Ọ̀pẹ—Igi Tó Wúlò fún Ọ̀pọ̀ Nǹkan
Láti ọwọ́ akọ̀ròyìn Jí! ní Erékùṣù Solomon
GUADALCANAL—lójú ọ̀pọ̀ ènìyàn, orúkọ erékúṣù yìí ní í ṣe pẹ̀lú díẹ̀ lára àwọn ìjà tó burú jáì tí wọ́n jà nígbà Ogun Àgbáyé Kejì. Àmọ́, lónìí, ẹnikẹ́ni tó bá tún padà lọ sí pápá ogun àtijọ́ tó wà ní Erékùṣù Solomon yìí yóò rí ohun tó yàtọ̀ pátápátá—ẹgbẹ́ ọmọ ogun tí ó lọ súà, tí kì í ṣe ti sójà, bí kò ṣe ti àwọn igi ọ̀pẹ tó dúró wáwáwá.
Ọ̀pọ̀ tọ́ọ̀nù bọ́ǹbù àti àwọn ohun ìjà eléwu mìíràn tí wọ́n fi jagun kù ti fìgbà kan rí wà lábẹ́ ilẹ̀ tí a gbin ọ̀pọ̀ yanturu ọ̀pẹ dáradára sí yìí. Àmọ́, a ti kó àwọn ohun ìjà wọ̀nyí kúrò níbẹ̀ láti rí àyè gbin ọ̀pẹ sí. Báwo ni gbígbin igi yìí ṣe bẹ̀rẹ̀? Èé ṣe tí a sì fi lè sọ pé igi tó gùn tó sì rẹwà yìí wúlò fún ọ̀pọ̀ nǹkan?
Ìtàn Tó Kún Rẹ́rẹ́
Àpèjúwe àkọ́kọ́ tí ó bóde mu fún igi kan tí ó jọ ọ̀pẹ ní èyí tí Venetian Alvise Ca’da Mosto, ẹni tí ó wá etíkun ìlà oòrùn Áfíríkà rí, ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀ ní àárín ọ̀rúndún kẹẹ̀ẹ́dógún. Lẹ́yìn náà, ní ohun tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ọdún sẹ́yìn, àwọn ẹrú ilẹ̀ Áfíríkà mú èso náà dání lọ sí àwọn orílẹ̀-èdè tó wà jákèjádò Àtìláńtíìkì. Nípa bẹ́ẹ̀, epo pupa wá di èyí tí ó tayọ bí ọ̀kan lára epo tí a ń lò jù lọ lágbàáyé lónìí. Ìpíndọ́gba epo tí hẹ́kítà kan ilẹ̀ tí a fi gbin igi ọ̀pẹ ń mú jáde pọ̀ ju ti irúgbìn èyíkéyìí tí ń mú epo jáde lọ. Láfikún sí i, ọ̀pẹ jẹ́ igi tí ó máa ń wà pẹ́ títí, tí ó máa ń mú èso àti epo jáde fún ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n sí ọgbọ̀n ọdún.
Kókó pàtàkì kan nínú ìmújáde epo pupa, pàápàá ní àwọn ilẹ̀ kan ní Ìlà Oòrùn Jíjìnnà Réré, ni èyí tí a ṣàwárí rẹ̀ ní òpin àwọn ọdún 1970. Tẹ́lẹ̀ rí, èrò wa ni pé ẹ̀fúùfù nìkan ló ń mú kí igi ọ̀pẹ gbakọ láti mú irú jáde. Nítorí náà, bí èso kan kò bá dára a máa ń sọ pé ojú ọjọ́ tí kò dára ló fà á. Àmọ́, ìwádìí ẹnu àìpẹ́ yìí fi hàn pé, àfi kòkòrò nìkan ni ó lè mú kí gbígba akọ ṣeé ṣe! Nítorí èyí, títa àtaré àwọn kòkòrò tí ó lè mú kí àwọn igi náà gbakọ láti Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà sí Ìlà Oòrùn Jíjìnnà Réré ti ṣàǹfààní.
Ẹyìn orí igi ọ̀pẹ máa ń mú oríṣi epo méjì jáde. Méjèèjì ní a máa ń lò fún onírúurú àwọn ohun tí a ń ṣe jáde, tí ó ṣeé ṣe kí o lò lára wọn. Kí a tó gbé ìwọ̀nyí yẹ̀ wò, ẹ jẹ́ kí a ṣe ìbẹ̀wò sí ẹbu kan, kí a sì wo bí a ṣe ń ṣe epo.
Ṣíṣe Epo
Bí a ṣe yọ sí ẹbu náà, afinimọ̀nà wá kí wa, ó sì mú wa wọlé. Àwọn ẹ̀rọ ńláńlá ń ṣisẹ́ ní gbogbo ibẹ̀. Ó ṣàlàyé pé ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lórí ẹyìn ni gbígbé e sínú àdògán jíjinnú ńlá kan tí ń lo ooru. Odi ẹyìn kọ̀ọ̀kan ní nǹkan bí igba ẹyìn tí wọ́n gùn ní ìwọ̀n sẹ̀ǹtímítà méjì ààbọ̀ sí márùn-ún, wọ́n sì fún pọ̀ mọ́ra pẹ́kípẹ́kí. Àdògán olóoru náà yóò mú kí ẹyìn náà rọ̀, yóò sì ṣèrànwọ́ láti mú kí àwọn ẹyìn náà ṣò lára odi ẹyìn.
