Kẹ́míkà Apakòkòrò Jewéjewé Ń pa Ju Kòkòrò Lọ
LÁTI ỌWỌ́ AKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ BRAZIL
BÍ ÀGBẸ̀ kan tó ń jẹ́ Domingos dos Santos ṣe wo àwọn ẹ̀gẹ́ tó gbìn sínú oko rẹ̀ ní gúúsù Brazil, ó sọ pé: “Ó wà pa.” Ìtẹ́lọ́rùn rẹ̀ kì í ṣe lórí òfo. Àwọn ewé ohun ọ̀gbìn rẹ̀ rí bí ẹni pé kòkòrò aṣèpalára kankan kò jẹ wọ́n rí. Ṣe àṣeyọrí mìíràn tí kẹ́míkà apakòkòrò ṣe nìyẹn? Rárá o. Domingos sọ pé: “Mi ò ra oògùn apakòkòrò kankan lọ́dún tó kọjá àti lọ́dún yìí.”
Domingos wà lára ẹgbẹ́ àwọn àgbẹ̀ kan tí wọ́n máa ń lọ́ tìkọ̀ láti fi kẹ́míkà apakòkòrò jewéjewé sí ohun ọ̀gbìn wọn.a Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n máa ń ṣe é lọ́nà tí wọn kò fi ní lo kẹ́míkà rárá tàbí, ó kéré tán, kí wọ́n dín lílo kẹ́míkà kù. Mo bi Sandro Müller, àgbẹ̀ kan tó ń ṣe àwọn àyẹ̀wò kan ni oko ọ̀gbìn ńlá kan nítòsí São Paulo pe: “Báwo lẹ ṣe ń ṣe é? Èé ṣe tó tiẹ̀ fi lọ́gbọ́n nínú fún àwọn àgbẹ̀ láti bẹ̀rẹ̀ sí í jáwọ́ nínú fífín oògùn apakòkòrò káàkiri?”
Ohun Tó Rọ̀ Mọ́ Lílo Oògùn Apakòkòrò Jewéjewé
Kí ń lè fojú inú wo jàǹbá kan tó wé mọ́ lílo àwọn oògùn apakòkòrò kéékèèké, Sandro sọ pé: “Fojú inú wo ẹgbẹ́ àwọn ọlọ́pàá kan tí wọ́n ń lé àwọn olè afọ́báǹkì. Kí àwọn olè lè sá lọ, wọ́n sá wọ inú ọ́fíìsì kan tí ọwọ́ àwọn ènìyàn ti dí. Àwọn ọlọ́pàá ké sí hẹlikọ́pítà kan láti wá ju bọ́ǹbù sí ọ́fíìsì náà nítorí pé àwọn olè ti dà pọ̀ mọ́ àwọn èrò ibẹ̀. Àwọn olè nìkan kọ́ ni bọ́ǹbù máa pa, yóò tún pa àwọn aláìmọwọ́mẹsẹ̀ tí ń ṣiṣẹ́ ní ọ́fíìsì náà àti àwọn ẹ̀ṣọ́ tí ń ṣọ́ ilé náà pẹ̀lú. Irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ló máa ń ṣẹlẹ̀ nígbà ti àgbẹ̀ kan bá ń fọ́n àwọn oògùn apakòkòrò tó lágbára sára nǹkan ọ̀gbìn rẹ̀ léraléra. Wọ́n ń pa àwọn kòkòrò tí ń ṣèpalára, ìyẹn àwọn olè, àmọ́ wọ́n tún ń pa àwọn ohun tó wúlò, ìyẹn àwọn ẹ̀ṣọ́.”
Mo wá dáhùn pé: “A sáà ti dáàbò bo irúgbìn náà.” Síbẹ̀, Sandro tún ṣàlàyé pé lílo oògùn apakòkòrò jewéjewé láìníwọ̀n jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ ìpalára tí kì í kásẹ̀ nílẹ̀ bọ̀rọ̀. Báwo ló ṣe jẹ́ bẹ́ẹ̀? Àwọn kòkòrò kan máa ń yè bọ́, nítorí pé àwọn oògùn apakòkòrò jewéjewé kan wà tí kì í ràn wọ́n. Lẹ́yìn náà àwọn kòkòrò wọ̀nyí yóò wá jẹ gàba sáàárín oko tí kò ní ‘ẹ̀ṣọ́’ kankan mọ́, tàbí tí kò ní àwọn kòkòrò tó wúlò mọ́—látàrí oògùn apakòkòrò tí àgbẹ̀ náà lò.
