Mo Dúpẹ́ Lọ́wọ́ Jèhófà Nítorí Àwọn Ọmọkùnrin Mi Márààrún
BÍ HELEN SAULSBERY ṢE SỌ Ọ́
Ọjọ́ kejì nínú oṣù March, ọdún 1997, jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọjọ́ tí ń bà mí nínú jẹ́ jù lọ nínú ìgbésí ayé mi. Nǹkan bí ẹgbẹ̀ta ọ̀rẹ́ àti ẹbí kóra jọ ní Wilmington, Delaware, Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, fún ìsìnkú Dean, ọkọ mi ọ̀wọ́n. Kristẹni alàgbà ló jẹ́ kó tó kú, òun sì ni alábòójútó olùṣalága ní ọ̀kan lára ìjọ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Bí mo ti ń ronú nípa ogójì ọdún tí a fi jọ wà láyọ̀ bíi tọkọtaya, mo nídìí púpọ̀ láti ṣọpẹ́. Mo mọ̀ pé Dean wà láìséwu níbi tó láàbò jù lọ, nínú ìrántí Jèhófà, Ọlọ́run Olódùmarè, àti pé a óò rí Dean lọ́jọ́ iwájú.
DEAN wọ ẹgbẹ́ ọmọ ogun òfuurufú lẹ́yìn tó kẹ́kọ̀ọ́ jáde ní ilé ẹ̀kọ́ gíga ní ọdún 1950. Kì í ṣe ẹni tó lẹ́mìí ìsìn, ó sì jọ pé kò fara mọ́ àwọn ẹ̀kọ́ ìsìn Ìjọ Kátólíìkì tí mo yàn láàyò nígbà yẹn. Ṣùgbọ́n a fohùn ṣọ̀kan láti fi ẹ̀kọ́ ìsìn Kátólíìkì kọ́ àwọn ọmọ wa. A máa ń kúnlẹ̀ gbàdúrà ìdákẹ́jẹ́ẹ́ lálaalẹ́. Mo máa ń ṣe àwítúnwí àwọn àdúrà tí ìsìn Kátólíìkì fi kọ́ mi, Dean yóò sì gba ohun yòówù tó wà lọ́kàn rẹ̀ ládùúrà. Ní àwọn ọdún mélòó kan lẹ́yìn náà, a bí àwọn ọmọkùnrin wa márùn-ún: Bill, Jim, Dean Kékeré, Joe, àti Charlie.
Mo máa ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì déédéé, mo sì máa ń mú àwọn ọmọkùnrin náà dání nígbà gbogbo. Àmọ́, ṣọ́ọ̀ṣì wá já mi kulẹ̀, ní pàtàkì nítorí ipa tó kó nínú Ogun Vietnam. Spellman, kádínà ìgbà yẹn tó ti di olóògbé báyìí, sọ fún àwọn ènìyàn tí ó ṣeé ṣe kí wọ́n gbé ìbéèrè dìde sí ìdí tí Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà fi gbé ìgbésẹ̀ tó gbé pé: “Ẹ̀yìn orílẹ̀-èdè mi ni mo wà, yálà ó ṣe ohun tó tọ́ tàbí èyí tí kò tọ́.” N kò lè fọwọ́ sí i pé kí àwọn ọmọ mi lọ jagun, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ṣọ́ọ̀ṣì mi lọ́wọ́ nínú rẹ̀. Síbẹ̀, mo máa ń gbàdúrà pé ó kéré tán, kí ọ̀kan lára wọn di àlùfáà àti pé kí ọkọ mi di Kátólíìkì.
Èrò Yí Padà
Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ Saturday kan, mo ń ṣe fàájì pẹ̀lú díẹ̀ lára àwọn ọmọ ìjọ Kátólíìkì àti àlùfáà kan ládùúgbò. Bí a ti ń mu nǹkan, tí a sì ń ṣe fàájì ni ọ̀kan lára àwọn obìnrin bi àlùfáà náà léèrè pé: “Fadá, ǹjẹ́ òtítọ́ ni pé bí ẹnì kan bá ṣe àríyá irú èyí tí a ń ṣe yìí tán ṣùgbọ́n tí kò lè dìde lówùúrọ̀ ọjọ́ kejì láti lọ fún ìsìn Máàsì ó ti dẹ́ṣẹ̀ tí ó lè fa ìparun?”
