Ǹjẹ́ O Máa ń sọ̀rọ̀ Nípa Ìsìn?
“Jọ̀ọ́, jẹ́ ká wá nǹkan mìíràn sọ. Ohun méjì ni n kì í bá ènìyàn sọ—ìsìn àti ìṣèlú!”
“Mo fi ọ̀ràn ìsìn sílẹ̀ fún ìyàwó àti àwọn ọmọ.”
“N kò fẹ́ sọ̀rọ̀ nípa ìsìn nísinsìnyí. Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ ti ṣọ́ọ̀ṣì dé ni.”
ǸJẸ́ o ti gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí rí? Àwọn kan kì í fẹ́ sọ̀rọ̀ nípa ìsìn nítorí wọ́n rò pé ọ̀ràn àárín àwọn àti Ọlọ́run ni. Jésù fúnra rẹ̀ sọ pé: “Nígbà tí o bá ń gbàdúrà, lọ sínú yàrá àdáni rẹ àti, lẹ́yìn títi ilẹ̀kùn rẹ, gbàdúrà sí Baba rẹ tí ń bẹ ní ìkọ̀kọ̀; nígbà náà Baba rẹ tí ń ríran ní ìkọ̀kọ̀ yóò san án padà fún ọ.”—Mátíù 6:6.
Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, Jésù àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ kò rò pé gbogbo ohun tó ní í ṣe pẹ̀lú ìsìn ló gbọ́dọ̀ jẹ́ ọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀. Fàlàlà ni wọ́n máa ń sọ̀rọ̀ nípa onírúurú ohun tẹ̀mí ní gbangba, èyí sì mú kí ohun tí wọ́n fi ń kọ́ni tàn káàkiri ayé. (Ìṣe 1:8; Kólósè 1:23) Ṣùgbọ́n kì í ṣe gbogbo ènìyàn ló ń fẹ́ láti bá wọn sọ̀rọ̀ nígbà yẹn, àwọn kan tí wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀ ń ṣiyè méjì.
Bákan náà ni lónìí, ìṣarasíhùwà olúkúlùkù ènìyàn sí sísọ̀rọ̀ nípa ìsìn yàtọ̀ síra, bẹ́ẹ̀ ló sì rí nínú àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ kan sí òmíràn. Fún àpẹẹrẹ, ní ọ̀pọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè ìhà Ìwọ̀ Oòrùn ayé, ohun tó jẹ àwọn ènìyàn lọ́kàn jù ni ọ̀ràn tí kò jẹ mọ́ ti ìsìn—ẹ̀kọ́, iṣẹ́, eré ìdárayá, kọ̀ǹpútà, tẹlifíṣọ̀n, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ní àwọn àdúgbò mìíràn, àwọn ènìyàn túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ sí sísọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tí wọ́n gbà gbọ́. Síbẹ̀, láìka irú ẹni tí àwọn ènìyàn jẹ́ látilẹ̀wá sí, àwọn ohun kan máa ń ṣẹlẹ̀ sí wọn tó máa ń sún àwọn kan tí wọ́n kì í fẹ́ sọ̀rọ̀ nípa ìsìn tẹ́lẹ̀ rí láti tún gbé àìní wọn nípa tẹ̀mí yẹ̀ wò.
Àìfún Ẹ̀sìn Lómìnira Ló Ń Kó Ìrẹ̀wẹ̀sì Bá Ọ̀pọ̀ Ènìyàn
Àwọn tí wọ́n kọ̀ láti sọ̀rọ̀ nípa ìsìn lè ti ṣẹlẹ́rìí ìjíròrò tí ó yọrí sí àríyànjiyàn líle koko tàbí kí ó ti ṣẹlẹ̀ sí wọn rí. Olùbánisọ̀rọ̀ kan tí ó gbajúmọ̀ sọ pé: “Aáwọ̀ tí àìṣe ẹ̀sìn kan náà ń fà pọ̀ ju èyí tí àìsí nínú ẹgbẹ́ òṣèlú kan náà ń fà lọ.” Bákan náà, Richard M. Johnson, igbákejì ààrẹ ilẹ̀ Amẹ́ríkà kẹsàn-án, sọ pé: “Ìtara ìsìn ló ń ru kèéta tó le jù lọ sókè lọ́kàn ẹ̀dá; tí a bá sì ṣì í lò, ó máa ń ru ẹ̀tanú bíburújáì tí a jogún sókè, pẹ̀lú ẹ̀tàn pé a ń sin Ọlọ́run.”