Ọ̀pọ̀ oúnjẹ àti àìsí ọ̀tá tí yóò gbógun ti àwọn kòkòrò tó yè bọ́ náà yóò wá mú kí wọ́n tètè gbèrú sí i, èyí yóò mú kí àgbẹ̀ náà tún fín oògùn mìíràn tó ṣeé ṣe kó tún jẹ́ oògùn tó lágbára ju ti àkọ́kọ́ lọ. Ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ ni àwọn àgbẹ̀ máa ń fín oogun apakòkòrò ní àwọn àgbègbè kan tí wọ́n ti ń gbin ẹ̀wà ni Gúúsù Amẹ́ríkà. Kí wá ni àbájáde fífọjọ́ gbogbo fín oògùn apakòkòrò yìí? Àgbẹ̀ kan sọ pé: “Bí o bá gbin oògùn apakòkòrò jewéjewé, wàá ká májèlé.”
Lílo Oògùn Apakòkòrò Jewéjewé —Ṣe Aburú Tí Ń Ṣe Kò Pọ̀ Ni?
Ìwádìí fi hàn pé ẹni tó ń fín oògùn sí kòkòrò ń fún ara rẹ̀ ní májèlé jẹ. Ìwé ìròyìn Guia Rural sọ pé, ní Brazil nìkan, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin [700,000] ènìyàn ló ń fa májèlé sínú lọ́dọọdún láti inú oògùn apakòkòrò jewéjewé—ìyẹn jẹ́ ìpíndọ́gba ènìyàn kan láàárín ìṣẹ́jú àáyá márùnlélógójì! Àjọ Ìlera Àgbáyé tún ròyìn pé ọ̀kẹ́ mọ́kànlá [220,000] ènìyàn ló ń kú lọ́dọọdún jákèjádò ayé nítorí pé wọ́n fara kó oògùn apakòkòrò jewéjewé. Yàtọ̀ sí ìyẹn, oògùn apakòkòrò jewéjewé tún ń ṣe ìpalára púpọ̀ fún àyíká wa.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan lónìí gbà pé ṣíṣí agolo oògùn apakòkòrò jewéjewé dà bí ṣíṣí àpótí wàhálà ni, àwọn mìíràn sábà máa ń wò ó bí ẹni pé ó sàn kí a lo oògùn apakòkòrò jewéjewé ju kí a má lò ó lọ. Ohun tí àwọn ènìyàn rò nìyí: Yálà kí a lo oògùn apakòkòrò jewéjewé kí oúnjẹ wà tàbí kí a máà lo oògùn apakòkòrò jewéjewé kí ebi wà. Ó ṣe tán, bí àwọn ènìyàn ṣe ń pọ̀ sí i láyé ni ilẹ̀ tí a fi ń dáko ń kéré sí i. Bí a bá ní láti dá ebi dúró lágbàáyé, a ní láti dáàbò bo ohun ọ̀gbìn lọ́wọ́ àwọn kòkòrò tó lágbára láti pa wọ́n run.
Ní kedere, àwọn kòkòrò ń fa ìṣòro ńlá. Àmọ́ ṣáá o, Ọlọ́run ṣe é pe púpọ̀ sí i àwọn àgbẹ̀ káàkiri àgbáyé ti wá ń mọ̀ pé ọ̀nà mìíràn wà tó dára ju kí a máa da ọ̀pọ̀ oògùn apakòkòrò jewéjewé sára ohun ọ̀gbìn lọ. A ń pè é ní ìpawọ́pọ̀ kápa kòkòrò jewéjewé, tàbí ìlànà IPM.