Ó fèsì pé: “Rárá, rárá. Kò sí ìṣòro. Ní alẹ́ ọjọ́ Tuesday a máa ń ṣe ìsìn Máàsì ní ilé àlùfáà. Nípa bẹ́ẹ̀, ẹni náà lè wá fún ìsìn Máàsì, kí ó sì ṣe ojúṣe rẹ̀.”
Wọ́n ti kọ́ mi láti kékeré pé ohun yòówù kó ṣẹlẹ̀, o gbọ́dọ̀ lọ fún ìsìn Máàsì ní ọjọ́ Sunday. Nígbà tí n kò gbà pẹ̀lú rẹ̀, ó gégùn-ún, ó sì fìbínú sọ pé obìnrin kò gbọ́dọ̀ tọ́ àlùfáà sọ́nà.
Mo rò nínú mi pé, ‘Ṣe ohun tí mo ti ń gbàdúrà pé kí ọmọ mi dà nìyí?’ Bí mo tilẹ̀ mọ̀ pé kì í ṣe bí gbogbo àwọn àlùfáà ṣe rí nìyẹn, ó yà mi lẹ́nu gan-an.
Láàárín àwọn ọdún 1960, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá sọ́dọ̀ wa ní Philadelphia, Pennsylvania, àti lẹ́yìn náà, ní Newark, Delaware. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo nífẹ̀ẹ́ sí ìtara tí wọ́n ní nínú ìsìn Kristẹni, mo sábà máa ń sọ pé: “Ẹ jọ̀wọ́. N kò nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ yín nítorí pé onísìn Kátólíìkì ni mí.”
Àmọ́, ní òwúrọ̀ ọjọ́ olótùútù kan ní November 1970, Àwọn Ẹlẹ́rìí náà tún padà wá. Wọ́n béèrè ìbéèrè kan nípa Bíbélì, wọ́n sì ka Sáàmù 119:105 pé: “Ọ̀rọ̀ rẹ jẹ́ fìtílà fún ẹsẹ̀ mi, àti ìmọ́lẹ̀ sí òpópónà mi.” Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn wọ̀ mí lọ́kàn. Mo rántí pé mo rò nínú ara mi pé, ‘Bíbélì! Bóyá ìdáhùn náà nìyẹn, àmọ́ n kò tilẹ̀ ní ọ̀kan.’ Wọ́n ti kọ́ mi pé àwọn Kátólíìkì kò nílò Bíbélì, pé yóò rú wa lójú, àti pé àwọn àlùfáà nìkan ni Bíbélì wà fún láti kà kí wọ́n sì ṣàlàyé rẹ̀. Mo rò pé mẹ́ńbà ìsìn Kátólíìkì tó jẹ́ olùṣòtítọ́ ni mí nítorí mi ò ní Bíbélì.
Mo gba ìwé tí ń ranni lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà, Otitọ ti Nsinni Lọ si Iye Aiyeraiye, lọ́wọ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí lọ́jọ́ yẹn. Mo kà á lọ́sẹ̀ yẹn, mo sì mọ̀ pé mo ti rí òtítọ́! Àwọn Ẹlẹ́rìí mú Bíbélì méjì wá nígbà tí wọ́n padà wá, ọ̀kan lára rẹ̀ jẹ́ ìtumọ̀ ti Kátólíìkì. Ó yà mí lẹ́nu láti rí i pé àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí a lò nínú ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yẹn wà nínú Bíbélì ti Kátólíìkì náà. Bí wọ́n ṣe bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé pẹ̀lú mi ní pẹrẹwu nìyẹn, mo sì ṣèrìbọmi ní August 1972, èmi àti ẹ̀gbọ́n mi obìnrin Sally, tí òun pẹ̀lú ti bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
Dean, ọkọ mi kò ta kò mí rí, àmọ́ ó yà á lẹ́nu láti rí i pé mo lọ́kàn ìfẹ́ sí ìsìn tó yàtọ̀ sí ìsìn Kátólíìkì. Ìgbà gbogbo ló máa ń fetí sílẹ̀ tó sì máa ń wòye ohun tí ń lọ. Tẹ́lẹ̀ rí, ó jọ pé ariwo ni mo máa ń pa lé àwọn ọmọkùnrin wa kí wọ́n tó lè fetí sílẹ̀. Ṣùgbọ́n mo wá mọ̀ pé Bíbélì kìlọ̀ nípa “ìrunú àti ìlọgun àti ọ̀rọ̀ èébú.” (Éfésù 4:31, 32) Àti pé, a kì í fi ogun lílọ̀ tọ́ ọmọ. Nígbà kan, mo gbọ́ tí ọkọ mi sọ fún ìyá rẹ̀ nípa Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé: “Mọ́mì, àwọn ènìyàn yẹn ń fi ohun tí wọ́n ń kọ́ni ṣèwà hù!” Kò pẹ́ lẹ́yìn náà, ó fàyè sílẹ̀ fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Dean di Ẹlẹ́rìí tí ó ṣèrìbọmi ní January 1975.
