ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g99 4/8 ojú ìwé 13
  • Oríṣi Àwọn Òbí Àgbà “Tuntun”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Oríṣi Àwọn Òbí Àgbà “Tuntun”
  • Jí!—1999
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Lájọṣe Tímọ́tímọ́ Pẹ̀lú Àwọn Òbí Mi Àgbà?
    Jí!—2001
  • Èé Ṣe Tó Fi Yẹ Kí N Sún Mọ́ Àwọn Òbí Mi Àgbà?
    Jí!—2001
  • Ayọ̀ Àti Ìpèníjà Tó Wà Nínú Jíjẹ́—Òbí Àgbà
    Jí!—1999
  • Nígbà Tí Àwọn Òbí Àgbà Bá Tún ń tọ́mọ
    Jí!—1999
Àwọn Míì
Jí!—1999
g99 4/8 ojú ìwé 13

Oríṣi Àwọn Òbí Àgbà “Tuntun”

“Ẹ káàbọ̀ sí ilé Ìyá Àgbà àti Bàbá Àgbà—A Óò Bá Yín Kẹ́ Àwọn Ọmọ Yín, Ẹ Sáà Ti Dúró.” Ohun tí wọ́n kọ sí ẹnu ọ̀nà àbáwọlé Gene àti Jane nìyẹn.

ÀMỌ́, bí o bá wọlé, o ò ní rí tọkọtaya arúgbó tí wọ́n wà lórí àga ìrọ̀gbọ̀kú. Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn tọkọtaya olókunlára, tí wọn kò dàgbà, tí ọjọ́ orí wọn wà láàárín ogójì sí àádọ́ta ọdún lo máa rí níbẹ̀. Níwọ̀n bí Gene àti Jane kò ti sá fún kíkó ipa wọn bí ‘àgbà ìlú,’ wọ́n fi ìdùnnú tẹ́wọ́ gba ipò jíjẹ́ òbí àgbà. Gene sọ pé: “Lóòótọ́, ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn àmì kéékèèké tí ń fi hàn pé àgbà ti ń kàn ọ́. Àmọ́, èyí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn èrè tí o ń gbà nídìí títọ́ àwọn ọmọ rẹ—níní àwọn ọmọ-ọmọ.”

Òwe àtijọ́ kan sọ pé: “Adé arúgbó ni àwọn ọmọ-ọmọ.” (Òwe 17:6) Àwọn òbí àgbà àti àwọn ọmọ-ọmọ sábà máa ń gbádùn ìdè ìfẹ́ àti ìsúnmọ́ra pàtàkì. Gẹ́gẹ́ bí ìwé àtìgbàdégbà Generations ṣe sọ, “lọ́nà tí irú rẹ̀ kò ṣẹlẹ̀ rí, àwọn tí iye wọ́n pọ̀ jù lọ láwùjọ Amẹ́ríkà ló jẹ́ òbí àgbà.” Kí ló fà á? Àpilẹ̀kọ náà ṣàlàyé pé: “Wọ́n ń pẹ́ láyé sí i àti pé àwọn ohun tuntun-tuntun ń ṣẹlẹ̀ nínú agbo ìdílé. Ìyípadà nínú iye àwọn tí ń kú àti àwọn tí a ń bí fi hàn pé ìdá mẹ́ta nínú mẹ́rin lára àwọn àgbàlagbà tí a fojú bù ni yóò di òbí àgbà . . . Èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn tí ọjọ́ orí wọ́n wà láàárín ogójì sí ọgọ́ta ọdún ló ń di òbí àgbà nígbà tí wọ́n wà ní nǹkan bí ọdún márùndínláàádọ́ta.”

Oríṣi àwọn òbí àgbà tuntun kan ti wà ní àwọn orílẹ̀-èdè kan. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ ló ń rí i pé àwọn túbọ̀ ń korí bọ iṣẹ́ títọ́ àwọn ọmọ-ọmọ wọn. Fún àpẹẹrẹ, ọmọ Gene àti Jane àti ìyàwó rẹ̀ tẹ́lẹ̀ rí ti kọ ara wọn sílẹ̀, wọ́n sì ń pín ọmọ wọn tọ́. Jane ṣàlàyé pé: “A ń gbìyànjú láti ṣèrànwọ́ nípa bíbójútó ọmọ-ọmọ wa nígbà tí ọmọ wa ń ṣiṣẹ́.” Gẹ́gẹ́ bí ohun tí ìwádìí kan fi hàn, àwọn òbí àgbà tí ń bójú tó àwọn ọmọ-ọmọ wọn ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà ń fi nǹkan bí ìpíndọ́gba wákàtí mẹ́rìnlá ṣe bẹ́ẹ̀ lọ́sẹ̀. Èyí tó iṣẹ́ bílíọ̀nù dọ́là mọ́kàndínlọ́gbọ̀n lọ́dún kan!

Àwọn ohun wo ló ń fún àwọn òbí àgbà láyọ̀ lóde òní? Àwọn ìpèníjà wo ni wọ́n dojú kọ? Àpilẹ̀kọ tó kàn gbé àwọn ìbéèrè wọ̀nyí yẹ̀ wò.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́