Ìlànà IPM—Ọ̀nà Àbájáde Mìíràn
Mo bi Ọ̀jọ̀gbọ́n Evôneo Berti Filho, tó jẹ́ olórí Ẹ̀ka Ẹ̀kọ́ Nípa Kòkòrò ní Yunifásítì São Paulo ní Piracicaba, tó tún jẹ́ aṣáájú olùwádìí nípa kíkápá kòkòrò, pé: “Kí ni ìlànà IPM?” Ọ̀jọ̀gbọ́n Berti ṣàlàyé pé ète ìlànà IPM ni láti dín lílo oògùn apakòkòrò kù dé ìwọ̀nba tó bá pọndandan àti láti lo kìkì àwọn oògùn apakòkòrò tó ń pa àwọn kòkòrò aṣèpalára pàtó kan. Fífi àwọn ohun alààyè kápá àwọn kòkòrò àrùn ti wá borí oògùn lílò.
Ọ̀nà kan tí a ń gbà kápá kòkòrò ni yíyí irú ohun tí a ń gbìn padà lọ́dọọdún. Fún àpẹẹrẹ, àgbẹ̀ kan lè máa fi ọ̀gbìn àgbàdo àti ti ẹ̀wà ṣe àgbégbà lọ́dọọdún. Yálà kí ebi pa àwọn kòkòrò tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ àgbàdo ṣùgbọ́n tí wọ́n kórìíra ẹ̀wà kú tàbí kí wọ́n sá lọ sí ibòmíràn tí àgbàdo pọ̀ sí. Lẹ́yìn náà, tí a bá tún gbin àgbàdo, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn kòkòrò náà yóò ti lọ—bí ó tilẹ̀ jẹ́ fún ìgbà díẹ̀. Ìgbà tí àwọn kòkòrò tó nífẹ̀ẹ́ àgbàdo bá sì tún padà dé, kò ní pẹ́ tí ohun ọ̀gbìn tí a fi ṣàgbégbà yóò tún lé wọn jáde.
Fífi àwọn ohun alààyè kápá kòkòrò jẹ́ ẹ̀ka mìíràn nínú ìlànà IPM. Ìyẹn ń ṣẹlẹ̀ nígbà tí àwọn àgbẹ̀ bá ṣe àmúlò àwọn bíi kòkòrò kéékèèké, bakitéríà, fáírọ́ọ̀sì, olú, àti àwọn ohun alààyè mìíràn tí wọ́n jẹ́ ọ̀tá àwọn kòkòrò jewéjewé bí olùgbèjà. Fún àpẹẹrẹ, àwọn olùwádìí ní Brazil ṣàkíyèsí pé, nítorí àdámọ́ tí wọ́n ni, ọ̀pọ̀ mùkúlú ló kú lẹ́yìn tí fáírọ́ọ̀sì kan tí a ń pè ní baculovirus kàn wọ́n lára. Wọ́n fojú díwọ̀n rẹ̀ pé níwọ̀n ìgbà tí fáírọ́ọ̀sì náà kò ti lè pa ènìyàn lára, wọ́n lè fín nǹkan olómi tó ní àwọn fáírọ́ọ̀sì yìí nínú sára ohun ọ̀gbìn wọn, yóò sì ṣiṣẹ́ bí ohun alààyè tó jẹ́ apakòkòrò láti fi pa àwọn mùkúlú tí ń jẹ ẹ̀wà sóyà àti ẹ̀gẹ́ wọn. Ó sì ṣiṣẹ́. Àwọn mùkúlú náà kú lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀ tí wọ́n jẹ àwọn ohun ọ̀gbìn tí a fín nǹkan sí lára náà. Gẹ́gẹ́ bí àjẹmọ́nú, àwọn òkú mùkúlú náà tún jẹ́ ohun ìjà ọ̀fẹ́ fún àgbẹ̀ náà láti jagun mìíràn lọ́jọ́ iwájú. Báwo?
Ọ̀jọ̀gbọ́n Berti ṣàlàyé pé: “Àgbẹ̀ náà yóò wulẹ̀ kó òkú àwọn mùkúlú tó ti ní fáírọ́ọ̀sì lára náà sínú ẹ̀rọ ìlọǹkan, yóò lọ̀ wọ́n, yóò sì sẹ́ èyí tó lọ̀ náà, yóò wá gbé omi tó fún jáde náà sínú ẹ̀rọ̀ amúǹkantutù kan kí ó lè dì.” Lẹ́yìn náà àgbẹ̀ náà yóò gbé omi tó ní fáírọ́ọ̀sì nínú tó ti dì náà sílẹ̀ kí ó lè yọ́, yóò fi omi sí i, yóò wá fín àdàpọ̀ náà sára ohun ọ̀gbìn rẹ̀.