Títọ́ Àwọn Ọmọkùnrin Wa Márààrún
Nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba, mo ronú pé àkókò tí a ń lò ní àwọn ìpàdé yẹn ti gùn jù fún àwọn ọmọ mi. Nítorí náà, mo máa ń jẹ́ kí wọ́n dúró ti bàbá wọn. Ó rọrùn, ó sì tù mí lára bí mo ṣe ń dá lọ. Àmọ́, nígbà tí olùbánisọ̀rọ̀ kan ní ìpàdé ń sọ̀rọ̀ nípa àkókò tí a fi ń ṣe àwọn ìpàdé Kristẹni, ó béèrè pé: “Ǹjẹ́ o ti ronú rí nípa iye àkókò tí àwọn ọmọ rẹ lè fi jókòó ti tẹlifíṣọ̀n?” Ibi tí àwọn ọmọ mi wà ní àkókò yẹn gan-an nìyẹn! Nítorí náà, mo ronú pé, ‘Ìyẹn kò ní ṣẹlẹ̀ mọ́! A ó jọ máa wá ni!’ Ọkọ mi gbà láti jẹ́ kí àwọn ọmọ wa máa tẹ̀ lé mi lọ, bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́, òun pẹ̀lú bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí ìpàdé.
Lílọ sí ìpàdé déédéé mú kí ìgbésí ayé ìdílé wa tò kí ó sì fẹsẹ̀ múlẹ̀. Ṣùgbọ́n kò tán síbẹ̀. Èmi àti Dean sábà máa ń gbìyànjú láti túbọ̀ ṣe ojúṣe wa dáadáa sí i gẹ́gẹ́ bí òbí, a máa ń gbà tí a bá ṣàṣìṣe, a sì ń fi àwọn ìtọ́sọ́nà Bíbélì sílò pẹ̀lú ìṣọ́ra. A kò gba ọ̀pá ìdiwọ̀n oríṣi méjì láyè. Ohun tó tọ̀nà fún èmi àti ọkọ mi ló tọ̀nà fún àwọn ọmọ wa. Àìgbọdọ̀máṣe ni ìgbòkègbodò ìwàásù ìtagbangba déédéé jẹ́ fún wa.
Tó bá di ọ̀ràn tí ohun àṣenajú, a kì í gba àwọn sinimá oníwà-ipá, oníwà pálapàla láyè. A sábà máa ń gbádùn ìgbòkègbodò ìdílé tó gbámúṣé pa pọ̀, títí kan eré yíyọ̀ lórí yìnyín, yíyí bọ́ọ̀lù lórí ilẹ̀, gbígbá bọ́ọ̀lù àfọ̀págbá, lílọ sí ọgbà ìṣiré, jíjáde fàájì, àti jíjẹ pizza ní alaalẹ́ Friday. Dean sì ni olórí ìdílé wa ọ̀wọ́n. Ní gbogbo àkókò tí a wà pọ̀ bíi tọkọtaya, a mọ̀ pé bí ó ṣe yẹ kí nǹkan rí nìyẹn.—Éfésù 5:22, 23.
Billy jẹ́ ọmọ ọdún méjìlá, Jimmy jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kànlá, Dean Kékeré jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́sàn-án, Joe jẹ́ ọmọ ọdún méje, Charlie sì jẹ́ ọmọ ọdún méjì nígbà tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí bá mi ṣèkẹ́kọ̀ọ́ ní ọdún 1970. Ó ti mọ́ wọn lára láti máa lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì, ṣùgbọ́n nígbà yẹn wọ́n ti wá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó ń dùn mọ́ wa nínú gan-an. Mo máa ń sọ fun wọn pé: “Ẹ wò ó! Ẹ wá wo kinní yìí! Ẹ wá wò ó!” Wọn yóò wá, a óò sì jíròrò ohun kan tó jẹ́ tuntun sí wa pẹ̀lú ìdùnnú. Nípasẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ wa nínú ìwé ìtọ́kasí tó lágbára jù lọ ni ilẹ̀ ayé, Bíbélì, àwọn ọmọ wa ń kẹ́kọ̀ọ́ láti nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, kí wọ́n sì lè mú ẹrù iṣẹ́ wọn ṣe níwájú rẹ̀ bí Ọlọ́run àti Ẹlẹ́dàá wọn—kì í ṣe sí bàbá àti ìyá wọn nìkan.
