Ṣíṣàyẹ̀wò Ìtàn Tí Ń Bani Nínú Jẹ́ Nípa Òwò Ẹrú Látijọ́
GẸ́RẸ́ tí a bá yà kúrò ní etíkun orílẹ̀-èdè Senegal, nítòsí ìlú Dakar, ní ilẹ̀ Áfíríkà, ni a óò rí Île de Gorée. Fún ọ̀ọ́dúnrún ó lé méjìlá [312] ọdún, títí dí ọdún 1848, ni erékùṣù yìí fi wà bí ibùdó fún òwò kan tí ń gbèrú tí a ń fi ọmọ ènìyàn ṣe. Àwọn ìwé tí a rí ní ibi tí ìjọba ń kó nǹkan pa mọ́ sí ní èbúté Nantes ti ilẹ̀ Faransé fi hàn pé láàárín ọdún 1763 sí 1775 nìkan, ó ju ọ̀kẹ́ márùn-ún ó lé ẹgbẹ̀ẹ́dógún [103,000] ènìyàn tí wọ́n tà lẹ́rú láti Gorée sí èbúté Nantes.
Lónìí, ìpíndọ́gba igba ènìyàn ló ń ṣèbẹ̀wò sí Maison des Esclaves, tí ó jẹ́ Ilé Ẹrú tí a ń kóhun ìṣẹ̀ǹbáyé sí, lóòjọ́. Joseph Ndiaye, tí ó jẹ́ afinimọ̀nà mẹ́nu ba díẹ̀ lára àwọn ohun ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ tí àwọn aláìlólùrànlọ́wọ́ tí ó ko àgbákò náà fara gbá, ó ní: “Wọ́n kó àwọn baba ńlá wa lọ, wọ́n tú ìdílé wọn ká, wọ́n fi irin gbígbóná sàmì sí wọn lára bí ẹni pé ẹran ọ̀sìn ni wọ́n.” Wọ́n á kó odindi ìdílé dé nínú ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ tí a fi dè wọ́n. Afinimọ̀nà náà sọ pé: “Ìyá lè lọ sí Amẹ́ríkà, kí bàbá lọ sí Brazil, kí àwọn ọmọ sì lọ sí Antilles.”
Ndiaye ṣàlàyé pé: “Lẹ́yìn tí wọ́n bá wọ̀n wọ́n tán, wọn óò díye lé àwọn ọkùnrin ní ìbámu pẹ̀lú ọjọ́ orí àti orírun wọn, wọ́n máa ń díye tó pọ̀ lé àwọn ẹ̀yà tí ara wọn gba ìyà dáadáa tàbí tí wọ́n rí i pé wọ́n lè bímọ púpọ̀. Fún àpẹẹrẹ, àwọn Yorùbá ni wọ́n máa ń díye lé ‘bí ọ̀wọ́ ẹṣin tí a kójọ láti máa bímọ.’”
Àwọn tí kò gbéwọ̀n nínú wọn ni wọ́n máa ń bọ́ sanra bí pẹ́pẹ́yẹ ńlá kí wọ́n tó tà wọ́n fún ẹni tó bá lè sanwó tó pọ̀ jù. Àwọn olówò ẹrú máa ń yan àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin tí wọn yóò lò fún adùn ìbálòpọ̀ lóròòru. Àwọn ẹrú tó bá ya ẹhànnà ni wọ́n máa ń fokùn sí láyà dípò ọrùn tí wọn yóò sì so wọ́n rọ̀ kí wọ́n lè joró ikú fún ìgbà pípẹ́.
Póòpù John Paul Kejì ṣèbẹ̀wò sí Gorée ní ọdún 1992. Ìwé ìròyìn The New York Times ròyìn pé, “ó bẹ̀bẹ̀ nítorí òwò ẹrú, ó tọrọ àforíjì fún gbogbo àwọn tó ṣòwò ẹrú, títí kan àwọn míṣọ́nnárì Kátólíìkì tí wọ́n gbà pé kíkó àwọn ọmọ Áfíríkà lẹ́rú jẹ́ apá kan ìgbésẹ̀ tó tọ́.”
Àmọ́, kì í ṣe gbogbo ènìyàn ló ṣe tán láti jẹ́wọ́ òtítọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀ gan-an. Ní ọdún méjì ààbọ̀ sẹ́yìn, kí àwọn Nantes tó wú àwọn ìwé àkọsílẹ̀ wọn jáde, Jesuit kan tí ó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Faransé fìtẹnumọ́ sọ pé igba sí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta péré ni àwọn ẹrú tí wọ́n ń tà lọ́dún ní Gorée. Títí di ìsinsìnyí, Ọ̀gbẹ́ni Ndiaye ṣàkíyèsí pé, “ayé kò tí ì jẹ́wọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò tẹ́wọ́ gba bí ìwà ibi yìí ṣe wúwo tó.”
[Àwọn àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 30]
Gianni Dagli Orti/Corbis
Yann Arthus-Bertrand/Corbis
A mú un jáde láti inú ÌRORÒ —Ìtàn Aláwòrán Ìwà Òǹrorò [Gẹ̀ẹ́sì]