Olùwádìí kan sọ pé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun alààyè tí ń pa kòkòrò yìí lè máà tètè ṣiṣẹ́ bíi ti aláfijọ rẹ̀ tí a fi kẹ́míkà ṣe, síbẹ̀, ó kéré tán, ó ti ní àṣeyọrí àádọ́rùn-ún nínú ọgọ́rùn-ún.
Fífi Àwọn Ohun Alààyè Kápá Kòkòrò
Kíkó àwọn kòkòrò tó wúlò wá láti ṣiṣẹ́ bí olùgbèjà tí ń gbógun ti àwọn kòkòrò aṣèpalára tún jẹ́ ọ̀nà pàtàkì mìíràn láti fi àwọn ohun alààyè kápa àwọn kòkòrò. Síbẹ̀, láìka gbogbo ìsapá tí a ṣe láti yí àwọn àgbẹ̀ lérò padà láti máa lo ìlànà àtikápá kòkòrò yìí, ọ̀pọ̀ àwọn àgbẹ̀ ní Brazil àti ní àwọn ibòmíràn ṣì ń lọ́ tìkọ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Èé ṣe? Ó dà bí ẹni pé bí àṣà mímọ̀ọ́mọ̀ da aáyán sínú ilé ẹni kò ṣe bọ́gbọ́n mu lójú àwọn tí ń gbé inú ilé ni àṣa mímọ̀ọ́mọ̀ da kòkòrò sínú oko ẹni ko ṣe bọ́gbọ́n mu lójú àwọn àgbẹ̀. Ọ̀jọ̀gbọ́n Berti sọ fún mi pé: “Lójú ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn àgbẹ̀, gbogbo kòkòrò ló ń jẹ irè oko. Àgbẹ̀ kì í sì í fẹ́ kí wọ́n pọ̀ sí i.”
Ó ṣe kedere nígba náà pé, fífi àwọn ohun alààyè kápá kòkòrò yóò di ohun tí a tẹ́wọ́ gbà kìkì nígbà tí àwọn àgbẹ̀ bá lóye pé àwọn kòkòrò kan jẹ́ olùgbèjà fún àwọn. Fún àpẹẹrẹ, àwọn tí ń gbin èso ní California, Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, lo àwọn kòkòrò tí ń jẹ kòkòrò jewéjewé láti ṣèrànwọ́ ní òpin àwọn ọdún 1800. Ní àkókò yẹn, àwọn kòkòrò aṣèpalára tí wọ́n ṣèèsì kó wá láti Ọsirélíà bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ igi òroǹbó kíkan àti igi ọsàn wọn, ó sì ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pa wọ́n tan. Kò gba àwọn kòkòrò tí ń jẹ kòkòrò jewéjewé wọ̀nyí tó ọdún méjì láti kápá wọn, tí wọ́n sì dáàbò bo àwọn igi eléso ilẹ̀ California!
Ìlànà Tó Jẹ́ Àrà Ọ̀tọ̀ Nínú Kíkápá Kòkòrò
Lóde òní, àwọn àgbẹ̀ kan ní Brazil tún ti ń ṣàwárí ipa tí joaninha (Joanna kékeré, orúkọ kòkòrò tí ń jẹ àwọn kòkòrò jewéjewé) ń kó gẹ́gẹ́ bí ‘ẹ̀ṣọ́ aláàbò’ tó ṣeé gbára lé. Bí a ṣe ń gba àárín ìlà àwọn igi ọsàn inú oko ọ̀gbìn ńlá tí Sandro ń bójú tó ló ń sọ fún mi pé: “Joaninhas ń gbógun ti àwọn iná ara ohun ọ̀gbìn nínú oko ti a gbin ọsàn sí yìí.” Ó dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ igi ọsàn kan, ó fa ẹ̀ka kan tó ní àwọn ewé kéékèèké lára, ó sì tẹ̀ ẹ́ wálẹ̀. A rí kòkòrò tí ń mu oje igi, tàbí iná ara ohun ọ̀gbìn—èyíinì ni àwọn kòkòrò tí wọ́n ń ṣe sùẹ̀sùẹ̀ tí wọn ko tóbi ju orí abẹ́rẹ́ lọ—tí wọ́n wà lórí àwọn ewé láìmira, wọ́n ki ẹnu bọ àwọn ewé náà, wọ́n sì ń fa oje mu.