Kí a tó kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ Bíbélì, a ti jẹ gbèsè tó pọ̀ gan-an. Láti lè san díẹ̀ lára gbèsè wa, a ta ilé wa, a sì háyà ilé kan. A tún ta ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ wa tuntun, a sì ra àlòkù kan. A gbìyànjú láti mú ìgbésí ayé wa rọrùn bí a ṣe lè ṣe tó. Èyí mú kí n lè máa wà nílé pẹ̀lú àwọn ọmọ wa dípò kí n máa ṣiṣẹ́ níta. A lérò pé àwọn ọmọ wa nílò ìyá wọn nílé. Èyí tún mú kí n lè lo àkókò púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni nígbà tí àwọn ọmọ wa bá lọ sí ilé ẹ̀kọ́. Àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, ní September 1983, mo di aṣáájú ọ̀nà (òjíṣẹ́ alákòókò kíkún). Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọ wa kì í fìgbà gbogbo ní àwọn ohun tó dára jù lọ nípa ti ara, wọn kò ronú pé a ń fi nǹkan du àwọn láìyẹ. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn lọ sí ilé ẹ̀kọ́ gíga ti ẹ̀kọ́ṣẹ́ ọwọ́, wọ́n sì kọ́ àwọn iṣẹ́ bí ìtọ́jú ewéko, gbẹ́nàgbẹ́nà, mẹkáníìkì, àti títẹ iṣẹ́ ọnà sórí ìwé. Nítorí náà, wọ́n ti gbára dì láti gbọ́ bùkátà ara wọn.
Lọ́pọ̀ ìgbà, mo máa ń ronú nípa ìgbésí ayé ìdílé wa, n ó sì sọ sínú pé, ‘Mo róye pé a jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìdílé tó láyọ̀ jù lọ lórí ilẹ̀ ayé yìí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò ní ọrọ̀ púpọ̀.’ Láìpẹ́, Dean bẹ̀rẹ̀ sí nàgà fún àǹfààní ẹrù iṣẹ́ nínú ìjọ, àwọn ọmọ wa náà sì ṣe bẹ́ẹ̀. Ní 1982, wọ́n yan Dean sípò gẹ́gẹ́ bí alàgbà Kristẹni. Ọdún mẹ́jọ lẹ́yìn náà, ní 1990, Bill, ọmọkùnrin wa tó dàgbà jù, di alàgbà. Lẹ́yìn náà, Joe di alàgbà ní ọdún yẹn kan náà, Dean Kékeré di alàgbà ní 1991, Charlie di alàgbà ní 1992, Jim sì di alàgbà ní 1993.
Mo mọ̀ pé a ṣe àwọn àṣìṣe kan bí òbí, kì í sì í rọrùn láti rántí àwọn ohun tí a ṣe dáradára nígbà gbogbo. Ọ̀rẹ́ kan bi àwọn ọmọ mi léèrè ohun tí wọ́n rántí nípa ìgbà tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ di Kristẹni àti ní pàtàkì àwọn ìlànà Bíbélì tí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ nígbà tí wọ́n ṣì kéré tí ó ràn wọ́n lọ́wọ́ láti nàgà di ẹni tí ó tóótun láti di alàgbà Kristẹni. Ohun tí wọ́n sọ dùn mọ́ mi nínú.
Ohun Tí Àwọn Ọmọ Mi Sọ
Bill: “Ohun tí a kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ nínú Róòmù 12:9-12 wọ̀ mí lọ́kàn gan-an. Ó kà lápá kan pé: ‘Nínú ìfẹ́ ará, ẹ ní ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì. Nínú bíbu ọlá fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, ẹ mú ipò iwájú. . . . Kí iná ẹ̀mí máa jó nínú yín. . . . Ẹ máa yọ̀ nínú ìrètí.’ Àwọn òbí mi ní agbára láti fi ohun tí ó túmọ̀ sí láti nífẹ̀ẹ́ àwọn ènìyàn hàn. Ẹnì kan lè rí i pé fífìfẹ́hàn sí àwọn ẹlòmíràn ń mú kí wọ́n láyọ̀. Ipò onífẹ̀ẹ́ tó wà nínú ìdílé wa yìí ló mú kí àwọn òtítọ́ Bíbélì di apá kan ọ̀nà ìrònú wa. Òun ló mú wa dúró nínú òtítọ́. Àwọn òbí mi nífẹ̀ẹ́ sí òtítọ́ Bíbélì lójú méjèèjì. Ní àbájáde rẹ̀, kò ṣòro fún mi rí láti nífẹ̀ẹ́ òtítọ́, kò sì ṣòro fún mi rí láti rọ̀ mọ́ ọn.”