Ìgbésẹ̀ kejì ni láti gbọn àwọn ẹyìn náà kúrò lára odi ẹyìn nípa lílo ẹ̀rọ kan tí a fi ń gbọn ẹyìn. A ó wá kó àwọn ẹyìn tí a yọ náà sínú ẹ̀rọ ńlá kan tí a fi ń po nǹkan, ibẹ̀ ni a ó ti yọ èkùrọ́ rẹ̀ kúrò. Èèpo tí a yọ kúrò lára èkùrọ́ ni a óò wá fún nínú ẹ̀rọ ńlá tí a fi ń fún nǹkan, tàbí kí a tẹ̀ ẹ́ láti mú ògidì epo pupa jáde. Lẹ́yìn yíyọ gbogbo ìdọ̀tí rẹ̀ kúrò tí a sì sọ ọ́ di mímọ́ tónítóní, ó ti yá láti gbé epo pupa lọ tà nìyẹn.
Síbẹ̀, oríṣi epo kejì tún wà. Èyí wá láti inú èkùrọ́. A gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ pa èkùrọ́ náà láti mú ọmọ inú rẹ̀ jáde. Lẹ́yìn náà ni a óò wá fún ọmọ èkùrọ́ náà kí àdín níníyelórí lè jáde nínú rẹ̀. Epo yìí ni a ń pè ní àdín àgbọn.
Ṣákítí ọmọ inú èkùrọ́ náà ni a fi ń ṣe oúnjẹ aṣaralóore fún àwọn ohun ọ̀sìn. Bákan náà, lẹ́yìn tí a bá gbọn ẹyìn kúro tán, ṣọṣọ tí ó ṣẹ́ kù ni a óò dá padà sínú oko láti fi ṣe ìdáàbòbò ọ̀rá ilẹ̀. Àwọn ihá àti eésan ni a tún yí pọ̀ láti lò bí ògùṣọ̀ fún ẹ̀rọ ìdáná. Ọ̀nà ìgbàṣisẹ́ tó pegedé mà lèyí o!
A Fi Ń Ṣe Áísìkirimù àti Gírísì Ìpajú
Epo pupa ni ó jẹ́ epo kejì tí a ń lò jù lọ lágbàáyé lẹ́yìn epo soya. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The World Book Encyclopedia sọ pé: “Àwọn Gẹ̀ẹ́sì lo epo pupa bí oògùn àti bíi gírísì ìpawọ́ láàárín àwọn ọdún 1700.” Bí ó ti wù kí ó rí, a lè rí i nínú áísìkirimù, bọ́tà, kéèkì, àti àwọn epo tí a fi ń se oúnjẹ, àti nínú àwọn nǹkan tí a kì í jẹ irú bí ọṣẹ àti èròjà ìṣaralóge.
A tún ń fi àdín àgbọn ṣe bọ́tà, bẹ́ẹ̀ ni a fi ń ṣe ṣokoléètì àti àwọn mindinmín-ìndìn mìíràn pẹ̀lú. Síbẹ̀, ìlò àwọn epo náà kò tí ì tán. Bí iṣẹ́ ti ń tẹ̀ síwájú sí i, a ń fi àwọn èròjà inú epo pupa àti ti àdín àgbọn ṣe oògùn, ọṣẹ, ọṣẹ àbùfọ̀, àbẹ́là, àti àwọn ohun abúgbàù pàápàá!
Láìsí àní-àní, igi ọ̀pẹ gbajúmọ̀ gan-an ní Erékùṣù Solomon. Bí ìpín mẹ́tàlá lára àwọn ohun tí orílẹ̀-èdè náà ń kó ránṣẹ́ sí ilẹ̀ mìíràn ṣe ń wá láti ara igi yìí fi ipa tí igi ọ̀pẹ ń kó nínú ọrọ̀ ajé wọn hàn.
Nígbà tí a bá gbójú sókè wo igi ọ̀pẹ kan, ó ń pani lẹ́rìn-ín láti finú wòye pé ohun kan tí ń jáde lára ẹyìn yìí lè wá di áísìkirimù tí ń ṣàn sílẹ̀ láti ẹnu ọmọ kan tí ń rẹ́rìn-ín, àti pé ó lè wà ní ojú ìyá rẹ̀ fún ìṣaralóge. Dájúdájú, igi ọ̀pẹ jẹ́ igi tí ó wúlò lọ́nà púpọ̀, a sì lè máa dúpẹ́ fún ọ̀pọ̀ ohun rere tí ń ti inú igi yìí wá.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Fífọwọ́ Ṣe Tọ́ọ̀nù Méjì Lójúmọ́
Gbì . . . gbì. Gbì . . . gbì! Ìró àwọn odi ẹyìn tí ń já bọ́ ló gba ilẹ̀ kan bí àwọn òṣìṣẹ́ inú oko ńlá náà ti ń kọ ẹyìn tó wà lórí ọ̀pẹ. Báwo ni wọ́n ṣe ń dé ibi tí ẹyìn náà wà, nígbà tó jẹ́ pé orí igi náà lókè pátápátá ló wà?
Akọ́rọ́ mímú tó wà lára igi kan tó ṣeé fà gùn ni àwọn olùkórè ń lò láti gé ẹyìn lulẹ̀ lórí igi tí ó máa ń ga tó ilé alájà mẹ́rin nígbà mìíràn. Ní ìpíndọ́gba, òṣìṣẹ́ kọ̀ọ̀kan máa ń kọ odi ẹyìn bí ọgọ́rin sí ọgọ́rùn-ún lójúmọ́, tí yóò sì kó wọn lọ sí ojú ọ̀nà fún ọkọ̀ akẹ́rù láti kó. Odi ẹyìn kọ̀ọ̀kan máa ń wọ̀n tó kìlógíráàmù mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n, ẹrù kékeré kọ́ nìyẹn o! A máa ń rí tọ́ọ̀nù kan epo pupa nínú tọ́ọ̀nù mẹ́rin ààbọ̀ ẹyìn.