Síbẹ̀síbẹ̀, oúnjẹ ni àwọn iná wọ̀nyí jẹ́ fún ‘àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò.’ Ní ti gidi, láàárín irú àwọn kòkòrò kan tí ń jẹ àwọn kòkòrò jewéjewé, ọ̀kan ṣoṣo lára wọn lè jẹ iná ara ohun ọ̀gbìn bí ẹgbẹ̀rin ní ìwọ̀nba àkókò tó fi wà láàyè. Ṣe ìyẹn sọ ọ́ di bàbàrà ni? Sandro sọ pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, bí o bá fi koríko àti èpò tó pọ̀ tó sílẹ̀ láàárín àwọn igi náà kí àwọn kòkòrò tí ń jẹ kòkòrò jewéjewé àti àwọn ohun alààyè mìíràn tí wọ́n jẹ́ ọ̀tá lè ríbi gbé.” Sandro ṣàkíyèsí pé, látijọ́, nígbà tí wọn kò tí ì bẹ̀rẹ̀ sí lo ìlànà fífi àwọn ohun alààyè kápá kòkòrò nínú ọgbà igi eléso yìí, ọ̀sẹ̀ méjì méjì ní wọ́n máa ń fín kẹ́míkà apakòkòrò níbẹ̀. Lónìí, a dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn ohun alààyè tí wọ́n jẹ́ ọ̀tá bíi kòkòrò tí ń jẹ àwọn kòkòrò jewéjewé àti àwọn kòkòrò mìíràn, tí wọ́n ti mú kí oògùn apakòkòrò di èyí ti a ń fín lẹ́ẹ̀kan lóṣù méjì tàbí mẹ́ta.
Kòkòrò tí ń jẹ kòkòrò jewéjewé yìí nìkan ni àwọn àgbẹ̀ fọkàn tán bí olùgbèjà lára ọ̀pọ̀ ohun alààyè tí wọ́n jẹ́ ọ̀tá àwọn kòkòrò jewéjewé. Àwọn bíi oyin, agbọ́n, ẹyẹ, aláǹtakùn, àkèré, àti ọ̀pọ̀lọ́ jẹ́ díẹ̀ lára gbogbo ọ̀wọ́ tí ń ṣiṣẹ́ àṣekára láti kápá àwọn kòkòrò jewéjewé. Kódà, ẹja pàápàá ti dípò agolo oògùn apakòkòrò. Báwo?
Olùwádìí Xiao Fan ti Ẹ̀ka Iṣẹ́ Àgbẹ̀ àti Àbójútó Igbó Gẹdú ní Nanking, Ẹkùn Ìpínlẹ̀ Kiangsu, ròyìn pé, ní China, lílo oògùn apakòkòrò dín kù gan-an nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í sin ẹja nínú omi tó kún inú àwọn oko ìrẹsì. Àwọn àgbẹ̀ wá ju okùn sórí àwọn ohun ọ̀gbìn náà kí wọ́n lè fi gbọn àwọn kòkòrò jábọ́ sínú omi. Fan ṣàlàyé pé: “Ó rọrùn fún àwọn ẹja láti jẹ àwọn kòkòrò wọ̀nyí nítorí pé wọ́n máa ń díbọ́n bí ẹni pé àwọ́n ti kú nígbà tí wọ́n bá jábọ́ lára ìrẹsì náà.”
Lílo àwọn oògùn apakòkòrò níwọ̀nba kì í jẹ́ kí a pa àwọn kòkòrò tó wúlò. Àwọn kòkòrò wọ̀nyí ń dara pọ̀ mọ́ ọ̀wọ́ àwọn ẹja ajẹkòkòrò láti gbógun ti àwọn kòkòrò jewéjewé. Fan sọ pé, ọpẹ́lọpẹ́ ìlànà fífi àwọn ohun alààyè kápá kòkòrò, lílo oògùn olóró tí ń pa kòkòrò ti di nǹkan àtijọ́. Ó fi kún un pe, àwọn àǹfààní tó ní lórí ìlera àti àyíká wa ti hàn gbangba.