Ǹjẹ́ kò yà ọ́ lẹ́nu pé ẹ̀kọ́ Bíbélì tó yẹ kó gbé ipò tẹ̀mí ẹni lárugẹ, kí ó sì wúni lórí ni a ń ṣì lò láti fi gbé àìfún ẹ̀sìn lómìnira, èrò ẹlẹ́tanú, àti ìkórìíra lárugẹ? Ní ti gidi, kì í ṣe àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì wọ̀nyẹn ni kò mú kí ìsìn wu ọ̀pọ̀ ènìyàn. Kàkà bẹ́ẹ̀, sísọ wọ́n dìbàjẹ́ ni. Fún àpẹẹrẹ, gbé ọ̀ràn nípa ìsìn Kristẹni yẹ̀ wò.
Nínú ọ̀rọ̀ àti ní ìṣe, Olùdásílẹ̀ Ìsìn Kristẹni, Jésù Kristi, kò ní kí a máa hùwà àìfún ẹ̀sìn lómìnira àti ìgbawèrèmẹ́sìn bí kò ṣe kí a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àti aládùúgbò wa. Ohun tí Kristi àti àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lò nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn ni ìfèròwérò àti ìyíniléròpadà. (Mátíù 22:41-46; Ìṣe 17:2; 19:8) Wọ́n sì gbàdúrà fún àwọn ọ̀tá wọn àti àwọn tí ń ṣenúnibíni sí wọn.—Mátíù 5:44; Ìṣe 7:59, 60.
Ìsìn tòótọ́ ń mú kí èrò inú àti ọkàn-àyà yè kooro, ó sì ń mú kí àwọn ènìyàn wà ní ìṣọ̀kan. Nítorí náà, ìjíròrò tí ó sunwọ̀n nípa ìsìn lè so èso rere fún àwọn tí wọ́n ń fi tọkàntọkàn wá òtítọ́ gẹ́gẹ́ bí a ó ṣe rí i.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 3]
Ohun Tí Àwọn Olókìkí Sọ
“Bó bá jẹ́ Jésù ni ọ̀nà àtidé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ó pọndandan fún àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù láti fi tó àwọn ẹlòmíràn létí.”—Ben Johnson, ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ẹ̀kọ́ ìjíhìnrere ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìsìn ti Columbia.
“Jésù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti mú ìhìn rere náà tọ àwọn ènìyàn lọ. Àṣẹ Gíga Jù náà sọ pé kí a lọ sí gbogbo ayé. Olúwa pàṣẹ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti lọ sí àwọn òpópó àti ibi gbogbo.”—Kenneth S. Hemphill, olùdarí Ibùdó Ìlọsíwájú Ṣọ́ọ̀ṣì ti Ìjọ Onítẹ̀bọmi Ìhà Gúúsù.
“Àyàfi tí a bá jẹ́ ẹlẹ́rìí ni a fi lè jẹ́ ojúlówó Kristẹni. . . . Gbogbo Kristẹni ni a pè láti jẹ́ míṣọ́nnárì àti ẹlẹ́rìí.”—Póòpù John Paul Kejì.
“Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn oníwàásù . . . ló lọ́kàn ìfẹ́ nínú kíkó ọmọ ìjọ púpọ̀ jọ àti iṣẹ́ kíkọ́ ṣọ́ọ̀ṣì àti iṣẹ́ olùṣọ́ àgùntàn tí wọ́n fẹ́ lọ ṣe dípò lílọ́kàn ìfẹ́ sí wíwàásù ìhìn iṣẹ́ tí kì í yẹ̀, tí kò sì bára dé tí ó wà nínú Ìhìn Rere.”—Cal Thomas, òǹkọ̀wé àti akọ̀ròyìn.
“Ó yẹ kí a lọ kànkùn . . . Bíi ti Àwọn Ẹlẹ́rìí (Jèhófà) àti àwọn mìíràn, ó yẹ kí a jáde lọ, kí a lọ pòkìkí Ìhìn Rere Jésù Kristi.”—Thomas V. Daily, bíṣọ́ọ̀bù ìjọ Kátólíìkì.