Jim: “Ọ̀kan lára àwọn ìlànà pàtàkì jù lọ tó wá sọ́kàn mi ni Mátíù 5:37 tó wí pé: ‘Kí ọ̀rọ̀ yín Bẹ́ẹ̀ ni sáà túmọ̀ sí Bẹ́ẹ̀ ni, Bẹ́ẹ̀ kọ́ yín, Bẹ́ẹ̀ kọ́; nítorí ohun tí ó bá ju ìwọ̀nyí lọ wá láti ọ̀dọ̀ ẹni burúkú náà.’ Èmi àti ẹ̀gbọ́n àti àwọn àbúrò máa ń mọ ohun tí àwọn òbí mi retí lọ́dọ̀ wa, a sì rí àpẹẹrẹ ohun tó yẹ kí àwọn Kristẹni jẹ́ lára wọn. Àwọn méjèèjì sábà máa ń wà níṣọ̀kan. Wọn kì í jiyàn. Bó bá tilẹ̀ ṣẹlẹ̀ pé wọn kò fohùn ṣọ̀kan lórí ohun kan, kò bọ́ sétígbọ̀ọ́ àwa ọmọ wọn rí. Wọ́n wà ní ìṣọ̀kan, ìyẹn sì wọ gbogbo wa lọ́kàn gan-an. A kò fẹ́ já Mọ́mì àti Dádì kulẹ̀, pàápàá jù lọ, Jèhófà.”
Dean: “Òwe 15:1 sọ pé: ‘Ìdáhùn kan, nígbà tí ó bá jẹ́ lọ́nà pẹ̀lẹ́, máa ń yí ìhónú padà, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ tí ń fa ìrora máa ń ru ìbínú sókè.’ Onínú tútù ni Dádì wa. N kò rántí pé mo bá a jiyàn rí—kódà nígbà tí mo jẹ́ ọ̀dọ́langba. Ó sábà máa ń hùwà pẹ̀lẹ́, kódà nígbà tó bá ń bínú. Nígbà mìíràn, ó máa ń lé mi lọ sínú iyàrá mi tàbí kí o fawọ́ àwọn àǹfààní kan sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ mi, ṣùgbọ́n a kò ja ara wa níyàn rí. Ọ̀rọ̀ pé ó jẹ́ bàbá wa nìkan kọ́. Ọ̀rẹ́ wa ló jẹ́ pẹ̀lú, a kò sì fẹ́ já a kulẹ̀.”
Joe: “Ní 2 Kọ́ríńtì 10:5, Bíbélì sọ nípa ‘mímú gbogbo ìrònú wá sí oko òǹdè láti mú un ṣègbọràn sí Kristi.’ Nínú ìdílé wa, wọ́n kọ́ wa láti jẹ́ onígbọràn sí àwọn ọ̀pá ìdiwọ̀n àti ìtọ́ni Jèhófà. Òtítọ́ ló gba gbogbo ìgbésí ayé wa. Lílọ sí ìpàdé jẹ́ ọ̀nà ìgbésí ayé wa. Èrò pé kí a máa ṣe ohunkóhun mìíràn ní ọjọ́ ìpàdé ṣì ṣàjèjì sí mi. Iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni pẹ̀lú jẹ́ apá kan ìgbésí ayé wa déédéé—kì í ṣe ọ̀ràn pé bóyá a fẹ́ ẹ. Gbọ̀ngàn Ìjọba ni a ti yan àwọn ọ̀rẹ́ wa. Kò sí ìdí láti tún máa wá ọ̀rẹ́ lọ sí ibòmíràn. Kí tún ni bàbá lè ṣe fún àwọn ọmọ rẹ̀ ju kí ó fi ojú wọn mọ ọ̀nà ìyè!”