Lóòótọ́, nítorí ètò ọrọ̀ ajé ni àwọn àgbẹ̀ ṣe túbọ̀ ń tẹ́wọ́ gba ìlànà IPM ju nítorí àjọṣepọ̀ àwọn ohun alààyè àti àyíká wọn. Ó ṣe tán, dídín lílo àwọn oògùn apakòkòrò jewéjewé tó gbówó lórí kù ń dín ìnáwó kù, ìyẹn sì túmọ̀ sí èrè ńlá—ìmóríyá tí kò mọ sí sáà kan àti ohun tó fani mọ́ra kárí ayé lèyí. Síbẹ̀síbẹ̀, bí èrè púpọ̀ sí i lórí ọrọ̀ ajé bá dín fífín májèlé sí irè oko àti bíba àyíká jẹ́ kù, nígbà náà ìlànà IPM ti mú ọ̀pọ̀ àǹfààní wá fún àwọn àgbẹ̀ àti àwọn aláràjẹ títí kan àwọn ohun alààyè àti àyíká wọn. Gẹ́gẹ́ bí alálàyé kan ṣe sọ ọ́, “gbogbo ènìyàn ló jàǹfààní” nínú ìlànà IPM.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwọn oògùn apakòkòrò jewéjewé tí ọ̀pọ̀ sábà máa ń lò ni (1) oògùn apakòkòrò kéékèèké, (2) oògùn pagipagi, (3) oògùn tí a fi ń pa olú, àti (4) oògùn pekupeku. Orúkọ àwọn ohun tí wọ́n ń pa ni a fi pe ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 23]
OÒGÙN APAKÒKÒRÒ ÀJOGÚNBÁ
Kódà bí gbogbo àgbẹ̀ bá tilẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í lo ìlànà fífi ìmọ̀ ẹ̀rọ kápá kòkòrò jákèjádò ayé láti òní lọ, ìṣòro oògùn apakòkòrò jewéjewé kò lè yanjú láé. Àjọ Oúnjẹ àti Iṣẹ́ Àgbẹ̀ ti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè (FAO) fojú díwọ̀n rẹ̀ pé ó lé ní ọ̀kẹ́ márùn-ún [100,000] tọ́ọ̀nù àlòkù oògùn apakòkòrò tí wọ́n kó pa mọ́ sí àwọn orílẹ̀-èdè tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà. Our Planet, ìwé ìròyìn tí Ètò Àbójútó Àyíká ti Àjọ Ìparapọ̀ Orílẹ̀-Èdè ṣe jáde sọ pé: “Èyí tó gbàfiyèsí jù lọ nínú ohun tí wọ́n kó jọ ni èyí tó ṣẹ́ kù lára àwọn oògùn apakòkòrò tí wọ́n fi ta wọ́n lọ́rẹ láti mú àdéhùn ṣẹ.” Àwọn ẹrù wọ̀nyí jẹ́ oògùn DDT tó pọ̀ gan-an àti àwọn oògùn apakòkòrò mìíràn tí a wá kà sí orísun ewu tí kò wúlò báyìí. Ìwé ìròyìn Our Planet, sọ pé, bí a kò bá mú oògùn apakòkòrò tó di àjogúnbá yìí kúrò, “a gbọ́dọ̀ retí jàǹbá.”
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé pípalẹ̀ wọ́n mọ́ tónítóní jẹ́ iṣẹ́ tí ń náni lówó gọbọi. Jíjáwọ́ nínú àṣà fífín oògùn apakòkòrò ní Áfíríkà nìkan lè ná ni tó ọgọ́rùn-ún mílíọ̀nù dọ́là. Ta ni yóò ná owó náà? Àjọ FAO ń bẹ àwọn orílẹ̀-èdè tó fi wọ́n ta wá lọ́rẹ láti wá ṣèrànwọ́. Síbẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Àjọ FAO ṣe sọ, “a tún gbọ́dọ̀ wá ìrànwọ́ lọ́dọ̀ àwọn ilé iṣẹ́ tó ń ṣe kẹ́míkà apakòkòrò, tí wọ́n sábà máa ń ṣe àwọn oògùn apakòkòrò jáde láṣejù.” Àmọ́ ṣá o, títí di ìsinsìnyí, àwọn ilé iṣẹ́ wọ̀nyí ṣì ń “lọ́ tìkọ̀ láti ṣètọrẹ owó tí a ó fi palẹ̀ àwọn oògùn tí a ti kójọ tipẹ́ mọ́.”
