ẹni tó ń wú fùkẹ̀, ìmúra wúruwùru lè mú èrò òdì tí o ní nípa ara rẹ pọ̀ sí i, wíwọ ṣẹ́ẹ̀tì alápá péńpé tí ń fi àwọn òṣèré tàbí àwọn eléré ìdárayá tàbí àwọn akọni mìíràn tí o nífẹ̀ẹ́ sí hàn lè sọ ọ́ di ẹni tí ń jọ́sìn àwọn akọni—ìbọ̀rìṣà sì nìyẹn. Dájúdájú, àwọn aṣọ rẹ ń bá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀—ó sì ń sọ bí o ṣe jẹ́ fún wọn.
Kí ni àwọn aṣọ rẹ ń sọ nípa rẹ bí o bá múra jù láti fi ṣe fọ́rífọ́rí tàbí tí o bá múra láti rùfẹ́ ẹni sókè? O ha ń gbé ìwà àbímọ́ni tó yẹ kí o máa làkàkà láti ṣẹ́pá lárugẹ bí? Láfikún sí i, irú ènìyàn wo ni o ń gbìyànjú láti fa ojú rẹ̀ mọ́ra? Ìmọ̀ràn tí ó wà nínú Róòmù 12:3 lè ràn wá lọ́wọ́ láti borí ìmọtara-ẹni-nìkan, ìgbéraga, àti èrò òdì. Níbẹ̀, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbà wá níyànjú “láti má ṣe ro ara [wa] ju bí ó ti yẹ ní rírò lọ; ṣùgbọ́n láti ronú kí [a] bàa lè ní èrò inú yíyèkooro.” Níní “èrò inú yíyèkooro” túmọ̀ sí jíjẹ́ olóye.
Èyí ṣe pàtàkì ní ti gidi fún àwọn tí ń bójú tó ẹrù iṣẹ́, tí a sì lè fọkàn tẹ̀. Àpẹẹrẹ wọn ní ipá lílágbára lórí àwọn ẹlòmíràn. Bí ó ṣe sábà máa ń rí, àwọn tí ń nàgà fún àǹfààní ẹrù iṣẹ́ nínú ìjọ Kristẹni àti àwọn ìyàwó wọn tó jẹ́ Kristẹni gbọ́dọ̀ fi ìwọ̀ntúnwọ̀nsì àti ọ̀wọ̀ hàn nínú ìwọṣọ àti ìmúra wọn. A kò ní fẹ́ dà bí ọkùnrin tí Jésù tọ́ka sí nínú àpèjúwe rẹ̀ nípa àsè ìgbéyàwó pé: “Nígbà tí ọba náà wọlé láti bẹ àwọn àlejò wò, ó tajú kán rí ọkùnrin kan tí kò wọ ẹ̀wù ìgbéyàwó.” Nígbà tí ó rí i pé ọkùnrin yìí kò ní ìdí tí ó ṣe gúnmọ́ láti wọ irú aṣọ tí kò bójú mu bẹ́ẹ̀, “ọba wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, ‘Ẹ dè é tọwọ́ tẹsẹ̀, kí ẹ sì jù ú síta.’”—Mátíù 22:11-13.
Nítorí èyí, ó ṣe pàtàkì fún àwọn òbí láti gbin ìṣarasíhùwà tó gbámúṣé àti ṣíṣe yíyàn tí ó dára nípa aṣọ sí ọkàn àwọn ọmọ wọn nípa ọ̀rọ̀ ẹnu àti àpẹẹrẹ àwọn fúnra wọn. Èyí lè túmọ̀ sí pé àwọn òbí yóò ṣàìgbagbẹ̀rẹ́ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan tí wọ́n bá ń jíròrò pẹ̀lú ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin wọn. Ìṣírí ńlá ló máa ń jẹ́ fún wa tí a bá ń gba ìyìn tí a kò retí nípa ọ̀pá ìdíwọ̀n gíga nínú ọ̀nà ìwọṣọ àti ìhùwà àwọn ọmọ wa àti ti àwa alára!
Dájúdájú, àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ti bọ́ lọ́wọ́ ohun asán, àṣà ìgbàlódé tó gbówó lórí, àti jíjẹ́ kí ìrísí ara ẹni gbani lọ́kàn. Wọ́n ní àwọn ìlànà àtọ̀runwá tí ń darí wọn, kì í ṣe ẹ̀mí ayé. (1 Kọ́ríńtì 2:12) Bí o bá ń gbé ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà wọ̀nyí, kò yẹ kí yíyan aṣọ rẹ jẹ́ ìṣòro. Síwájú sí i, gẹ́gẹ́ bí igi tí a fara balẹ̀ yàn láti gbé àwòrán kan dúró, aṣọ rẹ kò ní bo àkópọ̀ ìwà rẹ mọ́lẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni kò ní fi àbùkù kàn án. Àti pé bí o bá ṣe gbìyànjú láti jọ Ọlọ́run tó, ni ìwọ yóò ṣe mú ẹwà tẹ̀mí tí ó ju àkópọ̀ gbogbo aṣọ rẹ dàgbà.