Charlie: “Òwe 1:7 ń wà lọ́kàn mi nígbà gbogbo. Ó kà pé: ‘Ìbẹ̀rù Jèhófà ni ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìmọ̀. Ọgbọ́n àti ìbáwí ni àwọn òmùgọ̀ lásán-làsàn ti tẹ́ńbẹ́lú.’ Àwọn òbí mi ràn wá lọ́wọ́ láti rí i pé Jèhófà jẹ́ ẹni gidi àti láti lóye ìdí tó fi ṣe pàtàkì láti bẹ̀rù rẹ̀, kí a sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Wọ́n máa ń fèròwérò pẹ̀lú wa, wọn ó sọ pé: ‘Ẹ máà máa ṣe nǹkan kìkì nítorí pé a ní kí ẹ ṣe é. Kí ni èrò yín nípa rẹ̀? Báwo lẹ ṣe rò pé yóò rí lára Jèhófà tí ó bá rí èyí? Báwo lẹ ṣe rò pé yóò rí lára Sátánì?’
“Ìyẹn yóò jẹ́ ká rí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ gan-an. Dádì àti Mọ́mì kò lè máa wà pẹ̀lú wa ní gbogbo ìgbà. Ìwọ̀nba tí wọ́n bá lè ṣe ni wọ́n máa ṣe láti gbin òtítọ́ Bíbélì sí wa lọ́kàn. Ara wa ló kù wá kù ní ilé ẹ̀kọ́ ni, níbi iṣẹ́, àti pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ wa. Ìbẹ̀rù Jèhófà gbígbámúṣé yẹn mú kí a yàtọ̀ gan-an—bẹ́ẹ̀ ló sì ṣe wà lára wa lónìí.
“Bákan náà, gbogbo ìgbà ni Mọ́mì máa ń sọ nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà rẹ̀ àti àwọn ìrírí dídára tí ó ń ní. Gbogbo ìgbà ló máa ń ní ẹ̀mí títọ̀nà nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà, ìyẹn sì ní ipa àgbàyanu lórí wa. A ní ìfẹ́ àwọn ènìyàn bíi tirẹ̀, a sì wá mọrírì rẹ̀ pé a lè gbádùn iṣẹ́ ilé dé ilé náà gan-an.”
Ìdí Tí A Fi Ní Láti Kún fún Ìmoore
Àwọn ọmọ mi ti gbéyàwó báyìí, ìyàwó àwọn ọmọ mi márààrún sì lẹ́wà gidigidi, gbogbo wọn ń sin Jèhófà pẹ̀lú ìṣòtítọ́. A tún ti bù kún mi pẹ̀lú ọmọkùnrin márùn-ún mìíràn—bẹ́ẹ̀ ni, ọmọkùnrin márùn-ún tí àwọn ọmọ mi bí! Wọ́n ń tọ́ gbogbo wọn láti nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àti láti fi Ìjọba rẹ̀ sí ipò kìíní nínú ìgbésí ayé wọn. A gbàdúrà pé lọ́jọ́ kan àwọn náà yóò di alàgbà, bíi ti àwọn bàbá wọn àti bàbá wọn àgbà kó tó kú.
Láìpẹ́ lẹ́yìn tí Dean kú, ọ̀kan lára àwọn ọmọ mi kọ̀wé pé: “Aáyun bàbá mi yóò yun mí gan-an, nítorí pé ó ti sùn nísinsìnyí. Kò sí ìrora mọ́. Kò sí ìjìyà mọ́. Kò sí iṣẹ́ abẹ mọ́, kò sí abẹ́rẹ́ àti àwọn rọ́bà tí a fi ń fa oúnjẹ olómi síni lára mọ́—oorun ire ni ṣáá. N kò lè kí i pé ó dìgbóṣe kó tó kú. Nǹkan kì í sábà rí bí a ti wéwèé rẹ̀ ṣá. Mo wulẹ̀ lè sọ pé mo ti pinnu láti lo ìgbésí ayé mi kí n baà lè wà níbẹ̀ láti kí i káàbọ̀!”
Mo mà dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún ọkọ onífẹ̀ẹ́ tí mo ní àti ìrètí àjíǹde náà tó dájú o! (Jòhánù 5:28, 29) Mo sì dúpẹ́ lọ́wọ́ Rẹ̀ gan-an lórí àwọn ọmọkùnrin mi márààrùn!
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]
Helen Saulsbery àti ìdílé rẹ̀ lónìí