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 24]
Àwọn Irúgbìn tí A Tún Ṣe—Èé Ṣe Tó Fi Jẹ́ Ọ̀rọ̀ Àríyànjiyàn?
Ọgbọ́n ìhùmọ̀ ìmúkan-mọ́kan tún jẹ́ ohun ìjà mìíràn tí a ń lò láti gbógun ti àwọn kòkòrò jewéjewé. Pẹ̀lú bí ìmọ̀ àwọn ènìyàn ṣe ń pọ̀ sí i nípa bí molecule ásíìdì DNA ṣe ń ṣiṣẹ́ nínú lọ́hùn-ún, ó ti ṣeé ṣe fún àwọn olùwádìí láti da èérún ásíìdì DNA àwọn onírúurú ọ̀wọ́ pọ̀ kí wọ́n sì mú irúgbìn tó ní èròjà tí ń gbógun ti àwọn kòkòrò jewéjewé dàgbà.
Àpẹẹrẹ kan ni àgbàdo. Àwọn onímọ̀ nípa yíyí apilẹ̀ àbùdá padà tàtaré apilẹ̀ àbùdá kan láti orísun mìíràn sínú ásíìdì DNA àgbàdo. Àbùdá tí a tàtaré rẹ̀ náà tún wá mú èròjà protein tí ẹ̀rí fi hàn pé ó lè ṣekúpa àwọn kòkòrò jewéjewé jáde. Ìyọrísí rẹ̀ ni àgbàdo àpilẹ̀ṣe kan tí kòkòrò tó jẹ́ ọ̀tà rẹ̀ kò lè pa lára.
Síbẹ̀síbẹ̀, àríyànjiyàn ń wà nípa àwọn ohun ọ̀gbìn tí a yí apilẹ̀ àbùdá wọn padà. Àwọn alátakò jiyàn pé wọ́n lè mú àwọn ènìyàn ṣàìsàn tàbí pé irúgbìn àpilẹ̀ṣe náà lè di èpò gbígbèrú. Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kan kìlọ̀ pé, àwọn irúgbìn tí a fi apilẹ̀ àbùdá tó ń pa àwọn kòkòrò jewéjewé sí yóò tètè sọ àwọn kòkòrò jewéjewé di èyí tí oògùn kì í ràn. Berti, tó jẹ́ onímọ̀ nípa kòkòrò kìlọ̀ pé: “A gbọ́dọ̀ dẹwọ́ ìháragàgà wa nípa yíyí apilẹ̀ àbùdá padà. Ẹ rántí bí inú àwọn ènìyàn ti dùn tó nígbà tí wọ́n ń yin oògùn apakòkòrò bí ohun àgbàyanu ní àwọn ọdún 1950? A ti wá mọ̀ pé kò rí bẹ́ẹ̀ lóde òní. Àwọn àgbàyanu oògùn apakòkòrò ti mú àwọn àgbàyanu kòkòrò jáde. Ta ló mọ ìṣòro tí àwọn àgbàyanu irúgbìn tí a yí apilẹ̀ àbùdá wọn padà lòde òní yóò fà?”
Kódà bí a bá tilẹ̀ lè yanjú gbogbo ìṣòro tó jẹ mọ́ ti àwọn ohun alààyè, àníyàn nípa ìwà rere ti mú kí àwọn ènìyàn kan ṣe kàyéfì lórí bí àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ṣe ń kọwọ́ bọ apilẹ̀ àbùdá lójú. Àwọn kan ń nímọ̀lára pé ìmọ̀ ẹ̀rọ nípa ẹ̀dá lè yanjú ìṣòro tó ti wà tipẹ́ lórí oògùn apakòkòrò ṣùgbọ́n yóò dá àwọn ìṣòro tuntun lórí ìwà rere sílẹ̀ dípò rẹ̀.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Kòkòrò kan tí ń jẹ kòkòrò jewéjewé lè jẹ ọgọ́rọ̀ọ̀rún kòkòrò jewéjewé